Ìfẹ́ Ará Jẹ́ Agbékánkánṣiṣẹ́
Awọn Koko Itẹnumọ Lati inu Filemoni
JESU KRISTI fun awọn ọmọlẹhin rẹ ni “ofin titun” pe ki wọn nifẹẹ ara wọn ẹnikinni ẹnikeji gan-an gẹgẹbi oun ti nifẹẹ wọn. (Johanu 13:34, 35) Nitori ìfẹ́ yẹn, wọn yoo tilẹ kú fun ara wọn ẹnikinni ẹnikeji. Bẹẹni, ìfẹ́ ará lágbára tobẹẹ o si ńgbékánkánṣiṣẹ́.
Apọsteli Pọọlu ni idaniloju pe ìfẹ́ ara yoo sún Filemoni, Kristian kan ti o ndarapọ mọ ijọ ti o wà ni Kolose, ilu nla kan ni Asia Kekere. Ìfẹ́ ti sún Filemoni lati ṣi ile rẹ silẹ fun lilo gẹgẹbi ibi ipade Kristian. Onesimọsi ẹrú Filemoni ti salọ, o ṣeeṣe ki o jí owo ti yoo fi wọ ọkọ oju omi lọ si Roomu, nibi ti o ti pade Pọọlu nikẹhin ti o si tẹwọgba isin Kristian.
Nigba ti a fi sẹwọn ni Roomu ni nnkan bi 60 si 61 C.E., Pọọlu kọ lẹta kan ti a dari si Filemoni ni ipilẹ. O bẹ Filemoni lati gba Onesimọsi ti npada bọ pẹlu ẹmi ara. Ka lẹta yii, iwọ yoo si ri pe o jẹ apẹẹrẹ rere ti ìfẹ́ni ati ọgbọn ẹ̀wẹ́—ọkan ti awọn eniyan Jehofa le ṣafarawe daradara.
Ọ̀rọ̀ Ìwúrí fun Ìfẹ́ ati Ìgbàgbọ́
Ni biba Filemoni ati awọn miiran sọrọ, Pọọlu kọkọ funni ni ọ̀rọ̀ ìwúrí (ẹsẹ 1-7) Apọsteli naa ngbọ leralera nipa ìfẹ́ ti Filemoni ni fun Kristi ati gbogbo awọn eniyan mimọ ati nipa igbagbọ rẹ. Eyi sún Pọọlu lati dupẹ lọwọ Jehofa o si mu ayọ ati ìtùnú pupọ wá fun un. Njẹ awa gẹgẹ bi ẹnikan maa ńsọ̀rọ̀ ìwúrí fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa ti wọn jẹ awofiṣapẹẹrẹ ninu ìfẹ́ ati igbagbọ bi? Awa nilati maa ṣe bẹẹ.
Ọ̀rọ̀-ìyànjú ti a gbé kari ìfẹ́ ni a nfẹ nigba gbogbo ninu biba awọn Kristian ẹlẹgbẹ wa lo, gẹgẹbi awọn ọrọ Pọọlu ti fihan. (ẹsẹ 8-14) Lẹhin ìyọsíni ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, apọsteli naa wipe bi o tilẹ jẹ pe oun le paṣẹ “ohun ti o yẹ” fun Filemoni, kàkà bẹ́ẹ̀ oun yàn lati gbà á niyanju. Lati ṣe ki ni? Họ́wù, lati gba ẹrú naa Onesimọsi pada ni ọna oníyọ̀ọ́nú! Pọọlu ìbá ti fẹ lati dá Onesimọsi duro fun iṣẹ-isin wiwulo rẹ, ṣugbọn oun ko ni ṣe eyi laisi ìfọwọ́sí Filemoni.
