-
Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú ẸJí!—2014 | May
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú Ẹ
TÓ O bá mọ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Diana,a wàá rí i pé ó jáfáfá, ó lọ́yàyà, ó sì kóni mọ́ra. Àmọ́ bí ọ̀dọ́bìnrin yìí ṣe dára tó yìí, ìbànújẹ́ tó ń bá a fínra kọjá àfẹnusọ. Tí nǹkan ọ̀hún bá dé sí i báyìí, ńṣe ló máa ń rí ara rẹ̀ bí ẹni tí kò wúlò fún nǹkan kan, ó sì lè máa ṣe é bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù. Ó sọ pé: “Ọjọ́ kan ò ní lọ kí n má ronú pé ó sàn kí n kú. Ó dá mi lójú pé bí mo tiẹ̀ wà láàyè, mi ò ṣe ẹnì kankan láǹfààní.”
“Àwọn ìwádìí kan fi hàn pé gbogbo ìgbà tá a bá rí èèyàn kan tó gbẹ̀mí ara ẹ̀, ọgọ́rùn-ún méjì míì ló ti gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn, nígbà tó jẹ́ pé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [mìíràn] ń ronú láti gbẹ̀mí ara wọn.”—THE GAZETTE, MONTREAL, CANADA.
Diana sọ pé òun ò ní pa ara òun láé. Àmọ́, nígbà míì kò rí ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ kó ṣì wà láyé. Ó sọ pé: “Ohun tó máa ń wù mí jù lọ ni pé kí n kú sínú jàǹbá kan. Mo ti wá rí ikú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ mi, kì í ṣe ọ̀tá mi.”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ wọn náà jọ ti Diana. Àwọn kan tiẹ̀ ti ronú láti gbẹ̀mí ara wọn, nígbà tó jẹ́ pé àwọn míì ti gbìyànjú ẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun táwọn ọ̀mọ̀ràn sọ ni pé, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ti gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn ló jẹ́ pé kì í kúkú ṣe pé ó wu àwọn náà láti kú, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Ní kúkúrú, ayé ti sú wọn; àmọ́ wọ́n fẹ́ mọ ìdí tó fi yẹ káwọn ṣì wà láàyè.
Má ṣe jẹ́ káyé sú ẹ. Jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta tó fi yẹ kó o ṣì wà láàyè.
a A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 1 Torí Pé Nǹkan Máa Ń Yí Pa DàJí!—2014 | May
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ
1 Torí Pé Nǹkan Máa Ń Yí Pa Dà
“A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n a kò há wa ré kọjá yíyíra; ọkàn wa dàrú, ṣùgbọ́n kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbájáde rárá.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 4:8.
Àwọn kan sọ pé ńṣe ni pípara ẹni dà bí ìgbà tí èèyàn fi orí bíbẹ́ ṣe oògùn orí fífọ́. Tí ìṣòro ńlá kan bá ń bá èèyàn fínra, pàápàá tó dà bíi pé ó ti kọjá agbára onítọ̀hún, ó ṣì lè ní àtúnṣe. Ohun tá a sọ yìí lè má rọrùn láti gbà gbọ́ o, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé nǹkan ṣì lè yí pa dà láìrò tẹ́lẹ̀.—Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ sọ pé, “Ìbànújẹ́ Wọn Dayọ̀.”
Ká tiẹ̀ wá sọ pé nǹkan ò tíì yí pa dà, ohun tó dára jù ni pé kó o máa wá ohun tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.”—Mátíù 6:34.
Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ohun tó ń ṣe ẹ́ kò ní àtúnṣe ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé àìsàn kan tó lágbára ló ń ṣe ẹ́. Tó bá jẹ́ pé ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ kọ ara yín sílẹ̀ tàbí pé èèyàn rẹ kan kú ńkọ́?
