Ifẹ Fun Jehofa Ń Ru Ijọsin Tootọ Soke
“Nitori eyi ni ohun ti ifẹ Ọlọrun tumọsi, pe ki a kiyesi awọn aṣẹ rẹ̀.” —1 JOHANU 5:3, NW.
1, 2. Pẹlu isunniṣe wo ni a nilati ṣiṣẹsin Jehofa?
AWUJỌ awọn olubẹwo 80 lati Japan ń rìn yika Gbọngan Apejọ awọn Ẹlẹ́ rìí Jehofa ni California, U.S.A. Awọn ayika gbigbadun mọni, papọ pẹlu ọgbà ti ó kun fun awọn blue jay [awọn ẹyẹ ìwo ti Amẹrika], ẹyẹle, ati awọn ẹyẹ akùnyùngbà, mu wọn nimọlara wíwà timọtimọ pẹlu Atobilọla Ẹlẹdaa wọn, Jehofa Ọlọrun paapaa sii. Ẹni ti ń mu wọn lọ yika mọ laipẹ pe ó fẹrẹ jẹ́ ẹnikọọkan ti ó wà ninu awujọ naa ni ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna alakooko kikun kan. Nitori naa, lẹhin naa, awujọ naa ni a bi ni ibeere kan ti awọn miiran ti maa ń beere niye ìgbà pe: “Eeṣe ti ọpọlọpọ aṣaaju-ọna pupọ tobẹẹ fi wà ni Japan?” Fun iṣẹju diẹ idakẹrọrọ wà. Lẹhin naa ni ọdọbinrin kan fínnúfíndọ̀ fesipada pe: “Nitori pe a nifẹẹ Jehofa.”
2 Ifẹ fun Jehofa—ẹ wo bi eyi ṣe ń sún wa lati jẹ́ onitara tó ninu iṣẹ-isin rẹ̀! Loootọ, kii ṣe gbogbo eniyan ni ó lè ṣe aṣaaju-ọna. Nitootọ, ọpọ julọ ninu iye ti ó ju million mẹrin awọn akede Ijọba wa ni kò tii lè wá àyè fun anfaani yii. Ṣugbọn ọpọ awọn ẹni ti ipo ayika wọn yọnda ti nàgà fun un. Awa yooku pẹlu lè ‘gbẹkẹle Oluwa [“Jehofa,” NW], ki a sì maa ṣe rere,’ ni fifi ifẹ wa han nipa nini awọn ipá kan lati sà ninu iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin. (Saamu 37:3, 4) Gbogbo awọn olujọsin oluṣeyasimimọ si Jehofa sì lè ṣajọpin ninu mimu ẹmi aṣaaju-ọna dagba, ni fifun awọn wọnni ti wọn ń ṣe aṣaaju-ọna ni itilẹhin onifẹẹ.—Matiu 24:14; 28:19.
3. Iyatọ gédégédé wo ni a nilati ṣakiyesi laaarin ọpọ julọ awọn Kristẹni alafẹnujẹ ati awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
3 Ni iyatọ gédégédé si ọpọ julọ awọn Kristẹni alafẹnujẹ, ti wọn ń fi irọrun ka isin si àmọ́ lasanlasan ninu igbesi-aye wọn, awa Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣaṣefihan ifẹ mimuna fun Ọlọrun ti o ń sun wọn lati maa baa niṣo “ni wíwá ijọba naa ati ododo rẹ̀ lakọọkọ.” Eyi ti beere fun irubọ, ṣugbọn ẹ wo bi iru irubọ bẹẹ ti jẹ eyi ti o ni èrè ninu tó! (Matiu 6:33, NW; 16:24) O ti wà ni oju ila pẹlu aṣẹ titobi akọkọ naa, ti Mose kọkọ sọ ni ibẹrẹ ti Jesu Kristi sì sọ asọtunsọ rẹ̀ pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun wa Oluwa [“Jehofa,” NW] kan ni. Ki iwọ ki o sì fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkan rẹ, ati gbogbo iyè rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ.”—Maaku 12:29, 30; Deutaronomi 6:4, 5.
4, 5. Awọn wo ni a lè kà sí oluṣotitọ, bawo si ni a ṣe lè fi iṣotitọ han?
