-
Fi Ara Rẹ fún Ìwé KíkàIlé-Ìṣọ́nà—1996 | May 15
-
-
ìṣètò opó ṣíṣú, nípasẹ̀ Boasi, ó bí ọmọkùnrin kan “fún Naomi.” Rutu di ìyá ńlá Dafidi, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó di ìyá ńlá Jesu Kristi. Ó tipa bẹ́ẹ̀ gba “ẹ̀san iṣẹ́ rẹ̀.” Ní àfikún sí i, àwọn tí ń ka àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ náà kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n: Jẹ́ adúróṣinṣin sí Jehofa, a óò sì bù kún ọ jìngbìnnì.—Rutu 2:12; 4:17-22; Owe 10:22; Matteu 1:1, 5, 6.
16. Ìdánwò wo ni àwọn Heberu mẹ́ta nírìírí rẹ̀, báwo sì ni àkọsílẹ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
16 Àkọsílẹ̀ nípa àwọn Heberu tí ń jẹ́ Ṣadraki, Meṣaki, àti Abednego lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun nínú ipò tí ń dánniwò. Fojú inú wo ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí a ṣe ń ka Danieli orí 3 sókè. Ère gàgàrà tí a fi wúrà mọ rí gogoro lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura, níbi tí àwọn lọ́gàá-lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba Babiloni pé jọ sí. Nígbà tí ìró ohun èèlò orin dún, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn ère tí Ọba Nebukadnessari yá. Ìyẹn ni pé, gbogbo wọn ṣe bẹ́ẹ̀ àyàfi Ṣadraki, Meṣaki, àti Abednego. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdúróṣinṣin, wọ́n sọ fún ọba náà pé, àwọn kì yóò sin àwọn ọlọrun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn kì yóò jọ́sìn ère oníwúrà náà. A ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Heberu wọ̀nyí sínú iná ìléru tí ń jó fòfò. Ṣùgbọ́n kí ni ó ṣẹlẹ̀? Nígbà tí ó wo inú rẹ̀, ọbá rí ọkùnrin abarapá mẹ́rin, ọ̀kan nínú wọn “dà bí . . . Ọmọ Ọlọrun.” (Danieli 3:25) A mú àwọn Heberu mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jáde kúrò nínú iná ìléru, Nebukadnessari sì fi ìyìn fún Ọlọrun wọn. Fífojú inú wo àkọsílẹ̀ yìí ti mú èrè wá. Ẹ sì wo irú ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tí ó fúnni nípa ìṣòtítọ́ sí Jehofa lábẹ́ ìdánwò!
Àǹfààní Láti Inú Kíka Bibeli Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé
17. Ní ṣókí, sọ àwọn ohun ṣíṣàǹfààní tí ìdílé rẹ lè kọ́ nípasẹ̀ kíka Bibeli pa pọ̀?
17 Ìdílé rẹ lè gbádùn ọ̀pọ̀ àǹfààní bí ẹ bá ń lo àkókò láti ka Bibeli pa pọ̀ déédéé. Bí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ ní Genesisi, ẹ lè fojú inú wo ìṣẹ̀dá, kí ẹ sì rí Paradise ilé ènìyàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ẹ lè ṣàjọpín ìrírí àwọn bàbá ńlá olùṣòtítọ́ àti àwọn ìdílé wọn, kí ẹ sì tẹ̀ lé àwọn ọmọ Israeli bí wọ́n ṣe ń la orí ìyàngbẹ ilẹ̀ Òkun Pupa kọjá. Ẹ lè rí ọ̀dọ́ olùṣọ́ àgùtàn náà, Dafidi, bí ó ṣe ṣẹ́gun òmìrán ará Filistini náà, Goliati. Ìdílé rẹ lè ṣàkíyèsí kíkọ́ tẹ́ḿpìlì Jehofa ní Jerusalemu, ẹ lè rí ìsọdahoro rẹ̀ láti ọwọ́ agbo àwọn ará Babiloni, ẹ sì lè rí ṣíṣe àtúnkọ́ rẹ̀ lábẹ́ Gómìnà Serubbabeli. Pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀ olùṣọ́ àgùntàn nítòsí Betlehemu, ẹ lè gbọ́ ìkéde tí áńgẹ́lì náà ṣe nígbà ìbí Jesu. Ẹ lè rí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa batisí rẹ̀ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ẹ sì lè rí i tí ó fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn lélẹ̀ bí ìràpadà, ẹ sì lè ṣàjọpín ìdùnnú àjíǹde rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ẹ lè rin ìrìn àjò pẹ̀lú aposteli Paulu, kí ẹ sì ṣàkíyèsí ìdásílẹ̀ àwọn ìjọ bí ìsìn Kristian ṣe ń tàn kálẹ̀. Lẹ́yìn náà, nínú ìwé Ìṣípayá, ìdílé rẹ lè gbádùn ìran kíkọyọyọ tí aposteli Johannu rí nípa ọjọ́ ọ̀la, títí kan Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi.