Kódà tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ohun kan wà tó o lè yí pa dà, ìyẹn ojú tó o fi ń wo ìṣòro náà. Tí o kò bá da ara rẹ láàmú mọ́ lórí àwọn ìṣòro tó kọjá agbára rẹ, wàá lè máa ronú lọ́nà tó tọ́. (Òwe 15:15) Wàá tún kọ́ bó o ṣe lè fara da àwọn ìṣòro náà dípò tí wàá fi máa ronú láti gbẹ̀mí ara rẹ. Kí wá nìyẹn máa yọrí sí? Wàá rí i pé o ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá nǹkan ṣe sí ìṣòro tó dà bíi pé kò látunṣe rárá.—Jóòbù 2:10.
MÁA RÁNTÍ PÉ: O ò lè gun òkè kan lọ́wọ́ kan, àmọ́ o lè máa gùn ún díẹ̀díẹ̀. O lè ṣe ohun kan náà láti yanjú púpọ̀ jù lọ lára àwọn òkè ìṣòro tó ń bá ẹ fínra.
OHUN TÓ O LÈ ṢE LÓNÌÍ: Sọ ìṣòro rẹ fún ẹnì kan, ì báà jẹ́ ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí rẹ kan. Ó ṣeé ṣe kí onítọ̀hún ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ìṣòro tó ń bá ẹ fínra má bàa mú kó o ṣinú rò.—Òwe 11:14.
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 2 Torí Pé Ìrànlọ́wọ́ Wà fún ẸJí!—2014 | May
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ
2 Torí Pé Ìrànlọ́wọ́ Wà fún Ẹ
‘Kó gbogbo àníyàn rẹ lé Ọlọ́run, nítorí ó bìkítà fún ẹ.’—1 PÉTÉRÙ 5:7.
Bí ìṣòro tó lágbára bá ń bá ẹ fínra tó o sì rò pé kò sọ́nà àbáyọ̀, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o kú. Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan kan wa tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Àdúrà. Àdúrà kì í kàn ṣe oògùn amáratuni lásán. Bákan náà, kì í ṣe ìgbà tí ìṣòro bá pinni lẹ́mìí nìkan léèyàn ń gbàdúrà. Àmọ́, ó jẹ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gidi pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí kò fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣeré rárá. Jèhófà fẹ́ kó o sọ ìṣòro rẹ fún òun. Kódà, Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”—Sáàmù 55:22.
O ò ṣe gbàdúrà sí Ọlọ́run lónìí. Pe orúkọ rẹ̀, ìyẹn Jèhófà, kó o sì gbàdúrà tọkàntọkàn. (Sáàmù 62:8) Jèhófà fẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ òun. (Aísáyà 55:6; Jákọ́bù 2:23) Àdúrà jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nígbàkigbà àti níbikíbi.
Àjọ tó ń rí sí bí wọ́n ṣe lè dènà àṣà ṣíṣekú para ẹni lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn American Foundation for Suicide Prevention sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìwádìí fi hàn pé ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára awọn tó ń fọwọ́ ara wọn para wọn ló jẹ́ pé wọ́n ní àìsàn ọpọlọ nígbà tí wọ́n fi máa kú. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, wọn ò tiẹ̀ mọ̀ pé àwọn ní irú àìsàn bẹ́ẹ̀ débi tí wọ́n á fi lọ ṣàyẹ̀wò tàbí kí wọ́n lọ tọ́jú ara wọn dáadáa
Àwọn èèyàn tí kò fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣeré. Àwọn kan wà tí wọ́n fẹ́ràn ẹ, lára wọn ni àwọn ìdílé rẹ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣe ohun tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ àwọn lógún. Àwọn míì tún wà tí wọ́n fẹ́ràn ẹ àmọ́ tó ṣeé ṣe kó o má mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà míì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ń wàásù wọ́n máa ń pàdé àwọn tí ìbánújẹ́ dorí wọn kodò, tí wọ́n sì sọ pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ ti lè gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé ti mú kí wọ́n lè ran irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ Jésù làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé, ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn fi jẹ wọ́n lógún. Ọ̀rọ̀ tìẹ náà sì jẹ wọ́n lógún.—Jòhánù 13:35.