4 Ọkan lara awọn orile-iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sọ lẹnu aipẹ yii fun F. W. Franz, aarẹ Watch Tower Society ẹni ọdun 98 naa ti ó ti lo ohun ti o ju 70 ọdun ninu iṣẹ-isin alakooko kikun pe: “Iwọ ti jẹ apẹẹrẹ rere ti iṣotitọ, Arakunrin Franz.” Arakunrin Franz sì fesi pada pe: “Bẹẹni! Iwọ nilati jẹ́ oluṣotitọ.” Iyẹn ṣakopọ ọran naa. Ninu apa ẹka igbokegbodo Ijọba yoowu ti a ti ń ṣiṣẹsin, awa lè jẹ oluṣotitọ.—1 Kọrinti 4:2; Galatia 3:9.
5 Loootọ, ọpọlọpọ yoo fẹ lati ṣe pupọ sii ninu iṣẹ-isin Jehofa, ṣugbọn awọn ẹrù iṣẹ ti wọn ba Iwe Mimọ mu tabi iṣoro ilera lè ká wọn lọwọko lọna kan ṣaa. Bi o ti wu ki o ri, awọn wọnni ti wọn ko lè ṣe aṣaaju-ọna ni a ko nilati kà si awọn ti iṣotitọ wọn kò tó. Awọn kan ti duroṣinṣin labẹ awọn ipo ti ndanniwo julọ ati niye igba fun ọpọlọpọ ọdun. Bẹẹni, wọn ti jẹ́ oluṣotitọ! Wọn ti fi ifẹ fun Jehofa han wọn sì ti ṣiṣẹsin loju mejeeji ninu itilẹhin afitọkantọkanṣe ti awọn iṣeto iṣakoso Ọlọrun rẹ̀. Wọn ti ni ifẹ-ọkan mimuna ninu igbokegbodo awọn aṣaaju-ọna wọn sì ti fun awọn ti ó ṣeeṣe ki wọn di aṣaaju-ọna nisiiri, niye ìgbà awọn ọmọ tiwọn funraawọn, lati ṣiṣẹ siha ṣiṣe aṣaaju-ọna gẹgẹ bi iṣẹ ninu igbesi-aye ti ó tayọ gbogbo awọn miiran.—Fiwe Deutaronomi 30:19, 20.
6, 7. Bawo ni apẹẹrẹ iṣaaju ti a gbekalẹ ni 1 Samuẹli 30:16-25 ṣe ṣee fisilo lonii?
6 Igbesẹ iṣọkan onifẹẹ ti gbogbo awọn eniyan Ọlọrun lonii ni a lè ṣapejuwe nipa akọsilẹ ti ó wà ni 1 Samuẹli 30:16-25. Ninu ijakadi pẹlu awọn ara Amaleki, “Dafidi sì pa wọn lati afẹmọjumọ titi ti o fi di aṣalẹ” o sì kó ọpọlọpọ ikogun. Ni pipada si agọ, diẹ lara awọn ọkunrin jagunjagun Dafidi sọ pe ki wọn maṣe fun awọn wọnni ti wọn ko tẹsiwaju pẹlu wọn lọ si oju ija ni ọkankan lara awọn ikogun naa. Ṣugbọn Dafidi dahun pe: “Ta ni yoo gbọ́ tiyin ninu ọran yii? Ṣugbọn bi ipin ẹni ti o sọkalẹ lọ si ija ti ri, bẹẹ ni ipin ẹni ti o duro ti ẹrù; wọn o sì pin in bakan naa.”
7 Ilana kan naa ṣee fisilo lonii. Awọn aṣaaju-ọna wà ni iwaju ija ogun tẹmi wa. Ṣugbọn awọn ti o ku ninu ijọ funni ni itilẹhin afitọkantọkanṣe, aduroṣinṣin. Abajade titobilọla ti apapọ igbokegbodo wọn ni 1991 ni a fihan ninu ṣáàtì ti o tẹle e nisinsinyi.
Irohin Titayọ Kan
8. (a) Ki ni irohin yika aye fihan niti aropọ awọn akede ati wakati ti wọn lo ninu iṣẹ-isin Jehofa? (b) Awọn koko fifanilọkanmọra wo ni o ṣakiyesi fun awọn orilẹ-ede ti wọn ṣẹṣẹ nfarahan lọna titun ninu irohin naa?
