“Ẹ Yin Jah, Ẹ̀yin Ènìyàn!”
“Gbogbo ohun ẹlẹ́mìí—ẹ jẹ́ kí ó yin Jah.”—ORIN DAFIDI 150:6, NW.
1, 2. (a) Báwo ni ìsìn Kristian tòótọ́ ṣe gbilẹ̀ tó ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Ìkìlọ̀ wo ni àwọn aposteli fúnni? (d) Báwo ni ìpẹ̀yìndà ṣe bẹ̀rẹ̀?
JESU ṣètò àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìjọ Kristian, èyí tí ó gbilẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Láìka àtakò kíkorò ní ti ìsìn sí, ‘ìhìn rere náà ni a wàásù nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.’ (Kolosse 1:23) Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú àwọn aposteli Jesu Kristi, Satani fi ìyọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ gbé ìpẹ̀yìndà lárugẹ.
2 Àwọn aposteli ti kìlọ̀ ṣáájú nípa èyí. Fún àpẹẹrẹ, Paulu sọ fún àwọn alàgbà láti Efesu pé: “Ẹ kíyèsí ara yín ati gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín sípò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó, lati ṣe olùṣọ́ àgùtàn ìjọ Ọlọrun, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọkùnrin oun fúnra rẹ̀ rà. Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi awọn aninilára ìkookò yoo wọlé wá sáàárín yín wọn kì yoo sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, ati pé lati àárín ẹ̀yin fúnra yín ni awọn ọkùnrin yoo ti dìde wọn yoo sì sọ awọn ohun àyídáyidà lati fa awọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:28-30; tún wo 2 Peteru 2:1-3; 1 Johannu 2:18, 19.) Nípa báyìí, ní ọ̀rúndún kẹrin, ìsìn Kristian apẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ sí í lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Ilẹ̀ Ọba Romu. Àwọn ọ̀rúndún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Ilẹ̀ Ọba Romu Mímọ́, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú póòpù Romu, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lórí apá púpọ̀ nínú aráyé. Nígbà tí ó yá, Pùròtẹ́sítáǹtì Alátùn-ún-ṣe dìtẹ̀ lòdì sí àṣejù burúkú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, ṣùgbọ́n ó kùnà láti mú ìsìn Kristian tòótọ́ padà bọ̀ sípò.
3. (a) Báwo àti nígbà wo ni a wàásù ìhìn rere náà fún gbogbo ẹ̀dá? (b) Àwọn ìrètí wo tí a gbé karí Bibeli ni ó ní ìmúṣẹ ní 1914?
3 Síbẹ̀síbẹ̀, bí òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń sún mọ́lé, ọwọ́ àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli olóòótọ́ ọkàn tún dí fún wíwàásù àti nínawọ́ ‘ìrètí ìhìn rere yẹn sí gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.’ Lórí ìpìlẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli, ní ohun tí ó lé ní 30 ọdún ṣáájú, àwùjọ yìí tọ́ka sí ọdún 1914 bí èyí tí yóò sàmì sí òpin “awọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún awọn orílẹ̀-èdè,” sáà àkókò “ìgbà méje,” tàbí 2,520 ọdún, tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìsọdahoro Jerusalemu ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (Luku 21:24; Danieli 4:16) Ní ìmúṣẹ ohun tí wọ́n ń retí, 1914 jẹ́ àkókò ìyípadà pàtàkì nínú àlámọ̀rí ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Ní ọ̀run pẹ̀lú, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé ṣẹlẹ̀. Nígbà yẹn ni Ọba ayérayé gbé Ọba amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, Jesu Kristi, ka orí ìtẹ́ ní òkè ọ̀run, ní ìmúrasílẹ̀ fún gbígbá gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé àti láti tún Paradise dá sílẹ̀.—Orin Dafidi 2:6, 8, 9; 110:1, 2, 5.
Ẹ Wo Messia Ọba!
