ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Maa Kọni ni Gbangba ati Lati Ile De Ile
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | January 15
    • 17. Kinni a le sọ nipa ipo ti ijẹrii ní ninu igbesi-aye awọn Kristian ijimiji?

      17 Jijẹrii ni o ṣaaju julọ ninu igbesi-aye awọn Kristian ijimiji, ani bi o ti ri laaarin awọn eniyan Jehofa lonii. Edward Caldwell Moore ti Harvard University kọwe pe: “Ki a sọ ọ gan-an bi o ṣe jẹ, itara ọkan nlanla fun titan igbagbọ kalẹ jẹ ohun ti a fi mọ ẹgbẹ́ Kristian ni ọrundun mẹta akọkọ. Ìgbónára Kristian jẹ fun iṣẹ ihinrere, sisọ ihin iṣẹ itunrapada. . . . Bi o ti wu ki o ri, ni akoko ijimiji lọhun-un, itankalẹ agbara idari ati awọn ẹkọ Jesu jẹ iṣẹ awọn ọkunrin ti o yẹ ki a pe ni awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ṣugbọn ni ìwọ̀n kekere. O jẹ aṣeyọri awọn eniyan lati inu gbogbo ẹgbẹ iṣowo ati iṣẹ ọwọ ati lati inu gbogbo eto ẹgbẹ awujọ. Aṣiri igbesi aye ti o tubọ jinlẹ, ẹmi ironu titun siha aye ni [wọn] gbe lọ si ibi ti o jinna julọ ninu ilẹ-ọba [Romu], eyi ti o jẹ igbala ninu iriri wọn. . . . [Isin-Kristian ijimiji] gbagbọ daju lọna jijinlẹ nipa opin eto-aye isinsinyi tí nsunmọtosi. O gbagbọ ninu idasilẹ eto-aye titun kan lojiji ati lọna iyanu.”

      18. Ireti titobilọla wo ni o fi pupọpupọ tayọ àlá awọn aṣaaju oṣelu?

      18 Ninu ijẹrii ile-de-ile ati awọn oriṣi iṣẹ-ojiṣẹ wọn miiran, awọn Ẹlẹrii Jehofa nfi tayọtayọ dari awọn olugbọ wọn taarata si aye titun tí Ọlọrun ti ṣeleri. Awọn ibukun rẹ ti iwalaaye ailopin ti a sọtẹlẹ fi pupọpupọ tayọ àlá àfọkànfẹ́ julọ ti awọn wọnni ti wọn fẹ lati kọ́ eto aye titun kan loni. (2 Peteru 3:13; Iṣipaya 21:1-4) Bi o tilẹ jẹ pe yoo dabi pe olukuluku yoo fẹ lati walaaye ninu aye titun agbayanu ti Ọlọrun, ọran ko ri bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, ẹ jẹ ki a gbe awọn ọna gbigbeṣẹ diẹ yẹwo tẹle e ninu eyi ti awọn iranṣẹ Jehofa le kọ́ awọn wọnni ti wọn nwa ọna iye ayeraye.

  • Ẹ Wá Awọn Wọnni Tí Wọn ní Ìtẹ̀sí-Ọkàn Lọna Títọ́ fun Ìyè Àìnípẹ̀kun
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | January 15
    • Ẹ Wá Awọn Wọnni Tí Wọn ní Ìtẹ̀sí-Ọkàn Lọna Títọ́ fun Ìyè Àìnípẹ̀kun

      “Gbogbo awọn wọnni ti wọn ni itẹsi-ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun di onigbagbọ.”—IṢE 13:48, NW.

