-
Ìgbà Wo Ló Dàṣejù?Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
-
-
ORÍ 4
Ìgbà Wo Ló Dàṣejù?
Òótọ́ àbí irọ́ . . .
Kò sígbà tó dáa káwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà fọwọ́ kanra wọn.
□ Òótọ́
□ Irọ́
Báwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ò bá ní ìbálòpọ̀, wọ́n ṣì lè jẹ̀bi àgbèrè.
□ Òótọ́
□ Irọ́
Báwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ò bá tíì máa fẹnu kora wọn lẹ́nu, kí wọ́n sì máa lọ́ mọ́ra, wọn ò lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú.
□ Òótọ́
□ Irọ́
KÒ SÍ àníàní pé o lè ti máa da ọ̀rọ̀ yìí rò. Ó ṣe tán, téèyàn bá ti yófẹ̀ẹ́, ó máa ṣòro láti mọ̀ bóyá ọ̀nà téèyàn gbà ń fìfẹ́ hàn sónítọ̀hún ti dàṣejù. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí àwọn gbólóhùn mẹ́ta tó wà lókè yẹn, ká sì wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè náà “Ìgbà wo ló dàṣejù?”
● Kò sígbà tó dáa káwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà fọwọ́ kanra wọn.
Irọ́. Bíbélì ò sọ pé kéèyàn má fìfẹ́ hàn sẹ́ni téèyàn nífẹ̀ẹ́, bí ò bá ṣáà ti ní ìwàkiwà nínú. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọmọbìnrin ará Ṣúnémù kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ṣúlámáítì àti ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn kan tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà. Wọn ò hùwà tí kò tọ́ nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra wọn sọ́nà. Síbẹ̀, ó láwọn ọ̀nà kan tí wọ́n gbà fìfẹ́ hàn síra wọn kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. (Orin Sólómọ́nì 1:2; 2:6; 8:5) Lónìí pẹ̀lú, àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà tí wọ́n sì ní in lọ́kàn láti ṣègbéyàwó lè ronú pé ó yẹ káwọn máa fìfẹ́ hàn síra àwọn láwọn ọ̀nà kan tí ò la ìṣekúṣe lọ.a
Àmọ́ ṣá o, àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gan-an. Fífẹnu konu, lílọ́ mọ́ra tàbí ṣíṣe ohunkóhun tó lè ru ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ sókè lè yọrí sí àgbèrè. Ó rọrùn fáwọn tó ní in lọ́kàn láti fẹ́ra wọn sílé pàápàá láti hùwà pálapàla torí pé ó máa ń ṣòro láti wà lójúfò.—Kólósè 3:5.
● Báwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ò bá ní ìbálòpọ̀, wọ́n ṣì lè jẹ̀bi àgbèrè.
Òótọ́. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àgbèrè,” ìyẹn por·neiʹa, pín sí apá tó pọ̀. Ó kan onírúurú ìbálòpọ̀ téèyàn bá ṣe pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀, ó sì ní nǹkan ṣe pẹ̀lú lílo ẹ̀yà ìbímọ nílòkulò. Nítorí náà, kì í ṣe ìbálòpọ̀ nìkan ni àgbèrè. Béèyàn bá ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, téèyàn bá fẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, tàbí téèyàn ń gba ihò ìdí bá ẹlòmíì lò pọ̀, àgbèrè náà ni.
Yàtọ̀ síyẹn, àgbèrè nìkan kọ́ ni Bíbélì sọ pé kò dáa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn iṣẹ́ ti ara fara hàn kedere, àwọn sì ni àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu.” Ó wá fi kún un pé: “Àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—Gálátíà 5:19-21.
Kí ni “ìwà àìmọ́”? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ìwà àìmọ́ túmọ̀ sí ohunkóhun tó lè sọ èèyàn di aláìmọ́, ì bá à jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ìwà. Ó dájú pé ìwà àìmọ́ ni tí ọwọ́ ẹnì kan bá ń rìn gbéregbère lábẹ́ aṣọ ẹlòmíì, tó bọ́ aṣọ onítọ̀hún, tàbí tó ń fọwọ́ pa àwọn ẹ̀yà ara tó wà lábẹ́ aṣọ, irú bí ọmú. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló lè fọwọ́ pa ọmú ara wọn.—Òwe 5:18, 19.