8 Bẹẹni, awọn oju iwe mẹrin ti o ṣaaju ninu iwe irohin yii fihan bi isapa àpawọ́pọ̀ṣe ti gbogbo awọn onitara olujọsin Jehofa ti ṣe fikun imugbooro kan ti ń moriya kari ayé ni 1991. Gongo titun titayọ kan ti 4,278,820 awọn akede Ijọba ni a ṣakọsilẹ—ibisi ipin 6.5 ninu ọgọrun-un. Awọn wọnyi fi 951,870,021 wakati (ti o fẹrẹẹ tó billion kan!) fun iṣẹ-isin naa. Ẹ sì ṣakiyesi isapa titayọlọla tí awọn ará wa ni awọn orilẹ-ede tí ń farahan ni titun ninu irohin yika ayé nisinsinyi ṣe—Bulgaria, Cameroon, Czechoslovakia, Ethiopia, Mozambique, Nicaragua, Rwanda, ati U.S.S.R.
9, 10. (a) Bawo ni awọn aṣaaju-ọna ṣe dahunpada si ipenija awọn akoko lilekoko yii? (b) Iṣiri wo ni a pese fun wiwọnu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna?
9 Ni awọn ọdun aipẹ yii ẹmi aṣaaju-ọna ti tàn jakejado ayé. Ani ni awọn ilẹ nibi ti a ti yọnda fun ominira ijọsin lẹnu aipẹ yii, òtú aṣaaju-ọna nga sii. Awọn ipo iṣunna-owo lilekoko kò dí awọn Ẹlẹ́rìí alagbara wọnyi lọwọ kuro ninu lilo gbogbo ohun ti wọn ni fun ijọsin Jehofa. (Fiwe 2 Kọrinti 11:23, 27.) Ni ipindọgba oṣooṣu, ipin 14 ninu ọgọrun-un gbogbo awọn akede Ijọba ń ṣe aṣaaju-ọna. Gongo iye awọn aṣaaju-ọna jẹ́ 780,202, eyi ti o jẹ́ ipin titayọlọla ti ipin 18 ninu ọgọrun-un ninu gbogbo awọn akede.
10 Ni ṣiṣakiyesi ayọ ti awọn aṣaaju-ọna niriiri rẹ̀, awọn miiran ni a tun fun niṣiiri lati kowọnu iṣẹ-isin yii. Bi iwọ ko ba tii bẹrẹ ṣiṣe aṣaaju-ọna sibẹ, ifẹ rẹ fun Jehofa ha lè gbún ọ ni kẹṣẹ lati sọ, gẹgẹ bi a ti kà ni Aisaya 6:8 pe, “Emi niyii; ran mi” bi? Tabi nipasẹ ikẹkọọ Bibeli alaapọn rẹ, Ọrọ Ọlọrun ha lè tanna ran ifẹ ti ń jó ninu ọkan-aya rẹ, ki o baa lè jẹ́ pe iwọ ṣaa nilati gbegbeesẹ siwaju sii ti wiwọnu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna? Ani ni akoko adanwo paapaa, ọrọ Jehofa ru Jeremaya lọkan soke, debi pe oun ko le fasẹhin.—Jeremaya 20:9.
Iṣẹ-isin Onifẹẹ si Araye
11. Bawo ni igbokegbodo ikẹkọọ Bibeli inu ile ṣe kẹ́sẹjárí?
11 Ọ̀kan lara awọn iha titayọ ti irohin ọdun naa ni ibisi ninu iye awọn ikẹkọọ Bibeli ọfẹ inu ile, 3,947,261, ti a ń dari deedee ni oṣu kọọkan yika ayé. Eyi jẹ́ iṣeto onifẹẹ nipasẹ eyi ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nṣe itilẹhin siwaju sii fun awọn olufifẹhan ti wọn ba pade ninu iṣẹ ile-de-ile wọn. A layọ lati dari awọn ikẹkọọ Bibeli pẹlu awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede ati ẹ̀yà iran, ni ṣiṣiṣẹ pẹlu itara kan naa ti apọsiteli Pọọlu fihan. ‘Jijẹrii jalẹjalẹ fun awọn Juu ati awọn Giriiki’ tí ó ṣe laiṣiyemeji beere fun ọpọlọpọ wakati ti kikọni ni otitọ. (Iṣe 20:20, 21) Bakan naa ni lonii. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ran ‘gbogbo eniyan lọwọ lati ni igbala ki wọn sì wá sinu imọ otitọ.’—1 Timoti 2:4.
