ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìwọ Ha Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Bí?—Ohun tí àdúrà rẹ fi hàn
    Ilé Ìṣọ́—1997 | July 1
    • Ìwọ Ha Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Bí?—Ohun tí àdúrà rẹ fi hàn

      O HA ti ṣèèṣì fetí kọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹni méjì ń jíròrò bí? Kò sí iyè méjì kankan pé kò pẹ́ tí o fi mọ irú ipò ìbátan tí ó wà láàárín wọn—bóyá wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ tàbí wọ́n jẹ́ àjèjì sí ara wọn, bóyà wọ́n jẹ́ ojúlùmọ̀ lásán, tàbí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn. Lọ́nà kan náà, àdúrà wa lè ṣí ipò ìbátan tí a ní pẹ̀lú Ọlọ́run payá.

      Bíbélì mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Ní tòótọ́, ó rọ̀ wá láti mọ òun. A tilẹ̀ lè jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Orin Dáfídì 34:8; Jákọ́bù 2:23) A lè gbádùn ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀! (Orin Dáfídì 25:14) Ó ṣe kedere pé, ipò ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run ni ohun ṣíṣeyebíye jù lọ tí àwa ẹ̀dá ènìyàn aláìpé lè ní. Jèhófà sì ṣìkẹ́ ìbárẹ́ tí a ní pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ṣe kedere nítorí pé a gbé ìbárẹ́ tí a ní pẹ̀lú rẹ̀ ka ìgbàgbọ́ nínú Ọmọkùnrin rẹ̀ bíbí kan ṣoṣo, tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa.—Kólósè 1:19, 20.

      Nítorí náà, ó yẹ kí àdúrà wa fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ àti ìmọrírì fún Jèhófà hàn. Ṣùgbọ́n, ìwọ ha ti fìgbà kan rí nímọ̀lára pé, bí àdúrà rẹ tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́wọ̀, síbẹ̀ kò fi ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ gan-an hàn bí? Èyí kò ṣàjèjì. Kí ni ojútùú sí mímú nǹkan sunwọ̀n sí i? Mímú ìbárẹ́ tí o ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run dàgbà sí i.

      Wíwá Àkókò Láti Gbàdúrà

      Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ń gba àkókò láti bẹ̀rẹ̀ ìbárẹ́, kí a sì mú un dàgbà. O lè máa kí ọ̀pọ̀ ènìyàn—àwọn aládùúgbò, alábàáṣiṣẹ́, awakọ̀ èrò, àti akọ̀wé ilé ìtajà—lójoojúmọ́ tàbí kí o máa bá wọn sọ̀rọ̀. Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé o jẹ́ ọ̀rẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ti gidi. Ìbárẹ́ máa ń dàgbà bí o ṣe ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ fún àkókò púpọ̀ sí i, bí ó ṣe ń lọ láti orí ìtàkúrọ̀sọ sórí sísọ ìmọ̀lára rẹ ti inú lọ́hùn-ún àti èrò rẹ jáde.

      Lọ́nà kan náà, àdúrà ń ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ya àkókò tí ó tó sọ́tọ̀ fún un; a nílò ju àdúrà ìdúpẹ́ kúkúrú nígbà oúnjẹ lọ. Bí o bá ṣe túbọ̀ ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ yóò ṣe túbọ̀ lóye ìmọ̀lára rẹ, ìsúnniṣe rẹ, àti ìgbésẹ̀ rẹ. Ojútùú sí àwọn ìṣòro líle koko yóò bẹ̀rẹ̀ sí jẹ yọ bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń rán ọ létí àwọn ìlànà inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Orin Dáfídì 143:10; Jòhánù 14:26) Ní àfikún sí i, bí o ṣe ń gbàdúrà, Jèhófà yóò túbọ̀ máa di ẹni gidi sí ọ, ìwọ yóò sì túbọ̀ máa rí ọkàn ìfẹ́ tí ó ní nínú rẹ àti bí ó ṣe bìkítà nípa rẹ tó.

      Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì nígbà tí o bá rí ìdáhùn sí àdúrà rẹ. Họ́wù, Jèhófà lè “ṣe ju ọ̀pọ̀ yanturu gan-an ré kọjá gbogbo àwọn ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò”! (Éfésù 3:20) Èyí kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ń ṣe iṣẹ́ ìyanu fún ọ. Ṣùgbọ́n, nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀, àwọn ìtẹ̀jáde ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ ẹrú, tàbí nípasẹ̀ ẹnu àwọn arákùnrin àti arábìnrin onífẹ̀ẹ́, ó lè pèsè ìmọ̀ràn tàbí ìtọ́sọ́nà tí o nílò fún ọ. Tàbí kí ó fún ọ ní okun tí o nílò láti fara dà tàbí dènà ìdánwò. (Mátíù 24:45; Tímótì Kejì 4:17) Irú ìrírí bẹ́ẹ̀ ń fi ìmọrírì tí a ní fún Ọ̀rẹ́ wa ọ̀run kún inú ọkàn àyà wa!

      Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ wá àkókò láti gbàdúrà. Lóòótọ́, àkókò wọ́n púpọ̀ ní àwọn ọjọ́ onímásùnmáwo wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n nígbà tí o bá bìkítà gidigidi nípa ẹnì kan, o sábà máa ń wá àkókò láti lò pẹ̀lú ẹni náà. Ṣàkíyèsí ọ̀nà ti onísáàmù náà gbà sọ ọ̀rọ̀ ara rẹ̀: “Bí àgbọ̀nrín í ti máa mí hẹlẹ sí ipadò omi, Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ. Òǹgbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, ti Ọlọ́run alààyè: nígbà wo ni èmi óò wá, tí èmi óò sì yọjú níwájú Ọlọ́run”? (Orin Dáfídì 42:1, 2) O ha ní irú ìyánhànhàn kan náà láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, wá àkókò láti ṣe bẹ́ẹ̀!—Fi wé Éfésù 5:16.

      Fún àpẹẹrẹ, o lè gbìyànjú láti tètè máa jí lárààárọ̀ láti baà lè ní àkókò ìdákọ́ńkọ́ láti gbàdúrà. (Orin Dáfídì 119:147) Nígbà míràn, ó ha máa ń ṣẹlẹ̀ pé ó kì í rí oorun sùn lóru bí? Bí ó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ti onísáàmù náà, ó lè ka irú àwọn àkókò onídààmú bẹ́ẹ̀ sí àǹfààní kan láti sọ àníyàn rẹ̀ jáde fún Ọlọ́run. (Orin Dáfídì 63:6) Tàbí ó sì lè jẹ́ ọ̀ràn gbígbàdúrà kúkúrú mélòó kan ní ojúmọmọ. Onísáàmù náà wí fún Ọlọ́run pé: “Ìwọ ni èmi ń ké pè ní ojoojúmọ́.”—Orin Dáfídì 86:3.

      Mímú Àdúrà Wa Sunwọ̀n Sí I

      Nígbà míràn, ìwọ yóò rí i pé ó dára láti fa àdúrà rẹ gùn. Nígbà tí o bá ń gbàdúrà kúkúrú, o lè ní ìtẹ̀sí láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn tí kò jinlẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí o bá gbàdúrà gígùn tí ó sì jinlẹ̀, o lè sọ èrò inú àti ìmọ̀lára rẹ inú lọ́hùn-ún jáde láìlọ́tìkọ̀. Ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan, Jésù lo gbogbo òru ọjọ́ kan láti gbàdúrà. (Lúùkù 6:12) Kò sí iyè méjì pé ìwọ yóò rí i pé àwọn àdúrà rẹ di èyí tí ó jinlẹ̀ sí i, tí ó sì ń nítumọ̀ sí i bí o bá yẹra fún dídà wọ́n wuuru.

      Èyí kò túmọ̀ sí pé kí o máa fàtamọ́ mátamọ̀ nígbà tí o kò bá ni ohun púpọ̀ láti sọ; bẹ́ẹ̀ sì ni kò túmọ̀ sí yíyíjú sí wíwí àwítúnwí tí kò nítumọ̀. Jésù kìlọ̀ pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe wí ohun kan náà ní àwítúnwí, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe sọ ara yín dà bí wọn, nítorí Ọlọ́run Bàbá yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.”—Mátíù 6:7, 8.

      Àdúrà túbọ̀ máa ń nítumọ̀ nígbà tí o bá kọ́kọ́ ronú lórí kókó tí o fẹ́ sọ kínníkínní. Àwọn ohun tí a lè sọ̀rọ̀ lé lórí kò lópin—ìdùnnú wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, àìlera àti ìkù-díẹ̀-káàtó wa, ìjákulẹ̀ wa, àníyàn wa ní ti ètò ọrọ̀ ajé, pákáǹleke ní ibi iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́, ire ìdílé wa, àti ipò tẹ̀mí ìjọ wa, kí a mẹ́nu kàn díẹ̀ péré.

