Ojú Ìwòye Bíbélì
Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ àti Bíbélì Ha Fohùn Ṣọ̀kan Bí?
LÁTI orí àwọn ọkọ̀ òfuurufú àti àwọn bọ́ǹbù átọ́míìkì dé orí àwọn sẹ́ẹ̀lì tí apilẹ̀ àbùdá ń darí àti bíbí àgùntàn olóbìí kan tí ó jọ òbí rẹ̀, ọ̀rúndún ogún wa ti jẹ́ sànmánì tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ jọba lórí rẹ̀. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti gbé ènìyàn dórí òṣùpá, wọ́n ti mú àrùn ìgbóná kúrò, wọ́n ti yí iṣẹ́ àgbẹ̀ pa dà tegbòtigaga, wọ́n sì ti ṣe ìmọ̀ ẹ̀rọ ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lójú ẹsẹ̀ sí ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn jákèjádò ayé. Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé, nígbà tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ bá sọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn máa ń gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́. Àmọ́, kí a tilẹ̀ ní àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní nǹkan láti sọ nípa Bíbélì, kí ni wọ́n ní láti sọ? Àti pé, nídà kejì, kí ni Bíbélì rí sọ fún wa nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀?
Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Kò Ha Bá Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Mu Bí?
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ti lọ́wọ́lọ́wọ́ kan sọ pé: “Àwọn ènìyàn elérò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà gbọ́ nínú ipò ìbátan ‘okùnfà àti àbájáde.’ Wọ́n ronú pé, àlàyé àdánidá pípé kan wà fún ohun gbogbo.” Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú tẹ́wọ́ gba àwọn ìlànà ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí a fìdí ẹ̀rí rẹ múlẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n mọ̀ pé lọ́pọ̀ ìgbà ni Bíbélì ń jíròrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ oníṣẹ́ ìyanu tí a kò lè fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣàlàyé gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ènìyàn mọ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ ni ti oòrùn tí ó dúró sójú kan lọ́jọ́ Jóṣúà àti rírìn tí Jésù rìn lórí omi. (Jóṣúà 10:12, 13; Mátíù 14:23-34) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí agbára Ọlọ́run tí ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tí ó ta yọ ti ẹ̀dá.
Kókó yìí ṣe pàtàkì. Bí Bíbélì bá tẹnu mọ́ ọn pé, àwọn ènìyàn lè rìn lórí omi láìsí ìtìlẹ́yìn àtọ̀runwá tàbí pé, a lè dá lílọ kiri oòrùn tí a ń rí lójú òfuurufú dúró láìnídìí, ó lè jọ pé ó ta ko àwọn kókó ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó ka irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí agbára Ọlọ́run, kò ta ko ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, àmọ́ ó darí ìjíròrò náà sí ọ̀nà ìgbàrorí kan tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tí ì lè lóye.
Bíbélì Ha Ta Ko Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Bí?
Ní ọ̀nà míràn, àwọn ìgbà tí Bíbélì ń jíròrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lásán nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn tàbí tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn irúgbìn, àwọn ẹranko, tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí ti àdánidá ńkọ́? Ó dùn mọ́ni pé kò sí àpẹẹrẹ tí a fìdí ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ pé Bíbélì ta ko àwọn òkodoro òtítọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nígbà tí a bá gbé àyíká ọ̀rọ̀ àwọn ohun tí ó sọ yẹ̀ wò.
Fún àpẹẹrẹ, lọ́pọ̀ ìgbà ni Bíbélì ń lo ọ̀rọ̀ ewì tí ń fi agbára ìlóye àwọn ènìyàn tí ń gbé ayé ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn hàn. Nígbà tí ìwé Jóòbù ń sọ nípa pé Jèhófà ń lù tàbí rọ sánmà kí ó “le bí dígí dídà,” ńṣe ló ń ṣàpèjúwe sánmà bíi dígí onímẹ́táàlì tí ń gbé àwòrán híhàn kedere jáde lọ́nà yíyẹ. (Jóòbù 37:18, NW) Kò sí ìdí kankan láti wo àpèjúwe náà lọ́nà olówuuru, gẹ́gẹ́ bí o kò ti ní wo àpèjúwe náà pé, ayé ní “ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀” tàbí “òkúta igun” kan lọ́nà olówuuru.—Jóòbù 38:4-7, NW.
Èyí ṣe pàtàkì nítorí pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn oníròyìn ni wọ́n ti wo irú àwọn àpèjúwe bẹ́ẹ̀ lọ́nà olówuuru. (Wo Sámúẹ́lì Kejì 22:8; Orin Dáfídì 78:23, 24.) Wọ́n ti parí èrò sí pé, Bíbélì ń fi ohun kan kọ́ni bí èyí tí ó tẹ̀ lé e yìí, tí a fà yọ láti inú The Anchor Bible Dictionary.
