ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Jí!—2001 | November 8
    • Ìṣòro Tó Kárí Ayé

      “Ìṣòro ńlá ni ọ̀rọ̀ fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni jẹ́ fún ìlera ará ìlú.”—David Satcher, tó jẹ́ oníṣẹ́-abẹ àgbà fún Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1999 ló sọ bẹ́ẹ̀.

      ÌGBÀ àkọ́kọ́ rèé nínú ìtàn tí oníṣẹ́-abẹ àgbà èyíkéyìí ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà máa sọ pé ìṣòro tó kan gbogbo èèyàn ni fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni jẹ́. Àwọn èèyàn tó ń fọwọ́ ara wọn para wọn lórílẹ̀-èdè yẹn ti wá ń pọ̀ sí i ju àwọn táwọn ẹlòmíràn ń ṣekú pa. Abájọ tí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi kéde pé dídènà ìfọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú.

      Síbẹ̀, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1997, tí a bá kó ọ̀kẹ́ márùn-ún èèyàn jọ, iye tó lé ní mọ́kànlá ló fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn. Iye yìí sì kéré sí èyí tí Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé jáde lọ́dún 2000 tí wọ́n sọ pé tí a bá kó ọ̀kẹ́ márùn-ún èèyàn jọ lágbàáyé èèyàn mẹ́rìndínlógún lára wọn ló fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn. Láàárín ọdún márùnlélógójì sẹ́yìn, ìfọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni ti fi ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè jákèjádò ayé. Ní báyìí, láàárín ọdún kan ṣoṣo, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan èèyàn ló ń fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn káàkiri ayé. Ìyẹn ni pé, kó tó tó ìṣẹ́jú kan, ẹnì kan á ti fọwọ́ ara rẹ̀ gbẹ̀mí ara rẹ̀!

      Síbẹ̀, àwọn ìròyìn tí wọ́n ń gbé jáde kò lè rí gbogbo rẹ̀ tán o. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìdílé kò jẹ́ sọ òótọ́ pé fúnra ẹnì kan tó kú ló para rẹ̀. Bákan náà, wọ́n fojú bù ú pé téèyàn bá fi rí ẹnì kan tó para rẹ̀, àwọn bíi mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n á ti gbìyànjú rẹ̀ wò. Nínú ìwádìí kan, ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló jẹ́wọ́ pé lọ́dún tó ṣáájú ìyẹn, kò sóhun tó wà lọ́kàn àwọn ju pé káwọn gbẹ̀mí ara àwọn lọ; ìdá mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò náà sì sọ pé àwọ́n ti gbìyànjú rẹ̀ wò. Àwọn ìwádìí mìíràn ti fi hàn pé nǹkan bí ìdá márùn-ún sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà ló ti ronú láti pa ara wọn rí.

      Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Yàtọ̀ Síra Wọn

      Ojú táwọn èèyàn fi ń wo fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni yàtọ̀ síra gan-an. Ìwà ọ̀daràn làwọn kan kà á sí, àwọn mìíràn ka ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ sí ojo, tí kò lè kojú ìṣòro, síbẹ̀ àwọn kan wò ó pé ó jẹ́ ọ̀nà tó bójú mu láti fi hàn pé èèyàn kábàámọ̀ àṣìṣe ńlá kan. Àwọn kan tiẹ̀ gbà pé ó jẹ́ ọ̀nà láti fi ìwà akin hàn pé àwọn á máa jà nìṣó fún ẹ̀tọ́ àwọn. Kí ló fa èrò tó yàtọ̀ síra bẹ́ẹ̀? Kò ṣẹ̀yìn ìṣẹ̀dálẹ̀ kálukú. Kódà, ohun tí ìwé ìròyìn The Harvard Mental Health Letter sọ ni pé, àṣà àdúgbò lè “sún ẹnì kan láti pa ara rẹ̀.”

      Gbé ti orílẹ̀-èdè Hungary tó wà ní àárín gbùngbùn Yúróòpù yẹ̀ wò. Dókítà Zoltán Rihmer pe fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni ńláǹlà tó ń wáyé níbẹ̀ ní “ìṣẹ̀dálẹ̀” àwọn ará Hungary “tí ń bani nínú jẹ́.” Béla Buda, tó jẹ́ ọ̀gá ní Ibùdó Ètò Ìlera ti Ìjọba ní Hungary sọ pé, àwọn ara Hungary máa ń pa ara wọn láìbojúwẹ̀yìn, ohunkóhun ló sì lè mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Buda ṣe sọ, lára ohun tí wọ́n sábàá máa ń sọ ni pé “ẹni yẹn ní àrùn jẹjẹrẹ, ó sì mọ ọ̀nà tó yá láti fòpin sí i.”

      Àṣà ìsìn kan wà ní Íńdíà nígbà kan tí wọ́n ń pè ní suttee. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pẹ́ tí wọ́n ti fòfin de àṣà yìí, nínú èyí tí opó kan tí ọkọ rẹ̀ kú á ju ara rẹ̀ sínú iná tí wọ́n fi ń sun òkú ọkọ rẹ̀, síbẹ̀ àṣà yìí ò tíì tán pátápátá o. A gbọ́ pé nígbà tí obìnrin kan gbẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́nà yìí, ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn ládùúgbò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gbóṣùbà fún un. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn India Today sọ, ní àdúgbò yẹn ní Íńdíà, “ó ń lọ sí bí obìnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ sun ara wọn jóná láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.”

      Lọ́nà tó gbàfiyèsí, lórílẹ̀-èdè Japan, àwọn tó ń fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn ju ìlọ́po mẹ́ta àwọn tó kú nínú jàǹbá mọ́tò lọ! Ìwé kan tó ń jẹ́ Japan—An Illustrated Encyclopedia sọ pé: “Àṣà ilẹ̀ Japan tí kò fìgbà kankan bẹnu àtẹ́ lu ìpara ẹni, ní ààtò ìsìn kan nínú tí èèyàn á fọwọ́ ara rẹ̀ kó ìfun ara rẹ̀ jáde (àṣà seppuku tàbí hara-kiri).”