      1. Nipa ọkan-aya ẹda eniyan, agbara wo ni Jehofa ní?

      JEHOFA ỌLỌRUN le mọ ohun ti o wa ninu ọkan-aya. Eyi ni a muṣekedere nigbati wolii Samuẹli lọ lati fami ororo yan ọmọkunrin Jesse gẹgẹbi ọba Israẹli. Ni riri Eliabu, Samuẹli “lẹsẹkannaa wipe: ‘Dajudaju ẹni ami-ororo rẹ̀ wa niwaju Jehofa.’ Ṣugbọn Jehofa wi fun Samuẹli pe: ‘Iwọ ma ṣe wo irisi ati giga rẹ̀ ní iduro, nitori emi ti kọ̀ ọ́ tì. Nitori kii ṣe ọna ti eniyan ńgbà wò ni ọna ti Ọlọrun ńgbà wò, nitori pe eniyan lasan nwo ohun ti o farahan fun oju; ṣugbọn niti Jehofa, oun nwo ohun ti ọkan-aya jẹ.’” Ni ibamu pẹlu eyi, Samuẹli ni a dari lati fami ororo yan Dafidi, ẹni ti o jasi ẹni ti o ‘ṣeefaramọ fun ọkan-aya Ọlọrun.’—1 Samuẹli 13:13, 14, NW; 16:4-13, NW.

      2. Kinni o ta gbongbo ninu ọkan-aya iṣapẹẹrẹ eniyan, ki si ni a ka nipa eyi ninu Iwe mimọ?

      2 Ẹnikan maa nfi iṣesi titayọ kan han. Oun ni itẹsi-ọkan kan bayii ni pataki ti o ta gbongbo ninu ọkan-aya iṣapẹẹrẹ rẹ. (Matiu 12:34, 35; 15:18-20) Nipa bayii, a ka nipa ẹnikan ti “ọkan-aya rẹ̀ ní itẹsi si ìjà.” (Saamu 55:21, NW) A sọ fun wa pe “ẹnikẹni ti o ni itẹsi-ọkan si ìrunú pọ ni ìrékọjá.” A si ka pe: “Awọn alabakẹgbẹ kan nbẹ ti wọn ni itẹsi-ọkan lati fọ́ araawọn ẹnikinni keji si wẹwẹ, ṣugbọn ọrẹ kan nbẹ ti o faramọni timọtimọ ju arakunrin lọ.” (Owe 18:24, NW; 29:22) O munilayọ pe, ọpọlọpọ fihan pe wọn dabi awọn Keferi kan ni Antioku ti Pisidia igbaani. Ni gbigbọ nipa ipese Jehofa fun igbala, “wọn bẹrẹsii yọ ati lati fi ogo fun ọrọ Jehofa, ati gbogbo awọn wọnni ti wọn ni itẹsi-ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun di onigbagbọ.”—Iṣe 13:44-48, NW.

      Awọn Onigbagbọ Jẹ “Ọlọkan-aya Mimọgaara”

      3, 4. (a) Awọn wo ni ọlọkan-aya mimọgaara? (b) Bawo ni awọn wọnni ti wọn ni ọkan-aya mimọgaara ṣe ri Ọlọrun?

      3 Awọn onigbagbọ wọnni ni Antioku di awọn Kristian ti a baptisi, awọn oluṣotitọ laarin wọn si le lo awọn ọrọ Jesu naa fun araawọn pe: “Alayọ ni awọn ọlọkan-aya mimọgaara, niwọnbi wọn yoo ti ri Ọlọrun.” (Matiu 5:8, NW) Ṣugbọn awọn wo ni “ọlọkan-aya mimọgaara”? Ati bawo ni wọn ṣe “ri Ọlọrun”?

