ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣọ́ra fún Níní Èrò Òdì Síni
    Ilé Ìṣọ́—1997 | May 15
    • Ṣọ́ra fún Níní Èrò Òdì Síni

      GBAJÚGBAJÀ ajíhìnrere orí tẹlifíṣọ̀n kan fẹ̀sùn burúkú kan kan oníwàásù ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ fún ṣíṣe panṣágà. Ṣùgbọ́n, láàárín ọdún kan, a ká ajíhìnrere tí ó fẹ̀sùn kanni náà mọ́ ọ̀dọ̀ aṣẹ́wó.

      Nínú ọ̀ràn míràn, òléwájú agbára ayé kan rán àwọn ikọ̀ jáde láti lọ pẹ̀tù sọ́kàn àwọn ẹgbẹ́ tí ń bára wọn jagun. Láàárín àkókò náà, orílẹ̀-èdè kan náà rán àwọn oníṣòwò ohun ìjà ogun rẹ̀ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè ní bòńkẹ́lẹ́, láti lọ polówó ohun ìjà ogun tí ó tó ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là.

      Níwọ̀n bí àgàbàgebè pátápátá ti di ohun tí ó wọ́pọ̀, ó ha yani lẹ́nu pé ẹ̀mí iyè méjì ti gbapò ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá bí? Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, fífura sí èrò àwọn ẹlòmíràn ti di ara fún wọn.

      Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti má ṣe yọ̀ǹda fún irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ láti nípa lórí ipò ìbátan wa pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Bí Jésù Kristi tilẹ̀ rọ̀ wá láti “jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò” nígbà tí a bá wà láàárín àwọn ọ̀tá wa, kò sọ pé kí a máa fura sí àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́. (Mátíù 10:16) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, ewu wo ní ń bẹ nínú níní èrò òdì sí àwọn ẹlòmíràn? Àwọn àgbègbè wo ní pàtàkì ni ó yẹ kí a ti yẹra fún irú ìtẹ̀sí bẹ́ẹ̀? Báwo sì ni a ṣe lè dáàbò bo ipò ìbátan wa ṣíṣeyebíye pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa?

      Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Inú Ìṣẹ̀lẹ̀ Àtẹ̀yìnwá

      Níní èrò òdì sí àwọn ẹlòmíràn láìnídìí jẹ́ ohun kan náà pẹ̀lú dídá wọn lẹ́jọ́. Ṣe ni ó dà bí ẹni pé a ń tètè dé ìparí èrò pé àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn wulẹ̀ jẹ́ ẹ̀tàn lásán, tí ń fi békebèke àti àránkàn pa mọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, níní ojú ìwòye òdì nípa àwọn nǹkan gan-an ni ìṣòro náà, gẹ́gẹ́ bí a ti lè rí i nínú àkọsílẹ̀ tí a kọ sínú Bíbélì nínú Jóṣúà orí 22.

      Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun gbogbo Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ gba àgbègbè ìpínlẹ̀ ẹ̀yà wọn ni. Ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti Gáàdì àti ìlàjì ẹ̀yà Mánásè kọ́ pẹpẹ kan “tí ó tóbi láti wò” sí ẹ̀bá Odò Jọ́dánì. Àwọn ẹ̀yà yó kù rò pé èyí jẹ́ ìwà ìpẹ̀yìndà. Wọ́n rò pé àwọn ẹ̀yà mẹ́ta náà yóò lo pẹpẹ ńlá yìí fún ìrúbọ dípò lílọ sí àgọ́ àjọ ní Ṣílò, ibi tí a yàn fún ìjọsìn. Lójú ẹsẹ̀, àwọn ẹ̀yà tí ó fẹ̀sùn kàn wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í múra ogun.—Jóṣúà 22:10-12.

      Wọ́n ṣe dáadáa ní ti pé wọ́n bá àwọn arákùnrin wọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa rírán àwọn aṣojú tí Fíníhásì jẹ́ aṣáájú fún. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ẹ̀sùn àìṣòótọ́, ọ̀tẹ̀, àti ìpẹ̀yìndà sí Jèhófà tí a fi kàn wọ́n, àwọn ẹ̀yà tí a rò pé wọ́n hùwà láìfí náà ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi kọ́ pẹpẹ gàgàrà yí. Dípò tí yóò fi jẹ́ pẹpẹ fún ìrúbọ, wọ́n fẹ́ kí ó jẹ́ “ẹ̀rí” ìṣọ̀kan àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì nínú jíjọ́sìn Jèhófà. (Jóṣúà 22:26, 27) Àwọn aṣojú náà pa dà sílé pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn pé àwọn arákùnrin wọn kò ṣe ohun kan tí ó lòdì. A tipa báyìí yẹra fún ogun abẹ́lé àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ búburú jáì.

