-
Kíkó “Awọn Ohun Fifanilọkanmọra” Jọpọ̀ ni PolandIlé-Ìṣọ́nà—1992 | July 15
-
-
‘ṣe idajọ’ pẹlu igi oníkókó. Wọn lù mi wọn sì gbá mi lati ori dé àtàǹpàkò ẹsẹ kìkì nitori pe mo ń kẹgbẹpọ pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí. A lù mi bii kíkú bii yíyè debi pe mo nilo itọju iwosan kanjukanju a sì gbé mi lọ si ile iwosan. Jehofa ràn mi lọwọ, araami sì kọ́fẹ pada. Idile mi kọ̀ mi sílẹ̀. Nigba ti mo sọ eyi fun alufaa, o foju tẹmbẹlu mi, ni wiwi pe: ‘Ṣe nitori iwọnba ìgbátí diẹ ni o wá fẹjọsun fun?’”
Arabinrin miiran sọyeranti pe: “Lọdọọdun ni mo sábà maa ń lọ si Częstochowa lati rákòrò niwaju Ọ̀wọ́ Agbelebuu, eyi ti mo kà sí ojuṣe kan fun gbogbo Katoliki olotiitọ-ọkan. Mo ṣì ní awọn àpá ni awọn eékún mi.” Ni ẹni ọdun 18 ó kẹkọọ otitọ ó sì sọ fun alufaa ati idile rẹ̀ pe oun kò ni pada si ṣọọṣi mọ. Oun ni a lù lọna ti o lekoko—“ó buru debi pe mo ni ìkọlù ọpọlọ,” ni ó rohin. “Ṣugbọn ni ile iwosan mo kọ́fẹ pada lọna ti o tó lati lọ si Apejọpọ Agbegbe ‘Awọn Olùfẹ́ Ominira.’ Mo búsẹ́kún fun ayọ nigba ti mo rí iṣọkan tootọ ati ifẹ laaarin awọn eniyan laisi ẹmi ìgbawèrèmẹ́sìn—awọn ohun ti emi kò tíì rí rí ni Częstochowa. Mo ti layọ tó pe mo ti niriiri iwarere-iṣeun Jehofa ti mo sì ti kẹkọọ lati gbẹkẹle e.” Jehofa ń fun awọn wọnni ti wọn kó awọn ẹrù-ìnira wọn sara rẹ̀ lokun ó sì ń dì wọn mu.—Orin Dafidi 55:22.
Ọpọlọpọ awọn igbekun Babiloni Nla ni wọn ń kọbiara si ìpè naa lati “jade kuro ninu rẹ̀” nisinsinyi ni orilẹ-ede Katoliki yii, àní gẹgẹ bi wọn ti ń ṣe ni awọn ibomiran paapaa. Bi o bá jẹ́ ifẹ-inu Jehofa, awọn eniyan rẹ̀ alaibẹru yoo maa baa lọ lati kó pupọ sii “awọn ohun fifanilọkanmọra” ti wọn fọ́nkáàkiri jakejado Poland jọpọ sibẹ. Dajudaju, pupọ sii ṣì maa dahunpada sibẹ si ìpè naa pe: “Maa bọ. Ati ẹni ti o ń gbọ́ ki o wi pe, Maa bọ. Ati ẹni ti ongbẹ ń gbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o bá sì fẹ́, ki o gba omi ìyè naa lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìfihàn 18:4; 22:17.
-
-
Tẹ̀lé Ọ̀nà Ìfẹ́ Ti O Tayọ RekọjaIlé-Ìṣọ́nà—1992 | July 15
-
-
Tẹ̀lé Ọ̀nà Ìfẹ́ Ti O Tayọ Rekọja
JEHOFA ỌLỌRUN jẹ́ ogidi apẹẹrẹ ìfẹ́. (1 Johannu 4:8) Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, sọ pe a gbọdọ nifẹẹ Ọlọrun ati aladuugbo wa. (Matteu 22:37-40) Họ́wù, Ọlọrun ń dari gbogbo agbaye lori ipilẹ animọ yii! Nitori naa fun ìyè ainipẹkun ni ibikibi, a gbọdọ tẹle ọ̀nà ìfẹ́.
Ọlọrun fi ìfẹ́ hàn fun orilẹ-ede Israeli ṣugbọn lẹhin naa ó kọ eto-ajọ yẹn silẹ nitori aiṣotitọ. Ó wá fi ijọ awọn ọmọ-ẹhin Jesu hàn lẹhin naa gẹgẹ bi eto-ajọ Rẹ̀ titun. Bawo? Nipa ìfihàn akanṣe ti ẹmi mimọ ti ń fun wọn lagbara lati sọrọ ni èdè ahọ́n ati lati sọtẹlẹ. Nipa bayii, ni Pentekosti 33 C.E., 3,000 awọn Ju ati alawọṣe Ju di onigbagbọ wọn sì fi eto-ajọ ogbologboo naa silẹ lati darapọ mọ́ titun ti o jẹ ti Ọlọrun. (Iṣe 2:1-41) Niwọn bi o ti jẹ pe awọn ẹbun ẹmi naa ni a tú jade nipasẹ awọn aposteli Jesu lẹhin ìgbà naa, iru awọn ìfihàn bẹẹ dawọduro lẹhin ikú wọn. (Iṣe 8:5-18; 19:1-6) Ṣugbọn nigba naa lọhun-un ẹmi naa ti fihàn pe ojurere Ọlọrun wà lara Israeli tẹmi.—Galatia 6:16.
Awọn iṣẹ iyanu ti ń jẹ jade lati inu awọn ẹbun ẹmi ṣanfaani. Bi o ti wu ki o ri, fifi ifẹ tabi idaniyan aimọtara-ẹni-nikan hàn fun
-