      4 Awọn ọlọkan-aya mimọgaara mọtonitoni ní inu lọhun-un. Imọriri wọn, awọn ifẹni, ifẹ-ọkan, ati awọn ete-isunniṣe wọn mọgaara. (1 Timoti 1:5) Wọn nri Ọlọrun nisinsinyi niti pe wọn ṣakiyesi rẹ̀ ti o ngbegbeesẹ nititori awọn olupa iwatitọ mọ. (Fiwe Ẹksodu 33:20; Jobu 19:26; 42:5.) Ọrọ Giriiki naa ti a ṣetumọ si “rí” nihin-in tun tumọsi “lati ri pẹlu ero-inu, lati fi iwoye kiyesi, lati mọ̀.” Niwọnbi Jesu ti fi akopọ iwa Ọlọrun han lọna pipe, ijinlẹ-oye sinu akopọ iwa yẹn ni “awọn ọlọkan-aya mimọgaara” gbadun, awọn ẹni ti wọn lo igbagbọ ninu Kristi ati ninu ẹbọ etutu rẹ̀ fun ẹṣẹ, jere idariji fun awọn ẹṣẹ wọn, wọn si lè ṣe ijọsin ṣiṣetẹwọgba fun Ọlọrun. (Johanu 14:7-9; Efesu 1:7) Fun awọn ẹni ororo, riri Ọlọrun de òtéńté rẹ nigbati a ba ji wọn dide si ọrun, nibiti wọn ti ri Ọlọrun ati Kristi gan an. (2 Kọrinti 1:21, 22; 1 Johanu 3:2) Ṣugbọn riri Ọlọrun nipasẹ imọ pipeye ati ijọsin tootọ ni o ṣeeṣe fun awọn wọnni ti wọn jẹ ọlọkan-aya mimọgaara. (Saamu 24:3, 4; 1 Johanu 3:6; 3 Johanu 11) Wọn ni itẹsi-ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun ninu ọrun tabi lori paradise ilẹ aye kan.—Luku 23:43; 1 Kọrinti 15:50-57; 1 Peteru 1:3-5.

      5. Ọna kanṣoṣo wo ni ẹnikan le gba lati di onigbagbọ ati ọmọlẹhin tootọ fun Jesu Kristi?

      5 Awọn wọnni ti ko ni itẹsi-ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun ki yoo di onigbagbọ. Ko ṣeeṣe fun wọn lati mu igbagbọ lo. (2 Tẹsalonika 3:2) Ju bẹẹ lọ, ko si ẹnikan ti o le di ọmọlẹhin Jesu Kristi tootọ ayafi bi o ba jẹ ẹni ti o ṣee kọ ati bí Jehofa, ẹni ti o ri ohun ti ọkan-aya jẹ, bá fa ẹni yẹn. (Johanu 6:41-47) Òótọ ni pe, ninu wiwaasu lati ile de ile, awọn Ẹlẹrii Jehofa ko ṣedajọ ẹnikẹni ṣaaju. Wọn ko le mọ ohun ti o wa ninu ọkan-aya ṣugbọn wọn fi awọn iyọrisi rẹ silẹ sọwọ ìfẹ́ Ọlọrun.

      6. (a) Kinni a ti sọ nipa kíkannilára lẹnikọọkan ninu iṣẹ ojiṣẹ ile-de-ile? (b) Awọn ipese wo ni a ti ṣe lati ran awọn Ẹlẹrii Jehofa lọwọ lati ri awọn wọnni ti wọn ni itẹsi-ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun?

      6 Ọmọwe akẹkọọjinlẹ kan ti wi lọna bibamuwẹku: “[Pọọlu] kọni ni otitọ ni gbangba ati lati ile de ile. Kii ṣe kiki lati ori pepele, ṣugbọn ninu ijumọsọrọpọ pẹlu awọn ẹnikọọkan ti oun waasu Kristi fun. Niye igba kikannilara lẹnikọọkan gbeṣẹ ju iru tabi ọna miiran ninu dide ọdọ awọn eniyan.” (August Van Ryn) Iru awọn itẹjade bii Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun, Reasoning From the Scriptures, ati Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Wa nran awọn Ẹlẹrii Jehofa lọwọ lati sọ awọn asọye ati lati lo bibanisọrọpọ lẹnikọọkan ninu iṣẹ-ojiṣẹ papa wọn lọna didarajulọ. Awọn aṣefihan ninu Ipade Iṣẹ-isin ati imọran Ile-ẹkọ Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Ijọba Ọlọrun kun fun iranlọwọ pẹlu. Awọn wọnni ti wọn nwa si ile-ẹkọ naa ngba idalẹkọọ ṣiṣeyebiye ninu iru awọn animọ ọrọ sisọ bii awọn inasẹ-ọrọ didara, lilo awọn Iwe mimọ lọna titọna, imudagba ọrọ ti o ba ọgbọ́n ironu mu, àlàyé ọ̀rọ̀ ti o daju, ìlò awọn àkàwé, ati awọn ipari ọrọ gbigbeṣẹ. Ẹ jẹ ki a wo bi Bibeli ṣe tubọ fi iniyelori fun itọni yii ti o le mu ki awọn eniyan Ọlọrun gbeṣẹ sii bi wọn ti nwa awọn wọnni ti wọn ni itẹsi-ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun.