4. Báwo ni Jesu ṣe gbé ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ Mikaeli?
4 Ní 1914, Messia Ọba yìí, Jesu, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Nínú Bibeli, a tún pè é ní Mikaeli, tí ó túmọ̀ sí “Ta Ni Ó Dà Bí Ọlọrun?,” nítorí ète rẹ̀ dá lórí dídá ipò ọba aláṣẹ Jehofa láre. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Ìṣípayá 12:7-12, nínú ìran, aposteli Johannu ṣàpèjúwe ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ pé: “Ogun . . . bẹ́sílẹ̀ ní ọ̀run: Mikaeli ati awọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá diragoni naa ja ìjà ogun, diragoni naa ati awọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì ja ìjà ogun ṣugbọn oun kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni, a fi diragoni ńlá naa sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa, ẹni tí a ń pè ní Èṣù ati Satani, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀-ayé, a sì fi awọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹlu rẹ̀.” Ẹ wo irú ìṣubú ńláǹlà tí èyí jẹ́ ní tòótọ́!
5, 6. (a) Lẹ́yìn 1914, ìkéde amóríyá wo ni a ṣe láti ọ̀run? (b) Báwo ni Matteu 24:3-13 ṣe bá èyí mu?
5 Ariwo yèè tí ó ta ní ọ̀run pòkìkí pé: “Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé ati agbára ati ìjọba Ọlọrun wa ati ọlá-àṣẹ Kristi rẹ̀, nitori pé olùfisùn awọn arákùnrin wa ni a ti fi sọ̀kò sísàlẹ̀, ẹni tí ń fẹ̀sùnkàn wọ́n tọ̀sán tòru níwájú Ọlọrun wa! Wọ́n [àwọn Kristian olùṣòtítọ́] sì ṣẹ́gun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa [Kristi Jesu] ati nitori ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn, wọn kò sì nífẹ̀ẹ́ ọkàn wọn àní lójú ikú pàápàá.” Èyí túmọ̀ sí ìdáǹdè fún àwọn olùpa ìwà títọ́ mọ́, tí wọ́n ti lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà ṣíṣeyebíye ti Jesu.—Owe 10:2; 2 Peteru 2:9.
6 Ohùn rara náà ní ọ̀run ń bá a nìṣó ní pípolongo pé: “Nítìtorí èyí ẹ máa yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run ati ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn! Ègbé ni fún ilẹ̀-ayé ati fún òkun, nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” “Ègbé” tí a tipa báyìí sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé ti hàn kedere nínú àwọn ogun àgbáyé, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, ìmìtìtì-ilẹ̀, àti ìwà àìlófin tí ń bá ilẹ̀ ayé jà ní ọ̀rúndún yìí. Gẹ́gẹ́ bí Matteu 24:3-13 ṣe ṣàlàyé, Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, àwọn wọ̀nyí yóò jẹ́ apá kan ‘àmì òpin ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan ti ìsinsìnyí.’ Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, láti 1914, aráyé ti ní ìrírí ègbé lórí ilẹ̀ ayé lọ́nà tí kò ṣeé fi wé gbogbo ìtàn ẹ̀dá ènìyàn tí ó ti wà ṣáájú.
7. Èé ṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń wàásù pẹ̀lú ìjẹ́kánjúkánjú?
7 Nínú sànmánì ègbé Satani yìí, aráyé ha lè rí ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la bí? Họ́wù, bẹ́ẹ̀ ni, nítorí Matteu 12:21 sọ nípa Jesu pé: “Nítòótọ́, ninu orúkọ rẹ̀ ni awọn orílẹ̀-èdè yoo ní ìrètí”! Kì í ṣe ‘àmì òpin ètò ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan ìsinsìnyí’ nìkan ni ipò ìrọ́kẹ̀kẹ̀ tí ń bẹ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè sàmì sí, ṣùgbọ́n, ó tún jẹ́ ‘àmì wíwà níhìn-ín Jesu’ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Messia náà ní ọ̀run. Nípa Ìjọba náà, Jesu sọ síwájú sí i pé: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.” (Matteu 24:14) Àwọn ènìyàn kan ṣoṣo wo lórí ilẹ̀-ayé lónìí ní ń wàásù ìrètí kíkọyọyọ ti ìṣàkóso Ìjọba Ọlọrun? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni! Pẹ̀lú ìjẹ́kánjúkánjú, wọ́n ń pòkìkí ní gbangba àti láti ilé dé ilé pé, Ìjọba Ọlọrun ti òdodo àti ti àlàáfíà, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gba àkóso àlámọ̀rí ilẹ̀ ayé. Ìwọ́ ha ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí bí? Kò sí àǹfààní tí ìwọ́ lè ní, tí ó lè tún tóbi ju èyí lọ!—2 Timoteu 4:2, 5.
