ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Gbà Wọ́n Là Nígbà Àjálù
    Ilé Ìṣọ́—1997 | August 15
    • ṣẹlẹ̀. Ní tòótọ́, òun ni ojútùú kan ṣoṣo tí ó wà sí ìṣòro aráyé. Àwọn ènìyàn díẹ̀ lónìí ni wọ́n nímọ̀lára àìséwu àti ààbò. Láìka gbogbo ìsapá sáyẹ́ǹsì sí, àwọn àrùn tí ń gbèèràn túbọ̀ ń run àwọn olùgbé ayé. Àwọn ogun tí gbọ́nmisi-omi-ò-tó láàárín àwọn ìsìn, ẹ̀yà ìran, àti ìṣèlú ń fà ń gbẹ̀mi ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀dá ènìyàn. Ìyàn ń fi kún òṣì àti ìyà tí ń jẹ àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Ìwà ìbàjẹ́ ti fọ́ ìpìlẹ̀ àwùjọ túútúú; àní a ti ba àwọn ọmọdé pàápàá jẹ́.

      Lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí a kọ ní ohun tí ó lé ní 1,900 sẹ́yìn ṣàpèjúwe ipò wa. Ó sọ pé: “Ìwọ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò yóò kún fún ewu.”—Tímótì Kejì 3:1, The New Testament in Modern English, láti ọwọ́ J. B. Phillips; fi wé Mátíù 24:3-22.

      Ìwọ ha rò pé ó bọ́gbọ́n mu pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ yóò jẹ́ aláìbìkítà sí àwọn ìnira wa bí? Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run tìkara rẹ̀ tí ó mọ ayé, tí ó sì ṣe é, . . . kò dá a lásán, ó mọ ọ́n kí a lè gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Bẹ́ẹ̀ ni, kàkà tí ì bá fi yọ̀ǹda kí a pa pílánẹ́ẹ̀tì rèǹtè rente yìí run, kí gbogbo àwọn olùgbé rẹ̀ sì wá sí òpin, Ọlọ́run yóò dá sí i. Ìbéèrè náà ni pé, Báwo ni òun yóò ṣe ṣe é?

      Yan Ìyè!

      Bíbélì dáhùn nínú Orin Dáfídì 92:7 pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú bíi koríko, àti ìgbà tí gbogbo àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bá ń gbèèrú: kí wọn kí ó lè run láéláé ni.” Ojútùú tí Ọlọ́run ní sí àwọn ìṣòro ilẹ̀ ayé ni láti mú ìwà ibi kúrò pátápátá. Ó dùn mọ́ni pé, èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo ènìyàn ni yóò mú kúrò pátápátá. Orin Dáfídì 37:34 mú un dá wa lójú pé: “Dúró de Olúwa, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ayé: nígbà tí a bá ké àwọn ènìyàn búburú kúrò, ìwọ óò rí i.”

      Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi hàn pé àǹfààní wà pé a óò gbani là nígbà àjálù títóbi jù lọ tí yóò dé sórí aráyé. Ọlọ́run ti fún wa ní yíyàn kan. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè fi gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyànjú nígbà tí wọ́n ń múra láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí bá àwa náà mu lónìí pé: “Èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú ọmọ rẹ.” (Diutarónómì 30:19) Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnì kan ṣe lè “yan ìyè,” kí ó sì rí ìgbàlà? Kí ni ìgbàlà tòótọ́ túmọ̀ sí?

  • Ìgbàlà Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Gan-An
    Ilé Ìṣọ́—1997 | August 15
    • Ìgbàlà Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Gan-An

      ‘O HA ti rí ìgbàlà bí?’ Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí ń béèrè ìbéèrè yí ń rò pé àwọn ti rí ìgbàlà nítorí pé wọ́n ti ‘gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà wọn.’ Síbẹ̀ àwọn mìíràn rò pé onírúurú ọ̀nà ni ó lọ sí ìgbàlà, àti pé níwọ̀n bí ‘Jésù bá ti wà nínú ọkàn àyà rẹ,’ ohun yòó wù kí o gbà gbọ́ tàbí ṣọ́ọ̀ṣì yòó wù tí o ń lọ kò ṣe pàtàkì.

      Bíbélì sọ pé ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là.” (Tímótì Kíní 2:3, 4) Nípa báyìí, ìgbàlà wà fún gbogbo àwọn tí wọn yóò tẹ́wọ́ gbà á. Ṣùgbọ́n, kí ni ó tilẹ̀ túmọ̀ sí láti rí ìgbàlà? Ó ha jẹ́ ohun kan tí ó wulẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí ọ láìjẹ́ pé o sapá fún un bí?