      Awọn Inasẹ Ọrọ Ti Nmunironu

      7. Awọn ọrọ ibẹrẹ Iwaasu Jesu lori Oke kọni ni kinni nipa awọn inasẹ-ọrọ?

      7 Lati inu apẹẹrẹ Jesu, awọn wọnni ti nmurasilẹ fun ijẹrii ile-de-ile le kẹkọọ ohun kan nipa awọn inasẹ-ọrọ ti o nru ọkan ifẹ soke. Ni bibẹrẹ Iwaasu rẹ lori Oke, oun lo ọrọ naa “alayọ” nigba mẹsan-an. Fun apẹẹrẹ-atilẹhin, oun wipe: “Alayọ ni awọn wọnni ti aini wọn nipa tẹmi njẹ lọ́kàn, niwọnbi ijọba awọn ọrun ti jẹ tiwọn. . . . Alayọ ni awọn ọlọkantutu, niwọnbi wọn yoo ti jogun ilẹ aye.” (Matiu 5:3-12, NW) Awọn gbolohun ọrọ naa ṣe taarata wọn si ṣekedere. Inasẹ-ọrọ yẹn ru ọkan ifẹ soke dajudaju o si mu awọn olutẹtisilẹ rẹ wọnu ọrọ, tabi tani ko fẹ lati jẹ alayọ?

      8. Ninu iṣẹ ojiṣẹ ile-de-ile, bawo ni a ṣe nilati nasẹ akori fun ibanisọrọpọ?

      8 Akori eyikeyii fun Ibanisọrọpọ ti a lo ninu iṣẹ ojiṣẹ ile-de-ile ni a nilati nasẹ rẹ ni ọna ti o dunmọni ti o jẹ onifojusọna fun rere. Ṣugbọn ẹnikẹni ko nilati lo inasẹ ọ̀rọ̀ amunigbọnriri, iru gẹgẹ bi, “Mo ni iṣẹ kan lati jẹ fun ọ lati gbangba ojude ofuurufu.” Dajudaju ọrun ni orisun ihinrere naa, ṣugbọn iru inasẹ ọrọ bẹẹ le mu ki onile naa ṣe kayefi boya Ẹlẹrii naa ni oun nilati foju ṣiṣepataki wò tabi sọ fun ki o ba ẹsẹ rẹ sọrọ ni kiakia bi o ba ti le ṣeeṣe to.

      Mímójútó Ọrọ Ọlọrun Bi O Ti Yẹ

      9. (a) Bawo ni a ṣe nilati nasẹ, ka, ati fi awọn iwe mimọ silo ninu iṣẹ ojiṣẹ? (b) Apẹẹrẹ wo ni a tọkasi lati fi bi Jesu ṣe lo awọn ibeere hàn?

      9 Ninu iṣẹ-ojiṣẹ papa, gẹgẹbi o ti ri lori pepele, iwe mimọ ni a nilati nasẹ̀ rẹ̀ lọna titọna, kà á pẹlu itẹnumọ ti o yẹ, ki o si fisilo ni ọna ṣiṣekedere, ti o peye. Awọn ibeere ti nmu ki onile kan ronu nipa awọn koko Iwe mimọ ti o le ṣeranlọwọ pẹlu. Lẹẹkan sii, awọn ọna ti Jesu nlo maa nkọnilẹkọọ. Ninu iṣẹlẹ kan, ọkunrin kan ti o mọ Ofin Mose daradara beere lọwọ rẹ: “Olukọni, kinni emi yoo ṣe ki emi ki o le jogun iye ainipẹkun?” Ni ifesipada Jesu beere: “Kinni a kọ sinu iwe ofin? Bi iwọ ti ka a?” Laisi iyemeji, Jesu mọ pe ibeere yii ni ọkunrin naa le dahun. Oun si fesipada lọna titọ, ni wiwipe: “Ki iwọ ki o fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkan rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ; ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ.” Eyi mu ki Jesu gbóríyìn fun un, ijiroro siwaju sii tẹle e.—Luku 10:25-37.

