-
Ìbànújẹ́ Ńlá Ni Ikú Èèyàn Ẹni Máa Ń FàJí!—2018 | No. 3
-
-
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀
Ìbànújẹ́ Ńlá Ni Ikú Èèyàn Ẹni Máa ń fà
“Lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínlógójì [39] tí èmi àti Sophiaa ti ṣègbéyàwó, àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ kan gbẹ̀mí ẹ̀. Tẹbí-tọ̀rẹ́ dúró tì mí, mo sì tún ń wá nǹkan ṣe kó má bàa di pé mo kàn jókòó gẹlẹtẹ. Àmọ́, odindi ọdún kan ni ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára fi dà mí láàmú. Ìbànújẹ́ sorí mi kodò débi pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ara mi kì í balẹ̀. Kódà ní báyìí tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọdún mẹ́ta tó ti kú, inú mi máa ń ṣàdédé bà jẹ́ gan-an lẹ́kọ̀ọ̀kan.”—Kostas.
Ǹjẹ́ èèyàn ẹ kan ti kú rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kostas yìí ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà. Bóyá ni ohun míì wà tó ń fa ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára bí ikú ọkọ, aya, ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ ẹni. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń ṣèwádìí nípa ìrora táwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń ní gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé The American Journal of Psychiatry sọ pé “kò sóhun míì tó ń bani nínú jẹ́ tó ikú èèyàn ẹni.” Tí ìbànújẹ́ tó lagbára bá bá ẹnì kan tí èèyàn rẹ̀ kú, onítọ̀hún lè máa ronú pé: ‘Ṣé bí nǹkan á ṣe máa rí lọ rèé? Ṣé mo ṣì lè láyọ̀? Báwo ni mo ṣe lè rí ìtura?’
A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú Jí! yìí. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó bá jẹ́ pé èèyàn rẹ kan ṣẹ̀ṣẹ̀ kú lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àwọn àpilẹkọ tó kù máa sọ àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.
A gbà gbọ́ pé ohun tá a máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ báyìí á tu àwọn tó bá ń ṣọ̀fọ̀ nínú, á sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè rí ìtura.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí.
-
-
Àwọn Nǹkan Tó Lè Ṣẹlẹ̀Jí!—2018 | No. 3
-
-
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀
Àwọn Nǹkan Tó Lè Ṣẹlẹ̀
Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé oríṣiríṣi ìpele ni ọ̀rọ̀ ṣíṣọ̀fọ̀ pín sí, ọ̀nà tó yàtọ̀ síra sì làwọn èèyàn máa ń gbà ṣòfọ̀. Àmọ́, ṣé ìyàtọ̀ tó wà nínú báwọn èèyàn ṣe ń ṣọ̀fọ̀ yìí wá fi hàn pé inú àwọn kan kì í bà jẹ́ púpọ̀ tí èèyàn wọn bá kú, àbí ńṣe ni wọ́n kàn ń pa ìbànújẹ́ náà mọ́ra? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ni pé tí ẹnì kan bá fi bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ hàn nígbà tó ń ṣọ̀fọ̀, ó lè jẹ́ kí ara ẹ̀ tètè balẹ̀, àmọ́ kò sí ọ̀nà pàtó kan tá a lè sọ pé ó dára jù lọ láti gbà ṣọ̀fọ̀. Àwọn nǹkan tó máa ń fa ìyàtọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà ni àṣà ìbílẹ̀, irú ẹni tí èèyàn jẹ́, ohun tójú èèyàn ti rí àtàwọn nǹkan tó tan mọ́ ikú ẹnì kan.
ÀWỌN NǸKAN WO LÓ LÈ ṢẸLẸ̀?
