Polongo Ìhìn Rere Láìṣojo
1 Nínú ìtàn, a mọ àwọn Kristẹni tòótọ́ fún àìṣojo wọn. Àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá nínú èyí. Láìka jíjù tí a jù wọ́n sẹ́wọ̀n, tí a sì halẹ̀ mọ́ wọn sí, àwọn àpọ́sítélì wọ̀nyí ń bá sísọ òtítọ́ nìṣó láìbẹ̀rù àti láìṣojo. (Ìṣe 4:18-20, 23, 31b) Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú fi àìṣojo ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ, ní ìpínlẹ̀ tí ó nira, bí a tilẹ̀ ṣe inúnibíni sí i lọ́pọ̀lọpọ̀.—Ìṣe 20:20; 2 Kọr. 11:23, 28.
2 Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé, láìka hílàhílo ńláǹlà sí, ó ṣeé ṣe fún àwọn àpọ́sítélì àti àwọn Kristẹni mìíràn jálẹ̀ ìtàn láti máa bá a lọ ní pípolongo ìhìn rere láìṣojo? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè náà nínú Tẹsalóníkà Kìíní 2:2, níbi tí ó ti sọ pé: ‘A máyà le nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín.’ Bákan náà, ó ṣeé ṣe fún Pétérù àti Jòhánù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòó kù láti pòkìkí ìhìn rere láìṣojo. Lẹ́yìn tí a tú wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n tí a jù wọ́n sí, Pétérù àti Jòhánù mú ìròyìn tọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹlẹgbẹ́ wọn lọ. Nínú àdúrà, wọ́n bẹ Jèhófà láti fún wọn ní ìgboyà àti okun ‘láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀.’ Ọlọ́run dáhùn àdúrà wọn lọ́gán, nígbà tí ‘gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kún fún ẹ̀mí mímọ́, tí wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’—Ìṣe 4:29, 31.
3 Lílo Ìgbọ́kànlé Nínú Jèhófà: Àwọn àpọ́sítélì ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà ń tì wọ́n lẹ́yìn. Gbogbo ìlérí tí Jèhófà ti ṣe nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń ṣẹ. Ó sì fúnni ní ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà pé àwọn tí ó kù yóò tipasẹ̀ Jésù Kristi ní ìmúṣẹ. A ha ní ìgbọ́kànlé kan náà yìí láti polongo ìhìn rere láìṣojo bí? Bí a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀ ní àwọn ahọ́n àjèjì tàbí wo àwọn aláìsàn sàn, síbẹ̀síbẹ̀, a ní ẹ̀rí púpọ̀ yanturu fún ìtìlẹ́yìn Jèhófà. Nígbà tí a bá rí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí ń ṣẹ lójú wa, a ha ń sún wa láti sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láìṣojo bí?
4 Bí ó ti wù kí ó rí, a ní láti retí pé irú ìwàásù bẹ́ẹ̀ yóò bá àtakò pàdé. (Joh. 15:20) Bí ọ̀ràn ti rí pẹ̀lú Jésù àti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nìyẹn. Ṣùgbọ́n, èyí kò ṣèdíwọ́ fún wọn tàbí dín agbára tí wọ́n fi wàásù kù. Ní tòótọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, irú àtakò bẹ́ẹ̀ fún wọn ní àǹfààní púpọ̀ sí i láti tan ìhìn rere Ìjọba náà kálẹ̀. (Ìṣe 4:3, 8-13a) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, nítorí rírọ̀ tí a rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lórí àwọn ọ̀ràn ṣíṣe kókó, a sábà máa ń ké sí wa láti wá pèsè ìdí fún ìdúró tí a mú. A máa ń wo irú àkókò bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti polongo ìhìn rere láìṣojo. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ń fara wé Jésù Kristi àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.
5 Ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ń pèsè àǹfààní púpọ̀ sí i fún wa láti polongo ìhìn rere. Ọ̀pọ̀ yóò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní November. Àyíká ipò rẹ yóò ha fàyè gbà ọ́ láti forúkọ sílẹ̀ bí? Nípa sísapá láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, a ń fẹ̀rí hàn pé a dà bíi Pọ́ọ̀lù àti Bánábà. Ìṣe 14:3 sọ pé, “wọ́n lo àkókò gígùn ní sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú àìṣojo nípasẹ̀ ọlá àṣẹ Jèhófà.” Bí ó bá ṣeé ṣe fún wa láti ra àkókò padà nínú àwọn ìgbòkègbodò míràn, láti lo 60 wákàtí, ó kéré tán, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, láàárín oṣù kan, ó dájú pé àwọn ìbùkún wa yóò pọ̀ sí i.
6 Jíjẹ́ aláìṣojo nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣàǹfààní ní pàtàkì nígbà tí a bá ń fi ìwé ìròyìn, àsansílẹ̀ owó, àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí ó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run lọni. Ìhìn iṣẹ́ tí ń gba ẹ̀mí là, tí a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wà nínú wọn. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fà sẹ́yìn, ṣùgbọ́n, kí á wàásù láìṣojo ní fífara wé Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, Jésù, àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.