Nípìn-ín Nínú Iṣẹ́ Tí A Kì Yóò Tún Ṣe Mọ́ Láé
1 Ní onírúurú àkókò jálẹ̀ ìtàn aráyé, ó pọn dandan fún Jèhófà láti mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ṣùgbọ́n, nítorí àánú rẹ̀, ó pèsè àǹfààní fún àwọn ọlọ́kàn títọ́ láti rí ìgbàlà. (Orin Da. 103:13) Ìhùwàpadà wọn ni ó pinnu ohun tí ó dé bá wọn.
2 Fún àpẹẹrẹ, ṣáájú Ìkún Omi, ní ọdún 2370 ṣááju Sànmánì Tiwa, Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo.” Àwọn tí kò náání ìkìlọ̀ àtọ̀runwá ni ó ṣègbé. (2 Pét. 2:5; Héb. 11:7) Ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, Jésù sọ ìgbésẹ̀ tí ẹnì kan yóò gbé láti bọ́ lọ́wọ́ ìparun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà, ní kedere. Gbogbo àwọn tí ó kọ ìhìn iṣẹ́ ìkìlọ̀ rẹ̀ jìyà àwọn àbájáde bíbaninínújẹ́. (Lúùk. 21:20-24) Irú àwọn ìkìlọ̀ àti ìdájọ́ àtọ̀runwá bẹ́ẹ̀ ní a ṣe ní àṣetúnṣe lọ̀pọ̀ ìgbà jálẹ̀ ìtàn.
3 Iṣẹ́ Ìkìlọ̀ Òde Òní: Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, Jèhófà polongo pé òun yóò tú ìbínú òun sórí ètò ìgbékalẹ̀ búburú òde òní, àti pé, àwọn ọlọ́kàntútù nìkan ni yóò yè bọ́. (Sef. 2:2, 3; 3:8) Àkókò fún wíwàásù ìhìn iṣẹ́ ìkìlọ̀ yí ń yára tán lọ! “Ìpọ́njú Ńlá” ti dé tán, a sì ń kó àwọn ọlọ́kàntútù jọ nísinsìnyí. Ní tòótọ́, “àwọn pápá” ti “funfun fún kíkórè.” Nítorí náà, kò sí iṣẹ́ mìíràn tí ó dà bí èyí ní ti bí ó ti ṣe pàtàkì, tí ó sì jẹ́ kánjúkánjú tó.—Mát. 24:14, 21, 22; Jòh. 4:35.
4 A gbọ́dọ̀ nípìn-ín nínú ṣíṣe ìkìlọ̀ òde òní fún àwọn ẹlòmíràn, “bí wọn óò gbọ́, tàbí bí wọn óò kọ̀.” Iṣẹ́ àyànfúnni tí Ọlọ́run fúnni, tí a kò gbọ́dọ̀ kọ̀, ni èyí. (Ìsík. 2:4, 5; 3:17, 18) Nínípìn-ín tí a ń nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ yìí ń ṣàfihàn ìfẹ́ wa jíjinlẹ̀, tí ó dájú fún Ọlọ́run, ojúlówó àníyàn wa fún àwọn aládùúgbò wa, àti ìgbàgbọ́ tí kò mì, tí a ní nínú Olùgbàlà wa, Jésù Kristi.
5 Ìsinsìnyí Ni Àkókò Láti Gbégbèésẹ̀: Lẹ́yìn àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà ti ṣe sẹ́yìn, ìwà ibi sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun nítorí pé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́. Ṣùgbọ́n, lọ́tẹ̀ yí, yóò yàtọ̀. A óò mú agbára ìdarí Sátánì kúrò. A kì yóò tún nílò ìkìlọ̀ kárí ayé nípa “ìpọ́njú ńlá” tí ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀, mọ́ láé. (Ìṣí. 7:14; Róòm. 16:20) A ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ti jíjẹ́ apá kan iṣẹ́ kan tí a kì yóò tún ṣe mọ́ láé. Ìsinsìnyí ni àkókò fún wa láti lo àǹfààní yìí dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.
6 Nípa ìgbòkègbodò ìwàásù rẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìdánilójú gidigidi sọ pé: “Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo.” (Ìṣe 20:26) Òun kò nímọ̀lára ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nítorí ìkùnà èyíkéyìí láti kéde ìkìlọ̀ náà. Èé ṣe tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí pé òun lè sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé: “Fún ète yìí ni èmi ń ṣiṣẹ́ kára ní tòótọ́, mo ń tiraka.” (Kól. 1:29) Ẹ jẹ́ kí a gbádùn ìtẹ́lọ́rùn kan náà ti nínípìn-ín títí dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ṣíṣeéṣe jù lọ nínú iṣẹ́ tí a kì yóò tún ṣe mọ́ láé náà!—2 Tím. 2:15.