-
Kí Ni Òmìnira Ìsìn Túmọ̀ Sí fún Ọ?Ilé Ìṣọ́—1997 | February 1
-
-
mẹ́ńbà ìsìn yòó kù sí ewu fún ọlá àṣẹ ìṣèlú. Ìjọba kan tún lè ka ìsìn sí ewu fún ìṣèlú nítorí pé ìsìn lè fi ìtúúbá fún Ọlọ́run ṣíwájú ìgbọ́ràn sí orílẹ̀-èdè.”
Nítorí àwọn ìdí wọ̀nyí, àwọn ìjọba kan gbé ìkálọ́wọ́kò karí ìsìn ṣíṣe. Àwọn díẹ̀ kò fàyè gba ṣíṣe ìsìn èyíkéyìí rárá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ pé àwọn ń ṣalágbàwí òmìnira ìjọsìn, àwọn mìíràn ń ṣòfíntótó gbogbo ìgbòkègbodò àwọn ìsìn títí dé orí bíńtín.
Fún àpẹẹrẹ, gbé ipò tí ó gbilẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún ní Mexico yẹ̀ wò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin mú òmìnira ìsìn dáni lójú, ó sọ pé: “Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí a ń lò fún ìjọsìn ní gbangba jẹ́ ohun ìní Orílẹ̀-èdè, tí Ìjọba Àpapọ̀ ń ṣojú fún, òun ni yóò sì lè pinnu èwo ni a lè máa bá nìṣó láti lò bẹ́ẹ̀.” Ní 1991, a ṣàtúnṣe Òfin yẹn láti fòpin sí ìkálọ́wọ́kò yí. Síbẹ̀síbẹ̀, àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé ohun tí a túmọ̀ òmìnira ìsìn sí lè yàtọ̀ ní onírúurú ilẹ̀.
Irú Òmìnira Mìíràn Ní Ti Ìsìn
Òmìnira ìsìn ha wà ní ilẹ̀ tí o ń gbé bí? Bí ó bá wà, báwo ni a ṣe túmọ̀ rẹ̀? O ha lè jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí o bá yàn bí, tàbí a ha fi agbára mú ọ láti di mẹ́ńbà ìsìn Orílẹ̀-èdè bí? A ha fàyè gbà ọ́ láti ka àwọn ìwé ìsìn, kí o sì pín wọn kiri, tàbí ìjọba ha gbẹ́sẹ̀ lé irú àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ bí? O ha lè sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ẹ̀sìn rẹ, tàbí a ha ka èyí sí títẹ ẹ̀tọ́ wọn ní ti ìsìn lójú bí?
Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí sinmi lórí ibi tí o ń gbé. Bí ó ti wù kí ó rí, ó dùn mọ́ni pé irú òmìnira kan wà ní ti ìsìn, tí kò sinmi rárá lórí àgbègbè kan. Nígbà tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 32 Sànmánì Tiwa, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ óò sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:31, 32.
Kí ni Jésù ní lọ́kàn tí ó fi sọ gbólóhùn yí? Àwọn Júù tí ń tẹ́tí sí i ń yán hànhàn fún òmìnira kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù. Ṣùgbọ́n kì í ṣe òmìnira kúrò lábẹ́ ìnilára ìṣèlú ni Jésù ń jíròrò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń ṣèlérí ohun kan tí ó sàn jù fíìfíì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a óò ti rí i nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
-
-
Òtítọ́ Dá Wọn Sílẹ̀ LómìniraIlé Ìṣọ́—1997 | February 1
-
-
Òtítọ́ Dá Wọn Sílẹ̀ Lómìnira
NÍ United States, ó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí a há mọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n. Lára àwọn wọ̀nyí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta tí a ti dájọ́ ikú fún. Wo ara rẹ pé o wà ní ipò yẹn. Báwo ni ìmọ̀lára rẹ yóò ti rí? Ní ti gidi, èrò nípa irú ìfojúsọ́nà yẹn ń múni sorí kọ́. Síbẹ̀, lọ́nà kan, gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ni ó wà ní irú àyíká ipò kan náà. Bíbélì wí pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀ wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ádámù, a wà nínú “ẹ̀wọ̀n” ipò ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) Lójoojúmọ́, a máa ń nímọ̀lára híhá tí a há wa mọ́, gẹ́gẹ́ bí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti nímọ̀lára, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Mo rí nínú àwọn ẹ̀yà ara mi òfin mìíràn tí ń bá òfin èrò inú mi jagun tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.”—Róòmù 7:23.