12-14. Awọn irohin alayọ wo ni a ngbọ lati Europe?
12 Awọn irohin ibisi ninu igbokegbodo ikẹkọọ Bibeli ni Ila-oorun Europe ti runi soke tó! Fun ọpọ ẹwadun awọn ará wa nibẹ nilati padepọ ni awujọ keekeeke, pẹlu boya ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà ogbologboo kan, ti a fi ẹrọ mimeograph tẹ fun gbogbo awọn ti ó wà ninu awujọ naa. Ṣugbọn nisinsinyi ọpọ yanturu Bibeli ati iwe ikẹkọọ Bibeli ń ya wọnu awọn ilẹ wọnni. Ó ranni leti Orin Solomọni 2:4 pe: “Ó [Kristi Jesu] mu mi wá si ile ọti waini [tẹmi], ifẹ sì ni ọpagun rẹ̀ lori mi.” Bi wọn ti ni awọn ẹ̀dà iwe irohin tiwọn funraawọn, ọpọlọpọ ni o ti ń di ẹni ti a mura silẹ daradara lati mu “ọrọ otitọ bi o ti yẹ.”—2 Timoti 2:15.
13 Ijọ kan ti o ní 103 awọn akede ni St. Petersburg, Russia, rohin awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile ti o ju 300 lọ lẹnu aipẹ yii. Gẹgẹ bi eso isapa ikẹkọọ Bibeli yii, 53 awọn Ẹlẹ́rìí titun ni a bamtisi ni kiki oṣu mẹjọ. Iye ti o ju ilaji ijọ naa ni wọn wà ninu otitọ fun oṣu mẹjọ tabi ki ó din si i! Wọn kò sì ní alagba kankan—kiki iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ kanṣoṣo lati bojuto itẹsiwaju tẹmi wọn.
14 Akede Ijọba kan ni Estonia ni akẹkọọ Bibeli kan beere lọwọ rẹ̀ boya ó lè kesi diẹ lara awọn ọrẹ rẹ̀ wa si ikẹkọọ. Nigba ti Ẹlẹ́rìí naa dé si ile naa ni ọsẹ ti ó tẹle e, ó rí iye ti o ju 50 awọn eniyan ti wọn pejọ! Dajudaju, awọn iṣeto akanṣe ni a nilo fun abojuto alaidawọduro ti gbogbo awọn olufifẹhan wọnni.
15. Ki ni a lè sọ nipa awọn ti wọn wá si Iṣe-iranti ati bamtisimu?
15 Ọpọlọpọ ti ń kẹkọọ tọ́ ibakẹgbẹ Kristẹni wọn akọkọ wò nipa lilọ si Iṣe-iranti iku Jesu. Ni ọdun ti o kọja yii, iye awọn eniyan ti wọn wá kọja 10,000,000 fun ìgbà akọkọ, 10,650,158 pejọpọ yika ayé ni 66,207 ijọ fun iṣẹlẹ alayọ yii. Ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede Latin-America, Africa, ati Ila-oorun Europe, awọn eniyan ti wọn wá fi ilọpo mẹta tabi mẹrin kọja iye awọn akede Ijọba. Nisinsinyi a gbọdọ bẹrẹ sii mura silẹ fun Iṣe-iranti ti a o ṣe ni ọdun yii ni Friday, April 17. A nireti pe iye pupọ ti awọn akẹkọọ Bibeli titun ti wọn wá sí Iṣe-iranti yoo maa baa lọ lati tẹsiwaju siha iribọmi. Niti awọn iribọmi, ni 1991 a tun ri iye ti ó ju 300,000 ti ń ṣapẹẹrẹ iyasimimọ wọn si Jehofa Ọlọrun nipasẹ iribọmi ninu omi.