Awọn ohun ti wọn jẹyọ lọna ti o jọ bi aláìbáradé saba maa njasi àǹfààní, gẹgẹbi Pọọlu ti fihan tẹle e. (Ẹsẹ 15-21) Niti tootọ, sisalọ Onesimọsi ti yọrisi rere. Eeṣe? Nitori pe Filemoni le gbà á pada nisinsinyi gẹgẹbi alailabosi arakunrin Kristian kan, ti o ti muratan, kii ṣe gẹgẹbi ẹrú alábòsí ti ko muratan. Pọọlu sọ fun Filemoni lati fọyaya tẹwọgba Onesimọsi àní gẹgẹ bi a o ti fọyaya tẹwọgba Pọọlu paapaa. Bi Onesimọsi ba ti ṣẹ Filemoni ni ọna eyikeyii, apọsteli naa yoo ṣe ìsanfidípò. Lati mu ki Filemoni tubọ muratan lati gbà, Pọọlu ran an leti pe oun funraarẹ jẹ apọsteli naa ni gbese fun didi Kristian kan. Fun idi yii, Pọọlu ni idaniloju pe Filemoni yoo ṣe ani ju ohun ti a ni ki o ṣe lọ. Iru ifọranlọ ọlọgbọn ẹ̀wẹ́ ati onifẹẹ wo ni eyi jẹ! Niti tootọ, eyi ni ọna ti awa nilati gba ba awọn Kristian ẹlẹgbẹ wa lò.
Pọọlu pari lẹta rẹ pẹlu ìrètí, awọn ìkíni, ati awọn idaniyan rere. (Ẹsẹ 22-25) Oun ṣereti pe nipasẹ adura awọn ẹlomiran nitori oun, a o tú oun silẹ kuro ninu túbú. (Gẹgẹ bi lẹta Pọọlu keji si Timoti ti fihan, awọn adura wọnni ni a dahun.) Ni mimu lẹta rẹ wa si ipari, Pọọlu fi awọn ìkíni ranṣẹ o si sọ idaniyan naa pe ki inurere ailẹtọọsi ti Jesu Kristi wa pẹlu ẹmi ti Filemoni ati awọn olùjọsìn Jehofa ẹlẹgbẹ rẹ fihan jade.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ju Ẹrú Lọ: Nipa ìpadàbọ̀ ẹrú Filemoni, Onesimọsi ti o salọ, Pọọlu wipe: “Bọya idi rẹ̀ ni eyi ti o fi kuro lọdọ rẹ fun igba diẹ, ki iwọ ki o ba le ní in titi lae; kì í ṣe bi ẹrú mọ, ṣugbọn o ju ẹru lọ, arakunrin olufẹ, paapaa fun mi, meloomeloo ju bẹẹ lọ fun ọ, nipa ti ara ati nipa ti Oluwa.” (Filemoni 15, 16) Ni Ilẹ-ọba Roomu, òwò ẹrú ni a kàn-ń-pá lati ọwọ ijọba aláyélúwà, Pọọlu si mọ irú “awọn alaṣẹ onipo gigaju” bẹẹ daju. (Roomu 13:1-7) Oun ko ṣalágbàwí ìdìtẹ̀ ẹrú ṣugbọn o ran irú awọn ẹnikọọkan bẹẹ lọwọ lati jere ominira tẹmi gẹgẹbi Kristian. Ni ibaramuṣọkan pẹlu ìmọ̀ràn rẹ fun awọn ẹru lati wa ni itẹriba fun awọn oluwa wọn, Pọọlu rán Onesimọsi padà si Filemoni. (Kolose 3:22-24; Titu 2:9, 10) Onesimọsi ti ju ẹrú ti aye lọ nisinsinyi. Oun jẹ onigbagbọ ẹlẹgbẹ ààyò-olùfẹ́ ti yoo wà ni itẹriba aláàlà fun Filemoni gẹgẹbi ẹru didara ju, ọkan ti a dari nipasẹ awọn ilana oniwa-bi-Ọlọrun ti o si nfi ìfẹ́ ara hàn.