      Ọ̀rọ̀ náà “ìgbàlà” túmọ̀ sí “láti gbani nínú ewu tàbí nínú ìparun.” Nípa báyìí, ìgbàlà tòótọ́ ju níní ìmọ̀lára ìfọkànbalẹ̀ lọ. Ó túmọ̀ sí gbígbani nínú ìparun ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí àti nígbẹ̀yìngbẹ́yín gbígbani lọ́wọ́ ikú fúnra rẹ̀! Ṣùgbọ́n, ta ni Ọlọ́run yóò tilẹ̀ gbà là? Láti rí ìdáhùn, jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù Kristi fi kọ́ni lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí. Ìyọrísí ìwádìí wa lè yà ọ́ lẹ́nu.

      Ìgbàlà—A Ha Lè Rí I Nínú Gbogbo Ìsìn Bí?

      Nígbà kan, Jésù jíròrò pẹ̀lú obìnrin ará Samáríà kan. Bí kì í tilẹ̀ ṣe Júù, ó gbà gbọ́ lọ́nà tí ó tọ́ pé Mèsáyà ń bọ̀, “ẹni tí a ń pè ní Kristi.” (Jòhánù 4:25) Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ha tó fún un láti rí ìgbàlà bí? Rárá o, nítorí Jésù fìgboyà sọ fún obìnrin náà pé: “Ẹ̀yin ń jọ́sìn ohun tí ẹ kò mọ̀.” Jésù mọ̀ pé bí obìnrin yìí yóò bá rí ìgbàlà, yóò ní láti tún ọ̀nà tí ó ń gbà jọ́sìn ṣe. Nítorí náà, Jésù ṣàlàyé pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ń bọ̀, nísinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Bàbá ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Bàbá ń wá láti máa jọ́sìn òun.”—Jòhánù 4:22, 23.

      Àkókò míràn tí Jésù ṣí ojú ìwòye rẹ̀ nípa ìgbàlà payá kan àwọn Farisí, ẹ̀ya ìsìn gbígbajúmọ̀ kan nínú ìsìn àwọn Júù. Àwọn Farisí ti gbé ètò ìjọsìn kan kalẹ̀, wọ́n sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà á. Ṣùgbọ́n, gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn Farisí: “Ẹ̀yin àgàbàgebè! Aísáyà tọ̀nà nígbà tí ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín pé: ‘Ète wọn ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ń bọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn àyà wọn jìnnà sí mi. Asán ni wọ́n ń jọ́sìn mi; nítorí ẹ̀kọ́ wọ́n jẹ́ kìkì òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’”—Mátíù 15:7-9, New International Version.

      Ọ̀pọ̀ àwùjọ ìsìn lónìí tí ń sọ pé àwọn gba Kristi gbọ́ ńkọ́? Jésù yóò ha fọwọ́ sì gbogbo wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí ó tọ́ láti rí ìgbàlà bí? A kò ní láti méfò lórí èyí, nítorí Jésù sọ ní kedere pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ inú ìjọba àwọn ọ̀run, bí kò ṣe ẹni náà tí ń ṣe ìfẹ́ inú Bàbá mi tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò wá jẹ́wọ́ fún wọn dájúdájú pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.”—Mátíù 7:21-23.

      Ìmọ̀ Pípéye Nípa Jésù Ṣe Kókó fún Ìgbàlà

      Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wọ̀nyí ní ìtumọ̀ tí ń múni ronú jinlẹ̀. Wọ́n fi hàn pé ọ̀pọ̀ olùfọkànsìn ń kùnà láti “ṣe ìfẹ́ inú Bàbá.” Nígbà náà, báwo ni ẹnì kan ṣe lè rí ìgbàlà? Tímótì Kíní 2:3, 4 dáhùn pé: “Ìfẹ́ inú [Ọlọ́run] ni pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—Fi wé Kólósè 1:9, 10.

      Irú ìmọ̀ yẹn ṣe pàtàkì fún rírí ìgbàlà. Nígbà tí onítúbú kan tí ó jẹ́ ará Róòmù béèrè lọ́wọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Sílà, pé, “Kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìgbàlà?” wọ́n fèsì pé: “Gba Jésù Olúwa gbọ́ ìwọ yóò sì rí ìgbàlà, ìwọ àti agbo ilé rẹ.” (Ìṣe 16:30, 31) Ìyẹn ha túmọ̀ sí pé kìkì ohun ti onítúbú náà àti ìdílé rẹ̀ ní láti ṣe ni láti ní ìmọ̀lára kan nínú ọkàn àyà wọn bí? Rárá o, ìdí kan ni pé, wọn kò lè fi tòótọ́tòótọ̀ “gba Jésù Olúwa gbọ́” láìjẹ́ pé wọ́n ní òye díẹ̀ nípa ẹni tí Jésù jẹ́, ohun tí ó ṣe, àti ohun tí ó fi kọ́ni.