Àwọn ọ̀dọ́ kan tiẹ̀ máa ń fi àìnítìjú hùwà tí ò bá ìlànà òdodo Ọlọ́run mu. Wọ́n máa ń mọ̀ọ́mọ̀ ti àṣejù bọ̀ ọ́, tàbí kí wọ́n máa kó àfẹ́sọ́nà jọ kí wọ́n lè máa hùwà àìmọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn. Àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ lè jẹ̀bi ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “ìwà àìníjàánu.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìwà àìníjàánu” tún túmọ̀ sí ‘àṣerégèé, àṣejù, àfojúdi, fífi ìfẹ́ hàn láìkó ara ẹni níjàánu.’ Láìsí àníàní, o ò ní fẹ́ “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere” nípa jíjẹ́ kí “ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo” wọ̀ ẹ́ lẹ́wù.—Éfésù 4:17-19.
● Báwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ò bá tíì máa fẹnu kora wọn lẹ́nu, kí wọ́n sì máa lọ́ mọ́ra, wọn ò lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú.
Irọ́. Àwọn kan lè máa rò pé fífìfẹ́ hàn lọ́nà àìtọ́ ló máa ń jẹ́ káàárín àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà gún, àmọ́ ńṣe ló máa jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ra wọn nílẹ̀, wọn ò sì ní fọkàn tán ara wọn mọ́. Ronú lórí ìrírí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Laura. Ó ní: “Lọ́jọ́ kan àfẹ́sọ́nà mi wá sílé wa nígbà tí mọ́mì mi ò sí nílé, mo rò pé kó kàn wo tẹlifíṣọ̀n tán kó dẹ̀ máa lọ ni. Nígbà tó yá ó dì mí lọ́wọ́ mú. Àmọ́, kí n tó mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ pa mí lára. Ẹ̀rù ń bà mí láti sọ fún un pé kó fi mí sílẹ̀, torí ó lè bínú jáde.”
Kí lo rò? Ṣé àfẹ́sọ́nà Laura fẹ́ràn ẹ̀ ni, àbí ó kàn fẹ́ tẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn? Ṣé ẹni tó fẹ́ jẹ́ kó o hùwà àìmọ́ nífẹ̀ẹ́ ẹ lóòótọ́?
Bí ọmọkùnrin kan bá fòòró ọmọbìnrin kan débi tí ọmọbìnrin náà fi pa ẹ̀kọ́ Kristẹni tó ti kọ́ tì, tó sì ba ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ jẹ́, ọmọkùnrin yẹn ti tẹ òfin Ọlọ́run lójú, kò sì sí ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ ọmọbìnrin náà dénú. Bí ọmọbìnrin kan bá sì gbàgbàkugbà láyè, ńṣe ló tara ẹ̀ lọ́pọ̀. Èyí tó tún burú jù níbẹ̀ ni pé ó ti hùwà àìmọ́, ó tiẹ̀ lè ti jẹ̀bi àgbèrè pàápàá.b—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
Ẹ Mọ̀gbà Tí Àṣejù Wọ̀ Ọ́
Bó o bá ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́, báwo lo ṣe lè sá fún fífi ìfẹ́ hàn lọ́nà tí kò tọ́? Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé kẹ́ ẹ mọ̀gbà tí àṣejù wọ̀ ọ́. Òwe 13:10 sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” Nítorí náà, bá àfẹ́sọ́nà rẹ jíròrò àwọn ọ̀nà tó tọ́ téèyàn lè gbà fìfẹ́ hàn. Bẹ́ ẹ bá lọ dúró dìgbà tára yín ti wà lọ́nà kẹ́ ẹ tó pinnu ìgbà táṣejù wọ̀ ọ́, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tẹ́ ẹ dúró dìgbà tí iná di ńlá kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í bomi pa á.
