ORIN 127
Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà, kí ni mo lè fi san oore
Tó o ṣe ní ayé mi, tó o dá ẹ̀mí mi sí?
Mo fọ̀rọ̀ rẹ yẹ ọkàn mi wò bíi dígí.
Jọ̀ọ́, jẹ́ n lè mọrú ẹni tí mo jẹ́ dáadáa.
(ÀSOPỌ̀)
Mo ti pinnu pé màá fayé mi sìn ọ́.
Kì í ṣe pé wọ́n fipá mú mi láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Tọkàntọkàn ni mo yàn láti sìn ọ́.
Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n lè máa mú inú rẹ dùn.
Ràn mí lọ́wọ́ kí n lè yẹ ara mi wò,
Kí n sì lè mọ irú ẹni tó o fẹ́ kí n jẹ́.
Ìwọ máa ń ṣìkẹ́ àwọn adúróṣinṣin.
Jẹ́ kí n wà lára àwọn tó ń mọ́kàn rẹ yọ̀.
(Tún wo Sm. 18:25; 116:12; Òwe 11:20.)