“Láti Ẹnu Àwọn Ìkókó”
NÍGBÀ tí Samueli jẹ́ ọ̀dọ́mọdékùnrin, ó dìrọ̀mọ́ àwọn ìlànà títọ́ láìka ìwà burúkú àwọn ọmọkùnrin Eli Olórí Àlùfáà sí. (1 Samueli 2:22; 3:1) Ní ọjọ́ Elisha, ọmọ Israeli kékeré kan tí a kó ní ìgbèkùn lọ sí Siria fi tìgboyà-tìgboyà jẹ́rìí fún ọ̀gábìnrin rẹ̀. (2 Ọba 5:2-4) Nígbà tí Jesu jẹ́ ọmọ ọdún 12, ó fi àìṣojo bá àwọn olùkọ́ni Israeli sọ̀rọ̀, ní bíbéèrè ìbéèrè àti pípèsè ìdáhùn tí ó mú háà ṣe àwọn tí ń gbọ́ ọ. (Luku 2:46-48) Jálẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn àwọn ọ̀dọ́ olùjọ́sìn Jehofa ti fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sìn ín.
Àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn lónìí ha ń fi irú ẹ̀mí ìṣòtítọ́ kan náà hàn bí? Bẹ́ẹ̀ni, níti tòótọ́! Àwọn ìròyìn láti ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society fihàn pé àwọn ògowẹẹrẹ púpọ̀, púpọ̀ tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ ‘ń jẹ́ ọrẹ àtinúwá’ nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa. (Orin Dafidi 110:3) Àwọn àṣeyọrí rere tí akitiyan wọn ní ń fún gbogbo àwọn Kristian, tèwe-tàgbà, ní ìṣírí ‘[láti] máṣe jẹ́ kí wọ́n juwọ́sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.’—Galatia 6:9, NW.
Àpẹẹrẹ kan tí ó dára ni ti Ayumi, ọmọdébìnrin kékeré ará Japan tí ó di akéde nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà tí ó sì fi ṣe góńgó rẹ̀ láti jẹ́rìí fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó wà ní kíláàsì rẹ̀. A yọ̀ọ̀da fún un láti fi àwọn ìtẹ̀jáde mélòókan sínú àkójọ-ìwé ti kíláàsì náà, ní mímúra ara rẹ̀ sílẹ̀ fún dídáhùn ìbéèrè èyíkéyìí tí àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lè béèrè. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ àti àwọn olùkọ́ rẹ̀ ni wọ́n dojúlùmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde náà. Ní ọdún kẹfà rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, Ayumi ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli 13. Ó ṣèrìbọmi nígbà tí ó wà ní ipele-ẹ̀kọ́ kẹrin, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ sì ṣe ìrìbọmi ní ipele-ẹ̀kọ́ kẹfà. Síwájú síi, màmá àti àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli yìí pẹ̀lú kẹ́kọ̀ọ́ wọ́n sì ṣe ìrìbọmi.
Ìwà Rere Ń Jẹ́rìí
Aposteli Peteru wí pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín awọn orílẹ̀-èdè,” àwọn Kristian ọ̀dọ́ sì mú àṣẹ yìí ní ọ̀kúnkúndùn. (1 Peteru 2:12, NW) Ní ìyọrísí èyí, ìwà rere wọn sábà máa ń fúnni ní ìjẹ́rìí tí ó jíire. Ní Cameroon orílẹ̀-èdè kan ní Africa, ọkùnrin kan wá sí ìpàdé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún ìgbà kejì ó sì ṣẹlẹ̀ pé ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọmọdébìnrin kékeré kan. Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ náà rọ àwùjọ olùgbọ́ láti yẹ ẹsẹ Bibeli kan wò, ọkùnrin náà kíyèsii pé ọ̀dọ́mọbìnrin kékeré náà tètè rí ẹsẹ náà nínú Bibeli tirẹ̀ ó sì ń fi ojú bá kíkà náà lọ pẹ̀lú ìfarabalẹ̀. Ìwà rẹ̀ wú u lórí tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi tọ olùbánisọ̀rọ̀ náà lọ lẹ́yìn tí ìpàdé náà parí, tí ó sì wí pé: “Ọ̀dọ́mọbìnrin kékeré yìí ti mú kí n fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú yín.”