      Ẹ wo irú ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tí èyí jẹ́ fún wa láti má ṣe tètè máa ní èrò òdì sí àwọn ẹlòmíràn! Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí ó fara hàn bí òtítọ́ nípa ìwò fìrí lásán ni a lè rí i pé ó yàtọ̀ pátápátá nígbà tí a bá yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní. Èyí jẹ́ òtítọ́ nínú ọ̀pọ̀ apá ìgbésí ayé Kristẹni.

      Ojú Ìwòye Wa Nípa Àwọn Alàgbà

      Ní bíbójútó ẹrù iṣẹ́ wọn “láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run,” nígbà míràn, àwọn alàgbà máa ń rí i pé ó pọn dandan láti gba àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ nímọ̀ràn. (Ìṣe 20:28) Fún àpẹẹrẹ, báwo ni a ṣe ń hùwà pa dà nígbà tí alàgbà kan bá bá wa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ wa lórí irú ọ̀ràn bí ẹgbẹ́ búburú tàbí ìwà àìtọ́ pẹ̀lú ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹ̀yà kejì? A ha ń gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ sódì, tí a sì ń sọ fún ara wa pé, ‘Kò fìgbà kan nífẹ̀ẹ́ ìdílé wa’? Bí a bá fàyè gba irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ láti nípa lórí wa, a lè jẹ̀ka àbámọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ire tẹ̀mí àwọn ọmọ wa lè wà nínú ewu, ó sì yẹ kí a mọrírì ìrànlọ́wọ́ ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́.—Òwe 12:15.

      Nígbà tí alàgbà ìjọ kan bá fún wa nímọ̀ràn, ẹ má ṣe jẹ́ kí a gbà á sódì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a bi ara wa bí ọ̀nà kan bá wà tí a fi lè jàǹfààní láti inú ìmọ̀ràn rẹ̀ tí ó gbé karí Bíbélì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Lóòótọ́, kò sí ìbáwí tí ó dà bí [ohun ìdùnnú] nísinsìnyí, bí kò ṣe akó ẹ̀dùn ọkàn báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá fún àwọn wọnnì tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀ a máa so èso ẹlẹ́mìí-àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:11) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a kún fún ìmoore, kí a sì fi ẹ̀mí rere ronú lórí ọ̀ràn. Ẹ jẹ́ kí a rántí pé bí ó ṣe ṣòro lọ́pọ̀ ìgbà fún wa láti gba ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣòro fún àwọn alàgbà láti fún wa nímọ̀ràn.

      Ìmọ̀lára Nípa Àwọn Òbí

      Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ kan bá dojú kọ àwọn ìkálọ́wọ́kò kan láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn, wọ́n máa ń gbé ìbéèrè dìde sí èrò àwọn òbí wọn. Àwọn ọ̀dọ́ kan lè sọ pé: ‘Èé ṣe tí àwọn òbí mi fi ń ṣe òfin tí ó pọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ pé wọn kò fẹ́ kí n jayé orí mi ni.’ Ṣùgbọ́n, dípò tí wọn yóò fi máa dé irú ìparí èrò bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ ní láti fi ẹ̀mí rere ṣàyẹ̀wò ipò ọ̀ràn náà fínnífínní.

      Àwọn òbí ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú bíbójútó àwọn ọmọ wọn. Wọ́n ti ṣe èyí pẹ̀lú ìrúbọ ńláǹlà nípa ti ara àti lọ́nà míràn. Ìdí èyíkéyìí ha wà láti parí èrò sí pé wọ́n ti pinnu nísinsìnyí láti mú kí ìgbésí ayé àwọn ọmọ wọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́langba jẹ́ aláìláyọ̀? Kò ha bọ́gbọ́n mu jù láti ronú pé ìfẹ́ ní ń sún àwọn òbí wọ̀nyí láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn àti láti bójú tó wọn? Ìfẹ́ kan náà ko ha ní sún wọn láti gbé àwọn ìkálọ́wọ́kò kan kalẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ń dojú kọ àwọn ìpèníjà tuntun nínú ìgbésí ayé nísinsìnyí bí? Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ìwà ìkà àti àìmoore tó láti ní èrò òdì sí àwọn òbí onífẹ̀ẹ́!—Éfésù 6:1-3.