18, 19. Àwọn àbá wo ni a fúnni ní ti kíka Bibeli gẹ́gẹ́ bí ìdílé?
18 Bí ẹ bá ń ka Bibeli sókè gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ẹ kà á yékéyéké àti tìtaratìtara. Nígbà tí ẹ bá ń ka àwọn apá kan nínú Ìwé Mímọ́, mẹ́ḿbà ìdílé kan—tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ bàbá—lè ka ọ̀rọ̀ àkópọ̀ ìtàn náà. Àwọn mìíràn lè kó ipa àwọn ẹ̀dá ìtàn inú Bibeli, ní kíka àwọn apá tìrẹ pẹ̀lú ìmọ̀lára tí ó bá a mu.
19 Bí ẹ ṣe ń ṣàjọpín nínú Bibeli kíkà gẹ́gẹ́ bí ìdílé, agbára ìkàwé yín lè sunwọ̀n sí i. Ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀ yín nípa Ọlọrun pọ̀ sí i, èyí sì ní láti túbọ̀ fà yín sún mọ́ ọn. Asafu kọrin pé: “Ó dára fún mí láti sún mọ́ Ọlọrun: èmi ti gbẹ́kẹ̀ mi lé Oluwa Ọlọrun, kí èmi kí ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ gbogbo.” (Orin Dafidi 73:28) Èyí yóò ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti dà bíi Mose, ẹni tí “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni naa tí a kò lè rí,” ìyẹn ni, Jehofa Ọlọrun.—Heberu 11:27.
Ìwé Kíkà àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristian
20, 21. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú agbára ìkàwé wa?
20 Ìfẹ́ ọkàn wa láti jọ́sìn “Ẹni naa tí a kò lè rí” yẹ kí ó sún wa láti ṣiṣẹ́ lórí jíjẹ́ òǹkàwé tí ó já fáfá. Agbára ìkàwé lọ́nà tí ó já gaara ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́rìí láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Dájúdájú, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà lọ, èyí tí Jesu pa láṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tí ó wí pé: “Ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.” (Matteu 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Ìjẹ́rìí ni olórí iṣẹ́ àwọn ènìyàn Jehofa, agbára ìkàwé sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí rẹ̀.
21 Ó ń béèrè ìsapá láti lè jẹ́ òǹkàwé tí ó já fáfá àti olùkọ́ni tí ó dáńgájíá nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. (Efesu 6:17) Nítorí náà, ‘sa gbogbo ipá rẹ lati fi ara rẹ hàn fún Ọlọrun ní ẹni tí a fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.’ (2 Timoteu 2:15) Mú ìmọ̀ rẹ nípa òtítọ́ Ìwé Mímọ́ àti agbára ìkàwé rẹ pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa, nípa fífi ara rẹ fún ìwé kíkà.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Báwo ni ayọ̀ ṣe sinmi lórí kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun?
◻ Èé ṣe ti o fi ní láti ṣàṣàrò lórí ohun tí o kà nínú Bibeli?
◻ Èé ṣe tí a fi ní láti lo síso kókó pọ̀ àti fífi ojú inú wo nǹkan nígbà ti a bá ń ka Ìwé Mímọ́?
◻ Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ láti inú kíka Bibeli?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ka Bibeli sókè gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ìsopọ̀ wo sì ní ìwé kíkà ní pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian?
-
-
Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Kí O Sì Máa Ṣiṣẹ́ Sìn ín ní Òtítọ́Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | May 15
-
-
Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Kí O Sì Máa Ṣiṣẹ́ Sìn ín ní Òtítọ́
“Oluwa, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ; èmi óò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.”—ORIN DAFIDI 86:11.
1. Ní ti gidi, kí ni ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn yìí sọ nípa òtítọ́?
JEHOFA ń rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ jáde. (Orin Dafidi 43:3) Ó tún ń fún wa ní agbára láti ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn yìí—July 1879—wí pé: “Òtítọ́ dà bí òdòdó kékeré nínú aginjù ìgbésí ayé, tí àwọn èpò èké títutù yọ̀yọ̀ yí ká, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ fún pa. Bí ọwọ́ rẹ yóò bá tẹ̀ ẹ́, o gbọ́dọ̀ wà lójúfò. Bí ìwọ yóò bá rí ẹwà rẹ̀, o gbọ́dọ̀ rọ́ àwọn èpò èké àti igi ẹ̀gún ẹ̀tanú tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Bí ìwọ bá fẹ́ rí i já, o ní láti lóṣòó kí o tó lè rí i já. Má ṣe jẹ́ kí òdòdó kan nípa òtítọ́ tẹ́ ọ lọ́rùn. Bí ó bá jẹ́ pé ọ̀kan ti tó ni, kì bá tún sí òmíràn mọ́. Túbọ̀ máa kó o jọ, túbọ̀ máa wá púpọ̀ sí i.” Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye, kí a sì rìn nínú òtítọ́ rẹ̀.—Orin Dafidi 86:11.
-