      Fún àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ni nípa ìgbékalẹ̀ ìṣàkóso ti ọ̀run kan—“ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:43) Ó tún gbé ìlànà kalẹ̀ nípa ìwà àti ìṣe Kristẹni. (Mátíù, orí 5-7) Ó sọ ipò tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yóò dì mú nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ìṣèlú. (Jòhánù 15:19) Ó gbé ètò ẹ̀kọ́ kárí ayé kalẹ̀, ó sì fàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti kópa nínú rẹ̀. (Mátíù 24:14; Ìṣe 1:8) Bẹ́ẹ̀ ni, láti ‘gbà gbọ́ nínú Jésù’ túmọ̀ sí lílóye ọ̀pọ̀ nǹkan! Abájọ, nígbà náà, tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi “sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún [onítúbú náà] papọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn wọnnì tí ń bẹ ní ilé rẹ̀” ṣáájú kí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà gbọ́ wọ̀nyí tó ṣe ìbatisí.—Ìṣe 16:32, 33.

      Ìmọ̀ Pípéye Nípa Ọlọ́run Tún Ṣe Kókó

      Apá pàtàkì kan nínú fífi tòótọ́tòótọ́ gbà gbọ́ nínú Jésù ní í ṣe pẹ̀lú jíjọ́sìn Ọlọ́run tí Jésù alára jọ́sìn. Jésù gbàdúrà pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni náà tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.

      Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Ọmọkùnrin Ọlọ́run máa ń fìgbà gbogbo darí àfiyèsí sí Bàbá rẹ̀, kì í ṣe sí ara rẹ̀. Kò fìgbà kan sọ pé òun ni Ọlọ́run Olódùmarè. (Jòhánù 12:49, 50) Ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìgbà, Jésù mú kí ipò rẹ̀ nínú ìṣètò Ọlọ́run ṣe kedere nípa sísọ pé òun kéré sí Bàbá òun. (Lúùkù 22:41, 42; Jòhánù 5:19) Họ́wù, Jésù polongo pé: “Bàbá tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Ṣọ́ọ̀ṣì rẹ ha kọ́ ọ ní ipò ìbátan tòótọ́ tí ó wà láàárín Ọlọ́run àti Kristi? Àbí a ti sún ọ láti gbà gbọ́ pé Jésù fúnra rẹ̀ ni Ọlọ́run Olódùmarè? Ìgbàlà rẹ sinmi lórí níní òye tí ó tọ́nà.

      Nínú Àdúrà Olúwa, Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ti mú kí orúkọ Ọlọ́run fara sin, ní títúmọ̀ rẹ̀ sí “Olúwa.” Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ẹ̀dà àtijọ́ ti “Májẹ̀mú Láéláé,” orúkọ Ọlọ́run fara hàn ju ìgbà ẹgbàata lọ! Nípa báyìí, Orin Dáfídì 83:18 kà pé: “Kí àwọn ènìyàn kí ó lè mọ̀ pé ìwọ, orúkọ ẹnì kan ṣoṣo tí í jẹ́ Jèhófà, ìwọ ni Ọ̀gá Ògo lórí ayé gbogbo.” A ha ti kọ́ ọ láti lo orúkọ Ọlọ́run náà, Jèhófà, bí? Bí a kò bá tí ì kọ́ ọ, ìgbàlà rẹ wa nínú ewu, nítorí “olúkúlùkù ẹni tí ó bá . . . ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbà là”!—Ìṣe 2:21; fi wé Jóẹ́lì 2:32.

      Ní Ẹ̀mí àti Òtítọ́

      Jésù Kristi tún darí àfiyèsí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì. Nígbà tí ó bá ń ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa ojú ìwòye Ọlọ́run lórí àwọn ọ̀ràn kan, ó sábà máa ń sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé.” (Mátíù 4:4, 7, 10; 11:10; 21:13) Alẹ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí ó kú, Jésù gbàdúrà nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—Jòhánù 17:17.

      Níní òye àwọn ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, tún jẹ́ ohun mìíràn tí a ń béèrè fún láti rí ìgbàlà. (Tímótì Kejì 3:16) Bíbélì nìkan ṣoṣo ni ó dáhùn irú àwọn ìbéèrè bíi: Kí ni ìgbésí ayé túmọ̀ sí? Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi láti máa bá a lọ fún ìgbà pípẹ́ tó bẹ́ẹ̀? Kí ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan nígbà tí ó bá kú? Ọlọ́run ha ń dá àwọn ènìyàn lóró ní tòótọ́ nínú ọ̀run àpáàdì bí? Kí ni ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé?a Ẹnì kan kò lè jọ́sìn Ọlọ́run dáradára láìní òye tí ó tọ́ nípa àwọn ọ̀ràn yẹn, nítorí Jésù wí pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Bàbá ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:23.

