-
Ẹ̀rí Ọkàn Ṣé ẹrù ìnira ni tàbí ohun iyebíye?Ilé Ìṣọ́—1997 | August 1
-
-
ìtẹ́lọ́rùn ńlá àti ìfọ̀kànbalẹ̀. Ó lè tọ́ wa sọ́nà, dáàbò bò wá, kí ó sì sún wa ṣiṣẹ́. Ìwé The Interpreter’s Bible ṣàlàyé pé: “Ẹnì kan lè pa ìlera ọpọlọ àti ti ìmọ̀lára mọ́ kìkì bí ẹnì náà bá ń gbìyànjú láti dí ọ̀gbun tí ó wà láàárín ohun tí ó ń ṣe àti ohun tí ó rò pé ó yẹ kí òun máa ṣe.” Ọ̀nà wo ni ẹnì kan lè gbà dí ọ̀gbun náà? Ó ha ṣeé ṣe láti tọ́, kí a sì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́ bí? A óò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
-
-
Bí O Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Lẹ́kọ̀ọ́Ilé Ìṣọ́—1997 | August 1
-
-
Bí O Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Lẹ́kọ̀ọ́
“Ẹ̀ RÍ ọkàn rere ni ìrọ̀rí tí ó dára jù lọ.” Ọ̀rọ̀ àwọn àgbà yí tẹnu mọ́ òkodoro òtítọ́ ṣíṣe pàtàkì kan: Nígbà tí a bá tẹ́tí sí ẹ̀rí ọkàn wa, a ń gbádùn ìfọkànbalẹ̀ àti ìṣọ̀kan.
Ṣùgbọ́n, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ní ń yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Adolf Hitler kéde pé òun ní iṣẹ́ kan láti ṣe, láti mú kí àwọn ènìyàn bọ́ lọ́wọ́ ìtànjẹ, tàbí ẹ̀tàn, tí ń rẹni sílẹ̀ náà tí a mọ̀ sí ẹ̀rí ọkàn. Ìṣàkóso akópayàbáni rẹ̀ pèsè ìran amúnisoríkọ́ nípa bí àwọn ènìyàn ti lè rorò tó nígbà tí wọ́n bá kọ̀ láti jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wọn darí wọn. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀daràn oníwà ipá lóde òní—àwọn tí ń fipá báni lòpọ̀, tí wọ́n ń ṣìkà pànìyàn láìnímọ̀lára ohunkóhun—bákan náà jẹ́ aláìláàánú páàpáà. Iye tí ń pọ̀ sí i nínú àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí jẹ́ ọ̀dọ́mọdé. Ìwé kan tí ń ṣèwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yí ní ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ yí Children Without a Conscience (Àwọn Ọmọdé Tí Kò Ní Ẹ̀rí Ọkàn).
Nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò ní ronú láé láti hùwà ọ̀daràn oníwà ipá, ọ̀pọ̀ ni ẹ̀rí ọkàn wọn kò gún ní kẹ́ṣẹ́ rárá láti hùwà pálapàla, láti purọ́, tàbí láti ṣe awúrúju. Ìwà rere ń jó rẹ̀yìn jákèjádò ayé. Ní títọ́ka sí ìpẹ̀yìndà ńlá láti inú ẹ̀sìn tòótọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, àwọn Kristẹni kan yóò júwọ sílẹ̀ fún agbára ìdarí ayé, tí wọn yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ di “àwọn tí a ti sàmì sí inú ẹ̀rí ọkàn wọn gẹ́gẹ́ bíi pé pẹ̀lú irin ìsàmì.” (Tímótì Kíní 4:2) Ìgbòdekan ìwà ìbàjẹ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i lónìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (Tímótì Kejì 3:1) Nítorí náà, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti dáàbò bo ẹ̀rí ọkàn wọn. A lè ṣe èyí nípa kíkọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ àti mímú un sunwọ̀n sí i.