Àwọn dókítà. Ohun tó sábà máa ń mú kéèyàn máa ronú àtipara ẹ̀ ni ìmọ̀lára àti ìṣesí tó ń yí pa dà bìrí, irú bí ìsoríkọ́ tó lágbára gan-an. Kì í ṣe ohun ìtìjú rárá tó o bá ní ìsoríkọ́, bó ṣe jẹ́ pé o kì í tijú tí ara rẹ ò bá yá. Kódà, àwọn kan tiẹ̀ sọ pé ìsoríkọ́ jẹ́ “àìsàn tó lè ṣe ọpọlọ nígbàkigbà.” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló lè ní in, kì í sì í ṣe àìsàn tí kò gbóògùn.a
MÁA RÁNTÍ PÉ: Ńṣe ni ìsoríkọ́ dà bí ìgbà tó o wà nínú kòtò jíjìn kan, o ò lè dá jáde níbẹ̀. Àmọ́, tẹ́nì kan bá ràn ẹ́ lọ́wọ́, o lè bọ́ nínú ẹ̀.
OHUN TÓ O LÈ ṢE LÓNÌÍ: Lọ rí dókítà kan tó máa ń tọ́jú àwọn tí ìmọ̀lára àti ìṣesí wọn máa ń yí pa dà bìrí, irú bí àwọn tó ní ìsoríkọ́.
a Tó bá ń ṣe ẹ́ ní gbogbo ìgbà bíi pé kó o pa ara rẹ, wádìí nípa ibi tó o ti lè gba ìrànlọ́wọ́, o lè pe fóònù ilé ìwòsàn tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn tó fẹ́ pa ara wọn. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti wà ní sẹpẹ́ níbẹ̀ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 3 Torí Pé Ọ̀rọ̀ Rẹ Ò Kọjá ÀtúnṣeJí!—2014 | May
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ
3 Nítorí Pé Ọ̀rọ̀ Rẹ Ò Kọjá Àtúnṣe
“Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—SÁÀMÙ 37:11.
Bíbélì sọ pé ìgbésí ayé “kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Láyé tá a wà yìí, gbogbo èèyàn pátá ló ní ìṣòro kan tàbí òmíràn. Àmọ́ ìbànújẹ́ tó bá àwọn kan kọjá àfẹnusọ, ńṣe ló dà bíi pé òkùnkùn biribiri bo ìgbésí ayé wọn mọ́lẹ̀, kò sì jọ pé nǹkan lè dára fún wọn mọ́ láé. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, fọkàn balẹ̀, torí Bíbélì fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ ò kọjá àtúnṣe rárá. Bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀rọ̀ gbogbo aráyé pátá ò kọjá àtúnṣe. Bí àpẹẹrẹ:
Bíbélì kọ́ wa pé àwọn nǹkan tó dára gan-an wà tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún wa.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa sọ ayé di Párádísè.—Aísáyà 65:21-25.
Ó dájú pé ìlérí yẹn máa ṣẹ. Ìṣípayá 21:3, 4 sọ pé:
“Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”
Ohun tí Bíbélì sọ yìí kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ o. Jèhófà Ọlọ́run ti múra tán láti ṣe é. Ó ní agbára láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì tún ń wù ú gan-an láti ṣe é. Ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ṣeé gbára lé, á sì jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe tí ayé kò fi ní sú ẹ.”
MÁA RÁNTÍ PÉ: Bí ìmọ̀lára rẹ bá tiẹ̀ dà bí ìgbà tí omi òkun ń ru gùdù tó sì ń bi ọkọ̀ kiri lójú omi, ńṣe ni ìròyìn tó ń fúnni nírètí tó wà nínú Bíbélì dà bí ìdákọ̀ró tó máa mú kí ọkàn rẹ balẹ̀.
OHUN TÓ O LÈ ṢE LÓNÌÍ: Bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o lè ní ìrètí tó dájú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. O lè rí wọn ládùúgbò rẹ tàbí kó o wá àwọn ìsọfúnni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí ìkànnì wọn, ìyẹn, jw.org.a
a Àbá: Lọ sórí ìkànnì jw.org kó o sì wo abẹ́ ÌTẸ̀JÁDE > ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ. Tó o bá débẹ̀, wá àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìsoríkọ́” tàbí “para ẹni,” kó o lè rí ìrànlọ́wọ́.
-