Ká sòótọ́, irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ kì í rọrùn, ó tiẹ̀ máa ń tini lójú, pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra yín ni. Àmọ́, bẹ́ ẹ bá tètè pinnu ìgbà táṣejù wọ̀ ọ́, kò ní jẹ́ káwọn ìṣòro tó máa ju agbára yín lọ yọjú tó bá yá. Bẹ́ ẹ bá pinnu ìgbà tó lè dàṣejù, ó máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ bẹ́ ẹ bá ti fẹ́ kọjá àyè yín. Yàtọ̀ síyẹn, pé ẹ tiẹ̀ gbọ́n débi tẹ́ ẹ fi lè jíròrò irú ọ̀rọ̀ yẹn lè jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ bóyá àjọṣe yín á yọrí sí rere. Kódà, ìkóra-ẹni-níjàánu, sùúrù àti àìmọ-tara-ẹni-nìkan máa ń jẹ́ kéèyàn gbádùn ìbálòpọ̀ nínú ìgbéyàwó.—1 Kọ́ríńtì 7:3, 4.
Ká sòótọ́, kò rọrùn láti máa fàwọn ìlànà Ọlọ́run ṣèwà hù. Ṣùgbọ́n o lè gbẹ́kẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà. Ó ṣáà sọ nínú Aísáyà 48:17, pé òun ni “Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” Mọ̀ dájú pé Jèhófà ní ire ẹ lọ́kàn!
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 24 NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Pé o ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí ò sọ pé o kì í ṣèèyàn gidi. Kódà ìwọ gan-an lo gbọ́n jù. Kà nípa rẹ̀ fúnra rẹ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láwọn ibì kan lágbàáyé, kì í ṣe ìwà ọmọlúwàbí táwọn méjì tí ò tíì ṣègbéyàwó bá ń fìfẹ́ hàn síra wọn ní gbangba, kódà ìwà ìdọ̀tí ni. Àwa Kristẹni sì gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, ká má lọ máwọn ẹlòmíì kọsẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 6:3.
b Tọkùnrin tobìnrin lọ̀rọ̀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí bá wí.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Ìfẹ́ . . . kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.
ÌMỌ̀RÀN
Bíwọ àti àfẹ́sọ́nà ẹ bá fẹ́ jáde, ẹ máa lọ síbi táwọn èèyàn wà, tàbí kẹ́ ẹ máa rí i dájú pé ẹnì kan sìn yín lọ. Ẹ má máa dá wà nínú mọ́tò, nínú yàrá, tàbí nínú ilé àdáni.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Tó o bá ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́, ẹ gbọ́dọ̀ jọ jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tó kàn yín gbọ̀ngbọ̀n. Ṣùgbọ́n ẹ ní láti rántí pé ìwà àìmọ́ ni sísọ àwọn ọ̀rọ̀ àsọrégèé tó ń ru ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ sókè, kódà kó jẹ́ lórí fóònù tàbí fífi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí ẹ̀rọ alágbèéká.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Mo lè sá fún ìṣekúṣe nípa
Bẹ́ni tí mò ń fẹ́ bá fẹ́ mú mi hùwà àìmọ́, màá
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Ìgbà wo lo rò pé ìfararora pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ máa dàṣejù? ․․․․․
● Ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín àgbèrè, ìwà àìmọ́ àti ìwà àìníjàánu. ․․․․․
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 46]
Èmi àti àfẹ́sọ́nà mi ti ka àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè pa ìwà títọ́ mọ́. A sì mọrírì bí wọ́n ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.’’—Leticia
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 44]
Bá A Bá Ti Ṣàṣejù Ńkọ́?
Bẹ́ ẹ bá ti ṣèṣekúṣe ńkọ́? Ẹ má ṣe rò pé ẹ lè dá yanjú ọ̀rọ̀ náà láàárín ara yín o! Ọ̀dọ́mọbìnrin kan sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà pé, ‘Ràn wá lọ́wọ́ ká má ṣe dán irú ẹ̀ wò mọ́.’” Ó fi kún un pé: “Ó máa ń ṣiṣẹ́ láwọn ìgbà kan, àmọ́ kì í ṣiṣẹ́ nígbà míì.” Torí náà, ẹ sọ fáwọn òbí yín. Bíbélì náà tún fún wa nímọ̀ràn àtàtà yìí: “Pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ.” (Jákọ́bù 5:14) Àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí lè gbà yín nímọ̀ràn, wọ́n sì lè fìbáwí tọ́ yín sọ́nà kẹ́ ẹ lè pa dà bá Ọlọ́run rẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 47]
Kò dájú pé wàá dúró dìgbà tí iná bá di ńlá kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í bomi pa á. Kí nìdí tẹ́ ẹ fi ní láti dúró dìgbà tára yín bá wà lọ́nà kẹ́ ẹ tó ṣòfin ìwà híhù?