Báwo Ni “Òpin Náà” Yóò Ṣe Dé?
8, 9. (a) Báwo ni ìdájọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ “ní ilé Ọlọrun”? (b) Báwo ni Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ṣe pa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mọ́?
8 Aráyé ti wọnú sáà ìdájọ́ kan. A sọ fún wa ní 1 Peteru 4:17 pé ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀ “ní ilé Ọlọrun”—ìdájọ́ àwọn ètò àjọ Kristian aláfẹnujẹ́ tí ó ti hàn gbangba láti ìgbà tí “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpakúpa tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò Ogun Àgbáyé Kìíní ní 1914 sí 1918. Báwo ni ọ̀ran Kirisẹ́ńdọ̀mù ti rí nínú ìdájọ́ yìí? Tóò, gbé ìdúró àwọn ṣọ́ọ̀ṣì yẹ̀ wò nínú ṣíṣe ìtìlẹyìn fún ogun láti 1914. A kò ha ti fi “ẹ̀jẹ̀ ẹ̀mí àwọn tálákà àti aláìṣẹ̀” tí wọ́n wàásù fún láti lọ sí ojú ìjà, kó àbàwọ́n bá àwùjọ àlùfáà bí?—Jeremiah 2:34.
9 Ní ìbámu pẹ̀lú Matteu 26:52, Jesu sọ pé: “Gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n bá ń mú idà yoo ṣègbé nípasẹ̀ idà.” Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ òtítọ́ tó nínú àwọn ogun ọ̀rúndún yìí! Àwùjọ àlùfáà ti rọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin láti pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mìíràn nípakúpa, kódà àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà ìsìn wọn—Kátólíìkì ń pa Kátólíìkì, tí Pùròtẹ́sítáǹtì sì ń pa Pùròtẹ́sítáǹtì. A ti gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ga ju Ọlọrun àti Kristi lọ. Láìpẹ́ yìì, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, a ti fi ìsopọ̀ ẹ̀yà ìran ṣáájú àwọn ìlànà Bibeli. Ní Rwanda, níbi tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn olùgbé rẹ̀ ti jẹ́ Kátólíìkì, ó kéré tán, ọ̀kẹ́ márùndínlọ́gbọ̀n ènìyàn ni a pa nípakúpa nínú ìwà ipá ẹ̀yà ìran. Póòpù jẹ́wọ́ nínú ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà ti Vatican L’Osservatore Romano pé: “Èyí jẹ́ pípa ẹ̀yà ìran run yán-án-yán-án, tí ó ṣeni láàánú pé àwọn Kátóíìkì pàápàá ni wọ́n fà á.”—Fi wé Isaiah 59:2, 3; Mika 4:3, 5.
10. Ìdájọ́ wo ni Jehofa yóò mú ṣẹ lórí ìsìn èké?
10 Ojú wo ni Ọba ayérayé náà fi ń wo àwọn ìsìn tí ń fún àwọn ènìyàn ní ìṣírí láti pa ara wọn lẹ́nì kíní-kejì, tàbí tí ń ta kété nígbà tí àwọn mẹ́ḿbà agbo wọn bá ń pa mẹ́ḿbà míràn? Nípa Babiloni Ńlá, ètò ìgbékalẹ̀ ìsìn èké kárí ayé, Ìṣípayá 18:21, 24 sọ fún wa pé: “Áńgẹ́lì alókunlágbára kan sì gbé òkúta kan tí ó dàbí ọlọ ńlá sókè ó sì fi í sọ̀kò sínú òkun, ó wí pé: ‘Lọ́nà yii pẹlu ìgbésọnù yíyára ni a óò fi Babiloni ìlú-ńlá títóbi naa sọ̀kò sísàlẹ̀, a kì yoo sì tún rí i mọ́ láé. Bẹ́ẹ̀ ni, ninu rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ awọn wòlíì ati ti awọn ẹni mímọ́ ati ti gbogbo awọn wọnnì tí a ti fikúpa lórí ilẹ̀-ayé.’”
11. Àwọn ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ wo ni ó ti ń ṣẹlẹ̀ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù?
