-
Jehofa Ń Ranti Awọn Alaisan ati Awọn AgbalagbaIlé-Ìṣọ́nà—1993 | August 1
-
-
Jehofa Ń Ranti Awọn Alaisan ati Awọn Agbalagba
LATI dojukọ ‘akoko ibi’ lè lekoko gan-an. (Orin Dafidi 37:18, 19) Iru akoko bẹẹ lè wá ni ọ̀nà ọjọ́-orí ti ń ga sii ati awọn ailera ti ń bá a rìn. Awọn kan wọnu akoko ibi nigba ti wọn bá jiya ailera alakooko gigun, ti o wuwo rinlẹ. Wọn lè nimọlara bi ẹni pe aisan wọn ń dari igbesi-aye wọn, ní jíjẹgàba lori gbogbo ironu ati iṣesi wọn.
Bi o ti wu ki o ri, ó finilọ́kàn balẹ lati ranti pe oju Jehofa kò kuro lara gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀. Ó ń mú ọkan-aya rẹ̀ yọ̀ nigba ti awọn iranṣẹ rẹ̀ olufọkansin bá ń baa lọ lati fi iduroṣinṣin ati ọgbọ́n hàn laika ọjọ́-ogbó, aisan, tabi awọn ipo ti ń danniwo miiran sí. (2 Kronika 16:9a; Owe 27:11) Ọba Dafidi mú un dá wa loju pe: “Oluwa wà létí ọ̀dọ̀ gbogbo awọn ti ń képè é, . . . yoo gbọ́ igbe wọn pẹlu.” Bẹẹni, ó mọ̀ nipa ìjà-fitafita wọn; ó ń fokun fun wọn pẹlu ẹmi rẹ̀. “Yoo sì gbà wọn.” Ó ń ranti wọn ó sì ń ràn wọn lọwọ lati farada. (Orin Dafidi 145:18, 19) Ṣugbọn awa ńkọ́? Awa, bi Jehofa, ha ranti awọn alaisan ati awọn agbalagba bi?
Awọn ailera nitori aisan tabi ọjọ́-ogbó jẹ́ otitọ-gidi ti igbesi-aye ninu eto-igbekalẹ isinsinyi. Otitọ ti a gbọdọ dojukọ titi ti Jehofa yoo fi mú ète rẹ̀ fun ilẹ̀-ayé ati araye wá si imuṣẹ ni. Lonii, awọn eniyan pupọ pupọ sii ń dagba di ogbó gan-an ni, nitori naa iye pupọ ni wọn dojulumọ ailera iru awọn bẹẹ. Ni afikun, nigba ti wọn ṣì wà ni ọ̀dọ́, ọpọ ni ijamba tabi aisan tí ń halẹ̀ mọ́ iwalaaye tabi tí ń sọni di abirùn ń kọlu. Titi fi di ìgbà ti ayé ogbologbo yii bá kọja lọ, aisan, ati ọjọ́-ogbó yoo maa baa lọ lati jẹ́ lajori awọn ipenija.
Ẹ wo bi a ti mọriri awọn alaisan ati awọn agbalagba wa ti wọn ń baa lọ gẹgẹ bi apẹẹrẹ ninu “ìyà jíjẹ, ati suuru” tó! Bẹẹni, “awa . . . ka awọn ti o farada ìyà si ẹni ibukun.” (Jakọbu 5:10, 11) Ọpọ awọn agbalagba ti agbara wọn ti dinku nisinsinyi ti ṣajọpin ninu kikọni, didanilẹkọọ, ati gbígbé awọn wọnni ti wọn ń mú ipo iwaju ninu ijọ nisinsinyi ró fun ọpọ ẹwadun. Iye awọn agbalagba kan tun yọ̀ lati rí i pe awọn ọmọ wọn ti ṣajọpin ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun.—Orin Dafidi 71:17, 18; 3 Johannu 4.