-
-
Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Kí N Tó Ṣègbéyàwó?Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
-
-
ORÍ 5
Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Kí N Tó Ṣègbéyàwó?
“Ó máa ń ṣe mí bíi kí ọkùnrin bá mi sùn.”—Kelly.
“Bí mi ò ṣe tíì bá obìnrin sùn rí máa ń ṣe mí bákan.”—Jordon.
“ṢÉ ÌWỌ náà ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí?” Ìbéèrè yẹn lè ṣe ẹ́ bákan! Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi téèyàn máa dé láyé yìí tí wọn ò ní fojú ọ̀dẹ̀ tí ò rọ́ọ̀ọ́kán wo ọ̀dọ́ tí ò bá tíì ní ìbálòpọ̀ rí. Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ fi sábà máa ń ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó pé ọmọ ogún ọdún!
Bó Ṣe Ń Wù Mí Ṣe Làwọn Ojúgbà Mi Náà Ń Tì Mí Sí I
Bó o bá jẹ́ Kristẹni, ìwọ náà mọ̀ pé Bíbélì ní kó o “ta kété sí àgbèrè.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Àmọ́ ó lè má rọrùn fún ẹ láti kápá wíwù tó ń wù ẹ́ láti ní ìbálòpọ̀. Paul sọ pé: “Nígbà míì, màá kàn rí i pé mò ń ronú nípa ìbálòpọ̀ ṣáá, láìnídìí.” Fọkàn ẹ balẹ̀, bó ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn náà nìyẹn.
Àmọ́ ṣá o, ó máa ń káàyàn lára gan-an bí wọ́n bá ń fèèyàn ṣe yẹ̀yẹ́ léraléra, tí wọn ò sì yé sọ̀rọ̀ ẹ̀ torí pé kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí! Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ṣe báwọn ẹgbẹ́ ẹ bá sọ fún ẹ pé, ó dìgbà tó o bá ní ìbálòpọ̀ kó o tó lè pera ẹ ní ọkùnrin tàbí obìnrin? Ellen sọ pé: “Àwọn ojúgbà ẹ á jẹ́ kó o máa wo ìbálòpọ̀ bí ohun tí kò burú, tó máa ń múnú èèyàn dùn. Bó ò bá tíì máa ṣèṣekúṣe, ńṣe ni wọ́n á máa fojú ẹni tí ò bẹ́gbẹ́ mu wò ẹ́.”
Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà nípa níní ìbálòpọ̀ kéèyàn tó ṣègbéyàwó táwọn ojúgbà ẹ lè má sọ fún ẹ. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ọmọkùnrin tóun àti Maria jọ ń fẹ́ra bá a sùn tán, Maria sọ pé: “Ojú tì mí wẹ̀lẹ̀mù lẹ́yìn ìgbà yẹn. Mo sì kórìíra ara mí àti bọ̀bọ́ yẹn.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni ò mọ̀ pé ibi tọ́rọ̀ sábà máa ń já sí nìyẹn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé níní ìbálòpọ̀ kéèyàn tó ṣègbéyàwó sábà máa ń mú kéèyàn ki ìka àbámọ̀ bẹnu, ìbànújẹ́ kékeré sì kọ́ ló máa ń yọrí sí!
Síbẹ̀, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Shanda béèrè pé, “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fi ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ nígbà tó mọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n ní ìbálòpọ̀ àyàfi bí wọ́n bá ti ṣègbéyàwó?” Ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání nìyẹn. Àmọ́, ronú lórí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ná:
Ṣé ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ nìkan lohun tó máa ń wù ẹ́ gan-an? Rárá o. Jèhófà Ọlọ́run ti dá agbára tó máa ń jẹ́ kí oríṣiríṣi nǹkan wu èèyàn mọ́ ẹ.
Ṣé gbogbo nǹkan tó bá ti ń wù ẹ́ náà lo gbọ́dọ̀ máa ṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó bá ti wá sí ẹ lọ́kàn? Rárá o, ìdí ni pé Ọlọ́run dá ẹ lọ́nà tí wàá fi lè máa darí ara ẹ.