      Ọkàn rẹ ha máa ń rìn gbéregbère nígbà míràn tí o bá ń gbàdúrà bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, túbọ̀ sapá láti pọkàn pọ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà múra tán láti ‘fiyè sí igbe wa.’ (Orin Dáfídì 17:1) Kò ha yẹ kí a múra tán láti sapá gidigidi láti fiyè sí àwọn àdúrà wa fúnra wa? Bẹ́ẹ̀ ni, ‘gbé èrò inú rẹ ka orí àwọn ohun ti ẹ̀mí,’ má sì ṣe jẹ́ kí ó rìn gbéregbère kiri.—Róòmù 8:5.

      Ọ̀nà tí a gbà ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ tún ṣe pàtàkì. Bí ó tilẹ̀ fẹ́ kí a ka òun sí ọ̀rẹ́, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé Ọba Aláṣẹ àgbáyé ni a ń bá sọ̀rọ̀. Ka ìran amúnikún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tí a fi hàn nínú Ìṣípayá orí 4 àti 5, kí o sì ṣàṣàrò lé e lórí. Níbẹ̀, nínú ìran, Jòhánù rí ògo ẹwà Ẹni náà tí a ń bá sọ̀rọ̀ nínú àdúrà. Ẹ wo irú àǹfààní tí a ní láti lè tọ̀ ọ́ lọ, kí a sì rí ọ̀nà àtidé ọ̀dọ̀ “Ẹni náà tí ó jókòó lórí ìtẹ́”! Kí a má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa di èyí tí kò bọ̀wọ̀ fún un tàbí tí kò buyì fún un láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a sapá gidigidi láti mú kí ‘ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣàrò ọkàn wa kí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ni ojú Jèhófà.’—Orin Dáfídì 19:14.

      Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ kí a mọ̀ dájú pé, a kì í fi ọ̀rọ̀ dídùn fa Jèhófà mọ́ra. Àwọn ọ̀rọ̀ wa tí ó bọ̀wọ̀ fún un, tí ó tọkàn wá, láìka bí a ṣe gbé wọn kalẹ̀ lọ́nà rírọrùn tó, ń dùn mọ́ ọn nínú.—Orin Dáfídì 62:8.

      Ìtùnú àti Òye ní Àkókò Àìní

      Nígbà tí a bá nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú, a sábà máa ń yíjú sí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn fún ìrànlọ́wọ́ àti ìbákẹ́dùn. Toò, kò sí ọ̀rẹ́ kan tí ó rọrùn láti tọ̀ lọ tó Jèhófà. Òun ni “ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” (Orin Dáfídì 46:1, NW) Gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” ó lóye ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. (Kọ́ríńtì Kejì 1:3, 4; Orin Dáfídì 5:1; 31:7) Ó sì ní ojúlówó ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò àti ìyọ́nú fún àwọn tí wọ́n wà ní ipò líle koko gan-an. (Aísáyà 63:9; Lúùkù 1:77, 78) Ní lílóye pé Jèhófà jẹ́ ọ̀rẹ́ tí ń gba tẹni rò, a kì í lọ́ tìkọ̀ láti fi ìtara àti ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ bá a sọ̀rọ̀, a ń sún wa láti sọ ìbẹ̀rù jíjinlẹ̀ jù lọ tí a ní àti àníyàn wa jáde fún un. Nípa báyìí, a ń nírìírí ní tààràtà bí “ìtùnú” Jèhófà “fúnra rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣìkẹ́ ọkàn wa.”—Orin Dáfídì 94:18, 19, NW.

      Nígbà míràn, a lè nímọ̀lára pé a kò tóótun láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nítorí àwọn àṣìṣe wa. Ṣùgbọ́n bí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ kan bá ṣẹ̀ ọ́, tí ó sì tọrọ àforíjì ńkọ́? A kì yóò ha sún ọ láti tu ẹni náà nínú, kí o sì fi ọkàn rẹ̀ balẹ̀ bí? Nígbà náà, èé ṣe tí o fi retí pé Jèhófà yóò ṣe ohun tí ó dín kù sí èyí? Ó máa ń fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ dárí ji àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ nítorí àìpé ẹ̀dá ènìyàn. (Orin Dáfídì 86:5; 103:3, 8-11) Ní mímọ èyí, a kì í lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún un ní fàlàlà; a lè ní ìgbọ́kànlé nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀. (Orin Dáfídì 51:17) Bí àwọn ìkùdíẹ̀-kí-à-tó wa bá mú wa sorí kọ́, a lè rí ìtùnú nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jòhánù Kíní 3:19, 20: “Nípa èyí ni àwa yóò mọ̀ pé àwa pilẹ̀ ṣẹ̀ láti inú òtítọ́, àwa yóò sì fún ọkàn àyà wa ní ìdánilójú níwájú rẹ̀ ní ti ohun yòó wù nínú èyí tí ọkàn àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi, nítorí Ọlọ́run tóbi ju ọkàn àyà wa lọ ó sì mọ ohun gbogbo.”