11 Ní mímú àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ṣẹ, àwọn ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù. (Fi wé Jeremiah 5:30, 31; 23:14.) Ìdí púpọ̀ jẹ́, nítorí ìṣarasíhùwà onígbọ̀jẹ̀gẹ́ ti àwùjọ àlùfáà, ìwà pálapàla ti tàn kalẹ̀ nínú agbo wọn. Ní United States, tí a rò pé ó jẹ́ orílẹ̀-èdè Kristian, nǹkan bí ìdajì gbogbo ìgbéyàwó ń jálẹ̀ sí ìkọ̀sílẹ̀. Oyún àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ogún ọdún àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ láàárín àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ yamùra. Àwọn àlùfáà ń bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe—kì í wulẹ̀ ṣe ní ìgbà mélòó kan. A gbọ́ pé, owó ìtanràn ilé ẹjọ́ tí ó wé mọ́ àwọn ọ̀ràn yìí lè ná Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní United States ní bílíọ̀nù kan dọ́là láàárín ẹ̀wádún. Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ka ìkìlọ̀ aposteli Paulu ní 1 Korinti 6:9, 10 sí, pé: “Kínla! Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé awọn aláìṣòdodo ènìyàn kì yoo jogún ìjọba Ọlọrun? Kí a máṣe ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe awọn àgbèrè, tabi awọn abọ̀rìṣà, tabi awọn panṣágà, tabi awọn ọkùnrin tí a pamọ́ fún awọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tabi awọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dàpọ̀, tabi awọn olè, tabi awọn oníwọra ènìyàn, tabi awọn ọ̀mùtípara, tabi awọn olùkẹ́gàn, tabi awọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yoo jogún ìjọba Ọlọrun.”
12. (a) Báwo ni Ọba ayérayé yóò ṣe gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí Babiloni Ńlá? (b) Ní ìyàtọ̀ sí Kirisẹ́ńdọ̀mù, ìdí wo ni àwọn ènìyàn Ọlọrun yóò ṣe kọ ègbè orin “Hallelujah”?
12 Láìpẹ́, Ọba ayérayé náà, Jehofa, ní gbígbé ìgbésẹ̀ nípasẹ̀ Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò rẹ̀, Kristi Jesu, yóò tú ìpọ́njú ńlá náà sílẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, Kirisẹ́ńdọ̀mù àti gbogbo ẹ̀ka Babiloni Ńlá yòókù yóò jìyà ìmúṣẹ ìdájọ́ Jehofa. (Ìṣípayá 17:16, 17) Wọ́n ti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí aláìyẹ fún ìgbàlà tí Jehofa pèsè nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jesu. Wọ́n ti gan orúkọ mímọ́ Ọlọrun. (Fi wé Esekieli 39:7.) Ẹ wo bí ó ti jẹ́ yẹ̀yẹ́ lásán tó, pé wọ́n ń kọrin ègbè “Hallelujah” nínú àwọn ilé ìsìn olówó iyebíye wọn! Wọ́n yọ orúkọ Jehofa ṣíṣeyebíye kúrò nínú àwọn ìtumọ̀ Bibeli wọn, ṣùgbọ́n, ó dà bí ẹni pé, wọ́n gbàgbé òkodoro òtítọ́ náà pé “Hallelujah” túmọ̀ sí “Ẹ Yin Jah”—“Jah” sì jẹ́ ìkékúrú “Jehofa.” Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, Ìṣípayá 19:1-6 ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ègbè orin “Hallelujah” tí a óò kọ láìpẹ́ ní ṣíṣàjọyọ̀ ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọrun lórí Babiloni Ńlá.
13, 14. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo ni ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e? (b) Àbájáde aláyọ̀ wo ni ó jẹ́ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn olùbẹ̀rù Ọlọrun?