Àwọn tí èèyàn wọn kú lè má mọ àwọn nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú èèyàn wọn. Àmọ́, àwọn ìmọ̀lára àti ìṣòro kan wà tó sábà máa ń yọjú, tí èèyàn sì lè retí pé ó máa ṣẹlẹ̀. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó tẹ̀ lé e yìí:
Nǹkan lè máa tojú súni. Lára nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ ni ẹkún àsun-ùn-dá, kí àárò ẹni tó ti kú máa sọni gan-an, kí ìṣesí èèyàn máa ṣàdédé yí pa dà. Èèyàn tiẹ̀ lè máa rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí kó lá àwọn àlá tó máa ń dà bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Nígbà míì sì rèé, àyà rẹ á kọ́kọ́ já, wàá wá sọ pé kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Tiina rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tí ọkọ ẹ̀ Timo kú ikú òjijì. Ó ní: “Kò kọ́kọ́ ṣe mí bíi pé nǹkan kan ṣẹlẹ̀. Ńṣe ni ojú mi dá wáí, mi ò tiẹ̀ lè sunkún rárá. Gbogbo nǹkan wá tojú sú mi débi pé mi ò kì í lè mí dáadáa nígbà míì. Ńṣe ló dà bíi pé àlá ni mò ń lá.”
Àìbalẹ̀ ọkàn, ìbínú àti dídá ara ẹni lẹ́bi. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ivan sọ pé: “Láwọn àkókò kan lẹ́yìn tí ọmọ wa Eric tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún [24] kú. Inú bí èmi àti Yolanda ìyàwó mi gan-an! Ẹnu yà wá gan-an, torí pé a mọ̀ pé a kì í ṣe oníbìínú ẹ̀dá. Nígbà tó yá, a tún bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ká ní a tún gbìyànjú díẹ̀ sí i ni bóyá ọmọ wa ò ní kú, bá a tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara wa lẹ́bi nìyẹn.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Alejandro náà dá ara rẹ̀ lẹ́bi lẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀ kú lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́-pípẹ́ kan, ó ní: “Ohun tó kọ́kọ́ wá sí mi lọ́kàn ni pé tí Ọlọ́run bá lè gbà kí n máa jìyà tó báyìí, á jẹ́ pé èèyàn burúkú ni mí. Bó tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dùn mí nìyẹn pé mò ń dá Ọlọ́run lẹ́bi fún ohun tó ṣẹlẹ̀.” Kostas tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú náà sọ pé: “Nígbà míì, inú á máa bí mi sí Sophia fún bó ṣe kú. Tó bá tún yá, màá bẹ̀rẹ̀ sí dá ara mi lẹ́bi pé mò ń ronú bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, kì í ṣe ẹ̀bi tiẹ̀ náà.”
Èròkérò. Èèyàn lè máa ronú lódìlódì nígbà míì tàbí kó máa ro nǹkan tí kò bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tí èèyàn ẹ̀ kú lè máa ronú pé òun lè gbọ́ ohùn ẹni tó ti kú náà, òun lè fọwọ́ kàn án tàbí pé òun lè rí i. Ó sì lè ṣòro fún un láti pọkàn pọ̀ tàbí láti rántí nǹkan. Tiina sọ pé: “Nígbà míì tí èmi àti ẹnì kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, màá kàn rí i pé ọkàn mi ò sí níbẹ̀ mọ́ rárá! Ńṣe ni ọkàn mi á máa ro tibí ro tọ̀hún nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ kí Timo tó kú. Ó máa ń tojú súni gan-an tí èèyàn ò bá lè pọkàn pọ̀.”
Èèyàn lè má fẹ́ dá sí ẹnikẹ́ni. Tẹ́nì kan bá ń ṣọ̀fọ̀ ikú èèyàn rẹ̀, ara onítọ̀hún lè má balẹ̀ tó bá wà láàárín àwọn èèyàn. Kostas sọ pé: “Tí mo bá wà láàárín àwọn tọkọtaya, mo máa ń rí ara mi bí ẹni tí kò wúlò. Tí mo bá tún wà láàárín àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya, mo máa ń rí i pé ọ̀rọ̀ wa ò jọra rárá.” Yolanda ìyàwó Ivan sọ pé: “Kì í rọrùn fún mi láti wà pẹ̀lú àwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro wọn, nígbà tó jẹ́ pé kékeré làwọn ìṣòro wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiwa! Bákan náà, táwọn kan bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ọmọ wọn ṣe ń ṣe dáadáa sí, mo máa ń bá wọn yọ̀ o, àmọ́ kì í rọrùn fún mi láti tẹ́tí sí wọn. Èmi àti ọkọ mi kúkú mọ̀ pé ọmọ wa ti kú, kò sì sóhun tá a lè ṣe sí i, àmọ́ a ò ṣe tán láti gbà bẹ́ẹ̀, ká sì fara balẹ̀.”
