ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 5/1 ojú ìwé 4-7
  • Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Ayé Aláìpé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Ayé Aláìpé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí A Ṣe Kọ́kọ́ Pàdánù Ìwà Títọ́
  • Ìpìlẹ̀ Ìwà Títọ́
  • Jíjẹ́ Ẹni Tí Ó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé Lábẹ́ Ìdánwò
  • Ìwà Títọ́ Jóòbù
  • Ìwà Títọ́ àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
  • Ìwà Títọ́—Àwọn Èrè Rẹ̀
  • Máa Hùwà Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ṣé Wàá Pa Ìwà Títọ́ Rẹ Mọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Pa Ìwà Títọ́ Rẹ Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Máa Rìn Ní Ọ̀nà Ìwà Títọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 5/1 ojú ìwé 4-7

Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Ayé Aláìpé

“RERE tí mo dàníyàn ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò dàníyàn ni èmi fi ń ṣèwàhù.” Èyí ha jẹ́ òtítọ́ nínú ọ̀ràn tìrẹ bí? Yóò fún ọ níṣìírí láti mọ̀ pé, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ìṣòro kan náà; síbẹ̀, ó jẹ́ ọkùnrin oníwàtítọ́ Kristẹni títayọ lọ́lá. Èyí kò ha takora bí? Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Kristẹni ní Róòmù, Pọ́ọ̀lù ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ìṣòro náà, pé: “Wàyí o, bí ó bá jẹ́ pé ohun tí èmi kò dàníyàn ni ohun tí èmi ń ṣe, ẹni tí ń ṣe é kì í ṣe emi mọ́, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi.” Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni ó ń tọ́ka sí, báwo ni ó sì ṣe ṣẹ́pá rẹ̀, tí ó fi ṣeé ṣe fún un láti jẹ́ ọkùnrin oníwàtítọ́?—Róòmù 7:19, 20.

Ṣáájú, nínú lẹ́tà rẹ̀, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Ẹ̀ṣẹ̀ tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ inú ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.’ Ádámù ni “ènìyàn kan” náà. (Róòmù 5:12, 14) Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù—ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù—ni okùnfà àìpé àjogúnbá ti ìran ènìyàn, òun sì ni ìdí pàtàkì tí pípa ìwà títọ́ mọ́ fi jẹ́ ìpèníjà gidi.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí kò tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye Pọ́ọ̀lù nípa “ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́,” gẹ́gẹ́ bí a ti máa ń pè é, nítorí tí àwùjọ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ti kọ àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá sílẹ̀, wọ́n sì ti tẹ́wọ́ gba àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n. Àlàyé òde òní kan lórí Róòmù 5:12-14, sọ ọ́ lọ́nà yí: “Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ti pa gbogbo ẹsẹ náà tì.” Síbẹ̀, ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, àwọn àlàyé lórí Bíbélì ṣàlàyé lọ́nà tí ó bára mu délẹ̀ pé, “nígbà tí Ádámù ṣẹ̀ . . . ẹ̀ṣẹ̀ náà àti ohun tí ó yọrí sí ṣàkóbá fún gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀.”a

Bí A Ṣe Kọ́kọ́ Pàdánù Ìwà Títọ́

Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ lónìí ti sẹ́ wíwà Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe pa Sátánì, Èṣù, tì gẹ́gẹ́ bí ẹni ìtàn àròsọ lásán.b Ṣùgbọ́n, aláṣẹ títayọ lọ́lá náà, Jésù Kristi, sọ fún wa pé, ẹni yìí ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́,’ ní ọ̀rọ̀ míràn, kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. (Jòhánù 8:44) Sátánì ni ó sì sún Ádámù àti ìyàwó rẹ̀, Éfà, ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, tí wọ́n sì ba ìwà títọ́ wọn jẹ́ lábẹ́ ìdánwò.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-19.

Nítorí tí gbogbo wá ṣẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ádámù, gbogbo wa ni a jogún ìtẹ̀sí àtidẹ́ṣẹ̀. Sólómọ́nì, ọlọgbọ́n ọkùnrin náà, sọ pé: “Kò sí olóòótọ́ ènìyàn lórí ilẹ̀, tí ń ṣe rere, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀.” (Oníwàásù 7:20) Síbẹ̀, ènìyàn èyíkéyìí lè ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Báwo ni èyí ṣe ṣeé ṣe? Nítorí, kò dìgbà tí ènìyàn di ẹni pípé kí ó tó lè pa ìwà títọ́ mọ́.