      Ṣùgbọ́n, kò dìgbà tí a bá wà ní ipò líle koko gan-an kí a tó lè gbádùn àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ nínú ohunkóhun tí ó bá lè nípa lórí ire tẹ̀mí àti ti ìmọ̀lára wa. Bẹ́ẹ̀ ni, a kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé ìmọ̀lára wa, èrò wa, àti àníyàn wa kéré ju ohun tí a lè mẹ́nu kàn nínú àdúrà. (Fílípì 4:6) Nígbà tí o bá wà pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kòríkòsùn kan, ṣe kìkì ohun pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ ni ẹ máa ń jíròrò? Ẹ ha tún ń ṣàjọpín àwọn àníyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì bí? Lọ́nà kan náà, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa apá èyíkéyìí nínú ìgbésí ayé rẹ, ní mímọ̀ pé ‘ó bìkítà fún ọ.’—Pétérù Kíní 5:7.

      Àmọ́ ṣáá o, ọ̀rẹ́ kò lè tọ́jọ́ bí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ ṣáá. Bákan náà, kò yẹ kí àdúrà wa jẹ́ ti anìkànjọpọ́n. Ó yẹ kí a sọ ìfẹ́ àti àníyàn wa fún Jèhófà àti ire rẹ̀ jáde. (Mátíù 6:9, 10) Àdúrà kì í ṣe kìkì àǹfààní láti bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ọ̀nà láti sọ ọpẹ́ àti ìyìn jáde. (Orin Dáfídì 34:1; 95:2) ‘Gbígba ìmọ̀’ sínú nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí, bí ó ti ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ di ojúlùmọ̀ Jèhófà àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Jòhánù 17:3) Ní pàtàkì, o lè rí i pé yóò ṣèrànwọ́ láti ka ìwé Orin Dáfídì, kí o sì kíyè sí bí àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ ṣe sọ ìmọ̀lára wọn jáde fún Jèhófà.

      Ní tòótọ́, ìbárẹ́ tí a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye. Ǹjẹ́ kí a fi hàn pé a mọrírì rẹ̀ nípa mímú kí àdúrà wa túbọ̀ jinlẹ̀, kí ó jẹ́ látọkànwá, kí ó sì jẹ́ ti ara wa. Nígbà náà, a óò gbádùn ayọ̀ tí onísáàmù náà sọ jáde, ní pípolongo pé: “Alábùkúnfún ni ẹni tí ìwọ yàn, tí ìwọ sì mú láti máa sún mọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.”—Orin Dáfídì 65:4.

      [Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

      A lè gbàdúrà sí Ọlọ́run jálẹ̀ ọjọ́ bí àǹfààní ṣe ń ṣí sílẹ̀

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—1997 | July 1
    • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

      Inú wá dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àkàwé Jésù nípa àgùntàn àti ewúrẹ́. Pẹ̀lú ìlàlóye tuntun tí a gbé kalẹ̀ nínú “Ilé-Ìṣọ́nà” October 15, 1995, ǹjẹ́ a ṣì lè sọ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ lónìí bí?

      Bẹ́ẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, ọ̀pọ̀ ti ronú nípa èyí nítorí Mátíù 25:31, 32 sọ pé: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni òun yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a óò sì kó jọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.” Ilé-Ìṣọ́nà ti October 15, 1995, fi ìdí tí ó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀ ni àwọn ẹsẹ wọ̀nyí yóò ní ìmúṣẹ hàn. Jésù yóò dé nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, yóò sì jókòó sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀. Nígbà náà, yóò ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀. Lọ́nà wo? Òun yóò gbé ìdájọ́ rẹ̀ karí ohun tí àwọn ènìyàn ṣe tàbí tí wọ́n kùnà láti ṣe ṣáájú àkókò yẹn.

      A lè fi èyí wé àwọn sáà ìgbẹ́jọ́, tí ń ṣamọ̀nà sí ìdájọ́ nílé ẹjọ́. Ẹ̀rí yóò gbára jọ fún sáà gígùn kan, kí ilé ẹjọ́ tó ṣèdájọ́, kí ó sì tó sọ ìyà tí a óò fi jẹni. Ẹ̀rí bóyá àwọn ènìyàn tí ó wà láàyè nísinsìnyí yóò di àgùntàn tàbí ewúrẹ́ ti ń gbára jọ fún àkókò pípẹ́. Àwọn ẹ̀rí mìíràn ṣì ń wọlé wá. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ẹjọ́ náà yóò parí. Òun yóò ti ṣe tán láti ṣèdájọ́. A óò ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ yálà fún

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́