13 Ohun tí yóò tẹ̀ lé e ni, ‘dídé’ Jesu láti kéde ìdájọ́, kí ó sì mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ènìyàn. Òun fúnra rẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn [Kristi Jesu] bá dé ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn áńgẹ́lì pẹlu rẹ̀, nígbà naa ni oun yoo jókòó lórí ìtẹ́ [ìdájọ́] ògo rẹ̀. Gbogbo awọn orílẹ̀-èdè [orí ilẹ̀-ayé] ni a óò sì kó jọ níwájú rẹ̀, oun yoo sì ya awọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn kan ti ń ya awọn àgùtàn sọ́tọ̀ kúrò lára awọn ewúrẹ́. Oun yoo sì fi awọn àgùtàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀. Nígbà naa ni ọba yoo wí fún awọn wọnnì tí wọ́n wà ní ọ̀tún rẹ̀ pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín lati ìgbà pípilẹ̀ ayé.’” (Matteu 25:31-34) Ẹsẹ 46 ń bá a nìṣó ní ṣíṣàlàyé pé, ẹgbẹ́ ewúrẹ́ náà “yoo sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun, ṣugbọn awọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”
14 Ìwé Ìṣípayá nínú Bibeli ṣàpèjúwe bí “Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa,” Oluwa wa ọ̀run, Jesu Kristi, yóò ṣe gẹṣin jagun ní Armageddoni, ní pípa àwọn ètò ìgbékalẹ̀ Satani, ti ìṣèlú àti ti ìṣòwò, run. Nípa báyìí, Kristi yóò ti tú “ìbínú ìrunú Ọlọrun Olódùmarè” dà sórí pápá àkóso Satani lórí ilẹ̀ ayé látòkè délẹ̀. Bí ‘àwọn ohun àtijọ́’ wọ̀nyí ‘ti ń kọjá lọ,’ a óò mú àwọn ẹ̀dá ènìyàn olùbẹ̀rù Ọlọrun wọnú ayé tuntun ológo níbi tí Ọlọrun ‘yóò ti nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.’—Ìṣípayá 19:11-16; 21:3-5.
Àkókò Kan Láti Yin Jah
15, 16. (a) Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a kọbi ara sí ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ tí Jehofa sọ? (b) Kí ni àwọn wòlíì àti àwọn aposteli fi hàn pé a gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìgbàlà, kí sì ni èyí lè túmọ̀ sí fún ògìdìgbó?
15 Ọjọ́ náà fún mímú ìdájọ́ ṣẹ ti sún mọ́lé! Nítorí náà, yóò dára kí a kọbi ara sí ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Ọba ayérayé náà. Sí àwọn tí wọ́n ṣì wà nínú ẹ̀wọ̀n àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà ìsìn èké, ohùn kan láti ọ̀run polongo pé: “Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹlu rẹ̀ ninu awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára awọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n, níbo ni àwọn olùsálà yóò lọ? Òtítọ́ kan ṣoṣo ni ó lè wà, bí ó bá sì jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ni ó lè wà. (Ìṣípayá 18:4; Johannu 8:31, 32; 14:6; 17:3) Jíjèrè ìwàláàyè wa ayérayé sinmi lórí ṣíṣàwárí ìsìn náà àti ṣíṣègbọràn sí Ọlọrun rẹ̀. Bibeli darí wa sí i ni Orin Dafidi 83:18, tí ó kà pé: “Ìwọ, orúkọ ẹnì kan ṣoṣo tí í jẹ́ Jehofa, ìwọ ni Ọ̀gá Ògo lórí ayé gbogbo.”
16 Bí ó ti wù kí ó rí, a ní láti ṣe ju wíwulẹ̀ mọ orúkọ Ọba ayérayé náà lọ. A ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kí a sì kọ́ nípa àwọn ànímọ́ àti ète rẹ̀ títóbi lọ́lá. Lẹ́yìn náà, a ní láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ fún àkókò lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú Romu 10:9-13. Aposteli Paulu ṣàyọlò ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí a mí sí, ó sì parí rẹ̀ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jehofa ni a óò gbàlà.” (Joeli 2:32; Sefaniah 3:9) Gbà là kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé, ògìdìgbó tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè ìràpadà tí Jehofa ṣe nípasẹ̀ Kristi lónìí, yóò rí ìdáǹdè gbá kúrò nínú ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀, nígbà tí a óò mú ìdájọ́ ṣẹ sórí ayé Satani tí ó ti bà jẹ́.—Ìṣípayá 7:9, 10, 14.
17. Ìrètí kíkọyọyọ wo ni ó yẹ kí ó sún wa láti dara pọ̀ nísinsìnyí ní kíkọ orin Mose àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà?