Èrò Inú, Ọkàn Àyà, àti Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èmi ń sọ òtítọ́ nínú Kristi; èmi kò purọ́, níwọ̀n bí ẹ̀rí ọkàn mi ti ń jẹ́rìí pẹ̀lú mi nínú ẹ̀mí mímọ́.” (Róòmù 9:1) Nítorí náà, ẹ̀rí ọkàn lè jẹ́ni lẹ́rìí. Ó lè ṣàyẹ̀wò ìgbésẹ̀ tí a fẹ́ gbé, kí ó fọwọ́ sí i tàbí kí ó dẹ́bi fún un. Ọ̀pọ̀ òye tí a ní nípa ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ jẹ́ ohun tí Ẹlẹ́dàá wa ti dá mọ́ wa. Síbẹ̀, a lè tọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, kí a sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Lọ́nà wo? Nípa gbígba ìmọ̀ pípéye láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ̀yin lè fún ara yín ní ẹ̀rí ìdánilójú ìfẹ́ inú Ọlọ́run tí ó dára tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Bí o ti ń gbin ìrònú Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀ sínú èrò inú rẹ, ẹ̀rí ọkàn rẹ yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà tí ó túbọ̀ jẹ́ ti oníwà-bí-Ọlọ́run.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ jákèjádò ayé lọ́wọ́ láti ‘gba ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi sínú.’ (Jòhánù 17:3) Nípasẹ̀ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń fi ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà Ọlọ́run lórí ìbálòpọ̀, ọtí mímu, ìgbéyàwó, ìdókòwò, àti ọ̀pọ̀ kókó ẹ̀kọ́ mìíràn kọ́ àwọn aláìlábòsí ọkàn.a (Òwe 11:1; Máàkù 10:6-12; Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 10; Éfésù 5:28-33) Gbígba “ìmọ̀ pípéye” yìí sínú jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kan nínú níní ẹ̀rí ọkàn oníwà-bí-Ọlọ́run. (Fílípì 1:9) Dájúdájú, àní lẹ́yìn tí Kristẹni kan bá ti jèrè òye tí ó péye nípa Bíbélì pàápàá, ó gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ èrò inú rẹ̀ déédéé, bí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ yóò bá máa bá a lọ láti ṣiṣẹ́ dáradára.—Orin Dáfídì 1:1-3.
Bíbélì tún so ẹ̀rí ọkàn mọ́ ọkàn àyà ìṣàpẹẹrẹ, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀lára àti èrò ìmọ̀lára wa. (Róòmù 2:15) Èrò inú àti ọkàn àyà gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan bí ẹ̀rí ọkàn yóò bá ṣiṣẹ́ dáradára. Ìyẹn túmọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ ṣe ju kíkó ìsọfúnní sínú èrò inú lọ. O tún gbọ́dọ̀ tọ́ ọkàn àyà rẹ—ìmọ̀lára rẹ inú lọ́hùn-ún, ìfẹ́ ọkàn rẹ, àti ìyánhànhàn tí o ní. Nípa báyìí, ìwé Òwe lo irú àwọn gbólóhùn bíi, “fi ọkàn sí,” “fi ọkàn àyà rẹ sí,” àti “tọ́ àyà rẹ sí.” (Òwe 2:2; 23:19; 27:23, NW) Ọ̀nà kan láti gbà ṣe èyí jẹ́ nípa ṣíṣàṣàrò lórí Ìwé Mímọ́ àti ríronú jinlẹ̀ lórí rẹ̀. Orin Dáfídì 77:12 sọ pé: “Èmi óò máa ṣe àṣàrò gbogbo iṣẹ́ rẹ pẹ̀lú, èmi ó sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.” Ṣíṣàṣàrò ń ràn wá lọ́wọ́ láti dénú ìmọ̀lára àti ìsúnniṣe wa inú lọ́hùn-ún.
Fún àpẹẹrẹ, kí a sọ pé o ń hùwà àìmọ́ kan, irú bíi sísọ sìgá mímu di bárakú. Bí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn, kò sí àní-àní pé o mọ àkóbá tí ń ṣe fún ìlera. Síbẹ̀, láìka rírọ̀ tí àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé rẹ ń rọ̀ ọ́ sí, ó ṣòro fún ọ láti jáwọ́ nínú rẹ̀. Báwo ni ṣíṣàṣàrò lórí ìhìn iṣẹ́ inú Bíbélì ṣe lè fún ẹ̀rí ọkàn rẹ lókun nínú ọ̀ràn yí?
