ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/15 ojú ìwé 31
  • ‘Ẹ Má Ṣe Fi Àìdọ́gba So Pọ̀ Mọ́ra Sábẹ́ Àjàgà’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Má Ṣe Fi Àìdọ́gba So Pọ̀ Mọ́ra Sábẹ́ Àjàgà’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/15 ojú ìwé 31

‘Ẹ Má Ṣe Fi Àìdọ́gba So Pọ̀ Mọ́ra Sábẹ́ Àjàgà’

AKỌ màlúù méjèèjì tí a yà síhìn-ín lókun púpọ̀, tí ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wọn láti fìrọ̀rùn fa àwọn ẹrù wíwúwo. Ṣùgbọ́n, kí a sọ pé a fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rọ́pò ọ̀kan nínú àwọn màlúù náà ń kọ́. Níwọ̀n bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti kéré sí màlúù, tí kò sì lágbára tó o, ó ṣeé ṣe kí ó máa tàdí nípa fífa igi ìdábùú tí ó so wọ́n pọ̀ nínú àjàgà tí kò dọ́gba yìí. Nígbà náà, pẹ̀lú ìdí rere, òfin Ọlọrun fún Israeli sọ pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ fi akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túlẹ̀ pọ̀.”—Deuteronomi 22:10.

Aposteli Paulu kọ ohun kan tí ó fara jọ èyí nípa ẹ̀dá ènìyàn. Ó wí pé: “Ẹ máṣe fi àìdọ́gba sopọ̀mọ́ra sábẹ́ àjàgà pẹlu awọn aláìgbàgbọ́.” (2 Korinti 6:14) Ní pàtàkì, ó yẹ kí a fi èyí sọ́kàn nígbà tí a bá ń yan ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó. Ìgbéyàwó jẹ́ àjọṣepọ̀ wíwà pẹ́ títí, nítorí Jesu Kristi wí pé: “Ohun tí Ọlọrun ti sopọ̀ sábẹ́ àjàgà kí ènìyàn kankan máṣe yà á sọ́tọ̀.” (Matteu 19:6) Ó máa ń yọrí sí ọ̀pọ̀ ẹ̀dùn ọkàn nígbà tí tọkọtaya kan kò bá ṣàjọpín ìgbàgbọ́, ìlànà, àti ètè kan náà. Nítorí náà, bí ó ti wù kí ó mọ, ó lọ́gbọ́n nínú láti tẹ̀ lé ìṣílétí Bibeli náà láti gbéyàwó “kìkì ninu Oluwa.” (1 Korinti 7:39) Kíkó wọnú ìdè ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹnì kan tí kò ṣàjọpín ìgbàgbọ́ ìsìn rẹ yóò gbé ìṣòro tí ó ga ju ti síso akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ papọ̀ dìde.

Ìyàtọ̀ nínú ìgbàgbọ́ ìsìn wulẹ̀ jẹ́ kókó abájọ kan tí ó lè mú kí tọkọtaya kan fi àìdọ́gba so pọ̀ mọ́ra lábẹ́ àjàgà. Yóò dára bí àwọn tọkọtaya lọ́la—àní tí wọ́n tilẹ̀ ní ìgbàgbọ́ kan náà—bá bí ara wọn pé, ‘A ha ní góńgó kan náà bí? Níbo ni a óò gbé? Ta ni yóò bójú tó ìṣúnná owó? Àwa méjèèjì yóò ha máa ṣiṣẹ́ bí? Ṣe a óò bímọ? Inú rere àti ìgbatẹnirò yóò ha ṣàkóso ipò ìbátan wa bí?’

Títí dé àyè kan, ọ̀nà tí a bá gbà jíròrò irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè pinnu yálà àjàgà kan yóò dọ́gba tàbí kò ní dọ́gba. Àmọ́ ṣáá o, kò sí ẹni méjì tí ó bára mú délẹ̀délẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lékè gbogbo rẹ̀, bí àwọn mèjèèjì tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà bá lè para pọ̀ dojú kọ ìṣòro, kí wọ́n sì para pọ̀ yanjú rẹ̀, tí wọ́n bá sì lè máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ ní fàlàlà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n má fi àìdọ́gba so pọ̀ mọ́ra sábẹ́ àjàgà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́