Nítorí ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a jẹ́, ẹni kọ̀ọ̀kan wa wà lábẹ́ ìdájọ́ ikú, ká sọ ọ́ bẹ́ẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, nítorí Bíbélì wí pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Onísáàmù náà, Mósè, ṣàpèjúwe ipò wa lọ́nà tí ó bá a mu pé: “Àádọ́rin ọdún ni gbogbo ohun tí a ní—ọgọ́rin ọdún, bí a bá lágbára; síbẹ̀ gbogbo ohun tí wọ́n ń mú wá bá wa ni wàhálà àti ìbànújẹ́; láìpẹ́ ìwàláàyè yóò parí, a óò sì kọjá lọ.”—Orin Dáfídì 90:10, Today’s English Version; fi wé Jákọ́bù 4:14.
Sísìnrú tí aráyé ń sìnrú fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni Jésù ní lọ́kàn tí ó fi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Òtítọ́ yóò . . . dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, Jésù ń nawọ́ ìrètí ohun kan tí ó tóbi fíìfíì ju òmìnira kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀—ó ń fún wọn ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ikú! Báwo ni a óò ṣe fún wọn ní èyí? Jésù wí fún wọn pé: “Bí Ọmọkùnrin bá dá yín sílẹ̀ lómìnira, ẹ óò di òmìnira ní ti gàsíkíá.” (Jòhánù 8:36) Bẹ́ẹ̀ ni, nípa fífi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀, ‘Ọmọkùnrin náà,’ Jésù, dúró gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ètùtù láti ra ohun tí Ádámù ti sọ nù pa dà. (Jòhánù Kíní 4:10) Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún gbogbo aráyé onígbọràn láti gba ìtúsílẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run kú “kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà pa run ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
Nítorí náà, òtítọ́ tí ó lè dá wa sílẹ̀ lómìnira rọ̀ mọ́ Jésù Kristi. Àwọn tí ó di ọmọlẹ́yìn atẹ̀lé ipasẹ̀ rẹ̀ ní ìrètí dídi ẹni tí a tú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá gba ìṣàkóso gbogbo àlámọ̀rí ilẹ̀ ayé ní kíkún. Nísinsìnyí pàápàá, àwọn tí ó gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń nírìírí ojúlówó òmìnira. Ní àwọn ọ̀nà wo?
Òmìnira Kúrò Lọ́wọ́ Ìbẹ̀rù Àwọn Òkú
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lónìí ń gbé nínú ìbẹ̀rù àwọn òkú. Èé ṣe? Nítorí àwọn ìsìn wọn ti fi kọ́ wọn pé, ọkàn kan máa ń kúrò nínú ara nígbà ikú, tí ó sì ń kọjá lọ sí ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ àṣà fún àwọn ìbátan òkú ní àwọn ilẹ̀ kan láti ṣàìsùn òkú tí yóò gba ọ̀pọ̀ ọjọ́ tọ̀sántòru. Èyí sábà máa ń ní orin kíkọ sókè àti lílu ìlù nínú. Àwọn aṣọ̀fọ̀ gbà gbọ́ pé èyí yóò mú inú ẹni tí ó kú dùn, yóò sì dènà kí ẹ̀mí rẹ̀ má máa pa dà wá fara han àwọn alààyè. Àwọn ẹ̀kọ́ èké Kirisẹ́ńdọ̀mù nípa àwọn òkú wulẹ̀ mú kí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yìí máa bá a nìṣó ni.
Ṣùgbọ́n, Bíbélì ṣí òtítọ́ nípa ipò tí àwọn òkú wà payá. Ó sọ ní kedere pé ìwọ ni ọkàn rẹ, kì í ṣe ẹ̀yà ara kan lára rẹ tí ó jẹ́ àdììtú, tí ó ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4) Síwájú sí i, a kì í dá àwọn òkú lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣe apá kan ilẹ̀ ọba ẹ̀mí tí ó lè nípa lórí àwọn alààyè. Bíbélì wí pé: “Àwọn òkú kò mọ ohun kan . . . Kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà òkú níbi tí ìwọ ń rè.”—Oníwàásù 9:5, 10.
Àwọn òtítọ́ Bíbélì wọ̀nyí ti dá ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù àwọn òkú. Wọn kì í rú ẹbọ olówó gọbọi láti tu àwọn bàbáńlá wọn lójú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dààmú pé a ń fi ìwà àìláàánú dá àwọn olùfẹ́ wọn lóró nítorí àṣìṣe wọn. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Bíbélì ń nawọ́ ìrètí àgbàyanu sí àwọn tí ó ti kú, nítorí ó sọ fún wa pé ní àkókò tí Ọlọ́run ti yàn, “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” yóò wà. (Ìṣe 24:15; Jòhánù 5:28, 29) Nípa báyìí, àwọn òkú wulẹ̀ ń sinmi nísinsìnyí ni, bí ẹni pé wọ́n wà nínú orun àsùnwọra.—Fi wé Jòhánù 11:11-14.