      Inazo Nitobe, tó di igbá kejì akọ̀wé àgbà fún Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣàlàyé àṣà fífẹ́ láti kú yìí nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Bushido—The Soul of Japan. Ó kọ ọ́ pé: “Àṣà [seppuku] jẹ́ ohun tí wọ́n dá sílẹ̀ ní sànmánì ojú dúdú, èyí tí àwọn jagunjagun máa ń lò láti fòpin sí ìwà ibi tí wọ́n hù, láti bẹ̀bẹ̀ fún àṣìṣe wọn, láti bọ́ lọ́wọ́ ìtìjú fún àìdáa tí wọ́n ṣe sí àwọn ọ̀rẹ́ wọn, tàbí láti fi ẹ̀rí òótọ́ inú wọn hàn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni fún ìrúbọ yìí ti di ohun àtijọ́ níbi púpọ̀, àwọn díẹ̀ ṣì ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀ kí àwùjọ bàa lè tẹ́wọ́ gbà wọ́n.

      Àmọ́ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń wo fífọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni bí ìwà ọ̀daràn. Nígbà tó máa fi di ọ̀rúndún kẹfà àti ìkeje, Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì kì í dá sí àwọn tó bá fọwọ́ ara wọn para wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣe ààtò ìsìnkú wọn. Àwọn ibì kan wà tí wọ́n ti gba ìsìn kanrí débi pé, wọ́n ní àwọn àṣà tó gbòdì kan nípa àwọn tó bá fọwọ́ ara wọn para wọn, bíi gbígbé òkú ẹni náà kọ́gi, tí wọ́n á tiẹ̀ tún ki irin ṣóńṣó bọ̀ ọ́ lọ́kàn tá á sì gba òdìkejì jáde.

      Ìyàlẹ́nu gbáà ni pé, àwọn tó bá gbìyànjú láti pa ara wọn lè gba ìdájọ́ ikú. Wọ́n yẹgi fún ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún nítorí pé ó gbìyànjú àtipa ara rẹ̀ nípa fífọ̀bẹ gé ara rẹ̀ lọ́fun. Làwọn aláṣẹ bá kúkú bá ọkùnrin yìí parí ohun tí kò lè ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn tó bá gbìyànjú láti pa ara wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọdún 1961 ni Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tóó ṣẹ̀ṣẹ̀ kéde pé fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni tàbí gbígbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ kì í tún ṣe ìwà ọ̀daràn mọ́. Ní Ireland, ìwà ọ̀daràn ni wọ́n ṣì kà á sí títí di ọdún 1993.

      Lóde òní, àwọn òǹkọ̀wé kan dámọ̀ràn ìfọwọ́-ara-ẹni-pa-ara-ẹni bí ọ̀nà àbáyọ kan. Ìwé kan tí wọ́n ṣe jáde ní 1991 fún ìrànwọ́ àwọn aláìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ dábàá àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fòpin sí ìwàláàyè ara wọn. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn tí kì í ṣe aláìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ mú lò lára àwọn àbá tó wà nínú rẹ̀.

      Ṣé lóòótọ́ ni fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni jẹ́ ojútùú sáwọn ìṣòro téèyàn ní? Àbí, ṣé àwọn ìdí tó dára wà tó fi yẹ kéèyàn máa wà láàyè nìṣó? Ká tó gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ń fa fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni.

      [Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

      Láàárín ọdún kan ṣoṣo, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan èèyàn káàkiri ayé ló máa ń fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn. Ìyẹn ni pé, kó tó tó ìṣẹ́jú kan, ẹnì kan á ti fọwọ́ ara rẹ̀ gbẹ̀mí ara rẹ̀!

  • Ohun Tó Ń mú Káyé Sú Àwọn Èèyàn Kan
    Jí!—2001 | November 8
    • Ohun Tó Ń mú Káyé Sú Àwọn Èèyàn Kan

      “Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èèyàn tó ń para wọn ló ní ìdí kan pàtàkì tó ń mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀: àdììtú ni, kò sẹ́ni tó lè mọ̀ ọ́n, ó sì ń kó ìpayà báni.”—Kay Redfield Jamison, oníṣègùn ọpọlọ.

      “ÌNIRA ló jẹ́ láti wà láàyè.” Ohun tí Ryunosuke Akutagawa, òǹkọ̀wé kan tó gbajúmọ̀ ní Japan níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún kọ sílẹ̀ nìyẹn kó tó pa ara rẹ̀. Àmọ́ ohun tó kọ ṣáájú ọ̀rọ̀ yẹn ni pé: “Lóòótọ́, kò wù mí láti kú, àmọ́ . . . ”

      Bíi ti Akutagawa, kì í ṣe pé ó dìídì wu àwọn tó ń gbẹ̀mí ara wọn láti kú, ọ̀jọ̀gbọ́n kan nípa ìrònú òun ìhùwà sọ pé, ńṣe ni “wọ́n fẹ́ fòpin sí ohun yòówù tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn.” Àwọn ọ̀rọ̀ tó sábàá máa ń wà nínú ìwé táwọn tó ń gbẹ̀mí ara wọn máa ń kọ sílẹ̀ fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Àwọn gbólóhùn bíi, ‘Mi ò lè fara dà á mọ́’ tàbí ‘Kí ni mo tún ń ṣe láyé?’ fi hàn bó ṣe máa ń mú wọn lọ́kàn tó láti bọ́ lọ́wọ́ wàhálà ìgbésí ayé. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ògbóǹkangí kan sọ, ńṣe ni fífọwọ́ ara ẹni para ẹni “dà bí ìgbà téèyàn lọ kó sínú iná kí òtútù tó ń mú un bàa lè lọ.”

      Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi nǹkan ló ń fa káwọn èèyàn máa fọwọ́ ara wọn para wọn, àwọn nǹkan kan pàtó wà tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé tó sábà máa ń súnná sí i.

      Àwọn Ohun Tó Máa Ń Súnná Sí I

      Ó jẹ́ àṣà àwọn ọ̀dọ́ kí wọ́n máa sọ̀rètí nù kí wọ́n sì máa para wọn, kódà lórí àwọn ọ̀ràn tó lè máà jẹ́ nǹkankan lójú àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí ẹnì kan bá ṣe ohun kan tó dùn wọ́n tí wọn ò sì lè ṣe nǹkankan sí i, àwọn ọ̀dọ́ yìí lè wò ó pé tí àwọ́n bá pa ara àwọn sí ẹni náà lọ́rùn, àwọ́n á lè fi yé e. Hiroshi Inamura, ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀ràn àwọn èèyàn tí wọ́n ń gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn ní Japan, kọ̀wé pé: “Àwọn ọmọdé fẹ́ràn láti máa rò ó lọ́kàn wọn pé tí àwọn bá para àwọn, àwọn á lè fìyà jẹ ẹni tó dá àwọn lóró.”