Ìpìlẹ̀ Ìwà Títọ́

Ọba Dáfídì ti Ísírẹ́lì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe, títí kan ìwà panṣágà rẹ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà, tí ó ní àkọsílẹ̀. (Sámúẹ́lì Kejì 11:1-27) Ọ̀pọ̀ àṣìṣe Dáfídì tẹnu mọ́ ọn pé, òun kì í ṣe ẹni pípé rárá. Ṣùgbọ́n, kí ni Jèhófà rí lára ọkùnrin náà? Nígbà tí ó ń bá Sólómọ́nì, ọmọkùnrin Dáfídì, sọ̀rọ̀, Jèhófà sọ pé: “Rìn níwájú mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí Dáfídì bàbá rẹ ti rìn, pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn àyà àti pẹ̀lú ìdúróṣánṣán.” (Àwọn Ọba Kìíní 9:4, NW) Láìka ọ̀pọ̀ àṣìṣe rẹ̀ sí, Jèhófà ka jíjẹ́ tí Dáfídì jẹ́ ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé sí. Èé ṣe?

Dáfídì dáhùn ìbéèrè náà nígbà tí ó sọ fún Sólómọ́nì pé: “Olúwa a máa wá gbogbo àyà, ó sì mọ gbogbo ète ìrònú.” (Kíróníkà Kíní 28:9) Dáfídì ṣe àṣìṣe, ṣùgbọ́n, ó nírẹ̀lẹ̀, ó sì fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́. Ó tẹ́wọ́ gba ìbáwí àti àtúnṣe léraléra—ó tilẹ̀ béèrè fún un pàápàá. Ó béèrè pé: “Wádìí mi wò, Jèhófà, kí o sì dán mi wò; yọ́ kíndìnrín mi àti ọkàn àyà mi mọ́.” (Orin Dáfídì 26:2, NW) A sì yọ́ Dáfídì mọ́ ní tòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, ìkálọ́wọ́kò tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà mú wá wà títí di òpin ìgbésí ayé rẹ̀. Síbẹ̀, Dáfídì kò gbìyànjú rí láti wáwìíjàre ìwà àìtọ́ rẹ̀. (Sámúẹ́lì Kejì 12:1-12) Ní pàtàkì jù, kò fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀ rí. Fún ìdí yìí, àti nítorí ojúlówó ìkẹ́dùn àti ìrònúpìwàdà àtọkànwá Dáfídì, Jèhófà ṣe tán láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í, kí ó sì tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin oníwàtítọ́.—Tún wo Orin Dáfídì 51.

Jíjẹ́ Ẹni Tí Ó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé Lábẹ́ Ìdánwò

Sátánì Èṣù dán Jésù wò nínú ìsapá láti jẹ́ kí ó ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́. Òun ní láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ lójú ìnira àti ìjìyà, ní ìyàtọ̀ pátápátá sí Ádámù, tí a dán ìgbọràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé wò kìkì nípa ìtọ́ni tí a fún un láti ṣègbọràn sí òfin àtọ̀runwá. Ní àfikún sí i, Jésù ní ìdààmú ọkàn ní mímọ̀ pé, ìràpadà ìdílé ẹ̀dá ènìyàn sinmi lórí ìwà títọ́ òun.—Hébérù 5:8, 9.

Sátánì, tí ó pinnu láti ba ìwà títọ́ Jésù jẹ́, tọ̀ ọ́ lọ nígbà tí ó rẹ Jésù gan-an—lẹ́yìn tí ó ti lo 40 ọjọ́ ní ṣíṣàṣàrò àti gbígbààwẹ̀ nínú aginjù. Ó dán Jésù wò lẹ́ẹ̀mẹta—láti sọ òkúta di búrẹ́dì; láti bẹ́ láti orí odi orí òrùlé tẹ́ńpìlì, ní ríretí pé, àwọn ańgẹ́lì yóò dá sí i, wọn yóò sì dáàbò bò ó, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ fúnni ní àmì oníṣẹ́ ìyanu láti fẹ̀rí jíjẹ́ Mèsáyà rẹ̀ hàn; àti láti tẹ́wọ́ gba àkóso gbogbo ìjọba ayé yìí ní pàṣípààrọ̀ “ìṣe ìjọsìn kan” lásán fún Sátánì. Ṣùgbọ́n, Jésù kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdánwò náà, ní pípa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́.—Mátíù 4:1-11; Lúùkù 4:1-13.