Ilé-ẹ̀kọ́ kan wà ní South Africa níbi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 25 ti jẹ́ ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ìwà rere wọn ti yọrí sí ìfùsì rere fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Olùkọ́ kan sọ ní bòókẹ́lẹ́ fún òbí kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí pé òun kò lóye ọ̀nà tí àwọn Ẹlẹ́rìí gbà ń tọ́ àwọn ọmọ wọn dáradára bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì níwọ̀n bí ṣọ́ọ̀ṣì tòun kò ti tóótun láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́. Olùkọ́ titun kan wá láti ṣèrànwọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ náà kò sì pẹ́ tí ó fi ṣàkíyèsí ìwà rere àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí. Ó bi ọ̀kan lára àwọn ọmọdékùnrin tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí náà pé kí ni òun níláti ṣe kí òun baà lè di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ọmọdékùnrin náà ṣàlàyé pé ó níláti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó sì ṣètò fún àwọn òbí rẹ̀ láti padà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ náà.
Ní Costa Rica, Rigoberto gbọ́ ohùn òtítọ́ nígbà tí àwọn ọmọ kíláàsì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ méjì ń lo Bibeli láti dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀ nípa Mẹ́talọ́kan, ọkàn, àti hẹ́ẹ̀lì oníná. Ohun tí wọ́n sọ ní ipa tí ó dára lórí rẹ̀ kì í ṣe kìkì nítorí agbára-ìṣe wọn láti lo Ìwé Mímọ́ ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ nítorí pé ìwà ọmọlúwàbí wọn yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ó ti rí nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm. Láìka àtakò ìdílé sí, Rigoberto ń tẹ̀síwájú dáradára nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀.
Ní Spania àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa méjì—tí ọ̀kan lára wọn jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án—bẹ ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Onofre wò. Bí Ẹlẹ́rìí tí ó dàgbà ti ń sọ èyí tí ó pọ̀ jù nínú ọ̀rọ̀ náà, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí náà ń fojú bá kíkà Ìwé Mímọ́ náà lọ ó sì yan àwọn ẹsẹ̀ Bibeli láti orí. Orí Onofre wú. Ó pinnu pé òun fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní ibi kan náà gan-an tí ọmọdékùnrin yẹn ti kọ́ láti lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Nítorí èyí, ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ Sunday tí ó tẹ̀lé e, ó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó níláti dúró síta títí di ọjọ́kanrí, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà dé láti ṣe ìpàdé wọn. Láti ìgbà náà lọ, ó tẹ̀síwájú dáradára ó sì ti fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn láìpẹ́ yìí nípa ìrìbọmi nínú omi.
Àwọn Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Tí Wọ́n Jáfáfá
Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa ń lo tọmọdé-tàgbà láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́kàntútù. Èyí ni a tún rí síwájú síi nínú ìrírí kan láti Hungary. Níbẹ̀, nọ́ọ̀sì kan ní ilé-ìwòsàn ṣàkíyèsí pé nígbàkigbà tí àwọn àlejò bá wá láti rí aláìsàn kan tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, wọn yóò gbé àwọn ohun kíkà àti oúnjẹ wá fún un. Bí a ti ru ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ sókè, ó ṣe kàyéfì nípa irú àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ tí ọmọdébìnrin kékeré yìí lè máa kà ó sì rí i pé Bibeli ni. Nọ́ọ̀sì náà bá a sọ̀rọ̀ ó sì sọ lẹ́yìn náà pé: “Kíákíá, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà tí ọmọdébìnrin náà fi ilé-ìwòsàn sílẹ̀, ó késí nọ́ọ̀sì náà láti wá sí àpéjọpọ̀ kan, ṣùgbọ́n nọ́ọ̀sì náà kò tẹ́wọ́gba ìkésíni náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, lẹ́yìn èyí, ó gbà láti lọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Èdè Mímọ́gaara.” Kò pẹ́ kò jìnnà, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó ṣe ìrìbọmi ní ọdún kan lẹ́yìn náà—gbogbo èyí jẹ́ nítorí pé ọmọdébìnrin kékeré kan lo àkókò rẹ̀ ní ilé-ìwòsàn láti ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
Ana Ruth, ní El Salvador, ń lo ọdún rẹ kejì ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Ó ti di àṣà rẹ̀ láti máa fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli sílẹ̀ sórí tábìlì ìkọ̀wé rẹ̀ kí àwọn mìíràn baà lè kà á bí wọ́n bá fẹ́. Ó ṣàkíyèsí pé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ń pòórá tí ó sì tún ń padà rí i lẹ́yìn àkókò díẹ̀, Ana Ruth rí i pé ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ òun kan, Evelyn, ni ó ń kà á. Nígbà tí ó ṣe, Evelyn tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣe ìrìbọmi, ó sì ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ déédéé. Ana Ruth ṣì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé.
