Idi Ti A Fi Nilo Igbagbọ ati Ọgbọ́n
Awọn Koko Itẹnumọ Lati inu Lẹta Jakọbu
AWỌN IRANṢẸ Jehofa nilo ìfaradà nigba ti wọn ba wà labẹ ìdánwò. Wọn tun gbọdọ yẹra fun awọn ìwà ti yoo yọrisi airi itẹwọgba atọrunwa. Iru awọn kókó bẹẹ ni a tẹnumọ ninu lẹta Jakọbu, ti ṣiṣe ohun kan nipa wọn ní ṣàkó sì nbeere fun ìgbàgbọ́ mimuna ati ọgbọn ti ọ̀run.
Ẹniti o kọ lẹta yi ko fi ara rẹ hàn gẹgẹ bi ọkan lara awọn apọsteli Jesu meji ti a ńpè ni Jakọbu ṣugbọn gẹgẹ bi ‘ẹrú Ọlọrun ati Kristi.’ Lọna ti o farajọra, arakunrin iyèkan Jesu, Juuda wipe oun jẹ “ẹrú Jesu Kristi, ṣugbọn arakunrin Jakọbu.” (Jakọbu 1:1; Juuda 1; Matiu 10:2, 3) Fun ìdí yìí, lọna híhàn gbangba, arakunrin iyèkan Jesu ni o kọ lẹta naa ti a fi orukọ rẹ pè.—Maaku 6:3
Lẹta yi ko mẹnukan ìparun Jerusalẹmu ni 70 C.E., òpìtàn naa Josephus sì fihan pe Jakọbu ni a fi iku ajẹriiku pa ní kété lẹhin iku Fẹsitọsi òṣìṣẹ́-olóyè ti Roomu ni nnkan bii 62 C.E. Nigba naa, o farahàn gbangba pe lẹta naa ni a kọ ṣaaju 62 C.E. A kọ ọ́ si “awọn ẹ̀yà mejila” ti Israẹli tẹmi, nitori a dari rẹ ni tààràtà si awọn wọnni ti wọn ndi “igbagbọ Jesu Kristi Oluwa wa.” mú.—Jakọbu 1:1; 2:1; Galatia 6:16.
Jakọbu lo awọn àkàwé ti o le ràn wá lọ́wọ́ lati ranti ìmọ̀ràn rẹ̀. Fun apẹẹrẹ, oun fihan pe ẹnikan ti nbeere fun ọgbọn lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun kò nilati ṣiyèméjì, “nitori ẹni ti o ńṣiyèméjì dabi ìgbì omi okun, ti ńti ọwọ́ afẹfẹ bì siwa bì sẹhin ti a sì nru soke.” (1:5-8) Ahọ́n wa ni a nilati ṣàkóso nitori pe o le dari igbesẹ wa gẹgẹ bi ìtọ́kọ̀ kan ṣe ndari ọkọ oju omi kan. (3:1, 4) Ati lati kojú awọn àdánwò, awa nilati fi ìfaradà oni sùúrù han gẹgẹ bi àgbẹ̀ ti nṣe nigba ti o ba ńdúró de ìkórè.—5:7, 8.
Igbagbọ, Àdánwò, ati Iṣẹ
Jakọbu kọ́kọ́ fihan pe awa le jẹ alayọ gẹgẹ bi Kristian láìka awọn àdánwò wa sí. (1:1-18) Diẹ lara awọn àdánwò wọnyi, iru bi aisan, wọ́pọ̀ fun gbogbo eniyan, ṣugbọn awọn Kristian tun njiya lọwọ jijẹ ẹru Ọlọrun ati ti Kristi. Jehofa yoo fi ọgbọn ti a nilo lati farada fun wa bi awa ba nbaa lọ lati beere fun un pẹlu ìgbàgbọ́. Oun kò fi ibi dán wa wò ri, awa si le gbojule e lati pese ohun ti o dara fun wa.