Òtítọ́ náà nípa ipò àwọn òkú àti ìrètí àjíǹde lè dá wa sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ àìnírètí tí ikú lè mú lọ́wọ́. Irú ìrètí bẹ́ẹ̀ mú tọkọtaya kan ní United States dúró nígbà tí ọmọkùnrin wọn ọlọ́dún mẹ́rin kú nínú ìjàǹbá. Ìyá rẹ̀ wí pé: “A ní ìmọ̀lára òfò nínú ìgbésí ayé wa, tí kò lè dí títí di ìgbà tí a bá rí ọmọkùnrin wa lẹ́ẹ̀kan sí i nípasẹ̀ àjíǹde. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ẹ̀dùn ọkàn wa jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí Jèhófà ti ṣèlérí láti nu omijé ìbànújẹ́ wa kúrò.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Òmìnira Kúrò Lọ́wọ́ Ìbẹ̀rù Ọjọ́ Ọ̀la
Kí ni ọjọ́ ọ̀la ní ní ìpamọ́? A óò ha dáná sun ilẹ̀ ayé wa nínú ogun átọ́míìkì runlérùnnà bí? Pípa àyíká ilẹ̀ ayé wa run yóò ha mú kí pílánẹ́ẹ̀tì wa di aláìṣeégbé bí? Ìbàwàrerejẹ́ yóò ha yọrí sí rúgúdù àti rúkèrúdò bí? Ìwọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rù gidi fún ọ̀pọ̀ lónìí.
Ṣùgbọ́n, Bíbélì fúnni ní òmìnira kúrò lọ́wọ́ irú ìbẹ̀rùbojo bẹ́ẹ̀. Ó mú un dá wa lójú pé “ayé dúró títí láé.” (Oníwàásù 1:4) Jèhófà kò dá pílánẹ́ẹ̀tì wa láti wulẹ̀ rí i kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí kò níláárí pa á run. (Aísáyà 45:18) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà dá ilẹ̀ ayé láti jẹ́ ilé párádísè fún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn tí ó wà níṣọ̀kan. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ète rẹ̀ kò tí ì yí pa dà. Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run yóò “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.” (Ìṣípayá 11:18) Lẹ́yìn ìyẹn, Bíbélì wí pé: “Àwọn ọlọ́kàntútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Orin Dáfídì 37:11.
Ìlérí yìí ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, nítorí Ọlọ́run kì í ṣèké. Jèhófà sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò pa dà sọ́dọ̀ mi lófo, ṣùgbọ́n yóò ṣe èyí tí ó wù mí, yóò sì máa ṣe rere nínú ohun tí mo rán an.” (Aísáyà 55:11; Títù 1:2) Nítorí náà, a lè fi ìgbọ́kànlé wo iwájú fún ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run tí a kọ sínú Bíbélì ní Pétérù Kejì 3:13 pé: “Àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun kan wà tí àwa ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú àwọn wọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”
Òmìnira Kúrò Lọ́wọ́ Ìbẹ̀rù Ènìyàn
Bíbélì pèsè àwọn àpẹẹrẹ gíga lọ́lá fún wa nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n fi àìṣojo hàn nínú ìfọkànsìn wọn sí Ọlọ́run. Lára àwọn wọ̀nyí ni Gídéónì, Bárákì, Dèbórà, Dáníẹ́lì, Ẹ́sítérì, Jeremáyà, Ábígẹ́lì, àti Jáẹ́lì—ká mẹ́nu ba kìkì díẹ̀. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ wọ̀nyí fi ìṣarasíhùwà onísáàmù hàn, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run ni èmi gbẹ́kẹ̀ mi lé, èmi kì yóò bẹ̀rù kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi”?—Orin Dáfídì 56:11.
Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù fi irú àìṣojo kan náà hàn nígbà tí àwọn aláṣẹ ayé pàṣẹ fún wọn láti dá wíwàásù dúró. Wọ́n fèsì pé: “Ní tiwa, àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” Nítorí ìdúró gbọin wọn, a fi Pétérù àti Jòhánù sí ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn náà. Lẹ́yìn tí a ti tú wọn sílẹ̀ lọ́nà iṣẹ́ ìyanu, wọ́n tún pa dà sẹ́nu ìgbòkègbodò wọn, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ‘fífi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ Láìpẹ́, a mú Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòó kù wá sí iwájú Sànhẹ́dírìn Àwọn Júù. Àlùfáà àgbà sọ fún wọn pé: “A pa àṣẹ ìdarí fún yín ní pàtó láti má ṣe máa kọ́ni lórí ìpìlẹ̀ orúkọ yìí, síbẹ̀, sì wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù.” Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòó kù dáhùn pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 4:16, 17, 19, 20, 31; 5:18-20, 27-29.