      10. Kinni a nilati fisọkan nipa akori fun ibanisọrọpọ, ki si ni a nilati yẹra fun nigbati a ba nbi awọn onile ni ibeere?

      10 Awọn wọnni ti njẹrii lati ile de ile nilati tẹnumọ ẹṣin-ọrọ akori fun ibanisọrọpọ ki wọn sì mu idi fun kika awọn ẹsẹ iwe Bibeli ti o sọrọ lori koko ọrọ naa ṣekedere. Niwọnbi Ẹlẹrii naa ti ngbiyanju lati de inu ọkan-aya onile naa, oun nilati yẹrafun bibeere awọn ibeere ti nkojutibani. Ninu lilo Ọrọ Ọlọrun, ‘njẹ ki ọrọ wa ki o dapọ mọ oore ọfẹ nigbagbogbo, eyi ti a fi iyọ̀ dùn.’—Kolose 4:6.

      11. Ni lilo awọn Iwe mimọ lati ṣatunṣe awọn oju iwoye aitọ, apẹẹrẹ wo ni a ni lati inu adanwo Jesu lati ọwọ Satani?

      11 Paapaa ni pataki ni awọn ipadabẹwo o le jẹ ọranyan lati ṣatunṣe awọn oju-iwoye alaitọna nipa siso ohun ti awọn Iwe mimọ wi niti gidi tabi ti o tumọsi. Jesu ṣe ohun kan ti o farajọra ninu ṣíṣá Satani tì lọna lilekoko, ẹni ti o wipe: “Bi iwọ ba nṣe ọmọ Ọlọrun, bẹ silẹ fúnraàrẹ [lati ori ogiri odi tẹmpili naa, bi ohun ti o lè yọrisi ifọwọ ara ẹni pa ara ẹni]; a sa ti kọwe rẹ pe, yoo paṣẹ fun awọn angẹli rẹ nitori rẹ̀, ní ọwọ wọn ni wọn yoo si gbe ọ soke, ki iwọ ki o ma baa fi ẹsẹ rẹ gbún okuta.” Saamu 91:11, 12, tí Satani fayọ, ko da fifi iwalaaye, ẹbun kan lati ọdọ Ọlọrun sabẹ ewu lare. Mimọ daju pe ko tọna lati dan Jehofa wo nipa fifi ẹmi rẹ̀ sinu ewu, Jesu sọ fun Satani pe: “A tun kọ ọ pe, Iwọ ko gbọdọ dán Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ wò.” (Matiu 4:5-7) Dajudaju nitootọ, Satani kii ṣe olùwá otitọ. Ṣugbọn nigbati awọn eniyan ọlọgbọn-ninu ba sọ awọn oju iwoye aitọna ti o le di itẹsiwaju wọn nipa tẹmi lọwọ, ojiṣẹ Ọrọ Ọlọrun nilati fi ọgbọn ẹwẹ sọ ohun ti Iwe mimọ wi ti o si tumọsi han. Gbogbo eyi jẹ ara ‘mímójútó ọrọ otitọ bi o ti tọ’—ọkan lara awọn ẹkọ pataki ti a nkọni ninu Ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun.—2 Timoti 2:15.

      Iyinileropada ni Aye Tirẹ

      12, 13. Eeṣe ti o fi tọna lati lo iyinileropada ninu iṣẹ-ojiṣẹ?

      12 Iyinileropada ni aye titọna ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu rọ Timoti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ lati maa baalọ ninu awọn ohun ti oun ti kọ́ ti a si “yi i leropada lati gbagbọ.” (2 Timoti 3:14, NW) Ni Kọrinti, Pọọlu “yoo sọ ọrọ asọye ninu sinagọọgu ni gbogbo ọjọ isinmi yoo si yi awọn Juu ati Giriiki leropada.” (Iṣe 18:1-4) Ni Efesu, oun ‘sọ awọn ọrọ asọye o si lo iyinileropada nipa ijọba Ọlọrun’ lọna aṣeyọrisirere. (Iṣe 19:8) Nigba ti a faṣẹ ọba há a mọle ni Romu, apọsteli naa pe awọn eniyan sọdọ rẹ o si fun wọn ni ijẹrii, “ni lilo iyinileropada,” awọn kan si di onigbagbọ.—Iṣe 28:23, 24.