Lati ri iranlọwọ Ọlọrun gbà, awa gbọdọ jọsin rẹ nipasẹ awọn iṣẹ ti wọn nṣaṣefihan ìgbàgbọ́ wa. (1:19–2:26) Eyi beere pe ki awa jẹ “oluṣe ọrọ naa,” kì í ṣe olugbọ lásán. Awa gbọdọ ṣakoso ahọ́n, bojuto awọn ọmọ aláìní Baba ati awọn opó, ki a si pa ara wa mọ láìsí àbàwọ́n kuro ninu aye. Bi awa ba ṣojúṣàájú awọn ọlọrọ ti a si ṣàìka awọn òtòṣì si, awa yoo ṣẹ̀ si “Ofin ọba naa” ti ìfẹ́. O tun yẹ ki a ranti pe ìgbàgbọ́ ni a fihan nipa iṣẹ, gẹgẹ bi awọn apẹẹrẹ Abrahamu ati Rahabu ti ṣakawe daradara. Niti tootọ, ‘igbagbọ laisi iṣẹ jẹ oku.’
Ọgbọ́n ti Ọ̀run ati Àdúrà
Awọn olùkọ́ nilo ìgbàgbọ́ ati ọgbọn lati mú iṣẹ́ wọn ṣẹ. (3:1-18) Wọn ni ẹrù-iṣẹ́ wíwúwo gẹgẹ bi olùkọ́ni. Gẹgẹ bi tiwọn, awa gbọdọ ṣèkáwọ́ ahọ́n—ohun kan tí ọgbọn ti ọ̀run ràn wa lọwọ lati ṣe.
Ọgbọ́n yoo tun jẹ ki a mọ̀ dájú pe jíjuwọ́sílẹ̀ fun awọn ìtẹ̀sí ti aye yoo ba ipò ìbátan wa pẹlu Ọlọrun jẹ́ (4:1–5:12) Bi awa ba ti jìjàkadì lati lé ìfojúsùn onimọtara-ẹni-nikan bá tabi ti a ti dá awọn arakunrin wa lẹbi, awa nilati ronúpìwàdà. Bawo ni o sì ti ṣe pataki to lati yẹra fun ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹlu aye yii, nitori eyi jẹ panṣágà tẹmi! Ẹ maṣe jẹki a ṣàìfiyèsí ìfẹ́-inú Ọlọrun lae nipa ìwéwèé ohun ti ara, ǹjẹ́ ki a sì ṣọra lodisi ẹmi àìnísùúrù ati mímí ìmí ẹ̀dùn lòdìsí ara wa ẹnikinni keji.
Ẹnikẹni ti o ba ńṣàìsàn nipa tẹmi nilati wá ìrànlọ́wọ́ awọn alagba ìjọ. (5:13-20) Bi o ba ti dẹṣẹ, adura ati ìmọ̀ràn ọlọgbọn wọn yoo ṣèrànwọ́ lati mú ìlera tẹmi ẹlẹṣe ti o ronúpìwàdà naa padà bọ sipo. Niti tootọ, “ẹni ti o ba yi ẹlẹṣẹ kan pada kuro ninu ìṣìnà rẹ, yoo gba ọkan [ti oniwa àìtọ́ naa] là kuro lọwọ iku [tẹmi ati ti ayeraye].”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
Olùṣe Ọrọ Naa: Awa nilati jẹ “olùṣe ọrọ naa, kìí sii ṣe olùgbọ́ nikan.” (Jakọbu 1:22-25) Olùgbọ́ lasan “ni o dabi ẹnikan ti nwo oju ara rẹ ninu àwòjíìji.” Lẹhin àyẹ̀wò kukuru, oun lọ “lojukan naa o sì gbagbe bi oun ti ri.” Ṣugbọn ‘olùṣe ọrọ naa’ fi tìṣọ́ratìṣọ́ra wo ofin ti Ọlọrun pipe perepere ti o ni ohun gbogbo ti a beere lọwọ Kristian kan ninu. Oun “duro ninu rẹ,” ní bíbáa lọ lati yẹ ofin naa wò fínnífínní pẹlu ìrònú ṣiṣe awọn àtúnṣe ki o ba lè ba a ṣe deedee ni pẹ́kípẹ́kí. (Saamu 119:16) Bawo ni “olùṣe iṣẹ” ṣe yàtọ̀ si ẹni ti o wo àwòjíìji fìrí ti o si gbàgbé ohun ti o fihan? Họ́wù, olùṣe naa fi ọrọ Jehofa silò o si gbadun ojurere Rẹ!—Saamu 19:7-11.