Awọn Olùfẹ́ Ominira Oniwa-bi-Ọlọrun
16. Awọn irohin arunilọkansoke wo ni a ń gbọ lati Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùfẹ́ Ominira”?
16 Iha kan ti ó yẹ fun akiyesi nipa ọdun iṣẹ-isin 1991 ti jẹ́ ọ̀wọ́ Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùfẹ́ Ominira” ti a ti pari nisinsinyi ni Iha-ariwa Ilẹ-aye ṣugbọn ti o ń baa lọ wọnu 1992 ni Iha-guusu Ilẹ-aye. Fun ìgbà akọkọ, itolẹsẹẹsẹ kikun ti apejọpọ ni a gbekalẹ ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede Ila-oorun Europe, nibi ti awọn ará wa ti ń yọ̀ lati lo awọn ominira wọn ti wọn ṣẹṣẹ rí lati yin Jehofa. Ni October 1991 aropọ iye awọn eniyan ti a rohin pe wọn pesẹ ni 705 apejọpọ akọkọ ni 54 awọn orilẹ-ede jẹ́ 4,774,937.
17, 18. (a) Ominira wo ni awọn olujọsin Jehofa ń gbadun tí wọn sì nfojusọna fun? (b) Bawo ni ominira oniwa-bi-Ọlọrun ṣe yatọ si ominira ti ayé?
17 Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: ‘otitọ yoo sì sọ yin di ominira.’ (Johanu 8:32) Lonii, otitọ Bibeli ti sọ araadọta-ọkẹ dominira kuro ninu igbagbọ gbà-bẹ́ẹ̀-láìjanpata ti Kristẹndọmu. Araadọta-ọkẹ wọnyi ti mọ pe ipese Jehofa ti ẹbọ irapada Jesu yoo mu ki ó ṣeeṣe fun araye lati “di ominira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si ominira ogo awọn ọmọ Ọlọrun.” (Roomu 8:19-22) Ominira ńláǹlà wo ni iyẹn yoo jẹ́—wiwalaaye titilae ninu paradise ilẹ-aye kan laaarin aala titọ ti Jehofa nfi ifẹ pinnu!—Aisaya 25:6-8; fiwe Iṣe 17:24-26.
18 Ominira tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń gbadun nisinsinyi ti wọn sì reti lati gbadun lọpọ yanturu sii ninu eto igbekalẹ awọn nǹkan titun ti Ọlọrun, wá lati ọdọ Ọlọrun wa, Jehofa. (2 Kọrinti 3:17) Wọn kò gbarale idasilẹ oṣelu tabi iyipada afọtẹṣe eyikeyii. (Jakobu 1:17) Lati dena aṣiloye eyikeyii lori koko yii, baaji apejọpọ 1991 tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lẹ̀máyà ni awọn ilẹ Ila-oorun Europe diẹ ni awọn ọrọ naa “Awọn Olùfẹ́ Ominira Oniwa-bi-Ọlọrun” dipo ki o wulẹ jẹ “Awọn Olùfẹ́ Ominira.”
Ifẹ Mimuna Fun Jehofa
19. Bawo ni ìbárẹ́ timọtimọ taduratadura pẹlu Jehofa ṣe ń mu wa duro?
19 Ifẹ wa fun Jehofa ati igbẹkẹle wa ninu rẹ̀ yoo mu ki a wà timọtimọ pẹlu rẹ̀ ninu adura. Ìbárẹ́ timọtimọ yii pẹlu Jehofa ni o ti ran awọn ará wa lọwọ lati farada ọpọlọpọ inira ati inunibini. (Saamu 25:14, 15) Ni wakati adanwo titobi julọ rẹ̀, Jesu pa ìbárẹ́ timọtimọ pelu Baba rẹ̀ mọ́ nipasẹ adura. (Luuku 22:39-46) Iru ìbárẹ́ timọtimọ nipasẹ adura bẹẹ pẹlu Jehofa mu Sitefanu duro la ìroragógó iku ajẹriiku rẹ̀ já. Bi o ti tẹjumọ ọrun ṣaaju ki a to sọ ọ ni okuta pa, o wi pe: “Wò ó, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati Ọmọ eniyan [Jesu] ń duro ni ọwọ ọtun Ọlọrun.”—Iṣe 7:56.
20-22. Bawo ni iriri kan ṣe ṣapejuwe pe Jehofa ń gbọ adura?