Ni ọ̀nà ti o jọra, a mọriri awọn wọnni laaarin wa ti ara wọn kò yá lójú mejeeji ati sibẹ, laika awọn ijiya wọn sí, ti wọn ń dọgbọn fun wa niṣiiri nipasẹ iṣotitọ wọn. Nigba ti awọn wọnyi bá fi ẹ̀rí ireti wọn hàn láìfì sọ́tùn-ún-sósì, iyọrisi rẹ̀ jẹ́ arunisoke ati afúngbàgbọ́ lókun julọ. Alaafia ero-inu ati itẹlọrun wọn ṣipaya igbagbọ kan ti o yẹ ni ṣiṣafarawe nitootọ.
Ohun ijaya ni fun ẹnikan lati di ẹni ti káńsà, àrùn arọnilọ́wọ́-rọnilẹ́sẹ̀, tabi awọn ipo miiran tí ń yí iru igbesi-aye ẹni bẹẹ pada patapata kọlu. Ó tun jẹ́ idanwo lilekoko kan fun awọn òbí lati rí ki awọn ọmọ wọn di olókùnrùn tabi ki wọn jiya gẹgẹ bi iyọrisi ijamba kan. Ki ni awọn miiran lè ṣe lati ṣeranlọwọ? Iru akoko ibi eyikeyii bẹẹ jẹ́ idanwo kan fun gbogbo ẹgbẹ́-ará Kristian. Ó jẹ́ anfaani kan lati fihàn pe ‘ọ̀rẹ́ tootọ jẹ́ arakunrin ti a bí fun ìgbà ti ipọnju bá wà.’ (Owe 17:17) Lọna àdánidá, kìí ṣe gbogbo awọn alaisan ati awọn agbalagba ni o lè reti itilẹhin ara-ẹni lati ọ̀dọ̀ gbogbo mẹmba ijọ kọọkan. Ṣugbọn Jehofa yoo rí sí i pe nipasẹ ẹmi rẹ̀ ọpọlọpọ nimọlara isunniṣe lati ṣeranlọwọ ni oniruuru ọ̀nà. Awọn alagba sì lè wà lojufo ṣamṣam lati rí i daju pe kò sí ẹnikẹni ti a gbojufo dá.—Wo Eksodu 18:17, 18.
Gbiyanju Lati Lóye
Ni gbigbiyanju lati ran ẹnikan lọwọ, ó ṣe pataki lati ní ijumọsọrọpọ rere kan, iyẹn sì ń gba akoko, suuru, ati igbatẹniro. Gẹgẹ bi oluranlọwọ kan, iwọ lọna ti ẹ̀dá ń fẹ́ lati ‘fi ọ̀rọ̀ funni lókun’; ṣugbọn fetisilẹ daradara ki o tó sọrọ tabi huwa, bi kò ṣe bẹẹ iwọ lè pari rẹ̀ sí dídi “ayọnilẹnu onitunu.”—Jobu 16:2, 5.
Kò níí rọrùn fun awọn alaisan ati awọn agbalagba nigba miiran lati fi ijakulẹ wọn pamọ. Ọpọ ti ṣìkẹ́ ireti wọn ti wiwalaaye lati la ipọnju nla já, ati nisinsinyi wọn nimọlara pe awọn ti kowọnu eré-ìje kan bi akoko ti ń lọ, eré-ìje kan ti wọn kò ni idaniloju pe awọn yoo yọri. Pẹlupẹlu, ipo wọn sábà maa ń mú wọn ṣàárẹ̀ ki wọn sì ṣaniyan. Mímú ki igbagbọ walaaye ki o sì lagbara jẹ́ ijakadi, ni pataki nigba ti ẹnikan kò bá lè tẹle ifẹ ọkan-aya rẹ̀ mọ́ niti níní ipin kikun ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian. Kristian kan ti o jẹ́ alagba ṣebẹwo sọdọ arabinrin agbalagba kan; nigba ti o ń gbadura pẹlu rẹ̀, ó beere pe ki Jehofa dari ẹṣẹ wa jì wa. Lẹhin adura naa ó ṣakiyesi pe arabinrin naa ń sunkun. [Arabinrin] naa ṣalaye pe oun nimọlara pe oun nilo akanṣe idariji lati ọ̀dọ̀ Jehofa fun àìlè ṣajọpin ninu iwaasu ile-de-ile mọ́. Bẹẹni, imọlara jíjẹ́ aláìlágbára tabi jíjẹ́ aláìyẹ, bi o tilẹ jẹ pe kò si idi fun un, lè mú ki ọkàn ẹnikan bajẹ gidigidi.