Ìwà Títọ́ Jóòbù

Ìdúró Jóòbù, ní pípa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ lábẹ́ ìdánwò, jẹ́ ohun tí a mọ̀ dáradára. Lọ́nà tí ń ṣeni ní kàyéfì, Jóòbù kò lóye ìdí tí ìjábá fi dé bá a. Kò mọ̀ pé, Sátánì ti ní èrò òdì sí i, ní fífẹ̀sùn kàn pé, Jóòbù ń ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run fún ète ìmọtara-ẹni-nìkan, ó sì sọ pé, láti baà lè dáàbò bo ẹran ara rẹ̀, Jóòbù yóò mọ̀ọ́mọ̀ ba ìwà títọ́ rẹ̀ jẹ́. Ọlọ́run yọ̀ǹda kí Jóòbù jìyà ìrírí pípọ́nnilójú gidigidi, láti lè fi hàn pé Sátánì kò tọ̀nà.—Jóòbù 1:6-12; 2:1-8.

Àwọn ọ̀rẹ́ èké mẹ́ta wọnú ọ̀ràn náà. Wọ́n dìídì yí ọ̀pá ìdiwọ̀n àti ète Ọlọ́run po. Àní ìyàwó Jóòbù pàápàá, tí òun pẹ̀lú kò lóye àríyànjiyàn náà, kọ̀ láti fún ọkọ rẹ̀ níṣìírí, nígbà tí ó wà nínú àìní ńlá. (Jóòbù 2:9-13) Ṣùgbọ́n, Jóòbù dúró ṣinṣin. “Títí èmi óò fi kú, èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi. Òdodo mi ni èmi dì mú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́; àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi.”—Jóòbù 27:5, 6.

Àpẹẹrẹ Jóòbù gíga lọ́lá, àti ìwà títọ́ ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ mìíràn, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Bíbélì, fi hàn pé Sátánì jẹ́ elékèé.

Ìwà Títọ́ àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

Ìwà títọ́ ha jẹ́ ànímọ́ kan tí Jèhófà kà sí, kìkì fún ìtẹ́lọ́run ara rẹ̀ bí? Rárá o. Ìwà títọ́ ní ìjẹ́pàtàkì gíga fún àwa ẹ̀dá ènìyàn. Fún ire wa ni Jésù ṣe ṣí wa létí láti ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn àyà wa àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú wa.’ Ní tòótọ́, èyí ni “àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní,” ó sì ń béèrè fún ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé oníwàtítọ́ láti pa á mọ́. (Mátíù 22:36-38) Kí ni ó ní nínú, kí sì ni àwọn èrè rẹ̀?

Kì í ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ ọkùnrin oníwàtítọ́ kan nìkan ṣoṣo ni ó lè gbẹ́kẹ̀ lé e, ṣùgbọ́n, ní pàtàkì jù, Ọlọ́run pẹ̀lú lè gbẹ́kẹ̀ lé e. A ń rí ìmọ́gaara ọkàn àyà rẹ̀ nínú ìwà rẹ̀; kò sí àrékérekè kankan lọ́wọ́ rẹ̀. Kì í ṣe békebèke tàbí ìbàjẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ lọ́nà yí pé: “Àwa ti kọ àwọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tini lójú sílẹ̀ ní àkọ̀tán, a kò rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣe àbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ fífi òtítọ́ hàn kedere a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà olúkúlùkù ẹ̀rí ọkàn ẹ̀dá ènìyàn níwájú Ọlọ́run.”—Kọ́ríńtì Kejì 4:2.

Kíyè sí i pé, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àwọn ìṣarasíhùwà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Báwo ni òjíṣẹ́ Kristẹni kan ṣe lè ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn bí ọwọ́ rẹ̀ kò bá mọ́, bí òun kì í bá ṣe oníwàtítọ́ ènìyàn? Ọ̀ràn olórí ètò ìsìn ilẹ̀ Ireland kan, tí ó kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ láìpẹ́, mú kókó náà yéni dáradára. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Independent ti sọ, ó jẹ́wọ́ pé, òun “yọ̀ǹda fún àlùfáà abọ́mọdélòpọ̀ kan láti máa ṣiṣẹ́ nìṣó pẹ̀lú àwọn ọmọdé, tipẹ́tipẹ́ lẹ́yìn tí ìwà burúkú rẹ̀ ti di mímọ̀.” Ìròyìn náà fi yéni pé, ìwà ìṣekúṣe náà bá a lọ fún ọdún 24. A fi àlùfáà náà sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin, ṣùgbọ́n, ronú ìyà tí ó fi jẹ àwọn ọmọ tí ó bá ṣèṣekúṣe láàárín àwọn ọdún wọ̀nyẹn, nítorí pé, ọ̀gá rẹ̀ kò ní ìwà títọ́ láti gbé ìgbésẹ̀!