Àìlera. Àyípadà lè bá bó o ṣe ń jẹun, bó o ṣe tẹ̀wọ̀n tó àti bó o ṣe ń sùn tó. Aaron sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀, ó ní: “Mi ò kì í rí oorun sùn. Ó ti ní àkókò kan tí oorun máa ń dá lójú mi ní gbogbo òru, tí màá sì máa ronú nípa ikú bàbá mi.”
Alejandro rántí pé òun ò tiẹ̀ lè ṣàlàyé bó ṣe ń ṣe òun rárá, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni dókítà ti ṣàyẹ̀wò mi tí wọ́n sì sọ pé kò sóhun tó ń ṣe mí. Mo fura pé ẹ̀dùn ọkàn tó bá mi nítorí ikú ìyàwó mi ni ò jẹ́ kí n gbádùn ara mi.” Nígbà tó yá, ara ẹ̀ wá balẹ̀. Síbẹ̀ náà, ó bọ́gbọ́n mu bí Alejandro ṣe lọ rí dókítà. Ìdí ni pé tí èèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀, àwọn nǹkan tó ń gbógun ti àìsàn nínú ara lè má ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, ó sì lè ti àwọn àìsàn kan tó tí wà nínú ara tẹ́lẹ̀ jáde tàbí kí àìsàn tí kò ṣeni tẹ̀lẹ́ wá bẹ̀rẹ̀.
Ó lè ṣòro láti ṣe àwọn nǹkan tó pọn dandan. Ivan sọ pé: “Lẹ́yìn ikú Eric, ó pọn dandan pé ká sọ fún tẹbí-tọ̀rẹ́, tó fi mọ́ ọ̀gá àti onílé rẹ̀. Àwọn ìwé òfin kan tún wà tó yẹ ká fọwọ́ sí. Ó tún yẹ ká yẹ àwọn ẹrù Eric wò. Gbogbo nǹkan yìí ló sì gba pé kéèyàn pọkàn pọ̀, bẹ́ẹ̀ sì rèé ìrònú wa ò já geere lákòókò yẹn, ara wa ò le dáadáa, a sì tún ní ẹ̀dùn ọkàn.”
Àmọ́ àwọn míì wà tó jẹ́ pé ìgbà tí nǹkan máa ń le jù fún wọn ni tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ pé èèyàn wọn tó ti kú yẹn ló máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tiina nìyẹn. Ó sọ pé: “Timo ló máa ń bójú tó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ báǹkì àti iṣẹ́ wa. Àmọ́, ó ti wá di iṣẹ́ mi báyìí, ńṣe ni ìyẹn sì tún wá mú kí nǹkan túbọ̀ tojú sú mi. Ṣé mo lè ṣe gbogbo iṣẹ́ yìí láṣeyanjú ṣá?”
Tá a bá ronú nípa ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń báni tí èèyàn ẹni bá kú, bí ìrònú èèyàn ò ṣe ní já geere àti àárẹ̀ tó máa ń múni, a máa gbà lóòótọ́ pé àkókò tí kò bára dé gbáà ni àkókò ọ̀fọ̀. Ká sòótọ́, kò rọrùn rárá láti fara da ìbànújẹ́ ńlá tó máa ń báni tí èèyàn ẹni bá kú, àmọ́ tí èèyàn bá ti mọ àwọn nǹkan yìí tẹ́lẹ̀, ó lè mú káwọn tí èèyàn wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ kú lè fara dà á. Ó yẹ ká tún fi sọ́kàn pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń ní ìrírí gbogbo nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá ń ṣọ̀fọ̀. Bákan náà, ó lè tuni nínú láti mọ̀ pé kì í ṣe ohun tó ṣàjèjì tí èèyàn bá ní ẹ̀dùn ọ̀kan tó lágbára gan-an tí èèyàn ẹni bá kú.
ṢÉ MO ṢÌ LÈ LÁYỌ̀?