      Ìwádìí kan tó wáyé láìpẹ́ yìí ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi hàn pé, tí àwọn ọmọdé bá ń fojú winá ìwà ìkà, ìgbìdánwò láti pa ara wọn máa ń pọ̀ sí i ní ìlọ́po méje. Ẹ̀dùn ọkàn tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń ní kì í ṣe irọ́ o. Nínú ìwé kan tí ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́dún mẹ́tàlá kan kọ sílẹ̀ kó tó pokùn so, ó dárúkọ àwọn márùn-ún kan tí wọ́n hàn án léèmọ̀ tí wọ́n tún fipá gbowó lọ́wọ́ rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gba àwọn ọmọdé tó kù lọ́wọ́ ikú o.”

      Àwọn mìíràn lè gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn tí wọ́n bá kó sí wàhálà níléèwé tàbí lọ́dọ̀ ìjọba, tí olólùfẹ́ wọn bá já wọn sílẹ̀, tí wọ́n bá fìdí rẹmi níléèwé, tí ìdánwò bá kó wọn sírònú, tàbí tọ́jọ́ iwájú wọn bá ń kó ìbànújẹ́ bá wọn. Nígbà tó bá jọ pé àwọn ọ̀dọ́langba tó máa ń mókè níléèwé, tí wọ́n fẹ́ jẹ́ mo-mọ̀-ọ́n tán, bá rẹ̀yìn díẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ó lè di ohun tí wọ́n máa torí ẹ̀ fẹ́ para wọn.

      Ní ti àwọn àgbàlagbà, ìṣòro àìríná-àìrílò tàbí ìṣòro iṣẹ́ ló sábà máa ń fa tiwọn. Ní Japan, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí ọrọ̀ ajé wọn ti polúkúmuṣu, àwọn tó ń para wọn lọ́dún kan báyìí ti ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Mainichi Daily News ṣe sọ, nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ogójì ọdún sí ọgọ́ta ọdún tó para wọn ló jẹ́ pé “gbèsè, iṣẹ́ tí kò lọ déédéé, òṣì, àti àìríṣẹ́ṣe ló sún wọn sí i.” Kí ìdílé má tòrò náà tún lè fa fífọwọ́ ara ẹni para ẹni. Ìwé ìròyìn kan lédè Finnish sọ pé: “Àwọn ọkùnrin tí ìyàwó kọ̀ sílẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí” wà lára àwọn tó ṣeé ṣe jù pé kí wọ́n pa ara wọn. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Hungary sì fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n ń gbèrò àti fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn ló jẹ́ pé inú ìdílé tó ti pínyà ni wọ́n ti tọ́ wọn.

      Ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ àti òkùnrùn ara tún jẹ́ kókó pàtàkì tó ń fa ìpara ẹni, pàápàá láàárín àwọn arúgbó. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni aláìsàn kan á yàn láti pa ara rẹ̀ kó lè bọ́ lọ́wọ́ wàhálà, ó lè máà jẹ́ àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí ló ń ṣe é o, ṣùgbọ́n ó kàn lè wò ó pé ìyà náà ti pọ̀ jù, òun ò sì lè fara dà á mọ́.

      Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló jẹ́ pé pípa ni wọ́n á wá para wọn tí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ bá dé bá wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ni kò jẹ́ gbẹ̀mí ara wọn tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀. Kí wá ló dé o, tí àwọn kan máa ń wo fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni bí ọ̀nà àbáyọ, nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀?

      Àwọn Ohun Tó Ń Fà Á

      Kay Redfield Jamison, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìṣègùn ọpọlọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìṣègùn ti Yunifásítì Johns Hopkins sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ohun tó ń mú àwọn èèyàn pinnu láti kú sinmi lórí irú ojú tí wọ́n fi wo ohun tó ṣẹlẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ tí ọpọlọ wọn pé, kò jẹ́ ronú pé ìṣòro kan á le títí débi pe káwọn para àwọn.” Eve K. Mościcki láti Ibùdó Ẹ̀kọ́ Ìlera Ọpọlọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé, ọ̀pọ̀ nǹkan, tí òmíràn ṣe kókó àmọ́ tí kì í tètè hàn fáyé rí ló máa ń para pọ̀ sún ẹnì kan ṣe ohun tó lè gbẹ̀mí rẹ̀. Lára irú àwọn kókó bẹ́ẹ̀ ni kéèyàn ní ìdààmú ọpọlọ, àwọn àṣà kan tó ti di mọ́ọ́lí, bí àbùdá ẹnì kan ṣe rí, àti ọ̀nà tí ọpọlọ ń gbà ṣiṣẹ́. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára wọn.

      Èyí tó burú jù lọ nínú àwọn kókó yìí ni ìdààmú ọpọlọ àti kí àwọn ìṣòro kan tí di bárakú sára, bíi kéèyàn ní ìdààmú ọkàn, àrùn ọpọlọ tí ìsoríkọ́ fà, ọpọlọ dídàrú, àti ọtí ìmukúmu tàbí lílo oògùn nílòkulò. Ìwádìí tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Yúróòpù àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ ló wà lẹ́yìn ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún ìfọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni. Kódà, àwọn olùwádìí ní Sweden ti rí i pé, àwọn ọkùnrin tó gbẹ̀mí ara wọn àmọ́ tí wọn kò ní irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ kò pé mẹ́wàá nínú ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún, àmọ́ láàárín àwọn tó ní ìdààmú ọkàn, iye náà fò sókè sí àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta [650]! Àwọn ògbóǹkangí sì sọ pé àwọn ohun tó ń mú káwọn èèyàn fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn láwọn orílẹ̀-èdè Ìhà Ìlà Oòrùn Ayé kò yàtọ̀ síyẹn náà. Àmọ́ ṣá o, bí wọ́n tiẹ̀ sọ pé ìdààmú ọkàn ló ń fà á, ìyẹn ò sọ pé kí ìpara ẹni má ṣẹlẹ̀.