Ìwà Títọ́—Àwọn Èrè Rẹ̀

Àpọ́sítélì Jòhánù jẹ́ ọkùnrin onígboyà. Nítorí ìtara gbígbóná wọn, Jésù pe òun àti arákùnrin rẹ̀, Jákọ́bù, ní, “Ọmọkùnrin Ààrá.” (Máàkù 3:17) Jòhánù, ọkùnrin oníwàtítọ́ títayọ lọ́lá, àti Pétérù, ṣàlàyé fún àwọn alákòóso Júù pé, òun ‘kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀’ nípa àwọn ohun tí òun ti rí tí òun sì ti gbọ́, nígba tí ó wà pẹ̀lú Jésù. Jòhánù tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì tí ó sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 4:19, 20; 5:27-32.

Ó jọ pé, nígbà tí Jòhánù ti lé ní ẹni 90 ọdún, a fi sí ìgbèkùn ní Erékùṣù Kékeré Pátímọ́sì, “nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 1:9) Bí ó ti dàgbà tó, ó lè ti rò pé, iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun ti dópin. Ṣùgbọ́n, kìkì ọkùnrin oníwàtítọ́ bíi tirẹ̀ ni a lè fi iṣẹ́ ṣíṣàkọsílẹ̀ ìran amúnilọ́kànyọ̀ inú Ìṣípayá síkàáwọ́ rẹ̀. Jòhánù jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú èyí. Ẹ wo irú àǹfààní tí èyí jẹ́ fún un! Púpọ̀ sí i ṣì ń bọ̀ lọ́nà. Lẹ́yìn èyí, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ní àgbègbè Éfésù, ó kọ ìròyìn Ìhìn Rere rẹ̀ àti lẹ́tà mẹ́ta. Ẹ wo irú àǹfààní ọlọ́lá tí èyí jẹ́ láti fi kágbá iṣẹ́ ìsìn àfòtítọ́ṣe, tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, aláàádọ́rin ọdún nílẹ̀!

Láti jẹ́ oníwàtítọ́ ènìyàn ní gbogbogbòò ń mú ìtẹ́lọ́rùn ńláǹlà wá. Láti jẹ́ ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé lójú Ọlọ́run ń mú èrè ayérayé wá. Lónìí, a ń múra “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn olùjọsìn tòótọ́ sílẹ̀ láti wọnú ayé tuntun alálàáfíà àti ìṣọ̀kan, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìṣípayá 7:9) A gbọ́dọ̀ pa ìwà títọ́ mọ́ nínú àwọn ọ̀ràn pàtàkì ti ìwà híhù àti ìjọsìn, láìka ìdánwò ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan wọ̀nyí sí, àti onírúurú ìpèníjà tí Sátánì lè mú wá. Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé, nínú agbára tí Jèhófà ń fúnni, o lè ṣàṣeyọrí!—Fílípì 4:13.

Ní sísọ̀rọ̀ nípa ohun ti lọ́ọ́lọ́ọ́ àti ti ọjọ́ iwájú, Dáfídì, onísáàmù náà, mú un dá gbogbo wa lójú, nígbà tí ó sọ, nínú àdúrà ìdúpẹ́ sí Jèhófà pé: “Bí ó ṣe ti èmi ni, ìwọ dì mí mú nínú ìwà títọ́ mi, ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé. Olùbùkún ni Olúwa . . . Àmín, Àmín.”—Orin Dáfídì 41:12, 13.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àlàyé nínú The New Testament of Our Lord and Saviour Jesus Christ, according to the Authorised Version, with a brief commentary by various authors.

b Orúkọ náà, Sátánì, túmọ̀ sí “Alátakò.” “Èṣù” túmọ̀ sí “Abanijẹ́.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Láìka àwọn àṣìṣe rẹ̀ sí, Dáfídì fẹ̀rí hàn pé òun ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Jèsú fi àpẹẹrẹ ìṣeégbẹ́kẹ̀lé gíga jù lọ lélẹ̀ fún wa

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jíjẹ́ ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ń mú ìtẹ́lọ́rùn gíga wá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́