Jẹ́ ki o di mímọ̀ pe aniyan ati àárẹ̀ lè nipa lori ìwàdéédéé ti ero-ori. Nitori ailera ọjọ́-ogbó tabi ìgalára ti aisan ti ń sọni di alailera, ẹnikan lè nimọlara pe Jehofa ti kọ oun silẹ, boya ni wiwi pe: “Ki ni mo ṣe? Eeṣe ti mo fi nilati jiya?” Ranti awọn ọ̀rọ̀ Owe 12:25: “Ibinujẹ ní àyà eniyan níí dori rẹ̀ kọ odò; ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere níí mú un yọ̀.” Gbiyanju lati wá awọn ọ̀rọ̀ rere ti yoo tuni ninu. Awọn agbalagba tí wọn wà ninu irora paapaa, bi ti Jobu, lè fi ifẹ lati kú hàn. Kò yẹ ki eyi mú ọ gbọ̀nrìrì, gbiyanju lati lóye. Iru awọn àròyé bẹẹ kò fi dandan jẹ́ ẹ̀rí ainigbagbọ tabi igbẹkẹle. Jobu gbadura pe ki a ‘fi oun pamọ sinu ipo-oku,’ sibẹ awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kété lẹhin ọ̀rọ̀ yẹn ṣipaya igbagbọ rẹ̀ fifẹsẹmulẹ pe Jehofa yoo gbé oun dìde lẹhin naa. Igbagbọ lilagbara ń mú ki o ṣeeṣe lati la awọn akoko idaamu ati isorikọ já ati sibẹ ki a sunmọ Jehofa pẹkipẹki.—Jobu 14:13-15.
Fifi Ọlá Hàn fun Awọn Alaisan ati Awọn Agbalagba
Ó ṣe pataki gidigidi lati bá awọn alaisan ati awọn agbalagba lò pẹlu ọlá ati iyì. (Romu 12:10) Bi wọn kò bá huwapada ní kiakia bii ti iṣaaju tabi ti wọn kò lè ṣe pupọ tó, maṣe jẹ ki ó gèjíà rẹ. Maṣe yára lati dá sí ọ̀ràn wọn ki o sì ṣe awọn ipinnu fun wọn. Kò sí bi a ṣe lè ni èrò rere tó, bi a bá huwa ni ọ̀nà ajẹgàba léni lori tabi ni ọ̀nà apàṣẹwàá, ó sábà maa ń fi iyì ara-ẹni du awọn ẹlomiran. Ninu ìwé-àkọgboyèjáde fun ẹkọ onipo-giga ju ni yunifasiti ti a tẹjade ni 1988, oluwadii kan, Jette Ingerslev, ṣalaye ohun ti awujọ awọn ọlọ́jọ́-orí 85 funraawọn kà sí ohun ti o ṣe pataki julọ fun ijojulowo igbesi-aye wọn pe: “Awọn agbegbe mẹta ni wọn fi si ipo akọkọ julọ: wíwà pẹlu awọn ibatan; ilera rere; ati eyi ti o kẹhin ṣugbọn ti ijẹpataki rẹ̀ kò kere, lílè ṣe ipinnu tiwọn funraawọn.” Ṣakiyesi pe baba-nla awọn Heberu naa Jakọbu ni awọn ọmọkunrin rẹ̀ kò bá lò lọna rirẹlẹ nigba ti o ti darugbo; awọn idaniyan rẹ̀ ni wọn bọ̀wọ̀ fun.—Genesisi 47:29, 30; 48:17-20.