      Ìṣarasíhùwà Wa sí Àwọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ́ Wa

      Ọ̀pọ̀ ní ìtẹ̀sí láti dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́ láìwádìí ọ̀ràn, àti láti ní èrò kan pàtó nípa wọn. Bí àwa fúnra wa bá ti ní irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀, tí a sì ti ń fura sí àwọn ènìyàn kan ńkọ́? Ẹ̀mí ìrònú ayé ha lè nípa lórí wa lọ́nà yí bí?

      Fún àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa nípa tẹ̀mí ní ilé rèǹtè rente àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ olówó gọbọi kan. Ó ha yẹ kí a dé ìparí èrò kíákíá pé ó jẹ́ ẹnì kan tí ó nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tí kì í fi ire Ìjọba sí ipò kíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀ bí? Ó lè ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni kan láti ní àwọn nǹkan rèǹtè rente, ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí pé wọ́n ní èrò búburú tàbí pé wọn kò ‘wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ̀.’ Ọwọ́ wọn lè dí fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, ní fífi ọ̀làwọ́ lo ohun ìní wọn nípa ti ara láti gbé ire Ìjọba lárugẹ, bóyá lọ́nà kan tí kò hàn sí gbogbogbòò.—Mátíù 6:1-4, 33.

      Ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní kún fún àwọn ènìyàn onírúurú—ọlọ́rọ̀ àti tálákà. (Ìṣe 17:34; Tímótì Kíní 2:3, 4; 6:17; Jákọ́bù 2:5) Ọlọ́run kì í gbé ìjẹ́pàtàkì àwọn ènìyàn karí ipò wọn ní ti ìṣúnná owó, kò sì yẹ kí àwa pẹ̀lú ṣe bẹ́ẹ̀. A ní láti nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí a ti dán wò, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́, “láìṣe ohunkóhun ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbèsápákan.”—Tímótì Kíní 5:21.

      Nínú ayé tí ó wà lábẹ́ agbára Sátánì yí, níní èrò kan pàtó nípa ẹni àti fífura síni ń gba onírúurú ọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, a lè ka ẹnì kan sí oníwà ipá tàbí onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, kìkì nítorí ipò àtilẹ̀wá rẹ̀. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a kò gbọ́dọ̀ ṣubú sínú níní irú èrò bẹ́ẹ̀. Ètò àjọ Jèhófà kì í ṣe ibi tí a kì í ti í gba ojú ìwòye ẹlòmíràn, tí a sì ti ń fura síni. Gbogbo Kristẹni tòótọ́ ní láti fara wé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí “kò sí àìṣòdodo tàbí ojúsàájú” lọ́dọ̀ rẹ̀.—Kíróníkà Kejì 19:7; Ìṣe 10:34, 35.

      Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Sún Ọ

      Ìwé Mímọ́ sọ ní kedere pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀ wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Nítorí náà, ó yẹ kí a ka àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa sí àwọn tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa ní lílàkàkà láti ṣe iṣẹ́ ìsìn tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà. Bí a bá ti yọ̀ǹda fún ìfura tàbí ìmọ̀lára òdì míràn láti nípa lórí ipò ìbátan wa pẹ̀lú arákùnrin wa tàbí arábìnrin wa nípa tẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti gbéjà ko irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀, kí a má baà di ẹran ìjẹ fún Sátánì. (Mátíù 6:13) Ó yí Éfà lọ́kàn pa dà láti gbà pé Jèhófà ní èrò òdì, pé ire rẹ̀ kò jẹ ẹ́ lọ́kàn, pé ó sì ń fawọ́ òmìnira tí yóò mú un ní ayọ̀ tòótọ́ sẹ́yìn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Níní èrò òdì sí àwọn arákùnrin wa ń ṣiṣẹ́ fún ire Èṣù.—Kọ́ríńtì Kejì 2:11; Pétérù Kíní 5:8.

      Bí a bá rí i pé a ní ìtẹ̀sí láti ní èrò òdì sí àwọn ẹlòmíràn, ẹ jẹ́ kí a gbé àpẹẹrẹ Jésù Kristi yẹ̀ wò. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ Ọmọkùnrin pípé ti Ọlọ́run, kò wá èrò òdì nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù wá èrò rere tí ó wà nínú wọn. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń jà fún ipò ìyọrí-ọlá, kò ní èrò pé wọ́n ní èrò ìbàjẹ́, kí ó sì fi àpọ́sítélì 12 tuntun rọ́pò wọn. (Máàkù 9:34, 35) Nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìpé, àṣà àwọn apẹ̀yìndà ẹlẹ́sìn Júù, pẹ̀lú ìtẹnumọ́ wọn lórí ọ̀wọ̀ ara ẹni àti kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ti lè nípa lórí wọn lọ́nà kan. Jésù mọ̀ pé ìfẹ́ fún Jèhófà ni olórí ìsúnniṣe àwọn ọmọlẹ́yìn òun. Fún fífi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn àti rírọ̀ mọ́ Jésù, a san èrè ńláǹlà fún wọn.—Lúùkù 22:28-30.