Kí nìyẹn fi kọ́ ẹ? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn nǹkan kan wà tí ò lè ṣe kó má wù ẹ́, àmọ́ o lè darí ara rẹ láti mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Àti pé, tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tó bá ti ń wùùyàn láti ní ìbálòpọ̀ náà lèèyàn máa ń tẹra ẹ̀ lọ́rùn, ńṣe lèèyàn máa dà bí ẹni tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà tínú bá ń bí i ló máa ń lu àwọn èèyàn, ìwà òpònú gbáà nìyẹn.
Òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé, Ọlọ́run ò fún wa ní ẹ̀yà ìbímọ torí ká lè máa fi ṣèṣekúṣe. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.” (1 Tẹsalóníkà 4:4) Bí “ìgbà nínífẹ̀ẹ́ àti ìgbà kíkórìíra” ṣe wà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà tó yẹ kéèyàn ní ìbálòpọ̀ àti ìgbà tí kò yẹ kéèyàn ní in wà. (Oníwàásù 3:1-8) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìwọ fúnra ẹ lo lè ṣèkáwọ́ ara ẹ!
Àmọ́, kí lo lè ṣe, bí ẹnì kan bá fẹ́ gbọ́ tẹnu ẹ, tó wá sọ bí ẹni tọ́rọ̀ yà lẹ́nu pé, “Ṣóòótọ́ ni pé o ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí?” Máà jẹ́ kí wọ́n ko ẹ láyà jẹ. Bó bá jẹ́ pé ẹni yẹn kàn fẹ́ wọ́ ẹ nílẹ̀ lásán ni, o lè fèsì pé: “Hẹn, mi ò tíì ṣe é rí, ojú ò sì tì mí láti sọ ọ́!” O sì tún lè sọ pé, “Èmi ni mo mọ̀yẹn lọ́kàn ara mi, mi ò kì ń sọ ọ́ síta.”a (Òwe 26:4; Kólósè 4:6) Bó o bá sì wá rí i pé ó yẹ kẹ́ni yẹn mọ púpọ̀ sí i lóòótọ́, o lè ṣàlàyé àwọn ohun tó o mọ̀ látinú Bíbélì, tó mú kó o pinnu láti má ṣe ní ìbálòpọ̀, àyàfi bó o bá ṣègbéyàwó.
Kí lo tún lè sọ fẹ́ni tó bá bi ẹ́, torí àtigbọ́ tẹnu ẹ, pé: “Ṣó ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí lóòótọ́ ni?” Kọ èsì tó o tún lè fún un sórí ìlà yìí.
․․․․․
Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye
Irú ojú wo ni Ọlọ́run fi máa ń wo àwọn tó bá ń bára wọn sùn láì tíì ṣègbéyàwó? Ó dáa, jẹ́ ká sọ pe o ra ẹ̀bùn kan fún ọ̀rẹ́ rẹ kan. Àmọ́, ọ̀rẹ́ rẹ yẹn ò dúró kó o fún òun lẹ́bùn yẹn tó fi ṣí i wò! Ṣéyẹn ò ní bí ẹ nínú? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wo bó ṣe máa rí lójú Ọlọrun, bó o bá ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó. Ọlọ́run fẹ́ kó o dúró dìgbà tó o bá ṣègbéyàwó kó o tó gbádùn ẹ̀bùn ìbálòpọ̀ tó fún ẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
Kí ló wá yẹ kó o ṣe nípa ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ tó máa ń wá sí ẹ lọ́kàn? Ńṣe ni wàá kọ́ bó ò ṣe ní jẹ́ kírú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ mú ẹ ṣe ohun tí kò tọ́! Agbára ẹ sì gbé e láti ṣe bẹ́ẹ̀! Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹ̀mí rẹ̀ á fún ẹ lókun láti máa kóra ẹ níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) Má gbàgbé pé, Jèhófà “kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.” (Sáàmù 84:11) Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Gordon sọ pé: “Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí wá sí mi lọ́kàn pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ní ìbálòpọ̀ láì tíì ṣègbéyàwó, mo ronú lórí bó ṣe máa mú kí n pàdánù ojúure Jèhófà, mo wá rí i pé kò sóhun tí mo lè fi wé àjọṣe tó wà láàárín èmi àti Jèhófà.”