Awọn wọnni tí ara wọn kò dá ni a tun gbọdọ bá lò pẹlu iyì. Alagba kan padanu agbara rẹ̀ lati sọrọ, kawe, ati kọwe nitori aṣiṣe kan ti a ṣe nigba iṣẹ́-abẹ. Eyi jẹ́ àjálu lílékenkà kan, ṣugbọn awọn alagba ẹlẹgbẹ rẹ̀ pinnu lati ṣe ohun yoowu ti wọn lè ṣe lati mu ki o maṣe nimọlara jijẹ aláìwúlò. Wọn ń ka awọn lẹta ijọ fun un nisinsinyi wọn sì ń fi i kún ìwéwèé awọn ọ̀ràn ijọ miiran. Ni ipade awọn alagba, wọn a maa gbidanwo lati wadii ohun ti èrò rẹ̀ jẹ́. Wọn jẹ ki o mọ̀ pe awọn ṣì kà á si alagba ẹlẹgbẹ wọn kan ati pe awọn mọriri wíwàníbẹ̀ rẹ̀. Ninu ijọ Kristian, gbogbo wa lè sapa ki o baa lè jẹ pe kò sí awọn alaisan tabi agbalagba kankan ti yoo nimọlara‘ìṣátì’ tabi ìyọsílẹ̀.—Orin Dafidi 71:9.
Itilẹhin Lati Jere Okun Tẹmi
Gbogbo wa ni a nilo ounjẹ tẹmi lati mú ki igbagbọ wa walaaye ki o sì lagbara. Idi niyẹn ti a fi fun wa niṣiiri lati ka Bibeli ati awọn itẹjade ti a gbekari Bibeli lojoojumọ ki a sì fi itara ṣajọpin ninu awọn ipade Kristian ati awọn igbokegbodo iwaasu. Niye ìgbà, awọn alaisan ati awọn agbalagba nilo iranlọwọ lati ṣaṣepari eyi, ó sì ṣe pataki lati ṣe ohun ti o bọgbọnmu ninu ọ̀ràn tiwọn ni pataki. Lọna ti o muni layọ, ọpọ ṣì lè lọ si awọn ipade Kristian bi a bá pese ọkọ̀-ìrìnnà ati iwọnba itilẹhin ninu Gbọngan Ijọba. Lilọ si iru awọn ipade bẹẹ wọn wà fun iṣiri ńláǹlà fun ijọ. Ifarada wọn ń runisoke ó sì ń fun igbagbọ lokun.
Ninu ọpọlọpọ ọ̀ràn awọn alaisan ati awọn agbalagba tun lè ní ipin ti o ṣe gúnmọ́ ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian. Awọn kan ni a lè fikun awujọ inu ọkọ̀ ayọkẹlẹ kan fun ijẹrii, laiṣiyemeji wọn yoo sì nimọlara ìtura nipa lílè ṣe iwọnba ikesini diẹ, àní bi o tilẹ jẹ́ iwọnba diẹ. Nigba ti eyi kò bá ṣeeṣe mọ́, wọn lè rí ayọ ninu jijẹrii lọna aijẹ-bi-aṣa fun awọn ẹnikọọkan ti wọn bá ń bá pade. Arabinrin kan ti àrùn káńsà kọlu pinnu lati lo ohun yoowu ki o ṣẹku ninu igbesi-aye rẹ̀ ninu akanṣe isapa lati mú ihinrere tẹsiwaju. Iwaasu onigboya rẹ̀ jẹ́ iṣiri fun gbogbo eniyan. Ó tilẹ wéwèé isinku tirẹ̀ funraarẹ ki a baa lè fun awọn ibatan alaigbagbọ, oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ̀, ati awọn aladuugbo rẹ̀ ni ijẹrii gbígbámúṣé. Awọn ipo rẹ̀ ti ń banininujẹ tipa bayii “yọrisi ilọsiwaju ihinrere,” ti ipinnu rẹ̀ lati fi igbagbọ ati igbọkanle hàn sì fun awọn ọjọ ikẹhin rẹ̀ ni itumọ akanṣe.—Filippi 1:12-14.