20 Gẹgẹ bi awọn olujọsin Jehofa ti saba maa ń niriiri rẹ̀, Jehofa ń dahun adura ti ó wà ni ibamu pẹlu ifẹ-inu rẹ̀. Fun apẹẹrẹ, ni orilẹ-ede Africa kan nibi ti a ti fofin de iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí, aṣaaju-ọna akanṣe kan ti ń rinrin-ajo lọ si ariwa nipasẹ ọkọ bọọsi ní apo ńlá iwe ikẹkọọ Ijọba ati awọn apo iwe lati fi jiṣẹ. Olutọju èrò ti ń to ẹrù bọọsi naa beere lọwọ arakunrin naa pe: “Ki ni apo naa ní ninu?” Arakunrin naa sọ ohun akọkọ ti ó wá si ọkàn rẹ̀: “Ẹrù ifiweranṣẹ.”
21 Loju ọna, bọọsi naa sare kọja ibi ti a ti ń ṣayẹwo ọkọ irinna deedee loju popo, awọn ọlọpaa oju ọna naa fọkọsare lé bọọsi naa wọn sì daa duro, ni fifura pe o kó ẹrù ofin. Wọn paṣẹ pe ki gbogbo awọn èrò bọ silẹ ninu bọọsi ki wọn sì yẹ gbogbo ẹrù wò. Eyi jẹ akoko iṣoro ńláǹlà! Arakunrin naa rin siwaju diẹ kuro lara awọn èrò ti ń kùn, o sì bẹrẹ sori eekun rẹ̀, o gbadura si Jehofa. Nigba ti o darapọ mọ awọn èrò naa pada, ẹrù arinrin-ajo kọọkan ni a ń tú ti a sì ń yẹwo pẹlu iṣọra kínníkínní. Nigba ti a fẹ tú apo arakunrin naa, ó kepe Jehofa ni ìdákẹ́jẹ́ẹ́ fun iranlọwọ.
22 “Apo ta ni eyi, ki ni o sì wà ninu rẹ̀?” Ọkunrin ọlọpaa naa pariwo. Ṣaaju ki arakunrin naa tó yánu sọrọ, olutọju èrò bọọsi naa dahun o sì wi pe: “Ó jẹ́ ẹrù lati ile ifiweranṣẹ —— si ile ifiweranṣẹ ——.” Ọ́físà naa wi pe, “ó dara.” Ó gbé apo naa nilẹ ó sì gbe e fun olutọju èrò naa. “Ri i daju pe o tọju rẹ̀ si ibi ti ó laabo gan-an fun irin-ajo naa,” ó paṣẹ fun un. Aṣaaju-ọna akanṣe naa wolẹ sori eekun rẹ̀ lẹẹkan sii lati dupẹ lọwọ Olugbọ adura.—Saamu 65:2; Owe 15:29.
23. Ki ni Jehofa ti ṣaṣefihan rẹ̀, ati sibẹ eeṣe ti oun nigba miiran fi fayegba inunibini lati maa baa lọ delẹdelẹ?
23 Bi o ti wu ki o ri, eyi kò tumọ si pe awọn olujọsin Jehofa wà lominira patapata kuro lọwọ awọn iṣẹlẹ ajalu ibi. Ni awọn ipo kan, ni akoko ti a kọ Bibeli ati lonii, Jehofa ti ṣaṣefihan pe oun le dá awọn eniyan oun nídè. Ṣugbọn ni ila pẹlu yiyanju ariyanjiyan iwatitọ, oun nigba miiran jọ bi pe o fayegba inunibini lati maa baa lọ delẹdelẹ. (Fiwe Matiu 26:39). Siwaju sii, Jehofa kii daabobo awọn eniyan rẹ̀ kuro lọwọ jamba, rogbodiyan ilu, tabi iwa ọdaran loju ẹsẹ, bi o tilẹ jẹ́ pe ìlò ọgbọn gbigbeṣẹ ti a gbekari Bibeli lè niyelori. (Owe 22:3; Oniwaasu 9:11) Bi o ti wu ki o ri, a lè nigbẹkẹle pe yala a da wa nide kuro ninu awọn ipo ti ń danniwo tabi bẹẹkọ, iṣotitọ wa ni a o san èrè fun, kódà nipasẹ ajinde bi o bá pọndandan.—Matiu 10:21, 22; 24:13.