      13 Dajudaju nitootọ, laika bi Ẹlẹrii ti le gbiyanju lati jẹ ayinileropada si, kiki awọn wọnni ti wọn ni itẹsi-ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun ni yoo di onigbagbọ. Awọn alaye ọrọ ti wọn daju ati awọn alaye ṣiṣekedere, bi a ba fi ọgbọn ẹ̀wẹ́ gbe wọn kalẹ, le yi wọn leropada lati gbagbọ. Ṣugbọn kinni o tun le ṣeranlọwọ lati yi wọn leropada?

      Jẹ Ki Ọrọ Rẹ Ba Ọgbọn Ironu Mu ki o si Daju

      14. (a) Kinni ọrọ ọlọgbọn ninu, ti o bọ soju ọna lẹsẹẹsẹ wémọ́? (b) Alaye ọrọ ti o daju beere fun kinni?

      14 Ọkan lara awọn animọ ọrọ sisọ ti a tẹnumọ ninu Ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun ni lọgbọn ninu, bọsoju ọna lẹsẹẹsẹ. Eyi wemọ tito gbogbo awọn ero ti o ṣe pataki ati akojọ ọrọ bibaratan lẹsẹẹsẹ lọna ti o lọgbọn ninu. Eyi ti o tun ṣekoko ni alaye ọrọ ti o daju, ti o beere fun fifi ipilẹ rere lelẹ ati pipese ẹri yiyekooro. Ohun ti o farajọ eyi ni riran awọn olufetisilẹ lọwọ lati ronu jinlẹ nipa mimu ki koko ti ẹ jọ fohunṣọkan le lori maa baalọ, sisọrọ lori awọn koko lọna ti o to, ati fifi wọn silo lọna gbigbeṣẹ. Lẹẹkan sii, Iwe mimọ pese awọn itọsọna.

      15. (a) Bawo ni Pọọlu ṣe gba afiyesi ti o si fidi koko ajọfohunṣọkan lelori mulẹ nigbati oun sọrọ lori Oke Mars? (b) Ninu asọye Pọọlu ẹri wo ni a ni pe ọrọ ọlọgbọn ninu, ti o bọ soju ọna lẹsẹẹsẹ?

      15 Awọn animọ ọrọ sisọ wọnyi han gbangba ninu asọye olokiki ti apọsteli Pọọlu lori Oke Mars ni Ateni igbaani. (Iṣe 17:22-31) Inasẹ ọrọ rẹ gba afiyesi o si fi idi koko ajọfohunṣọkan mulẹ, nitori oun wipe: “Ẹyin ara Ateni, mo woye pe ni ohun gbogbo ẹ kun fun oniruuru isin ju.” Fun wọn, eyi laiṣiyemeji jọ bi ọrọ iyin. Lẹhin mimẹnukan pẹpẹ kan ti a yasimimọ fun “Ọlọrun Aimọ,” Pọọlu tẹsiwaju pẹlu ọrọ rẹ ti o lọgbọn ninu, ti o bọ soju ọna lẹsẹẹsẹ ati alaye ọrọ ti o daju. Oun tọka jade pe Ọlọrun yii ti wọn ko mọ ni o ti “da aye ati ohun gbogbo ti o nbẹ ninu rẹ.” Laidabi Atena tabi awọn ọlọrun ajọsinfun Giriiki miiran, ‘oun kii gbe ile ti a fi ọwọ kọ; bẹẹ ni a kii fi ọwọ eniyan sìn ín.’ Apọsteli naa fihan lẹhin naa pe Ọlọrun yii fun wa ni ìyè ko si jẹ ki a táràrà fun oun bi afọju. Lẹhin naa Pọọlu ronújinlẹ pe Ẹlẹdaa wa, ti o ti gbojufo awọn ìgbà àìmọ̀ oloriṣa da, ‘nsọ fun gbogbo eniyan nibi gbogbo lati ronupiwada.’ Eyi, lọna ti o ba ọgbọn ironu mu ṣamọna si koko naa pe ‘Ọlọrun yoo ṣe idajọ awọn olugbe aye ni ododo, nipasẹ ọkunrin naa ti oun ti yan ẹni ti oun ti ji dide kuro ninu oku.’ Niwọnbi Pọọlu ti “nwaasu Jesu, oun ajinde,” awọn ara Ateni wọnni mọ pe Onidaajọ yii yoo jẹ Jesu Kristi.—Iṣe 17:18.