Ó dara lati ran awọn alaisan ati awọn agbalagba lọwọ lati lókun nipa tẹmi. Awọn idile lè késí wọn lati ṣajọpin ninu ibakẹgbẹ pẹlu idile ni àṣálẹ́, tabi ki wọn maa lọ ṣe apakan ikẹkọọ idile wọn lóòrèkóòrè ni ile ẹni naa ti kò lè jade. Ìyá kan mú awọn ọmọ rẹ̀ ti o kere julọ wá si ile arabinrin agbalagba kan ki wọn baa lè ka Iwe Itan Bibeli Mi papọ. Eyi mú ki inu arabinrin agbalagba naa dùn, awọn ọmọ naa sì gbadun afiyesi ti o fifun wọn.
Bi o ti wu ki o ri, awọn akoko a maa wà, nigba ti a kò nilati yọ alailera kan lẹnu ju, ó sì lè dara julọ nigba naa lati wulẹ ka awọn akojọpọ-ọrọ soke fun wọn lóòrèkóòrè. Bi o ti wu ki o ri, ranti, pe bi ẹnikan bá jẹ́ alailera jù niti ara-ìyára lati ṣajọpin ninu ijumọsọrọpọ kan, ẹni yii ṣì lè nilo tabi ki o lọkan-ifẹ si ìwọ̀n ibakẹgbẹ tẹmi kan. A lè gbadura pẹlu iru awọn ẹni bẹẹ, kawe fun wọn, tabi sọ awọn iriri; ṣugbọn a nilati ṣọra ki a máṣe pẹ́ ju bi ara wọn ti lè gbàá lọ.
Iṣẹ-isin mimọ ọlọ́wọ̀ kan ṣì wà ti ọpọ julọ awọn alaisan ati awọn agbalagba lè ṣe: adura nititori awọn ẹlomiran. Awọn ọmọ-ẹhin ijimiji so ijẹpataki ńlá mọ iṣẹ-ojiṣẹ yii. Ni akoko kan wọn pín ẹrù iṣẹ ti o wà ninu ijọ ni iru ọ̀nà kan bẹẹ ti awọn aposteli fi lè kó afiyesi jọ sori adura. Epafra oluṣotitọ ni a mẹnukan gẹgẹ bi ẹni ti ‘ń fi ìwàyá-ìjà gbadura nititori awọn miiran.’ (Kolosse 4:12; Iṣe 6:4) Iru adura bẹẹ ṣe pataki julọ ó sì ṣanfaani.—Luku 2:36-38; Jakọbu 5:16.
Jehofa ń ranti awọn alaisan ati awọn agbalagba ó sì ń bojuto wọn ni akoko ibi wọn. Ó fi ẹ̀tọ́ reti pe ki awa pẹlu gbé ohun ti a lè ṣe lati ràn wọ́n lọwọ ki a sì tì wọn lẹhin yẹwo. Aniyan ti a fihàn ṣagbeyọ ipinnu wa lati pa iwatitọ tiwa mọ́. A sì layọ lati ronu nipa awọn ọ̀rọ̀ Ọba Dafidi pe: “Oluwa mọ ọjọ ẹni iduroṣinṣin: ati ilẹ̀-ìní wọn yoo wà laelae.”—Orin Dafidi 37:18.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Fifunni ni Iranlọwọ Gbigbeṣẹ Pẹlu Òye
AWỌN ọ̀rẹ́ ati ibatan nilati gba ìmọ̀ akọkọbẹrẹ ṣugbọn ti o tọna nipa bi a tií bojuto awọn alaisan ati awọn agbalagba. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a lè fun wọn niṣiiri lati ni iṣarasihuwa titọ nipa igbesi-aye lati nimọlara pe a nilo ti a sì mọriri wọn, ati lati ní imọlara pe wọn jámọ́ nǹkan. Nipa bayii animọ igbesi-aye wọn yoo maa wà lori iwọn ti yoo pa ayọ wọn ninu Jehofa mọ́, laika awọn ẹfọri ati irora wọn sí. A ti kiyesi i pe ọpọlọpọ ninu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń walaaye titi di arugbo kùjọ́kùjọ́. Okunfa alagbara ti ń dakun un laiṣiyemeji ni ọkàn-ìfẹ́ wọn ti o walaaye ninu ireti ti o wà niwaju, itẹsi ti ero-ori wọn ti o mọ́lẹ̀ yòò, ati ikopa wọn ninu igbokegbodo Ijọba naa dé iwọn ti o ṣeeṣe. Ààrẹ Watch Tower Society ti o ti dolóògbé, Frederick W. Franz, ẹni ti o fọwọ́rọrí kú ni ìgbà ti ó ń lo ọgọrun-un ọdun rẹ̀ lọ lẹhin igbesi-aye ti o fi tayọtayọ jẹ́ amesojade, jẹ́ apẹẹrẹ titayọ kan nipa eyi.—Fiwe 1 Kronika 29:28.