      Ọ̀jọ̀gbọ́n Jamison tóun alára ti gbìyànjú láti para rẹ̀ nígbà kan rí sọ pé: “Ó jọ pé àwọn èèyàn máa ń lè fára da ìdààmú ọkàn níwọ̀n ìgbà tí ìrètí bá ṣì wà pé nǹkan á dára.” Ṣùgbọ́n, obìnrin yìí ṣàwárí pé, bí àìsírètí bá ṣe ń ga sí i, tó sì ń di pé kò ṣe é fara dà mọ́, bẹ́ẹ̀ ni agbára tí ọpọlọ ní láti dènà wíwù tó ń wu onítọ̀hún láti kú á bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù díẹ̀díẹ̀. Ó fi ìṣòro náà wé bí bíréèkì ọkọ̀ ṣe máa ń jẹ díẹ̀díẹ̀ bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ ẹ́ nígbà gbogbo.

      Ó ṣe pàtàkì láti ṣàkíyèsí irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ torí pé ìdààmú ọkàn kì í ṣe ohun tí kò ṣeé wò sàn. Àwọn ìmọ̀lára tó ń wá látinú àìsírètí sì ṣeé mú kúrò. Táa bá bójú tó àwọn ìṣòro tó ń fa fífọwọ́ ara ẹni gbẹ̀mí ara ẹni, ìbànújẹ́ ọkàn àti àìfararọ tó sábà máa ń súnná sí ìpara ẹni lè máà kó wàhálà bá èèyàn mọ́.

      Àwọn kan ronú pé bí àbùdá ẹnì kan ṣe rí lè jẹ́ ohun tó ń fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn. Òótọ́ ni pé àbùdá ní ipa tó ń kó nínú bí ẹnì kan ṣe rí ara gba nǹkan sí, ìwádìí sì ti fi hàn pé àwọn ìdílé kan wà tí pípara ẹni kò jẹ́ nǹkan tuntun sí bíi tàwọn mìíràn. Síbẹ̀, Jamison sọ pé: “Bí àbùdá àwọn kan bá tiẹ̀ ń mú kí wọ́n tètè juwọ́ sílẹ̀ láti gbẹ̀mí ara wọn, ìyẹn kò torí ẹ̀ sọ pé kí àwọn èèyàn mìíràn gbẹ̀mí ara wọn.”

      Ọ̀nà tí ọpọlọ ń gbà ṣiṣẹ́ náà tún lè jẹ́ ìdí mìíràn. Ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn iṣan inú ọpọlọ ló jọ máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Àwọn ibì kan ní ìparí àwọn fọ́nrán iṣan náà máa ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ káàkiri inú ọpọlọ. Bí agbára ọ̀kan lára àwọn iṣan náà bá ṣe pọ̀ sí lè wà lára ohun tó lè mú kí ẹnì kan máa fẹ́ láti para rẹ̀. Ìwé Inside the Brain ṣàlàyé pé: “Tó bá ṣẹlẹ̀ pé èròjà kan tó ń jẹ́ serotonin nínú ọpọlọ bá lọ sílẹ̀ . . . ó lè fa kí èèyàn máà láyọ̀ mọ́ nínú ìgbésí ayé, táá sì máa mú kí ìfẹ́ ẹni yẹn láti wà láàyè máa dín kù, tí ẹdùn ọkàn rẹ̀ á máa ga sí i, táá sì máa rò pé ó kúkú sàn kóun pa ara òun.”

      Ṣùgbọ́n òótọ́ ibẹ̀ ni pé, a kò dá a mọ́ ẹnikẹ́ni pé kó fọwọ́ ara rẹ̀ para rẹ̀. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń kojú ìbànújẹ́ ọkàn àti wàhálà. Bí àwọn kan kò ṣe rí ara gbà á sí ló ń mú kí wọ́n máa para wọn. Àmọ́ kì í ṣe àwọn ohun tó kọ́kọ́ fà á nìkan lèèyàn gbọ́dọ̀ mójú tó o, ó tún kan àwọn ìṣòro tó ti dá sílẹ̀.

      Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lèèyàn lè ṣe láti bẹ̀rẹ̀ sí í nírètí pé nǹkan á dára tá á sì mú kéèyàn tún fẹ́ láti gbádùn ìgbésí ayé?

      [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]

      Ìhà Tí Tọkùnrin-Tobìnrin Kọ sí Ìfọwọ́-Ara-Ẹni-Gbẹ̀mí-Ara-Ẹni

      Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti fi hàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin máa ń gbìyànjú láti pa ara wọn ju àwọn ọkùnrin lọ, àwọn ọkùnrin gan-⁠an ló ṣeé ṣe kí wọ́n pa ara wọn jù. Àwọn obìnrin sábà máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn ju àwọn ọkùnrin lọ, èyí sì lè jẹ́ ìdí tó ń mú wọn fẹ́ para wọn. Àmọ́, bó ti wù kí ìbànújẹ́ wọn pọ̀ tó, wọ́n lè máà fi bẹ́ẹ̀ ṣe ohun tó la ikú lọ. Ṣùgbọ́n ní tàwọn ọkùnrin, wọ́n lè lo agídí kí wọ́n sì rí i pé àwọn ṣe ohun tó wà lọ́kàn wọn yẹn gan-⁠an.

      Àmọ́ ṣá, nílẹ̀ China, àwọn obìnrin ló ń para wọn ju àwọn ọkùnrin lọ. Kódà, ìwádìí kan fi hàn pé nínú gbogbo ìfọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn obìnrin lágbàáyé, ilẹ̀ China nìkan kó nǹkan bí ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-⁠ún, àgàgà láwọn àrọko. A gbọ́ pé ọ̀kan lára ohun tó ń mú kí àwọn obìnrin ibẹ̀ máa gbèrò láti pa ara wọn láìbojúwẹ̀yìn ni níní tí wọ́n ní àwọn oògùn apakòkòrò tó ń ṣekú pani níkàáwọ́.