17 Kí ni ìfẹ́ Ọlọrun fún àwọn tí wọ́n ní ìrètí lílà á já? Òun ni pé, kí a dara pọ̀ àní nísinsìnyí, nínú kíkọ orin Mose àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, ní yíyin Ọba ayérayé ní ìfojúsọ́nà fún ìṣẹ́gun rẹ̀. A ń ṣe èyí nípa sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ète rẹ̀ ológo. Bí a ti ń tẹ̀ síwájú nínú òye Bibeli, a ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Ọba ayérayé náà. Ìyẹn yóò yọrí sí wíwà láàyè wa títí ayérayé lábẹ́ ìṣètò tí Ọba ńlá yìí ṣàpèjúwe, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i ní Isaiah 65:17, 18 pé: “Èmi óò dá ọ̀run tuntun [Ìjọba Messia Jesu] àti ayé tuntun [àwùjọ tuntun ti aráyé olódodo]: a kì yóò sì rántí àwọn ti ìṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí àyà. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó yọ̀, kí [ẹ sì kún fún ìdùnnú-ayọ̀, NW] títí láé nínú èyí tí èmi óò dá.”
18, 19. (a) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ Dafidi ní Orin Dafidi 145 yẹ kí ó sún wa ṣe? (b) Kí ni a lè máa fi ìgbọ́kànlé retí lọ́wọ́ Jehofa?
18 Dafidi onipsalmu náà ṣàpèjúwe Ọba ayérayé náà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Títóbi ni Oluwa, ó sì ní ìyìn púpọ̀púpọ̀; àwámáridìí sì ni títóbi rẹ̀.” (Orin Dafidi 145:3) Bẹ́ẹ̀ ni, àwámáridìí ni títóbi rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpin gbalasa òfuurufú àti ayérayé ti jẹ́! (Romu 11:33) Bí a ti ń bá a nìṣó ní gbígba ìmọ̀ Ẹlẹ́dàá wa àti ìpèsè ìràpadà rẹ̀ nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀, Kristi Jesu, sínú, àwa yóò fẹ́ láti túbọ̀ yin Ọba wa ayérayé púpọ̀púpọ̀ sí i. Àwa yóò fẹ́ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí Orin Dafidi 145:11-13 ti là á lẹ́sẹẹsẹ pé: “Wọn óò máa sọ̀rọ̀ ògo ìjọba rẹ, wọn óò sì máa sọ̀rọ̀ agbára rẹ: Láti mú iṣẹ́ agbára rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn, àti ọlá ńlá ìjọba rẹ̀ tí ó lógo, Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni, àti ìjọba rẹ láti ìrandíran gbogbo.”
19 A lè fi ìgbọ́kànlé retí pé Ọlọrun wa yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé: “Ìwọ́ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ́ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” Ọba ayérayé náà yóò ṣáájú wa lọ ní jẹ̀lẹ́ńkẹ́ títí dé òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, nítorí, Dafidi mú un dá wa lójú pé: “Oluwa dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí: ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn búburú ni yóò pa run.”—Orin Dafidi 145:16, 20.
20. Báwo ni o ṣe ń dáhùn padà sí ìkésíni Ọba ayérayé náà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ọ́ nínú àwọn psalmu márùn ún tí ó gbẹ̀yìn?
20 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn psalmu márùn-ún tí ó kẹ́yìn nínú Bibeli bẹ̀rẹ̀, wọn sì parí pẹ̀lú ìkésíni, “Hallelujah.” Nípa báyìí, Orin Dafidi 146 (NW) ké sí wa pé: “Ẹ yin Jah, ẹ̀yin ènìyàn! Yin Jehofa, ìwọ ọkàn mi. Èmi yóò yin Jehofa nígbà tí mo wà láàyè. Èmi yóò kọrin adùnyùngbà sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo ṣì ń bẹ.” Ìwọ yóò ha dáhùn sí ìpè yẹn bí? Dájúdájú, o yẹ kí o fẹ́ láti yìn ín! Ǹjẹ́ kí o wà lára àwọn tí a ṣàpèjúwe ní Orin Dafidi 148:12, 13 pé: “Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn wúńdíá, àwọn arúgbó ènìyàn àti àwọn ọmọdé; kí wọn kí ó máa yin orúkọ Oluwa; nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá; ògo rẹ̀ borí ayé òun ọ̀run.” Ǹjẹ́ kí a dáhùn padà tọkàntọkàn sí ìkésíni náà pé: “Ẹ yin Jah, ẹ̀yin ènìyàn!” Lápapọ̀, ẹ jẹ́ kí a yin Ọba ayérayé!