Ni gbogbogboo, afiyesi fun awọn ọ̀ràn ipilẹ ti itọju ojoojumọ ṣe pataki gan-an: imọtoto ti o dara, ounjẹ ti o bojumu, ohun olómi ti o pọ̀ tó ati iyọ̀, idaraya ti o bọgbọnmu, afẹfẹ tútù, fifi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wọ́nilára, ati ijumọsọrọpọ ti ń runisoke. Ounjẹ ti o bojumu lè pakun iṣiṣẹ agbara ìgbọ́ràn, ìríran, iṣiṣẹ ero-ori, ati iwalalaafia ti ara-ìyára, ati idena àrùn ti o ga bakan naa. Fun awọn agbalagba ọ̀ràn rírọrùn nipa ounjẹ ti o bojumu ati ọpọ ohun olómi lè tumọsi iyatọ laaarin ipo ti o dara ati arán-ṣíṣe. Ó lè beere fun ironu diẹ lati rí iru eré idaraya ti o yẹ ẹnikọọkan. Arabinrin kan ti ń wá lati kawe fun arabinrin arugbo kan ti o sì ti fẹrẹẹ di afọju ń bẹrẹ ó sì ń pari ọsẹ kọọkan pẹlu rírọra jó yika ninu iyàrá pẹlu arabinrin naa. Ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ naa maa ń wà ni sẹpẹ́ nigba gbogbo pẹlu orin ti a ti ṣàyàn, awọn mejeeji sì gbadun “eré idaraya ifidanrawo” yii.
Ni ọpọ orilẹ-ede, awọn eto-ajọ aṣètìlẹhìn lè pese iranlọwọ gbigbeṣẹ ti o ṣeyebiye ki wọn sì funni ni isọfunni ati amọran niti awọn ipo pàtó ati bi a ṣe lè koju wọn. (Nitootọ, Kristian kan nilati maa ṣọra nigba gbogbo ki o má di ẹni ti a pa léte dà wọnu awọn igbokegbodo ti ń tabuku si iṣẹ-ojiṣẹ Kristian tootọ wa.) Nigba miiran aranṣe ni a ń fifunni ni ọ̀nà ti yíyá ibusun ile-iwosan, ìfaratì, ọ̀pá agbáradúró, àga alágbàá kẹ̀kẹ́, aranṣe igbọran, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Niwọn bi ọpọ awọn agbalagba ti nimọlara pe awọn kò nilo ohunkohun tabi pe kò niyelori lati gba iru awọn ohun titun bẹẹ, awọn ibatan gbọdọ maa fun wọn ni amọran ti o yekooro nigba gbogbo tabi ki wọn tilẹ lo iyinileropada. Ohun ìdìmú ti o bọgbọnmu fun ilẹkun ile-iwẹ lè ṣokunfa ayọ tootọ pupọ sii ju apẹ̀rẹ̀ òdòdó kan lọ.