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò sóhun tó burú nínú ẹ̀ béèyàn ò bá ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó. Ìṣekúṣe ló burú jáì, kò yẹ ọmọlúwàbí rárá, àkóbá tó sì ń ṣe fáwọn èèyàn ò mọ níwọ̀n. Torí náà, má ṣe jẹ́ kí wọ́n firọ́ tàn ẹ́ jẹ, kó o wá lọ máa ronú pé ìlànà Bíbélì tó ò ń tẹ̀ lé ni ò jẹ́ kó o mọ ohun tó ò ń ṣe. Bó o bá kọ̀ láti ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó, o ò ní í kó àrùn, ọkàn ẹ ò sì ní máa dá ẹ lẹ́bi. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wàá ní àjọṣe tó dán mọ́ràn pẹ̀lú Ọlọ́run.
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 23, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a O ò rí i pé, Jésù pàápàá ò sọ̀rọ̀ nígbà tí Hẹ́rọ́dù béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. (Lúùkù 23:8, 9) Ohun tó máa ń dáa jù ni pé kéèyàn má fèsì bí wọ́n bá bi í ní ìbéèrè tí kò mọ́gbọ́n dání.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Bí ẹnikẹ́ni bá ti pinnu . . . nínú ọkàn-àyà ara rẹ̀, láti pa ipò wúńdíá tirẹ̀ mọ́, òun yóò ṣe dáadáa.”—1 Kọ́ríńtì 7:37.
ÌMỌ̀RÀN
Má ṣe bá àwọn tí kò níwà ọmọlúwàbí rìn, àní bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn kan náà lẹ jọ ń ṣe.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ìgbéyàwó ò ní kí ẹni tó bá ti sọ ìṣekúṣe dàṣà tẹ́lẹ̀ yí pa dà. Àmọ́ àwọn tó bá ti mọ́ lára láti máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run kí wọ́n tó ṣègbéyàwó, kì í sábà yẹ àdéhùn ìgbéyàwó wọn.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Kí n má bàa ní ìbálòpọ̀ kí n tó ṣègbéyàwó, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․
Báwọn tí mò ń bá rìn ò bá fẹ́ jẹ́ kí n ṣe ohun tí mo ti pinnu yìí, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí lo rò pé ó fà á táwọn kan fi máa ń fàwọn tí kò bá tíì ní ìbálòpọ̀ rí ṣe yẹ̀yẹ́?
● Kí ló lè mú kó ṣòro láti wà láìní ìbálòpọ̀?
● Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn má tíì ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó?
● Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé fún àbúrò ẹ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn má tíì ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 51]
“Bí mo bá ti ń rántí pé ‘kò sí alágbèrè kankan tàbí aláìmọ́ tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú ìjọba Ọlọ́run,’ ńṣe ni mo máa ń gbọ́kàn kúrò lórí ìbálòpọ̀.” (Éfésù 5:5)—Lydia
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 49]
Tí mo kọ èrò mi sí
Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Gan-an?
Àwọn ojúgbà ẹ, àwọn eléré àtàwọn olórin kì í sábà sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, tó bá kan àwọn àkóbá tí ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó máa ń fà. Wo àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta yìí, kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí gan-an? ․․․․․
● Ọmọléèwé ẹ kan ń ṣakọ pé àìmọye ọmọbìnrin lòun ti bá sùn. Ó ní àwọn jọ gbádùn ara àwọn ni, nǹkan kan ò sì ṣe ẹnì kankan nínú àwọn. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sóun àtàwọn ọmọbìnrin yẹn gan-an? ․․․․․
● Nígbà tí wọ́n máa parí fíìmù kan, àwọn ọ̀dọ́ méjì tí kò tó ọmọ ogún ọdún bára wọn sùn láti fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Tó bá jẹ́ pé ojú ayé ni, kí ló lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ gan-an? ․․․․․
● O rí bọ̀bọ́ kan tó dáa lọ́mọkùnrin, ó sì ní kó o jẹ́ kóun bá ẹ sùn. Ó ní kò sẹ́ni táá mọ̀. Bó o bá gbà fún un, tíwọ náà sì ṣẹnu mẹ́rẹ́n, kí ló máa ṣẹlẹ̀ gan-an? ․․․․․
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 54]
Bó o bá ń ní ìbálòpọ̀ láì tíì ṣègbéyàwó, ńṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń ṣí ẹ̀bùn tí wọn ò tíì fún ẹ wò
-