Fún àpẹẹrẹ, gbìyànjú ṣíṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí ó wà nínú Kọ́ríńtì Kejì 7:1 pé: “Nítorí náà, níwọ̀n bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” Lóye àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dáradára. Bí ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ni “àwọn ìlérí wọ̀nyí” tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí?’ Nípa kíka àwọn àyíká ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìwọ yóò kíyè sí i pé àwọn ẹsẹ tí ó ṣáájú rẹ̀ sọ́ pé: “‘“Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,” ni Jèhófà wí, “kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́ kan ohun àìmọ́”’; ‘“dájúdájú èmi yóò sì gbà yín wọlé.”’ ‘“Èmi yóò sì jẹ́ bàbá fún yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún mi,” ni Jèhófà Olódùmarè wí.’”—Kọ́ríńtì Kejì 6:17, 18.
Àṣẹ Pọ́ọ̀lù pé kí a ‘wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀gbin’ ti ní àfikún agbára nísinsìnyí! Gẹ́gẹ́ bí ìsúnniṣe lílágbára sí ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ṣèlérí láti ‘gbà wá wọlé,’ ìyẹn ni pé, láti fi wá sábẹ́ àbójútó aláàbò rẹ̀. O lè bi ara rẹ léèrè pé, ‘Èmi yóò ha gbádùn ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ bí—gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ó wà láàárín ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin àti bàbá rẹ̀?’ Èrò dídi ẹni tí Ọlọ́run ọlọgbọ́n àti onífẹ̀ẹ́ ‘gbà wọlé’ tàbí jíjẹ́ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ sí kò ha fani mọ́ra bí? Bí èrò yẹn bá ṣàjèjì sí ọ, ṣàkíyèsí bí àwọn bàbá onífẹ̀ẹ́ ṣe ń fi ìfẹ́ àti ìfẹ́ni hàn sí àwọn ọmọ wọn. Nísinsìnyí, finú wòye irú ìdè bẹ́ẹ̀ láàárín ìwọ àti Jèhófà! Bí o bá ṣe ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ rẹ fún irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ yóò máa pọ̀ sí i.
Ṣùgbọ́n má gbàgbé: Ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣeé ṣe kìkì bí o bá “jáwọ́ nínú fífọwọ́ kan ohun àìmọ́.” Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Sísọ sìgá mímu di bárakú kò ha wà lára “ohun àìmọ́” tí Ọlọ́run dẹ́bi fún bí? Mímu ún yóò ha jẹ́ “ẹ̀gbin ti ẹran ara” bí, ní ṣíṣí ara mi payá sí onírúurú ewu tí ó lè ṣàkóbá fún ìlera? Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run aláìléèérí, tàbí “mímọ́,” òun yóò ha fọwọ́ sí mímọ̀ọ́mọ̀ tí mo ń mọ̀ọ́mọ̀ sọ ara mi di ẹlẹ́gbin ní ọ̀nà yí bí?’ (Pétérù Kíní 1:15, 16) Kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù tún kìlọ̀ lòdì sí ‘ẹ̀gbin ti ẹ̀mí,’ tàbí ti ìtẹ̀sí èrò orí ẹni. Bí ara rẹ léèrè pé: ‘Sìgá mímu tí mo sọ di bárakú yìí ha ń jọba lórí ìrònú mi bí? Èmi yóò ha lọ jìnnà láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́rùn bí, bóyá dórí fífi ìlera mi, ìdílé mi, tàbí ìdúró mi pẹ̀lú Ọlọ́run pàápàá sínú ewu? Dé ìwọ̀n wo ni mo ti yọ̀ǹda kí sísọ tí mo sọ sìgá mímu di bárakú yìí ba ìgbésí ayé mi jẹ́?’ Kíkojú àwọn ìbéèrè tí ń roni lára wọ̀nyí lè fún ọ ní ìṣírí láti jáwọ́ nínú rẹ̀!
Dájúdájú, o lè nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn láti ṣẹ́pá sìgá mímu. Síbẹ̀, ṣíṣàṣàrò lórí Bíbélì lè ṣe púpọ̀ láti kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ lẹ́kọ̀ọ́ àti láti fún un lókun kí o bá a lè jàjàbọ́ lọ́wọ́ sísọ sìgá mímu di bárakú.