Bibojuto awọn agbalagba lè mú ìgalára ti ero-ori nlanla wa, ni pataki bi ẹni naa bá ń ṣarán. Arán-ṣíṣe niye ìgbà maa ń wọle wá láìmọ̀. Ẹnikan lè gbiyanju lati gbéjàkò ó nipa ṣiṣediwọ fun alaisan agbàtọ́jú naa kuro ninu jíjẹ́ amójúkúrò. Ẹnikan ti ń ṣarán lè binu si ẹni ti o ní ifẹ si gidigidi lojiji. Awọn ibatan gbọdọ mọ̀ pe ẹnikan ti ń darugbo tilẹ lè gbagbe gbogbo ohun ti o níí ṣe pẹlu otitọ paapaa—iyọrisi kan ti ń banininujẹ nipa iwolulẹ ara-ìyára ni, kìí ṣe ẹ̀rí ipadanu igbagbọ.
Bi alaisan agbàtọ́jú naa bá wà ni ile-iwosan tabi ile itọju, rírí awọn oṣiṣẹ naa daradara pọndandan ki awọn mẹmba oṣiṣẹ baa lè mọ̀ ohun ti wọn nilati ṣe ni isopọ pẹlu ọjọ́-ìbí, Keresimesi, tabi awọn họlide ayé miiran. Bi iṣẹ́-abẹ kan bá pọndandan, awọn ibatan lè ṣalaye ki wọn sì ṣakọsilẹ oju-iwoye tí alaisan agbàtọ́jú naa dimu niti ifajẹsinilara.
-
-
Ipade ỌdọọdunIlé-Ìṣọ́nà—1993 | August 1
-
-
Ipade Ọdọọdun
OCTOBER 2, 1993
IPADE ỌDỌỌDUN ti awọn mẹmba Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a o ṣe ni October 2, 1993, ni Gbọngan Apejọ ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. Ipade àṣeṣaájú ti kìkì awọn mẹmba ni a o pe apejọpọ rẹ̀ ni 9:30 òwúrọ̀, ti ipade ọdọọdun ti gbogbogboo yoo sì tẹlee ni 10:00 òwúrọ̀.
Awọn mẹmba Ajọ-Ẹgbẹ nilati fi tó Ọfiisi Akọwe leti nisinsinyi nipa iyipada eyikeyii ninu awọn adirẹsi ifiweranṣẹ wọn ni aarin ọdun ti o kọja ki awọn lẹta ìfitónilétí ti a ń lò deedee ati iwe àṣẹ ìṣojúfúnni baa lè dé ọ̀dọ̀ wọn kété lẹhin August 1.
Awọn iwe àṣẹ ìṣojúfúnni naa, ti a o fi ranṣẹ si awọn mẹmba pẹlu ìfitónilétí nipa ipade ọdọọdun, ni a nilati dá pada ki ó baa lè dé Ọfiisi Akọwe Society laipẹ ju August 15 lọ. Mẹmba kọọkan nilati kọ ọ̀rọ̀ kún iwe àṣẹ ìṣojúfúnni tirẹ̀ ni kíámọ́sá ki ó sì dá a pada, ni sisọ yala oun yoo wà ni ibi ipade naa fúnra-òun tabi bẹẹkọ. Ìsọfúnni ti a fifunni lori iwe àṣẹ ìṣojúfúnni kọọkan nilati ṣe pàtó lori kókó yii, niwọn bi a o ti gbarale e fun pipinnu awọn wo ni yoo wà nibẹ fúnraawọn.
A reti pe gbogbo akoko ijokoo naa, titikan awọn ipade iṣẹ àmójútó elétò-àṣà ati awọn irohin, ni a o pari rẹ̀ ni 1:00 ọ̀sán tabi kété lẹhin naa. Kì yoo sí akoko ijokoo ọ̀sán. Nitori ààyè ti o mọniwọn, ìgbàwọlé yoo jẹ́ nipasẹ tikẹẹti nikanṣoṣo. Kò sí iṣeto kankan ti a o ṣe fun siso ipade ọdọọdun naa pọ̀ mọ wáyà tẹlifoonu lọ si awọn gbọngan awujọ miiran.
-