      16. Bawo ni asọye Pọọlu lori Oke Mars ati idanilẹkọọ ninu Ile-ẹkọ Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Iṣakoso Ọlọrun ṣe lè nipa lori iṣẹ-ojiṣẹ ẹnikan?

      16 Loootọ, Pọọlu ko waasu lati ile de ile lori Oke Mars. Ṣugbọn lati inu asọye rẹ ati idanilẹkọọ ti a fifunni ninu Ile-ẹkọ Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Iṣakoso Ọlọrun, awọn Ẹlẹrii Jehofa le kẹkọọ ohun pupọ ti o le ṣalekun iṣẹ-ojiṣẹ papa wọn. Bẹẹni, gbogbo eyi ṣeranwọ lati sọ wọn di ojiṣẹ gbigbeṣẹ sii, ani gẹgẹ bi ọrọ ti o lọgbọ ninu ati alaye ọrọ ti o daju Pọọlu ṣe yi diẹ lara awọn ara Ateni wọnni leropada lati di onigbagbọ.—Iṣe 17:32-34.

      Lo Awọn Akawe Akọnilẹkọọ

      17. Iru awọn akawe wo ni a nilati lo ninu iṣẹ-ojiṣẹ?

      17 Ile-ẹkọ Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Iṣakoso Ọlọrun tun ran awọn ojiṣẹ Ọlọrun lọwọ lati lo awọn akawe rere ninu iwaasu ile-de-ile ati awọn ọna iṣẹ ojiṣẹ wọn miiran. Lati tẹnumọ awọn koko pataki, awọn àkàwé rirọrun ti o ṣeegbọ ni a nilati lò. Ẹlẹrii naa nilati fa wọn yọ lati inu awọn ipo ti a mọ̀dunjú ki o si ṣọra lati mu ifisilo wọn ṣekedere. Awọn àkàwé Jesu doju ila gbogbo awọn ohun ti a beere fun wọnyi.

      18. Bawo ni Matiu 13:45, 46 ṣe jasi eyi ti o wulo ninu iṣẹ-ojiṣẹ?

      18 Fun apẹẹrẹ, gbe awọn ọ̀rọ̀ Jesu yẹwo: “Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi ọkunrin oniṣowo kan, ti nwa peali ti o dara: nigba ti o ri peali olówò iyebiye kan, o lọ, o si ta gbogbo nnkan ti o ni, o si ra a.” (Matiu 13:45, 46) Peali jẹ okuta iyebiye ti a nri ninu awọn ikarawun ìsán ati awọn ẹran onikarawun miiran. Ṣugbọn kiki awọn peali diẹ ni o “dara.” Olówò naa ni oye-inu ti a nilo lati mọriri iniyelori titayọ ti peali kan yii o si muratan lati jọwọ ohun gbogbo yooku lati jere rẹ̀. Boya nigba ipadabẹwo tabi ikẹkọọ Bibeli ile, àkàwé yii ni a lè lo lati fihan pe ẹnikọọkan ti o mọriri Ijọba Ọlọrun nitootọ yoo huwa gẹgẹbi olówò yẹn. Iru ẹni bẹẹ yoo fi Ijọba naa si ipo kin-inni ninu igbesi-aye, ni mimọ pe o yẹ fun irubọ eyikeyii.