Ohun tó lè ṣẹlẹ̀: Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìbànújẹ́ ńlá tó máa ń báni tí èèyàn ẹni bá kú ṣì máa lọ sílẹ̀. Èyí ò túmọ̀ sí pé ẹ̀dùn ọkàn yẹn máa lọ pátápátá tàbí pé a máa gbàgbé èèyàn wa tó ti kú. Àmọ́, díẹ̀díẹ̀ ni ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára yẹn á máa lọ sílẹ̀. Irú ẹ̀dùn ọkàn bẹ́ẹ̀ tún lè pa dà wá láwọn ìgbà tá ò tiẹ̀ rò rárá tàbí kó jẹ́ láwọn àkókò ayẹyẹ ọdọọdún kan tá a máa ń ṣe pẹ̀lú èèyàn wa tó kú náà. Àmọ́, fún àwọn èèyàn tó pọ̀ jù, tó bá ti tó àkókò kan, wọ́n á ti gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn dé ìwọ̀n àyè kan, tí wọ́n á sì máa bá àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ nìṣó bíi ti tẹ́lẹ̀. Èyí sábà máa ń rí bẹ́ẹ̀ tí tẹbí-tọ̀rẹ́ bá ṣe àwọn nǹkan pàtàkì láti dúró ti ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ náà.
Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó? Fún àwọn kan, ó pẹ́ tán, oṣù bíi mélòó kan. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ó máa ń tó ọdún kan tàbí ọdún méjì kí wọ́n tó rí i pé ara àwọn ti wá ń balẹ̀. Ní ti àwọn míì, ọgbẹ́ ọkàn wọn ṣì máa ń wà síbẹ̀ fún àkókò gígùn.a Alejandro sọ pé: “Ó tó nǹkan bí ọdún mẹ́ta tí mo fi ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an.”
Máa ṣe sùúrù. Má ṣe kó ohun tó pọ̀ jù sọ́kàn, má sì ṣe ohun tó ju agbára ẹ lọ. Fi sọ́kàn pé ìbànújẹ́ tó máa ń báni tí èèyàn ẹni bá kú kì í wà bẹ́ẹ̀ títí ayé. Àmọ́, ṣé àwọn nǹkan kan wà tó o lè máa ṣe tó lè jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn ẹ lọ sílẹ̀, tí kò sì ní jẹ́ kó o ṣọ̀fọ̀ kọjá bó ṣe yẹ?
Kì í ṣe ohun tó ṣàjèjì tí èèyàn bá ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an tí èèyàn ẹni bá kú
a Àwọn èèyàn díẹ̀ kan wà tó jẹ́ pé ọgbẹ́ ọkàn wọn máa ń lágbára, ó sì máa ń pẹ́ gan-an débi tá a fi lè sọ pé ó ti kọjá bó ṣe yẹ. Ó ṣe pàtàkì pé kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ rí dókítà tó ń rí sí ìlera ọpọlọ, kí wọ́n lè gba ìtọ́jú tó yẹ.
-
-
Ohun Tó Lè Ran Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Lọ́wọ́Jí!—2018 | No. 3
-
-
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀
Ohun Tó Lè Ran Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Lọ́wọ́— Ohun Tó O Lè Ṣe
Tó o bá ṣe ìwádìí nípa ohun tó lè ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́, àìmọye àbá lo máa rí, wọ́n sì gbéṣẹ́ ju ara wọn lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó fà á ni pé, ọ̀nà tí kálukú ń gbà ṣọ̀fọ̀ yàtọ̀ síra. Ohun tó ran ẹnì kan lọ́wọ́ lè má ran ẹlòmíì lọ́wọ́.
Síbẹ̀, àwọn ìlànà pàtàkì kan wà tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ gan-an. Àwọn tó máa ń gba àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nímọ̀ràn máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà náà dáadáa, wọ́n jẹ́ ìlànà àtayébáyé tó wà nínú ìwé ọgbọ́n náà Bíbélì, ọ̀pọ̀ ló sì ti rí i pé àwọn ìlànà yẹn wúlò gan-an.
1: JẸ́ KÍ ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ ÀTÀWỌN Ọ̀RẸ́ RẸ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́
Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé èyí ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó lè ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o dá nìkan wà. O tiẹ̀ lè máa bínú sí àwọn tó fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa.