Kí Ni Ọ̀rọ̀ Ìlóhùnsí Rẹ?
◻ Kí ni àwọn aposteli Jesu kìlọ̀ tẹ́lẹ̀?
◻ Bẹ̀rẹ̀ ní 1914, àwọn ìgbésẹ̀ onípinnu wo ni ó tí wáyé?
◻ Àwọn ìdájọ́ wo ni Jehofa yóò mú ṣẹ láìpẹ́?
◻ Èé ṣe tí àkókò yìí fi jẹ́ àkókò pàtàkì jù lọ láti yin Ọba ayérayé?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
Sànmánì Àjálù Onírúkèrúdò Yìí
Òkodoro òtítọ́ náà pé, ilẹ̀ sànmánì onírúkèrúdò mọ́ ní kùtùkùtù ọ̀rúndún ogún yìí, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti jẹ́wọ́ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìfáárà ìwé náà, Pandaemonium, tí a kọ láti ọwọ́ Aṣòfin Àgbà ti United States, Daniel Patrick Moynihan, tí a tẹ̀ jáde ní 1993, ọ̀rọ̀ àkíyèsí kan lórí “àjálù 1914” kà pé: “Ogún dé, ayé sì yí padà—pátápátá. Orílẹ̀-èdè mẹ́jọ péré ni ó wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí, tí wọ́n jọ wà ní 1914, tí a kò sì tí ì fi ìwà ipá yí ọ̀nà ìṣàkóso rẹ̀ padà láti ìgbà náà wá. . . . Nínú nǹkan bí 170 tí ó ṣẹ́ kù tí wọ́n jọ wà nísinsìnyí, yóò ti yá jù fún àwọn kan láti ní ìrírí púpọ̀ nínú rúkèrúdò lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí nítorí pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá wọn sílẹ̀ ni.” Ní tòótọ́, sànmánì náà láti 1914 ti rí àjálù lórí àjálù!
Ní 1993, a tún tẹ ìwé náà, Out of Control—Global Turmoil on the Eve of the Twenty-First Century, jáde. Òǹṣèwé náà ni Zbigniew Brzezinski, ọ̀gá àgbà tẹ́lẹ̀ rí fún Àjọ Aláàbò Orílẹ̀-Èdè United States. Ó kọ̀wé pé: “Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún ni ọ̀pọ̀ àwọn asọ̀rọ̀ àkíyèsí kókìkí gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀ gidi fún Sànmánì Ọgbọ́n Orí. . . . Ní ìtakora pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, ọ̀rúndún ogún ti di ọ̀rúndún ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti ìkórìíra lọ́nà púpọ̀ jù lọ fún ẹ̀dá ènìyàn, ọ̀rúndún ìṣèlú amúnimúyè àti ìpakúpa oníwà ẹhànnà. Ìwà ìkà di èyí tí a ṣètò dé ìwọ̀n tí kò láfiwé, ìpànìyàn ni a sì ti ṣètò lọ́nà gíga pelemọ. Ìyàtọ̀ láàárín àwọn ohun rere tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lè mú wá àti ìwà ibi ìṣèlú tí a gbé yọ ń kó jìnnìjìnnì báni. Kò tí ì sí ìgbà kankan rí nínú ìtàn, tí ìpakúpa gbalé gbòde kárí ayé tó bẹ́ẹ̀, kò tí ì sí ìgbà kankan rí, tí ẹ̀mí ṣègbé tó bẹ́ẹ̀, kò tí ì sí ìgbà kankan rí, tí a lépa pípa ẹ̀dá ènìyàn run pẹ̀lú ìsapá ìtìlẹyìn àjùmọ̀ṣe tí a gbé karí irú àwọn góńgó tí kò bọ́gbọ́n mu, tí a fi ìgbéraga gbé kalẹ̀ tó bẹ́ẹ̀.” Ẹ wo bí ìyẹ́n ti jẹ́ òtítọ́ tó!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Mikaeli fi Satani àti agbo ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìgbékalẹ̀ Ìjọba náà ní 1914