24. Awọn ẹ̀bùn onifẹẹ wo ni Jehofa ti pese, bawo sì ni awa ṣe lè dahunpada si ifẹ rẹ?
24 Ẹ wo bi awọn ẹ̀bùn onifẹẹ Jehofa ti jẹ́ agbayanu tó! Ẹ̀bùn rẹ̀ ti ilẹ-aye yii ati ohun gbogbo ti ó wà ninu rẹ̀ fun araye jẹ́ ifihan titayọ ifẹ rẹ̀. (Saamu 104:1, 13-16; 115:16) Ẹ̀bùn ìyọ́nú Ọlọrun ti Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, lati ra araye pada kuro ninu ẹṣẹ ati ikú ni ẹ̀bùn onifẹẹ julọ ti a tii funni rí. “Nipa eyi ni a gbe fi ifẹ Ọlọrun han ninu wa, nitori ti Ọlọrun ran Ọmọ bibi rẹ̀ kanṣoṣo si ayé, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀. Ninu eyi ni ifẹ wà, kii ṣe pe awa fẹ Ọlọrun, ṣugbọn oun fẹ́ wa ó sì ran Ọmọ rẹ̀ lati jẹ etutu fun ẹṣẹ wa.” (1 Johanu 4:9, 10) Ni idahunpada si ifẹ yẹn, njẹ ki o da wa loju pe “kii ṣe ikú, tabi ìyè, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun ìgbà isinsinyi, tabi ohun ìgbà ti nbọ, tabi oke, tabi, ọ̀gbun, tabi ẹ̀dá miiran kan ni yoo le yà wá kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti ó wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa.”—Roomu 8:38, 39.
Ṣiṣatunyẹwo Ọrọ-Ẹkọ Yii
◻ Ki ni o tumọsi lati jẹ́ oluṣotitọ?
◻ Ninu ayika igbokegbodo wo ni a lè fi ifẹ han fun Jehofa?
◻ Awọn iha irohin ọdun iṣẹ-isin wo ni ó fà ọ́ lọkan mọra julọ?
◻ Bawo ni a ṣe lè fi imọriri han fun awọn ẹ̀bùn onifẹẹ Jehofa?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
EEṢE TI ỌPỌLỌPỌ TOBẸẸ FI Ń ṢE AṢAAJU-ỌNA?
Gẹgẹ bi a ti rohin rẹ̀, fun 2,600 ọdun awọn ara Japan jẹ́ olujọsin onitara fun olu-ọba wọn. Ninu awọn ogun ọgọrun-un ọdun lọna ogún yii nikan, iye ti ó ju aadọta-ọkẹ mẹta awọn jagunjagun Japan fi ẹmi wọn rubọ, nitori wọn rò pe kò si ọla titobi kankan ju lati kú fun ọlọrun olu-ọba wọn lọ. Ṣugbọn gbigbarale ẹgbẹ́ ogun Buddha-oun-Shinto kuna ninu Ogun Agbaye Keji, ati lẹhin naa olu-ọba naa kọ jíjẹ́ ọlọrun rẹ̀ silẹ. Ki ni ó lè kún àfo onisin yii? Pẹlu ayọ, awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile tí awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun Ẹlẹ́rìí Jehofa ati lẹhin naa awọn Ẹlẹ́rìí adugbo dari ran ọpọlọpọ lọwọ lati rí Ọlọrun tootọ, Jehofa, ati lati ya igbesi-aye wọn si mimọ fun un. Iyasimimọ yii tumọ si ohun pupọ fun awọn Ẹlẹ́rìí ara Japan. Bi o ba jẹ pe ni igba ti o ti kọja wọn yoo ti fi ẹmi wọn rubọ fun ọlọrun olu-ọba kan, bawo ni itara wọn ti pọ sii tó nisinsinyi ti wọn fi ń lo okun wọn gẹgẹ bi aṣaaju-ọna ninu jijọsin Ọlọrun alaaye ati Ẹlẹdaa agbaye—Jehofa Oluwa Ọba-Alaṣẹ!
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 10-13]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1991 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Awọn olùfẹ́ ominira oniwa-bi-Ọlọrun—Awọn Olujọsin Jehofa ni apejọpọ ni Prague, August 9-11, 1991