Nínú iṣẹ́ ìwàásù nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ń ṣe, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ń sakun láti fara wé ìtara àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Àní àwọn èwe tí ń bẹ láàárín wọn pàápàá fẹ̀rí hàn pé wọn kò bẹ̀rù, nípa sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìgbàgbọ́ wọn. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
Stacie, ọ̀dọ́langba kan, jẹ́ onítìjú. Nítorí èyí, bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ kọ́kọ́ ṣòro. Kí ni ohun tí ó ṣe láti ṣẹ́pá ìtìjú rẹ̀? Ó wí pé: “Mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì rí i dájú pé mo lóye ohun tí mo ń sọ. Ó mú kí ó rọrùn, mo sì túbọ̀ dá ara mi lójú.” A ròyìn ìwà rere tí Stacie ní nínú ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò. Ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà, tí olùkọ́ kan ní ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ kọ, kà pé: “Ó dà bíi pé ìgbàgbọ́ [Stacie] ti fún un lókun láti gbéjà ko ìnira tí ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀dọ́ máa ń nímọ̀lára rẹ̀. . . . Ó nímọ̀lára pé iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọ́run ni ó gbọ́dọ̀ jọba lọ́kàn rẹ̀.”
Tommy bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún péré. Àní nígbà tí ó ṣì kéré, ó mú ìdúró aláìṣojo fún ìjọsìn tòótọ́. Nígbà tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní kíláàsì ń ya àwọn àwòrán họlidé, Tommy ya àwòrán Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba, Tommy kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Dípò wíwọ̀ ṣin nítorí ìbẹ̀rù, ó béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ rẹ̀ bóyá òun lè bá kíláàsì jíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn kí òun baà lè dáhùn gbogbo ìbéèrè wọn lẹ́ẹ̀kan. A fún un láyè láti ṣe èyí, ó sì jẹ́rìí àtàtà.
Nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 17, Markietta rí àǹfààní dídára jù lọ láti bá àwọn ẹlòmíràn ní kíláàsì rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó wí pé: “A fún wa ní iṣẹ́ àyànfúnni láti gbé ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀. Mo yan àkòrí mi láti inú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.a Mo yan orí márùn-ún láti inú ìwé náà, mo sì kọ àkọlé wọn sí ojú pátákó ìkọ̀wé. Mo sọ fún kíláàsì láti to ìwọ̀nyí ní ìtòtẹ̀léra bí wọ́n ṣe ronú pé wọ́n ṣe pàtàkì sí.” Ìjíròrò tí kíláàsì lóhùn sí tẹ̀ lé e. Markietta parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo fi ìwé náà han kíláàsì, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mélòó kan sì béèrè fún ẹ̀dà tiwọn. Kódà olùkọ́ mi pàápàá sọ pé òun fẹ́ ọ̀kan.”
Òtítọ́ Lè Dá Ọ Sílẹ̀ Lómìnira
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, òtítọ́ tí ó wà nínú Bíbélì ní agbára ìdarí tí ń sọni dòmìnira lórí tọmọdétàgbà tí ó bá kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tí wọ́n sì fi ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ sọ́kàn. Ó ń sọ wọ́n dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù àwọn òkú, kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ọjọ́ ọ̀la, àti kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ènìyàn. Níkẹyìn pátápátá, ìràpadà Jésù yóò dá aráyé onígbọràn sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ẹ wo ìdùnnú tí yóò jẹ́ láti wà láàyè títí láé nínú párádísè ilẹ̀ ayé kan, tí ipò ẹ̀ṣẹ̀ wa kì yóò tún gbé wa dè mọ́!—Orin Dáfídì 37:29.
Ìwọ yóò ha fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run ṣèlérí? Bí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ni ó yẹ kí o ṣe? Jésù wí pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni náà tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Nítorí náà, bí o bá fẹ́ láti nírìírí òmìnira tí Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, o gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọkùnrin rẹ̀. O ní láti mọ ohun tí ìfẹ́ inú Ọlọ́run jẹ́, kí o sì ṣe é, nítorí Bíbélì wí pé: “Ayé ń kọjá lọ bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—Jòhánù Kíní 2:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a óò dá aráyé sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ àìsàn àti ikú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn
-