Má ṣe rò pé dandan ni káwọn èèyàn máa wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo, síbẹ̀ náà má ṣe lé àwọn èèyàn dà nù. Má gbàgbé pé o ṣì lè nílò ìrànlọ́wọ́ wọn tó bá yá. Fara balẹ̀ sọ ohun tó o fẹ́ káwọn èèyàn ṣe fún ẹ ní báyìí àti ohun tí o kò fẹ́.
Ronú dáadáa nípa ohun tó o nílò, kó o lè mọ ìgbà tó o fẹ́ káwọn èèyàn wà pẹ̀lú rẹ àti ìgbà tó o fẹ́ dá nìkan wà.
ÌLÀNÀ: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan . . . Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.”—Oníwàásù 4:9, 10.
2: Máa Jẹ Oúnjẹ Aṣaralóore, Kó O Sì Máa Ṣe Eré Ìdárayá
Tó o bá ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú àìfararọ tí ẹ̀dùn ọkàn máa ń mú wá. Máa jẹ oríṣiríṣi èso, ẹ̀fọ́ àtàwọn oúnjẹ tó ní èròjà purotéènì àmọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rá nínú.
Máa mu omi dáadáa, àtàwọn ohun mímu míì tó ń ṣara lóore.
Tí o kò bá lè jẹ oúnjẹ púpọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, kọ́kọ́ jẹ díẹ̀, tó bá tún yá kó o jẹ sí i. O tún lè ní kí dókítà rẹ sọ àwọn oògùn tó ní èròjà oúnjẹ nínú tó o lè lò.a
O lè máa rìn kánmọ́kánmọ́ káàkiri tàbí kó o ṣe àwọn eré ìdárayá míì, èyí á jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn ẹ fúyẹ́. Tó o bá ń ṣeré ìdárayá, ó lè jẹ́ kó o ráyè láti ronú nípa èèyàn rẹ tó kú tàbí kó jẹ́ kó o gbọ́kàn kúrò níbẹ̀.
ÌLÀNÀ: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.”—Éfésù 5:29.
3: MÁA SÙN DÁADÁA
Gbogbo wa ló yẹ ká máa sùn dáadáa, àmọ́ ní pàtàkì àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, torí pé ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń bá wọn máa ń mú kó túbọ̀ rẹ̀ wọ́n.
Má ṣe máa mu ọtí líle àti kọfí lámujù, torí pé wọ́n lè má jẹ́ kó o rí oorun sùn.
ÌLÀNÀ: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Òwe 4:6.
4: ṢE OHUN TÓ MÁA RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́
Jẹ́ kó yé ẹ pé bí kálukú ṣe ń ṣọ̀fọ̀ yàtọ̀ síra. Torí náà, ìwọ fúnra rẹ lo máa mọ ohun táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ jù lọ.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé táwọn bá fi ìmọ̀lara àwọn hàn síta, ó máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn fúyẹ́, àmọ́ ńṣe ni àwọn míì máa ń pa ẹ̀dùn ọkàn wọn mọ́ra. Èrò tó yàtọ̀ síra làwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní lórí ọ̀rọ̀ bóyá kí èèyàn fi ìmọ̀lára ẹ̀ hàn síta, tàbí kó pa á mọ́ra. Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fẹ́nì kan, àmọ́ tí kò yá ẹ lára láti ṣe bẹ́ẹ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, bóyá kó o sọ díẹ̀ lára ẹ̀dùn ọkàn ẹ fún ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ kan.
Àwọn kan ti wá rí i pé táwọn bá sunkún, ó máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn fúyẹ́, àmọ́ ní ti àwọn míì, ara wọn máa ń balẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bí wọn ò tiẹ̀ sunkún.
ÌLÀNÀ: “Ọkàn-àyà mọ ìkorò ọkàn ẹni.”—Òwe 14:10.
5: YẸRA FÚN ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ ṢÀKÓBÁ FÚN ARA RẸ
Àwọn kan tó ń ṣọ̀fọ̀ rò pé àwọn lè fi ọtí tàbí oògùn olóró pa ìrònú rẹ́. Ńṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣàkóbá fún ara wọn. Tí ara bá tiẹ̀ tù wọ́n, fún ìgbà díẹ̀ ni, ohun tó sì máa ń gbẹ̀yìn irú àṣà yẹn kì í dáa rárá. Ohun tí kò ní ṣàkóbá fún ẹ ni kó o fi pa ìrònú rẹ́.