      [Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

      Bí Ìnìkanwà Ṣe Bá Fífọwọ́-Ara-Ẹni-Gbẹ̀mí-Ara-Ẹni Tan

      Ìnìkanwà jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn èèyàn tí wọ́n sì máa ń fẹ́ gbẹ̀mí ara wọn. Jouko Lönnqvist, tó ṣáájú ikọ̀ tó ń ṣèwádìí lórí ọ̀ràn fífọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni ní orílẹ̀-èdè Finland sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lọ [lára àwọn tó gbẹ̀mí ara wọn], ló jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa ń dá wà lójoojúmọ́. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ àkókò ṣùgbọ́n wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní alájọṣe.” Kenshiro Ohara tó jẹ́ oníṣègùn ọpọlọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìṣègùn ti Yunifásítì Hamamatsu ní Japan ṣàlàyé pé “àìní alábàárò” ló fà á tí àwọn ọkùnrin lórílẹ̀-èdè náà fi ń gbẹ̀mí ara wọn lọ́nà bíbùáyà lẹ́nu àìpẹ́ yìí.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

      Ní ti àwọn àgbàlagbà, ìṣòro àìríná-àìrílò tàbí ìṣòro iṣẹ́ ló sábà ń fa tiwọn

  • O Lè Rí Ìrànwọ́
    Jí!—2001 | November 8
    • O Lè Rí Ìrànwọ́

      ỌKÙNRIN ara Switzerland kan tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n kó oògùn oorun, oníhóró mọ́kàndínláàádọ́ta, ó di wì nínú kọ́ọ̀pù. Ó wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé kí n kó o mì àbí kí n máà kó o mì.’ Ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, ó sì wà nínú ìbànújẹ́ ọkàn tó pabanbarì. Àmọ́ lẹ́yìn tó da oògùn ọ̀hún jẹ tán ló bá figbe bọnu pé: ‘Rárá o. Mi ò fẹ́ kú mọ́!’ Ọlọ́run bá a ṣé e, kò kú, ẹnu ara rẹ̀ ló sì fi ṣàlàyé ohun tójú rẹ̀ rí. Gbogbo ìgbà kọ́ ni ìgbìyànjú láti gbẹ̀mí ara ẹni máa ń yọrí sí ikú.

      Nípa ti àwọn ọ̀dọ́langba tó máa ń gbìyànjú láti pa ara wọn, Alex Crosby tó wà ní Ibùdó Tó Ń Káwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Tó o bá kàn tiẹ̀ lè dá wọn dúró fún wákàtí díẹ̀ kí wọ́n tó ṣe é, o lè gbà ẹ̀mí wọ́n là. Tó o bá wá nǹkan ṣe, ọ̀pọ̀ ni o lè gbà sílẹ̀ kó tó di pé wọ́n para wọn. O lè dá ẹ̀mí wọn sí.”

      Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Hisashi Kurosawa ń ṣiṣẹ́ ní Ibùdó Ọ̀ràn Pàjáwìrì àti Ìgbẹ̀mílà ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Ìṣègùn ti Japan, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn tó ti fẹ́ gbẹ̀mí ara wọn tẹ́lẹ̀ ló ràn lọ́wọ́ tí wọ́n fi nífẹ̀ẹ́ láti tún wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó dájú pé, téèyàn bá lo ọ̀nà èyíkéyìí tó mọ̀ láti fi dí wọn lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí la lè gbà là. Irú ìrànlọ́wọ́ wo ni wọ́n nílò?

      Àwọn Ohun Tó Fà Á Ni Kí O Bójú Tó

      Gẹ́gẹ́ báa ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó gbẹ̀mí ara wọn ló ní ìdààmú ọpọlọ tàbí kó jẹ́ pé wọ́n ń lo oògùn olóró. Èyí ló mú Eve K. Mościcki tó wà ní Ibùdó Ẹ̀kọ́ Ìlera Ọpọlọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ìrètí tó ga jù lọ fún dídènà ìfọwọ́-ara-ẹni-gbẹ̀mí-ara-ẹni láàárín onírúurú èèyàn ni pé kí á dènà ìṣòro inú ọpọlọ àti ti oògùn olóró.”

      Ohun tó wá báni nínú jẹ ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìṣòro yìí ni kì í wá ìrànwọ́. Kí nìdí? Yoshitomo Takahashi, tó wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àrùn Ọpọlọ ti Ìlú Tokyo àti Àgbègbè Rẹ̀ sọ pé: “Ojú burúkú ni wọ́n máa ń fi wo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láwùjọ.” Ó fi kún un pé èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé, kódà, àwọn tó ń fura pé nǹkan kan ń yọ wọ́n lẹ́nu kì í tètè wá ìtọ́jú.

      Àmọ́ ṣá, àwọn kan wà, tí wọn kò jẹ́ jẹ́ kí ìtìjú di àrùn sí àwọn lára. Gbangba báyìí ni Hiroshi Ogawa, ìlúmọ̀ọ́ká olùpolówó orí tẹlifíṣọ̀n kan, tó tiẹ̀ ti ń gbé eré tiẹ̀ gan-an jáde ní Japan fún ọdún mẹ́tàdínlógún ti sọ pé, òún ní ìsoríkọ́ àti pé díẹ̀ ló kù kóun gbẹ̀mí ara òun. Ogawa sọ pé: “Ìdààmú ọkàn kò yàtọ̀ sí àìsàn kan tó máa ń yọ ọpọlọ lẹ́nu.” Ó ṣàlàyé pé kò sẹ́ni tí kò lè ṣẹlẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe láti bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

      Wá Ẹnì Kan Bá Sọ̀rọ̀

      Béla Buda, òṣìṣẹ́ ètò ìlera ní Hungary tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú sọ pé: “Nígbà tẹ́nì kan bá ń dá nìkan kojú ìṣòro rẹ̀, ńṣe lá máa wò ó pé kò sí ẹni tí ìṣòro rẹ̀ tó tòun àti pé kò sí ọ̀nà àbáyọ.” Ńṣe ni ọrọ̀ yìí tẹnu mọ́ ọgbọ́n tó wà nínú òwe àtijọ́ inú Bíbélì náà pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.”—Òwe 18:1.

      Fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yẹn o. Máà dá nìkan kojú ìṣòro rẹ. Wá ẹni tó o lè fọkàn tán tí wàá lè sọ gbogbo tinú ẹ fún. Àmọ́, o lè wá sọ pé, ‘ṣùgbọ́n mi ò lẹ́nì kankan tí mo lè finú hàn.’ Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń lérò bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Naoki Sato tó jẹ́ ọ̀gá nínú ọ̀ràn ìlera ọpọlọ ti sọ. Sato sọ pé àwọn èèyàn náà lè máà sọ tinú wọn jáde fún ẹnikẹ́ni torí wọn kì í fẹ́ kí ẹnì kankan mọ ibi tí wọ́n kù sí.

      Ibo wá lẹnì kan lè yíjú sí láti rí ẹni tó máa tẹ́tí gbọ́ ọ? Níbi púpọ̀, ó lè wá ìrànwọ́ àwọn àjọ tó ń dènà ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni tàbí kó tẹ àwọn tó máa ń ran ẹni tó bá níṣòro lọ́wọ́ láago tàbí kẹ̀ kó wá dókítà gidi tó mọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú àròdùn ọkàn. Àmọ́ àwọn ògbógi kan tún sọ ohun mìíràn tó lè ṣèrànwọ́—ìyẹn ni ìsìn. Ọ̀nà wo nìyẹn fi lè ṣèrànwọ́?

      Wọ́n Rí Ìrànlọ́wọ́ Tí Wọ́n Nílò Gbà

      Marin, tó jẹ́ aláìlera tó ń gbé ní Bulgaria, ti wò ó pé kò sí ohun tó kù mọ́ ju kí òun para òun lọ. Lọ́jọ́ kan, ó ṣèèṣì rí ìwé ìròyìn ẹlẹ́sìn náà, Ilé Ìṣọ́, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Ó tẹ́wọ́ gba ìkésíni tó wà nínú ìwé ìròyìn náà pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ òun. Marin sọ ohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀ pé: “Mo kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ wọn pé ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn kan látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run àti pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣera wa léṣe tàbí ká fọwọ́ ara wa gbẹ̀mí ara wa. Fún ìdí yẹn, mo pa èrò tí mo ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ láti pa ara mi tì mo sì tún padà nífẹ̀ẹ́ láti wà láàyè!” Marin tún rí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìlera èèyàn ṣì ni síbẹ̀, ó sọ pé: “Ìgbésí ayé mi tí kún fún ayọ̀ báyìí, ó sì tòrò minimini, mo ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó gbádùn mọ́ni tí mo lè ṣe—kódà wọ́n pọ̀ débi pé mi ò lè ṣe wọ́n tán! Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà àti àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ló mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe.”

      Ọkùnrin ará Switzerland tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ náà rí ìrànwọ́ gbà lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́jọ́ òní, ó máa ń sọ nípa “inú rere tí ìdílé Kristẹni kan fi hàn” tí wọ́n gbà á sínú ilé wọn. Ó fi kún un pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn náà làwọn mẹ́ńbà ìjọ [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] fi ń ké sí mi lọ́kọ̀ọ̀kan láti wá máa jẹun nílé wọn. Kì í ṣe bí wọ́n ṣe ṣaájò mi nìkan lohun tó ṣèrànwọ́, àmọ́ bí mo ṣe ń rí ẹni bá sọ̀rọ̀.”

      Ẹ̀kọ́ tí ọkùnrin yìí kọ́ nínú Bíbélì tún fún un níṣìírí gan-an ni, àgàgà nígbà tó wá mọ̀ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run òtítọ́ náà, Jèhófà, ní fún aráyé. (Jòhánù 3:16) Ní ti tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run á tẹ́tí sí ọ nígbà tó o bá ‘tú ọkàn-àyà rẹ jáde’ fún un. (Sáàmù 62:8) “Ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé,” kì í ṣe láti wá àṣìṣe àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n “láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Jèhófà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”—Aísáyà 41:10.

      Nígbà tí Ọkùnrin ará Switzerland náà ń sọ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ayé tuntun, ó sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ tí èyí ṣe nínú sísọ ìṣòro mi di fífúyẹ́ kò kéré.” Ìrètí yìí, èyí tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ “ìdákọ̀ró fún ọkàn,” ní í ṣe pẹ̀lú ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Hébérù 6:19; Sáàmù 37:10, 11, 29.

      Ìwàláàyè Rẹ Jẹ Àwọn Mìíràn Lógún

      Lóòótọ́, o lè máa kojú àwọn ìṣòro tó lè mú kí o máa rò pé o ò lẹ́nì kan àti pé ikú rẹ kò ná ẹnikẹ́ni ní ohunkóhun. Àmọ́, má gbàgbé pé: Ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín kéèyàn ronú pé ńṣe lòún nìkan wà àti nínìkan wà lóòótọ́. Lásìkò tí kíkọ Bíbélì ń lọ lọ́wọ́, wòlíì Èlíjà bá ara rẹ̀ nínú ipò kan tó kó o sí ìbànújẹ́ gan-an. Ó sọ fún Jèhófà pé: ‘Wọ́n ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ, tí ó fi jẹ́ pé èmi nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́ kù.’ Bẹ́ẹ̀ ni, bí ẹni pé Èlíjà nìkan ló ṣẹ́ kù ló rí lára rẹ̀, ó sì nídìí. Àwọn wòlíì ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ti pa kì í ṣe kékeré. Ikú ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí òun náà, ó sì ń sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. Àmọ́ ṣe òótọ́ ni pé òun nìkan ló kù? Rárá o. Jèhófà jẹ́ kó mọ̀ pé, ó ṣì ku nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje àwọn èèyàn tó jẹ́ adúróṣinṣin, tó jẹ́ pé, bíi tiẹ̀, wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ sapá láti sin Ọlọ́run òtítọ́ làwọn àkókò tó kún fún ẹ̀rù yẹn. (1 Àwọn Ọba 19:1-18) Ìwọ náà ń kọ́? Ṣé ó lè jẹ́ pé o ò dá wà bó o ṣe rò pé o dá wà?