      Bí a bá ní láti wo àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tìfuratìfura, èyí yóò dà bíi fífi awò tí ń yí ìrísí ẹni pa dà wo nǹkan. Kò sí ohun tí yóò fara hàn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí gan-an. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi awò ìfẹ́ wo nǹkan. Ẹ̀rí rẹpẹtẹ ń bẹ pé àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa adúróṣinṣin nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì yẹ fún ìgbatẹnirò onínúure wa. (Kọ́ríńtì Kíní 13:4-8) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ hàn sí wọn, kí a sì ṣọ́ra fún níní èrò òdì síni.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

      Ojú wo ni o fi ń wo àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ń fi òtítọ́ jọ́sìn Ọlọ́run?

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

      Ìgbẹ́kẹ̀lé àti ọ̀wọ̀ mú kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìdílé aláyọ̀ tí ó wà níṣọ̀kan

  • “Wọ́n Ń Fi Ohun Tí Ẹ̀sìn Wọn Kọ́ Wọn Sílò”
    Ilé Ìṣọ́—1997 | May 15
    • “Wọ́n Ń Fi Ohun Tí Ẹ̀sìn Wọn Kọ́ Wọn Sílò”

      OBÌNRIN kan láti Miami, Florida, U.S.A., fi lẹ́tà tí ó tẹ̀ lé e yìí ránṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde kan: “Ní ọjọ́ 10 oṣù Dec., wọ́n yọ pọ́ọ̀sì ọmọkùnrin mi mọ́ ọn lára ní ọjà ẹrù tòkunbọ̀ kan. Ìwé ìwakọ̀ rẹ̀, káàdì Ètò Ìpèsè Ìrànwọ́ fún Ọjọ́ Ogbó, àti oríṣiríṣi nǹkan mìírán wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú 260 dọ́là.

      “Lẹ́yìn tí ó ti fi ọ̀rọ̀ náà tó máníjà létí, ó pa dà wá sílé. Ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, obìnrin kan tí ń sọ èdè Spanish tí alámòójútó [tẹlifóònù] ṣe ògbufọ̀ fún, tẹ̀ ẹ́ láago, ó sì sọ fún un pé òun ti bá a rí pọ́ọ̀sì rẹ̀.

      “Obìnrin náà sọ àdírẹ́sì rẹ̀ fún un. . . . Ó fún un ní pọ́ọ̀sì náà, èyí tí ó ṣì wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀, títí kan 260 dọ́là tí ó wà nínú rẹ̀.

      “Ó rí jáwójáwó náà nígbà tí ó ń yọ pọ́ọ̀sì náà, ó sì kígbe. Jáwójáwó náà ju pọ́ọ̀sì náà sílẹ̀, ó sì fẹsẹ̀ fẹ́ẹ. Nígbà tí yóò fi bojú wòkè kò rí ọmọkùnrin mi mọ́, nítorí náà, ó mú pọ́ọ̀sì náà lọ sílé ó sì tẹ ọmọkùnrin mi láago.

      “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọmọbìnrin náà àti ìdílé rẹ̀. Ó hàn gbangba gbàǹgbà pé wọ́n ń fi ohun tí ẹ̀sìn wọn kọ́ wọn sílò.”

      Kì í ṣe nítorí kí àwọn ènìyàn baà lè yìn wọ́n ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń fi ìwà àìlábòsí hàn. (Éfésù 6:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fẹ́ láti fi tọkàntọkàn mú ìyìn wá fún Bàbá wọn ọ̀run, Jèhófà. (Kọ́ríńtì Kíní 10:31) Ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run àti fún àwọn aládùúgbò wọn ń sún wọn láti polongo “ìhìn rere” Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Nípasẹ̀ Ìjọba náà, Ọlọ́run ṣèlérí láti sọ ilẹ̀ ayé di párádísè ẹlẹ́wà kan. Nígbà náà, ilẹ̀ ayé kì yóò jẹ́ ibi ẹlẹ́wà tí a lè fojú rí nìkan, ṣùgbọ́n yóò tún jẹ́ ibi tí ìwà rere títayọ wà, ibi tí àìlábòsí yóò ti gbilẹ̀ títí láé.—Hébérù 13:18; Pétérù Kejì 3:13.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́