ÌLÀNÀ: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin.”—2 Kọ́ríńtì 7:1.
6: ṢÈTÒ ÀKÓKÒ RẸ
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé ó ṣèrànwọ́ gan-an bí wọ́n ṣe pín àkókò tí wọ́n fi ń ṣọ̀fọ̀ sí méjì, (ìyẹn bí wọ́n ṣe ní ẹ̀dùn ọkàn àti ohun tí wọ́n ṣe láti kápá ẹ̀dùn ọkàn náà). Bí wọ́n ṣe ṣe é ni pé wọ́n máa ń ṣe àwọn nǹkan tó máa gbé ọkàn wọn kúrò nínú ẹ̀dùn ọkàn náà fún àkókò díẹ̀.
O lè rí i pé ara tù ẹ́ díẹ̀ tó o bá ń sún mọ́ àwọn èèyàn tàbí tó ò ń mú kí àárín ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ gún régé sí i, o tún lè kọ́ àwọn nǹkan tuntun tàbí kó o máa lọ síbi ìgbafẹ́.
Tó bá yá, wàá rí i pé nǹkan máa yí pa dà. O lè wá kíyè sí i pé àkókò tó o fi ń ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o gbọ́kàn kúrò nínú ẹ̀dùn ọkàn rẹ túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ó sì tún ń ṣe lemọ́lemọ́ sí i. Kó o tó mọ̀, wàá rí i pé ara ti bẹ̀rẹ̀ sí í tù ẹ́.
ÌLÀNÀ: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà sísunkún àti ìgbà rírẹ́rìn-ín; ìgbà pípohùnréré ẹkún àti ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri.”—Oníwàásù 3:1, 4.
7: MÁ ṢE JÓKÒÓ GẸLẸTẸ
Má ṣe jẹ́ kó pẹ́ kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀.
Tó o bá ti ní àkókò tó o máa ń sùn, àkókò iṣẹ́, àti àkókò tó o máa ń ṣe àwọn nǹkan míì, ó ṣeé ṣe kí ara rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í balẹ̀ pa dà.
Tó o bá ń fi àkókò rẹ ṣe àwọn nǹkan gidi, èyí á mú kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ lọ sílẹ̀.
ÌLÀNÀ: “Kì í ṣe ìgbà gbogbo ni yóò máa rántí àwọn ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ mú ọwọ́ rẹ̀ dí pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà rẹ̀.”—Oníwàásù 5:20.
8: MÁ ṢE KÁNJÚ ṢE ÀWỌN ÌPINNU PÀTÀKÌ
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe ìpinnu pàtàkì ní gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí èèyàn wọn kú ló máa ń kábàámọ̀ àwọn ìpinnu náà.
Tó bá ṣeé ṣe, ṣe sùúrù dáadáa kó o tó kó lọ sí ibòmíì, kó o tó fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀, tàbí kó o tó sọ pé kò sóhun tó o fẹ́ fi ẹrù èèyàn rẹ tó ti kú ṣe.
ÌLÀNÀ: “Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.”—Òwe 21:5.
9: MÁ GBÀGBÉ ÈÈYÀN RẸ
Ọ̀pọ̀ àwọn tí èèyàn wọn kú ló gbà pé ó dáa kéèyàn máa ṣe àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kó gbàgbé ẹni tó kú náà.
Ó lè jẹ́ ohun ìtùnú fún ẹ tó o bá ṣàkójọ àwọn fọ́tò tàbí àwọn ohun míì táá jẹ́ kó o máa rántí onítọ̀hún, tàbí kó o kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wù ẹ́ kó o máa rántí.
Tọ́jú àwọn nǹkan tó lè rán ẹ létí àwọn nǹkan tó dáa nípa onítọ̀hún, kó o wá máa yẹ̀ wọ́n wò tó bá yá.
ÌLÀNÀ: “Rántí àwọn ọjọ́ láéláé.” —Diutarónómì 32:7.