      Àwọn èèyàn tó bìkítà nípa rẹ wà. O lè ronú nípa àwọn òbí rẹ, ọkọ rẹ, ìyàwó rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Kò tán síbẹ̀ o. Nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè rí àwọn Kristẹni tí wọ́n dàgbà dénú tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ lọ́kàn, tí wọ́n á fara balẹ̀ tẹ́tí gbọ́ ọ, tí wọ́n á gbàdúrà pẹ̀lú rẹ tí wọ́n á sì tún gbàdúrà fún ọ. (Jákọ́bù 5:14, 15) Kódà, ká tiẹ̀ wá ní gbogbo èèyàn aláìpé já ọ kulẹ̀, Ẹnì kan wà tí kò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé. Ọba Dáfídì ìgbàanì sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Dájúdájú, Jèhófà ‘bìkítà fún ọ.’ (1 Pétérù 5:7) Má fìgbà kankan gbàgbé láé pé o ṣeyebíye lójú Jèhófà.

      Ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Òótọ́ ni pé, ìgbà mìíràn wà tí ìgbésí ayé lè dà bí ìnira, tí kò ní jọ ẹ̀bùn níbì kankan. Rò ó wò ná, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ ká ní o fún ẹnì kan ní ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye kan, kẹ́ni yẹn wá sọ ọ́ nù láìtiẹ̀ tíì lò ó rárá? Àwa èèyàn aláìpé kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀bùn ìwàláàyè rárá ni ká sọ. Kódà gan-an, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé irú ìgbésí ayé tá a ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí kì í ṣe ‘ìgbésí ayé tòótọ́’ lójú Ọlọ́run. (1 Tímótì 6:19) Ó dájú pé, láìpẹ́ sí àkókò yìí, ìgbésí ayé wa máa lójú ju báyìí lọ, yóò nítumọ̀, yóò si kún fún ayọ̀. Báwo?

      Bíbélì sọ pé: ‘[Ọlọ́run] yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’ (Ìṣípayá 21:3, 4) Fojú inú wo bí ìgbésí ayé rẹ á ṣe rí nígbà táwọn ọ̀rọ̀ yẹn bá nímùúṣẹ. Fara balẹ̀ ronú nípa rẹ̀. Gbìyànjú láti fọkàn rẹ yàwòrán rẹ̀ ní kíkún, pẹ̀lú àrímáleèlọ ẹwà. Àwòrán yìí kì í ṣe àlá lásán o. Bó o ti ń ṣàṣàrò lórí ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò láwọn àkókò tó kọjá, ìgbọ́kànlé tó o ní nínú rẹ̀ á pọ̀ sí i, àwòrán tó o fọkàn yà yẹn á sì túbọ̀ wá jẹ́ òótọ́ sí ọ.—Sáàmù 136:1-26.

      Ó lè gba àkókò díẹ̀ kí ìfẹ́ rẹ láti wà láàyè tó padà dọ̀tun. Máà dẹ́kun gbígbàdúrà sí “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 5:17) Jèhófà á fún ẹ ní okun tó o nílò. Á jẹ́ kó o mọ̀ pé kò sóhun tó dùn tó kí o wà láàyè.—Aísáyà 40:29.

      [Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

      Ǹjẹ́ O Lè Ran Ẹnì Kan Tó Fẹ́ Para Rẹ̀ Lọ́wọ́?

      Kí ló yẹ kó o ṣe tẹ́nì kan bá sọ létí rẹ pé òun fẹ́ pa ara òun? Ibùdó Tó Ń Káwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà dámọ̀ràn pé, “Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa.” Fún un láyè láti ṣàlàyé bí nǹkan náà ṣe rí lára rẹ̀ gan-an. Àmọ́ ṣá o, lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tó fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀ kì í dá sí ẹnì kankan kò sì ní í sọ fún ẹ. Jẹ́ kó mọ̀ pé lóòótọ́ lo gbà pé ara ń ni í tàbí pé kò nírètí mọ́.

      Tó o bá rọra fọgbọ́n sọ àwọn ìyípadà pàtàkì kan tó o ti kíyè sí nínú ìṣesí rẹ̀ fún un, ó lè sún un láti sọ tinú rẹ̀ jáde.

      Bó o ti ń tẹ́tí gbọ́ ọ, máa fi ọ̀rọ̀ náà rora rẹ wò. Ibùdó tó Ń Káwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì kó o tẹnu mọ́ ọn pé ìwàláàyè ẹni náà jẹ ọ́ lógún, pé ó tún jẹ àwọn mìíràn lógún pẹ̀lú.” Jẹ́ kó mọ bí ikú rẹ̀ ṣe máa kó ìdààmú bá ìwọ àtàwọn mìíràn tó. Ran ẹni náà lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bìkítà nípa rẹ̀.—1 Pétérù 5:7.

      Àwọn ògbógi tún dámọ̀ràn pípalẹ̀ ohunkóhun tí ẹni náà lè lò láti fi gbẹ̀mí ara rẹ̀ mọ́ kúrò nílẹ̀—àgàgà ìbọn. Tí ọ̀rọ̀ náà bá ti kúrò ní kékeré, o lè gba ẹni náà nímọ̀ràn pé kó lọ rí dókítà. Tó bá sì le ju, kò sóhun méjì tí wàá ṣe ju pé kí ìwọ alára pe àwọn onítọ̀ọ́jú pàjáwìrì.

      [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

      ‘Ṣé Ọlọ́run Á Dárí Jì Mí fún Níní Irú Èrò Yẹn?’

      Kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti borí èrò tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ láti pa ara wọn. Síbẹ̀, kò sẹ́ni tí àwọn ohun tí ń kó ìbànújẹ́ báni ní ìgbésí ayé yọ sílẹ̀ lóde òní. Ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti ronú láti para wọn tẹ́lẹ̀ sábà máa ń dààmú wọn, tí á sì máa dá wọn lẹ́bi fún níní irú èrò yẹn. Ńṣe ni dídára wọn lẹ́bi á wulẹ̀ tún dá kún ìṣòro wọn. Nítorí náà, ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà kojú irú èrò bẹ́ẹ̀?