      Ìgbàgbọ́ Ń Súnni Gbégbèésẹ̀

      Ìgbàgbọ́ ní nínú ju wíwulẹ̀ kó ìsọfúnni jọ lọ. Nínú ọkàn àyà tí ó ṣí sílẹ̀, ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run ń pèsè ìgbàgbọ́. (Róòmù 10:10, 17; Hébérù 11:6) Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ń sún ẹnì kan gbégbèésẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì ṣíni létí pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà kí ẹ sì yí pa dà kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àwọn àsìkò títunilára lè wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.”—Ìṣe 3:19.

      Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbàgbọ́ tún kan mímú ara ẹni bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run ní ti ìwà àti ìṣe mu. Lábẹ́ agbára ìdarí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń yíni pa dà, àwọn ìwà bí irọ́ pípa àti màkàrúrù tí ó ti wọni lẹ́wù ń di èyí tí a ń fi àìlábòsí àti sísọ òtítọ́ rọ́pò. (Títù 2:10) A ń pa àwọn ìwà pálapàla, irú bí ìbẹ́yàkannáà-lòpọ̀, panṣágà, àti àgbèrè tì, a sì ń fi ìwà mímọ́ rọ́pò rẹ̀. (Kọ́ríńtì Kíní 6:9-11) Èyí kì í ṣe títakété sí ìwà àìmọ́ fún ìgbà díẹ̀, èyí tí a gbé karí ìmọ̀lára, bí kò ṣe ìyípadà wíwà pẹ́ títí tí ó wá láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó jíire láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fífi í sílò.—Éfésù 4:22-24.

      Bí àkókò ti ń lọ, ìfẹ́ àti ìmọrírì fún Ọlọ́run ń sún aláìlábòsí ọkàn láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ pátápátá fún Ọlọ́run, kí ó sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ìbatisí nínú omi. (Mátíù 28:19, 20; Róòmù 12:1) Lójú Ọlọ́run, àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ṣe batisí ti rí ìgbàlà. (Pétérù Kíní 3:21) Nígbà ìparun ayé búburú yìí tí ń bọ̀, Ọlọ́run yóò gbà wọ́n là pátápátá nípa pípa wọ́n mọ́ la ìpọ́njú yẹn já.—Ìṣípayá 7:9, 14.

      Ohun Tí Ìgbàlà Lè Túmọ̀ Sí fún Ọ

      Ó ṣe kedere láti inú ìjíròrò ráńpẹ́ yìí pé, rírí ìgbàlà ní nínú ju wíwulẹ̀ ‘ní Jésù Olúwa nínú ọkàn àyà rẹ’ lọ. Ó túmọ̀ sí níní ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi àti ṣíṣe àwọn ìyípadà tí ó yẹ nínú ìgbésí ayé ẹni. Ṣíṣe èyí lè dà bí ohun tí ń páni láyà, ṣùgbọ́n Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tán láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú ìsapá yìí. Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ipa ọ̀nà tí ó lọ sí ìgbàlà tòótọ́.b

      Lójú ìwòye ìsúnmọ́lé ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run tí ń bọ̀, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kánjúkánjú ju ti ìgbàkígbà rí lọ! Ìsinsìnyí ni àkókò náà láti kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì náà pé: “Kí ọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá yín. Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ayé, tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ẹ wá òdodo, ẹ wá ìwà pẹ́lẹ̀: bóyá a óò pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.”—Sefanáyà 2:2, 3.

      [Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

      a Fún ìjíròrò lórí àwọn kókó ẹ̀kọ́ wọ̀nyí, jọ̀wọ́ wo Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

      b Bí ìwọ yóò bá fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, jọ̀wọ́ kàn sí ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ládùúgbò rẹ. Tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tí ó ṣe ìwé ìròyìn yí jáde.

      [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

      Ìgbàlà Ń Wá Láti Inú ...

      ◻ Níní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti Jésù.—Jòhánù 17:3.

      ◻ Lílo ìgbàgbọ́.—Róòmù 10:17; Hébérù 11:6.

      ◻ Ríronúpìwàdà àti yíyípadà.—Ìṣe 3:19; Éfésù 4:22-24.

      ◻ Ìyàsímímọ́ àti ìbatisí.—Mátíù 16:24; 28:19, 20.

      ◻ Bíbá a lọ láti ṣe ìpolongo ní gbangba.—Mátíù 24:14; Róòmù 10:10.

      [Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

      Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, fífi ohun tí a kọ́ sílò, ìyàsímímọ́, àti ìbatisí jẹ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí ń sinni lọ sí ìgbàlà

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́