10: MÁA ṢERÉ JÁDE
O lè rìnrìn-àjò lọ síbì kan kó o lọ sinmi.
Tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti lọ lo àkókò ìsinmi ọlọ́jọ́-púpọ̀, o lè gbìyànjú àwọn nǹkan míì fún bí ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, bóyá kó o fẹsẹ̀ rìn lọ sáwọn ibì kan, kó o lọ sí ibi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí tàbí kó o wakọ̀ lọ síbì kan.
Tó o bá gbìyànjú ohun tó yàtọ̀ sáwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó lè mú kí ara tù ẹ́.
ÌLÀNÀ: “Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.” —Máàkù 6:31.
11: MÁA RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́
Fi sọ́kàn pé gbogbo ìgbà tó o bá ran àwọn míì lọ́wọ́, ńṣe lara á máa tu ìwọ náà.
O lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tó kú náà, ó lè jẹ́ ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ táwọn náà ní ẹ̀dùn ọkàn, tí wọ́n sì ń wá ẹni tó máa tù wọ́n nínú.
Bó o ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́, tó o sì ń tù wọ́n nínú, inú rẹ á máa dùn, ayé rẹ á sì túbọ̀ nítumọ̀.
ÌLÀNÀ: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
12: RONÚ NÍPA ÀWỌN NǸKAN TÓ O KÀ SÍ PÀTÀKÌ JÙ
Tí èèyàn ẹni bá kú, ó lè jẹ́ kéèyàn wá ronú nípa ohun tó ṣe pàtàkì jù láyé.
Lo àkókò yìí láti ronú nípa ohun tó ò ń fi ayé rẹ ṣe.
Tó o bá rí i pé kì í ṣe àwọn nǹkan gidi lo kà sí pàtàkì jù, ṣe àtúnṣe tó bá yẹ.
ÌLÀNÀ: “Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé àkànṣe àsè, nítorí pé ìyẹn ni òpin gbogbo aráyé; ó sì yẹ kí alààyè fi í sí ọkàn-àyà rẹ̀.” —Oníwàásù 7:2.
Òótọ́ ni pé kò sí nǹkan tó lè mú ẹ̀dùn ọkàn rẹ kúrò pátápátá. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tí èèyàn wọn kú ti jẹ́rìí sí i pé tí èèyàn bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì kan, bí irú àwọn tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó máa ń mú kí ara tuni. Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan miì wà tó o lè ṣe àmọ́ tá ò sọ̀rọ̀ nípa wọn. Àmọ́, tó o bá gbìyànjú àwọn kan lára àwọn àbá yìí, wàá rí i pé ara máa tù ẹ́ gan-an.
a Ìwé ìròyìn Jí! kì í sọ irú ìtọ́jú pàtó tó yẹ kẹ́nì kan gbà.
-
-
Ìrànlọ́wọ́ Tó Dára Jù Lọ Fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀Jí!—2018 | No. 3
-
-
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀
Ìrànlọ́wọ́ Tó Dára Jù Lọ Fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀
LẸ́NU ÀÌPẸ́ YÌÍ, ÀWỌN ÈÈYÀN TI ṢE ÌWÁDÌÍ PÚPỌ̀ NÍPA ỌGBẸ́ ỌKÀN TÍ IKÚ ÈÈYÀN ẸNI MÁA Ń FÀ. Àmọ́, bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, èyí tó dára jù nínú àwọn ìmọ̀ràn táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n máa ń fúnni bá ohun tó wà nínú ìwé àtayébáyé àti ìwé ọgbọ́n náà mu, ìyẹn Bíbélì. Èyí jẹ́ kó ṣe kedere pé kò sígbà tí ìmọ̀ràn inú Bíbélì kì í wúlò. Àmọ́, kì í ṣe àwọn ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé nìkan ló wà nínú Bíbélì. Àwọn nǹkan míì tún wà nínú Bíbélì tó jẹ́ pé a ò lè rí níbòmíì, ó sì ń mú ìtùnú ńlá wá fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀.
Ó dájú pé àwọn èèyàn wa tó ti kú kò sí níbì kan tí wọ́n ti ń jìyà
Oníwàásù 9:5 sọ pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Sáàmù 146:4 náà sì sọ pé ‘àwọn ìrònú wọn ti ṣègbé.’ Ńṣe ni Bíbélì tún fi ikú wé oorun àsùnwọra.—Jòhánù 11:11.
Ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run ìfẹ́ ń tuni nínú
Bíbélì sọ ní Sáàmù 34:15 pé: “Ojú Jèhófàa ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” Bíbá Ọlọ́run sọ ohun tó wà lọ́kàn wa kì í wulẹ̀ ṣe ohun tó kàn ń mú ara yá gágá lásán, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀nà láti wulẹ̀ sọ èrò ọkàn wa jáde kí ara kàn lè tù wá. Àmọ́, ó jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa, ó sì lè fi agbára rẹ̀ tù wá nínú.
Ìgbà ọ̀tun ṣì máa wọlé dé
Ronú nípa bó ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú nígbà táwọn tó ti kú bá jíǹde pa dà sórí ilẹ̀ ayé níbí! Léraléra ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àkókò tá à ń wí yìí. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa rí lójọ́ iwájú yẹn, ó sọ pé Ọlọ́run ‘yóò nu omijé gbogbo kúrò ní ojú wa, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.’—Ìṣípayá 21:3, 4.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí okun gbà gan-an nígbà tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ikú èèyàn wọn, torí wọ́n gba Ọlọ́run tó ni Bíbélì gbọ́, wọ́n sì nírètí pé àwọn ṣì máa rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú pa dà. Bí àpẹẹrẹ, Obìnrin kan tó ń jẹ́ Ann tí ọkọ rẹ̀ kú, tó sì jẹ́ pé wọ́n ti ń bá ara wọn bọ̀ láti ọdún márùndínláàádọ́rin [65] sọ pé: “Bíbélì fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn èèyàn wa tó ti kú kò sí níbì kan tí wọ́n ti ń jìyà, àti pé Ọlọ́run ṣì máa jí gbogbo àwọn tó wà ní ìrántí rẹ̀ dìde. Àwọn nǹkan tó máa ń wá sọ́kàn mi rèé nígbàkigbà tí mo bá ti ń ronú nípa ikú ọkọ mi, ńṣe ni èyí sì máa ń mú kí n lè fara da ohun tó bà mí lọ́kàn jẹ́ jù lọ láyé mi!”
Tiina tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Látìgbà tí Timo ọkọ mi ti kú ni mo ti ń rọ́wọ́ Ọlọ́run lára mi. Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ gan-an lákòókò wàhálà. Mo nígbàgbọ́ tó lágbára pé àwọn òkú máa jíǹde bí Bíbélì ṣe sọ. Èyí ń fún mi lókun láti máa fara dà á nìṣó, títí dìgbà tí màá tún rí Timo pa dà.”
Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí náà rèé lára ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n gbà gbọ́ dájú pé Bíbélì ṣeé gbára lé. Tó bá tiẹ̀ ń ṣe ẹ́ bíi pé àlá tí kò lè ṣẹ ni àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, jọ̀wọ́ ṣe ìwádìí kó o lè mọ̀ bóyá àwọn ìmọ̀ràn àti ìlérí tó wà nínú rẹ̀ ṣeé gbára lé lóòótọ́. Ìwọ fúnra rẹ lè wá rí i pé Bíbélì ló lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú jù lọ.
KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA ÌRÈTÍ TÓ WÀ FÚN ÀWỌN TÓ TI KÚ
Wo àwọn fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa èyí lórí ìkànnì wa, jw.org/yo
Bíbélì sọ pé a máa rí àwọn èèyàn wa tó ti kú pa dà lọ́jọ́ iwájú
KÍ LÓ Ń ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN TÓ TI KÚ?
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti kú? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ń tuni nínú tó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀
Lọ sí OHUN TÁ A NÍ > ÀWỌN FÍDÍÒ (Fídíò: BÍBÉLÌ)
ṢÉ O FẸ́ GBỌ́ ÌRÒYÌN AYỌ̀?
Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé ìròyìn burúkú là ń gbọ́ káàkiri yìí, ibo la ti lè gbọ́ ìròyìn ayọ̀?
Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀLÀÁFÍÀ ÀTI AYỌ̀
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú Bíbélì.
-