Nígbà Tí A Bá Ṣe Ohun Tí Kò Tọ́
Láìka ìsapá dídára jù lọ tí a ṣe láti ṣe ohun tí ó tọ́ sí, àìpé ẹran ara wa máa ń ṣẹ́pá wa nígbà míràn, a sì máa ń ṣàṣìṣe. Ẹ̀rí ọkàn wa yóò sì dà wá láàmú, ṣùgbọ́n a máa ń nítẹ̀sí láti gbìyànjú láti ṣàìkọbi ara sí i. Tàbí a lè di ẹni tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá débi pé a fẹ́ juwọ́ sílẹ̀ pátápátá ní sísin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, rántí ọ̀ràn Ọba Dáfídì. Lẹ́yìn tí ó ti ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ dà á láàmú. Ó júwe ìrora tí ó nímọ̀lára rẹ̀ pé: “Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni ọwọ́ rẹ wúwo lára mi. Ọ̀rinrin ìgbésí ayé mi ni a ti yí pa dà bíi ti àkókò ooru gbígbẹ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.” (Orin Dáfídì 32:4, NW) Ṣé ó ro ó lára? Bẹ́ẹ̀ ni! Síbẹ̀, ìbànújẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run yìí sún Dáfídì láti ronú pìwà dà, kí ó sì di ẹni tí ó pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. (Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 7:10.) Ẹ̀bẹ̀ onírora ọkàn tí Dáfídì bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ pèsè ẹ̀rí tí ó pọ̀ tó pé ìrònúpìwàdà rẹ̀ jẹ́ láti ọkàn wá. Nítorí tí ó gbọ́ràn sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, a ran Dáfídì lọ́wọ́ láti yí pa dà, kí ó sì jèrè ayọ̀ rẹ̀ pa dà nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Orin Dáfídì 51.
Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ lónìí. Àwọn kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí ó ti kọjá, ṣùgbọ́n wọ́n jáwọ́ nígbà tí wọ́n kọ́ pé ìgbésí ayé wọn kò bá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga Ọlọ́run mu. Bóyá wọn ń gbé pọ̀ pẹ̀lú mẹ́ńbà ẹ̀yà kejì láìṣègbéyàwó tàbí wọ́n jẹ́ ẹrú ìwà àìmọ́. Ẹ̀rí ọkàn wọn kó ìrora bá wọn!
Bí o bá wà nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, gbé ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù, tí ó sọ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì yẹ̀ wò. Nígbà tí ó tú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Júù ará ìlú rẹ̀ fó, “ó gún wọn dé ọkàn àyà.” Dípò jíjuwọ́sílẹ̀, wọ́n kọbi ara sí ìmọ̀ràn Pétérù pé kí wọ́n ronú pìwà dà, wọ́n sì jèrè ojú rere Ọlọ́run. (Ìṣe 2:37-41) Ìwọ pẹ̀lú lè ṣe ohun kan náà! Kàkà tí ìwọ yóò fi fi òtítọ́ sílẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ ń dà ọ́ láàmú, jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn rẹ sún ọ láti ‘ronú pìwà dà kí o sì yí padà.’ (Ìṣe 3:19) Pẹ̀lú ìpinnu àti ìsapá, o lè ṣe ìyípadà tí ó yẹ láti rí ojú rere Ọlọ́run.
“Di Ẹ̀rí Ọkàn Rere Mú”
Yálà o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà tàbí o ti ní ìrírí ọ̀pọ̀ ọdún gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tí ó dàgbà dénú, ìṣílétí Pétérù ṣe rẹ́gí pé: “Di ẹ̀rí ọkàn rere mú.” (Pétérù Kíní 3:16) Ohun iyebíye ni, kì í ṣe ẹrù ìnira. Kọ́ ọ nípa fífi ọgbọ́n tí ń bẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, bọ́ èrò inú àti ọkàn àyà rẹ. Tẹ́tí sí ẹ̀rí ọkàn rẹ nígbà tí ó bá kìlọ̀ fún ọ. Gbádùn ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ṣíṣègbọràn sí ẹ̀rí ọkàn ẹni máa ń mú wá.
A gbà pé, kíkọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ lẹ́kọ̀ọ́ àti títọ́ ọ kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Ṣùgbọ́n, o lè gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run láti ràn ọ́ lọ́wọ́. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti sin Ọlọ́run “láti inú ẹ̀rí ọkàn rere àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè.”—Tímótì Kíní 1:5.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lómìnira fàlàlà láti kàn sí ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò tàbí láti kọ̀wé sí àwọn tí ń tẹ ìwé ìròyìn yí jáde, bí ìwọ yóò bá nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lófẹ̀ẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ṣíṣàṣàrò lé e lórí ń ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́
-