Ní Panama arábìnrin kan bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àtakò sí òtítọ́ débi tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fi fẹ́rẹ̀ẹ́ dúró. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwà ọkọ náà rọ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn náà, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin, tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, sọ fún un pé kí ó ṣe agogo ìdágìrì kan sínú ilé òun nítorí àwọn gbéwiri. Bí ó ti ń ṣe agogo ìdágìrì náà lọ́wọ́, ọmọbìnrin ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án wá sílé, ojú rẹ̀ sì kọ́rẹ́ lọ́wọ́. Ó bi í pé kí ló ṣẹlẹ̀, ó sì sọ pé òun àti ẹ̀gbọ́n òun obìnrin ti lọ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan ṣùgbọ́n ẹni náà kò sí nílé, nítorí náà kò tí ì ṣeé ṣe fún òun láti ṣe ohunkóhun fún Jehofa ní ọjọ́ yẹn. Àbúrò bàbá rẹ̀ sọ fún un pé: “Èéṣe tí o kò fi wàásù fún mi? Nípa bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò lè ṣe ohun kan fún Jehofa.” Ọmọbìnrin ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi tayọ̀tayọ̀ sáré lọ gbé Bibeli rẹ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ kan sì bẹ̀rẹ̀.
Ìyá rẹ̀ (aya ẹ̀gbọ́n ọkùnrin náà) ń tẹ́tísílẹ̀. Ó rò pé àwàdà lásán ni gbogbo rẹ̀, ṣùgbọ́n ní gbogbo ìgbà tí ọkùnrin náà bá lọ sí ilé wọn, ó máa ń sọ pé kí ọmọbìnrin ẹ̀gbọ́n òun kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú òun. Nígbà tí màmá náà rí i pé àbúrò ọkọ òun kò fi ọ̀ràn náà ṣeré tí ó sì ní àwọn ìbéèrè tí ó nira, ó pinnu láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà fúnraarẹ̀ lójú ọmọbìnrin náà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ ní ìgbà méjì lọ́sẹ̀ ó sì tẹ̀síwájú lọ́nà yíyára kánkán. Níkẹyìn, ó bá a dé orí ìyàsímímọ́, òun àti aya rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ kan náà—ọpẹ́lọpẹ́ ìrànlọ́wọ́ ìwà àtàtà ọmọbìnrin ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
Ìgboyà Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Fúnni Ní Ìjẹ́rìí
Bibeli sọ pé: “Jẹ́ onígboyà kí o sì mú àyà le. Bẹ́ẹ̀ni, ní ìrètí nínú Jehofa.” (Orin Dafidi 27:14, NW) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé fi sílò fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun, tọmọdé-tàgbà ni ó sì ti fi wọ́n sílò ní èṣí. Ní Australia, nígbà tí ọmọdébìnrin kan ẹni ọdún márùn-ún bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ titun, màmá rẹ̀ lọ bá olùkọ́ láti ṣàlàyé èrò-ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Olùkọ́ náà wí pé: “Mo ti mọ ohun tí ẹ gbàgbọ́. Ọmọbìnrin rẹ ti ṣàlàyé rẹ̀ fún mi.” Ojú kò ti ọ̀dọ́mọbìnrin yìí láti bá olùkọ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ fúnra rẹ̀ láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ̀.
Andrea ọmọ ọdún márùn-ún ní Romania lo ìgboyà pẹ̀lú. Nígbà tí màmá rẹ̀ fi ṣọ́ọ̀ṣì Orthodox sílẹ̀ láti di Ẹlẹ́rìí, àwọn aládùúgbò rẹ̀ kọ̀ láti tẹ́tísilẹ̀. Ní ọjọ́ kan ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, Andrea gbọ́ tí alábòójútó iṣẹ́-ìsìn tẹnumọ́ àìní náà láti wàásù fún àwọn aládùúgbò ẹni. Ó ronú gidigidi nípa èyí, nígbà tí ó sì padà délé ó sọ fún màmá rẹ̀ pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti lọ sí ibi iṣẹ́, èmi yóò gbéra nílẹ̀, ń óò sì kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sí inú àpò mi gan-an gẹ́gẹ́ bí ìṣe yín, Mọ́mì, èmi yóò sì gbàdúrà sí Jehofa láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè bá àwọn aládùúgbò sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́.”