      Pari Ọrọ Pẹlu Isunniṣe

      19. Ninu iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile, kinni awọn ipari ọrọ nilati fihan onile naa?

      19 Ninu Ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun, awọn eniyan Ọlọrun tun kẹkọọ pe ipari ọrọ asọye tabi ijiroro nilati ni ibatan taarata pẹlu ẹṣin-ọrọ o si nilati fihan awọn olugbọ ohun ti wọn nilati ṣe ki o si fun wọn ni iṣiri lati ṣe e. Ninu iṣẹ-ojiṣẹ ile-de-ile, onile naa ni a nilati fi ipa-ọna ti a reti pe ki ó tẹle ni pato han, iru bii titẹwọgba iwe-itẹjade Bibeli tabi fifohunṣọkan fun ipadabẹwo kan.

      20. Apẹẹrẹ rere wo nipa ipari ọrọ asunniṣiṣẹ ni a ní ní Matiu 7:24-27?

      20 Ipari asọye Jesu lori Oke pese apẹẹrẹ rere. Nipasẹ àkàwé ti o rọrun lati loye, Jesu fihan pe yoo jẹ ipa-ọna ọlọgbọn lati kọbiarasi awọn ọrọ rẹ. Oun pari ọrọ rẹ pe: “Nitori naa ẹnikẹni ti o ba gbọ ọrọ temi wọnyi, ti o ba si ṣe wọn, emi yoo fiwe ọlọgbọn eniyan kan, ti o kọ ile rẹ si ori apata: òjò si rọ, ikun-omi si de, afẹfẹ si fẹ, wọn sì bilu ile naa; ko si wo, nitori ti a fi ipilẹ rẹ sọlẹ lori apata. Ẹnikẹni ti o ba si gbọ ọrọ temi wọnyi, ti ko si ṣe wọn, oun ni emi yoo fi wé aṣiwere eniyan kan ti o kọ ile rẹ si ori iyanrin: òjò sì rọ ikun-omi si de, afẹfẹ si fẹ, wọn si bilu ile naa, o si wo; wíwó rẹ̀ si pọ̀ jọjọ.” (Matiu 7:24-27) Bawo ni eyi ti fihan daradara to pe awọn ojiṣẹ Ọlọrun nilati sakun lati sun awọn onile ṣiṣẹ!

      21. Kinni ijiroro wa ti ṣàkàwé, ṣugbọn kinni a gbọdọ mọdaju?

      21 Awọn koko ti a mẹnukan ṣaaju naa ṣakawe bi Ile-ẹkọ Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Iṣakoso Ọlọrun ti le ran ọpọlọpọ lọwọ lati di olupokiki Ijọba títóótun. Dajudaju nitootọ titootun wa ní kíkún nti ọdọ Ọlọrun wa lakọkọ. (2 Kọrinti 3:4-6) Ati laika bi ojiṣẹ naa ti le tootun si, ko si ẹni ti o le yi awọn eniyan leropada lati di onigbagbọ ayafi bi Ọlọrun ba fa wọn nipasẹ Kristi. (Johanu 14:6) Sibẹ, awọn eniyan Ọlọrun nilati lo anfaani gbogbo awọn ipese tẹmi ti a ṣe lati ọwọ́ Jehofa dajudaju gẹgẹbi wọn ti nwa awọn wọnni ti wọn nitẹsi-ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun.

      Kinni Awọn Idahun Rẹ?

      ◻ Awọn wo ni “ọlọkan-aya mimọgaara,” bawo si ni wọn ṣe “ri Ọlọrun”?

      ◻ Awọn koko ṣiṣepataki wo ni a nilati gbeyẹwo nigbati a ba nnasẹ ihin-iṣẹ Ijọba naa ninu iṣẹ ile-de-ile?

      ◻ Bawo ni a ṣe le mójútó Ọrọ Ọlọrun bi o ti yẹ ninu iṣẹ-ojiṣẹ?

      ◻ Kinni yoo ran wa lọwọ lati ṣe igbekalẹ ọrọ ti o lọgbọ ninu, ti o si daju ninu iṣẹ isin pápá?

      ◻ Kinni a nilati ranti nipa awọn àkàwé ti a nlo ninu iṣẹ-ojiṣẹ?

      ◻ Kinni a nilati ṣaṣepari rẹ nipasẹ awọn ipari ọ̀rọ̀ ti a nlo ninu iṣẹ ijẹrii?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́