      Ó dára láti mọ̀ pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ kan wà lásìkò tí kíkọ Bíbélì ń lọ lọ́wọ́, tí wọ́n ní ìrònú tó gbòdì gan-an nípa ìgbésí ayé. Ìṣòro kan nínú ìdílé kó Rèbékà, aya Ísákì baba ńlá náà sí ìbànújẹ́ nígbà kan débi tó fi sọ pé: “Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí.” (Jẹ́nẹ́sísì 27:46) Jóòbù, tó pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀, àlááfíà rẹ̀, ọrọ̀ rẹ̀, àti ipò rẹ̀ láwùjọ, sọ pé: “Dájúdájú, ọkàn mi kórìíra ìgbésí ayé mi tẹ̀gbintẹ̀gbin.” (Jóòbù 10:1) Mósè ké pe Ọlọ́run nígbà kan rí pé: “Jọ̀wọ́ kúkú pa mí dànù.” (Númérì 11:15) Èlíjà, tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run sọ nígbà kan pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Wàyí o, Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò.” (1 Àwọn Ọba 19:4) Bẹ́ẹ̀ sì ni wòlíì Jónà sọ léraléra pé: “Kí n kú dànù sàn ju kí n wà láàyè.”—Jónà 4:8.

      Ǹjẹ́ Jèhófà bínú sí àwọn èèyàn náà pé nǹkan rí báyìí lára wọn? Ó tì o. Àní ó tiẹ̀ tún pa àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ mọ́ sínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì láti kíyè sí i pé, kò sí ọ̀kankan nínú àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí tó jẹ́ kí bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn sún wọn lọ gbẹ̀mí ara wọn. Jèhófà kà wọ́n sí; ó fẹ́ kí wọ́n wà láàyè. Ohun kan tó jẹ́ òótọ́ ni pé, ìwàláàyè àwọn ènìyàn búburú pàápàá jẹ Ọlọ́run lógún. Ó pàrọwà sí wọn pé kí wọ́n yí ọ̀nà wọn padà kí wọ́n sì “máa wà láàyè nìṣó.” (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Mélòómélòó wá ló fẹ́ kí àwọn tó tún ń ṣàníyàn láti rí ojú rere rẹ̀ wà láàyè!

      Ọlọ́run ti pèsè ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀, ìjọ Kristẹni, Bíbélì, àti àǹfààní láti gbàdúrà. Ọ̀nà láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ yìí, ìyẹn nípasẹ̀ àdúrà, kì í dí nígbà kankan. Ọlọ́run lè tẹ́tí sí gbogbo àwọn tó bá tọ̀ ọ́ wá, tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti òótọ́ inú. “Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.”—Hébérù 4:16.

      [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

      Ṣé O Ní Ẹnì Kan Tó Ti Fọwọ́ Ara Rẹ̀ Para Rẹ̀?

      Nígbà tí ẹnì kan bá fọwọ́ ara rẹ̀ para rẹ̀, ìrònú tó máa ń kó ẹbí àti ọ̀rẹ́ sí kì í ṣe kékeré rárá. Ọ̀pọ̀ ló máa ń dá ara wọn lẹ́bi fún ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà. Wọ́n á máa sọ àwọn nǹkan bíi: ‘Ká ní mi ò kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ bọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn,’ ‘Ká ní mi ò sọ́ ọ̀rọ̀ tí mo sọ lásìkò yẹn ni,’ ‘Ká ní mo mọ̀ kí n ti ṣe nǹkankan láti ràn án lọ́wọ́.’ Wọ́n á wá máa kìka àbámọ̀ bọnu pé, ‘Ká ní mo ti ṣegbá ni, ká ní mo ti ṣàwo ni, èèyàn mi yìí ì bá máà kú.’ Àmọ́, ṣé ó bójú mu kó o máa dá ara rẹ lẹ́bi nítorí ẹni tó fọwọ́ ara rẹ̀ para rẹ̀?

      Rántí o, ìgbà tí ìfọwọ́-ara-ẹni-para-ẹni bá ti ṣẹlẹ̀ tán lèèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń ronú nípa àwọn àmì tó rí. Kó tóó ṣẹlẹ̀, kì í rọrùn láti rí àwọn àmì yẹn. Bíbélì sọ pé: “Àyà mọ ikorò ara rẹ̀; ko si alejo kan tii ṣe alábapin ayọ̀ rẹ̀.” (Òwe 14:10, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Nígbà mìíràn, kò tiẹ̀ ṣeé ṣe rárá ni láti mọ ohun tí ẹlòmíràn ń rò tàbí tó ń bá yí. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ń gbèrò àti pa ara wọn ni kì í lè ṣàlàyé ohun tó wà nínú wọn lọ́hùn-ún fún àwọn ẹlòmíràn, kódà fáwọn ẹbí wọn tó sún mọ́ wọn jù lọ pàápàá.

      Ìwé kan tó ń jẹ́ Giving Sorrow Words sọ nípa àwọn àmì tó lè fi hàn pé ẹnì kan fẹ́ láti pa ara rẹ̀, ó sọ pé: “Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti mọ irú àwọn àmì bẹ́ẹ̀.” Ìwé yìí kan náà tún sọ pé, ká tiẹ̀ ní o rí àwọn àmì kan, ìyẹn kò fi dandan túmọ̀ sí pé o lè dá ìpara ẹni náà dúró kó má ṣẹlẹ̀. Dípò tí wàá fi máa dára rẹ lóró, o lè rí ìtùnú nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ọlọgbọ́n ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Èèyàn rẹ yìí ò sí níbì kankan tó ti ń joró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn tó kó wàhálà bá ọpọlọ rẹ̀, èyí tó mú kó lọ fọwọ́ ara rẹ̀ pa ara rẹ̀ ti dópin. Kò sí nínú ìrora rárá; ńṣe ló ń sinmi.

      Ohun tó máa dára jù lọ báyìí ni pé kó o gbájú mọ́ àlááfíà àwọn tó kù láàyè àti ti ìwọ fúnra rẹ̀. Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é” nígbà tó o ṣì wà láàyè. (Oníwàásù 9:10) Fọkàn balẹ̀ pé ìrètí ìwàláàyè ọjọ́ iwájú àwọn tó pa ara wọn wà lọ́wọ́ Jèhófà, “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́ríńtì 1:3.a

      [Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Wàá rí èrò tó tọ́ nípa ìrètí ọjọ́ iwájú tó wà fáwọn tó fọwọ́ ara wọn pa ara wọn nínú àpilẹ̀kọ náà “Oju Ìwoye Bíbélì: Ipara Ẹni—Ajinde Nkọ?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti March 8, 1991.

      [Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

      Wá ẹnì kan bá sọ̀rọ̀

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

      Ìwàláàyè rẹ̀ ṣe pàtàkì lójú àwọn ẹlòmíràn

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́