Ní ọjọ́ kejì Andrea mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Lẹ́yìn náà, ní lílo ìgboyà, ó tẹ aago ilé aládùúgbò wọn kan. Nígbà tí aládùúgbò wá sí ẹnu ìlẹ̀kùn, ọ̀dọ́mọbìnrin kékeré náà wí pé: “Mo mọ̀ pé láti ìgbà tí màmá mi ti di Ẹlẹ́rìí, ẹ kò fẹ́ràn rẹ̀. Ó ti gbìyànjú láti bá yín sọ̀rọ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ láti tẹ́tísí i. Èyí ń bí i nínú, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ yín.” Lẹ́yìn náà, Andrea ń bá a nìṣó láti fúnni ní ìjẹ́rìí tí ó jíire. Ní ọjọ́ kan, ó fi ìwé-ńlá mẹ́fà, ìwé-ìròyìn mẹ́fà, ìwé-pẹlẹbẹ mẹ́rin, àti ìwé àṣàrò kúkúrú mẹ́rin síta. Láti ìgbà náà, ó ti ń ṣe déédéé nínú iṣẹ́-ìsìn pápá.
Ní Rwanda àwọn arákùnrin wa níláti fi ìgboyà ńláǹlà hàn nítorí ìjà tí ó wáyé níbẹ̀. Ní ìgbà kan a fi ìdílé Ẹlẹ́rìí kan sí inú yàrá kan níbi tí àwọn ṣọ́jà ti ṣetán láti pa wọ́n. Ìdílé náà béèrè ìyọ̀ọ̀da láti kọ́kọ́ gbàdúrà. Wọ́n yọ̀ọ̀da fún wọn, gbogbo wọn ni wọ́n gbàdúrà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, àyàfi ọmọbìnrin náà, Deborah. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ṣe fi tóni létí, Deborah gbàdúrà sókè pé: “Jehofa, èmi àti Bàbá ti fi ìwé ìròyìn márùn-ún sóde lọ́sẹ̀ yìí. Báwo ni a óò ṣe padà tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ láti kọ́ wọn ní òtítọ́ kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìyè? Jù bẹ́ẹ̀ lọ, báwo ni èmi yóò ṣe di akéde báyìí? Mo fẹ́ láti ṣe ìrìbọmi kí n baà lè sìn ọ́.” Ní gbígbọ́ èyí, ṣọ́jà kan wí pé: “Nítorí ọmọdébìnrin kékeré yìí a kò lè pa yín.” Deborah fèsì pé: “Ẹ ṣeun.” A dá ìdílé náà sí.
Nígbà tí Jesu wọ Jerusalemu pẹ̀lú ayọ̀ ìṣẹ́gun ní gẹ́ńgẹ́rẹ́ òpin ìgbésí-ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, ogunlọ́gọ̀ rẹpẹtẹ tí ń hó yèè kí i. Tọmọdé-tàgbà ni ó parapọ̀ wà nínú ogunlọ́gọ̀ náà. Bí àkọsílẹ̀ náà ṣe sọ, àwọn ọmọdékùnrin “ń ké jáde ní tẹmpili tí wọ́n sì ń wí pé: ‘Gba Ọmọkùnrin Dafidi là, ni awa bẹ̀bẹ̀!’” Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé fi ẹ̀hónú hàn sí èyí, Jesu dá wọn lóhùn padà pé: “Ṣé ẹ̀yin kò tí ì ka èyí rí pé, ‘Lati ẹnu awọn ìkókó ati ọmọ-ẹnu-ọmú ni iwọ ti mú ìyìn jáde’?”—Matteu 21:15, 16, NW.
Ko ha múni lọ́kàn yọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ Jesu jásí òtítọ́ lónìí pàápàá bí? “Láti ẹnu awọn ìkókó ati ọmọ-ẹnu-ọmú”—a sì tún lè fi, àwọn ọ̀dọ́langba àti ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin kún un pẹ̀lú—ni Jehofa ti mú ìyìn jáde. Níti tòótọ́, nígbà tí ó bá di ti yíyin Jehofa, kò sí ẹni tí ó kéré jù.—Joeli 2:28, 29.