“A rò pé ilẹ̀ ayé tí aráyé ń gbé inú rẹ̀ jẹ́ ohun roboto, tí ó lágbára, bóyá ohun pẹlẹbẹ tí ó rí roboto kan, tí ó léfòó sórí agbami òkun tí kò láàlà. Àgbájọ omi mìíràn, tí òun pẹ̀lú kò láàlà, wà ní ìpele kan náà pẹ̀lú àgbájọ omi rírẹlẹ̀ yí lófuurufú, tí omi ń ti inú rẹ̀ gba àárín àwọn ihò àti ọ̀nà tí ó dáhò sára adágún ọ̀run wá sílẹ̀ bí òjò. Òṣùpá, oòrùn, àti àwọn ohun atànmọ́lẹ̀ míràn wà lójú kan bí ìgbékalẹ̀ kọdọrọ tí ó tẹ̀ kọdọrọ bo ilẹ̀ ayé. Ìgbékalẹ̀ yí ni ‘ìtẹ̀kọdọrọ òfuurufú’ (rāqîa‛) tí a mọ̀ dunjú náà, tí àwọn àlùfáà ròyìn.”
Ní kedere, àpèjúwe yìí kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ òde òní. Ṣùgbọ́n èyí ha jẹ́ ìfojúdíwọ̀n aláìlábòsí nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa ọ̀run bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopædia sọ pé, irú àwọn àpèjúwe àgbáálá ayé Hébérù bẹ́ẹ̀ jẹ́ “èyí tí a gbé karí àwọn èrò tí ó gbalẹ̀ ní ilẹ̀ Europe láàárín Sànmánì Ojú Dúdú kàkà kí a gbé e karí àwọn ọ̀rọ̀ gidi nínú M[ájẹ̀mú] L[áéláé] ní gidi.” Ibo ni àwọn èrò sànmánì agbedeméjì wọ̀nyẹn ti wá? Bí David C. Lindberg ti ṣàlàyé nínú ìwé náà, The Beginnings of Western Science, dé ayè tí ó lọ jìnnà, a gbé wọn karí ẹ̀kọ́ nípa àgbáálá ayé lọ́nà ti ọlọ́gbọ́n èrò orí Gíríìkì ìgbàanì náà, Aristotle, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ ní sànmánì agbedeméjì.
Ì bá ti jẹ́ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu, tí ó sì ń pín ọkàn níyà pé kí Ọlọ́run ṣàgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lọ́nà tí yóò fa ọkàn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ní ọ̀rúndún ogun mọ́ra. Dípò àwọn ìgbékalẹ̀ tí ó jẹ́ ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, Bíbélì ní ọ̀pọ̀ àwọn àpèjúwe ṣíṣekedere tí a fà yọ láti inú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n kọ́kọ́ kọ wọ́n sílẹ̀—àpèjúwe ṣíṣekedere tí ó ní ipa agbára aláìlópin lọ́jọ́ òní pàápàá.—Jóòbù 38:8-38; Aísáyà 40:12-23.
Ìmọ̀ Láti Orísun Gíga Jù Kan
Bí ó ti wù kí ó rí, ó dùn mọ́ni pé àwọn ìtọ́kasí kan tí a ṣe nínú Bíbélì rí bí èyí tí ó gbé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ènìyàn tí ń gbé nígbà yẹn yọ. Jóòbù ṣàpèjúwe Ọlọ́run pé ó “na àríwá sórí ibi ṣíṣófo, ó so ilẹ̀ ayé rọ̀ sórí òfo.” (Jóòbù 26:7, NW) Èrò náà pé a so ayé rọ̀ “sórí òfo” yàtọ̀ gan-an sí àwọn ìtàn àròsọ tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn ìgbàanì mọ̀, tí ó gbé e sórí àwọn erin tàbí àwọn ìjàpá òkun, ń sọ. Òfin Mósè ní àwọn ohun àbèèrèfún nítorí ìmọ́tótó nínú tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìṣègùn ìgbà náà tó dé. Láìsí àní-àní, àwọn ìlànà fún lílé àwọn ènìyàn tí a fura sí pé wọ́n ní àrùn ẹ̀tẹ̀ kúrò láàárín ìlú àti ìkàléèwọ̀ lòdì sí fífọwọ́kan òkú ènìyàn gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là. (Léfítíkù 13; Númérì 19:11-16) Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra gédégédé, a ṣàpèjúwe ọ̀nà ìṣègùn àwọn ará Ásíríà gẹ́gẹ́ bí “àdàlù ìsìn, iṣẹ́ wíwò, àti ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀mí èṣù,” ó sì kan fífi ìgbẹ́ ajá àti ìtọ̀ ènìyàn ṣètọ́jú.
Bí ẹnì kan ti lè retí láti inú ìwé kan tí ó ní ìmísí Ẹlẹ́dàá, Bíbélì ní àwọn ìsọfúnni pípé ní ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, tí ó hàn kedere pé wọ́n ti lọ jìnnà gédégédé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wọnú àwọn àlàyé lọ́nà ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ì bá máà nítumọ̀ tàbí kí ó da nǹkan rú mọ́ àwọn ènìyàn ìgbàanì lójú. Bíbélì kò ní ohunkóhun tí ó ta ko àwọn kókó ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí a mọ̀ nínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn àbá èrò orí tí a kò fìdí ẹ̀rí wọn múlẹ̀, bí àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n nínú.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
Ọ̀rọ̀ Jóòbù pé, ayé ‘so rọ̀ sórí òfo’ fi ìmọ̀ tí àwọn alájọgbáyé rẹ̀ kò ní hàn
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
NASA