Àwọn Àjọ̀dún Ìkórè Ha Dùn Mọ́ Ọlọ́run Nínú Bí?
ÈSO pupa ròbòtò, ewébẹ̀ títutù yọ̀yọ̀, àti ṣírí àgbàdo bọ̀ọ̀pà bọ̀ọ̀pà tí a tò jọ gègèrè jẹ́ ohun tí ń fani mọ́ra. Nígbà ìkórè, irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe orí pẹpẹ àti àga ìwàásù ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì lọ́ṣọ̀ọ́ jákèjádò England. Ní Europe, bíi ti ibò míràn, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ayẹyẹ ń sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ìgbà ìkórè.
Ní pàtàkì, àwọn tí wọ́n gbára lé ilẹ̀ fún gbígbọ́ bùkátà wọn máa ń dúpẹ́ fún irè oko. Ní tòótọ́, Ọlọ́run ké sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì láti máa ṣàjọ̀dún mẹ́ta lọ́dọọdún, tí ó ní í ṣe ní pàtàkì pẹ̀lú ìkórè. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé, nígbà Àjọ Àìwúkàrà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fún Ọlọ́run ní ṣírí àkọ́so ọkà báálì tí wọ́n kórè. Nígbà Àjọ Ọ̀sẹ̀ (tàbí, Pẹ́ńtíkọ́sì) ní òpin ìgbà ìrúwé, wọ́n yóò fi àkàrà tí a fi àkọ́so àlìkámà ṣe rúbọ. Ìgbà ìwọ́wé ni Àjọ Ìkórè Oko, tí ó sàmì sí òpin ọdún iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Ísírẹ́lì. (Ẹ́kísódù 23:14-17) Àwọn àjọ wọ̀nyí jẹ́ “àpéjọ mímọ́,” wọ́n sì jẹ́ àkókò àjọyọ̀.—Léfítíkù 23:2; Diutarónómì 16:16.
Nígbà náà, ṣíṣàjọ̀dún ìkórè lóde òní ńkọ́? Wọ́n ha dùn mọ́ Ọlọ́run nínú bí?
Ìsopọ̀ Rẹ̀ Pẹ̀lú Ìbọ̀rìṣà
Nítorí tí ẹ̀mí ayé tí àsè ìkórè aláṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ní àti ọtí àmupara tí ń wáyé nígbà àjọ̀dún náà kó ìdààmú bá a, àlùfáà ìjọ Áńgílíkà ní Cornwall, England, pinnu ní ọdún 1843 láti mú àṣà ìkórè ti Sànmánì Agbedeméjì sọ jí. Ó mú díẹ̀ lára àwọn ọkà tí a kọ́kọ́ kórè, ó fi ṣe búrẹ́dì fún ayẹyẹ ara olúwa nínú ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó mú kí àjọ̀dún Lammas—ayẹyẹ “àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni” tí àwọn kan sọ pé ó pilẹ̀ níbi ìjọsìn Lugh, ọlọ́run àwọn Celt, ní ìgbà láéláé, máa bá a nìṣó.a Nípa báyìí, àjọ̀dún ìkórè òde òní tí àwọn Áńgílíkà ń ṣe pilẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà.
Àwọn ayẹyẹ mìíràn tí ń wáyé ní òpin ìgbà ìkórè ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ti sọ, ọ̀pọ̀ àṣà tí ń bá àwọn àjọ̀dún wọ̀nyí rìn pilẹ̀ láti inú “ìgbàgbọ́ tí àwọn onímọlẹ̀ ní nínú ẹ̀mí àgbàdo [ọkà] tàbí ẹ̀mí yèyé àgbàdo.” Ní àwọn ẹkùn kan, àwọn àgbẹ̀ gbà gbọ́ pé ẹ̀mí kan ń gbé nínú ṣírí ọkà tí a bá kórè kẹ́yìn. Láti lé ẹ̀mí náà jáde, wọ́n yóò fi póńpó lu ọkà náà mọ́lẹ̀. Níbò míràn, wọn yóò fi díẹ̀ nínú ewé ọkà náà hun “ọmọláńgidi àgbàdo” tí wọn yóò tọ́jú pa mọ́ fún “oríire” títí di ìgbà ìfúnrúgbìn ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn náà, wọn yóò pa dà gbin ṣírí ọkà náà ní ìrètí pé èyí yóò mú kí ohun ọ̀gbìn tuntun náà dára sí i.
Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu kan so àkókò ìkórè mọ́ ìjọsìn ọlọ́run àwọn ará Bábílónì náà, Támúsì, ọkọ abo ọlọ́run afúnnilọ́mọ, Íṣítà. Gígé orí ọkà tí ó ti gbó sọnù ń ṣàpẹẹrẹ ikú àìtọ́jọ́ tí Támúsì kú. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu mìíràn tilẹ̀ so àkókò ìkórè mọ́ fífi ẹ̀dá ènìyàn rúbọ—àṣà kan tí Jèhófà Ọlọ́run kórìíra gidigidi.—Léfítíkù 20:2; Jeremáyà 7:30, 31.
Kí Ni Ojú Ìwòye Ọlọ́run?
Ìbálò Ọlọ́run pẹ̀lú Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣí i payá ní kedere pé Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àti Orísun ìwàláàyè, fi dandan gbọ̀n béèrè ìfọkànsìn àyàsọ́tọ̀ gédégbé lọ́wọ́ àwọn olùjọ́sìn rẹ̀. (Orin Dáfídì 36:9; Náhúmù 1:2) Ní ọjọ́ wòlíì Ìsíkẹ́ẹ̀lì, àṣà sísunkún níwájú ọlọ́run Támúsì jẹ́ “ìríra ńlá” lójú Jèhófà. Èyí, pa pọ̀ pẹ̀lú ààtò ìsìn èké mìíràn, mú kí Ọlọ́run máà gbọ́ àdúrà àwọn olùjọsìn èké wọ̀nyẹn.—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 8:6, 13, 14, 18.
Fi èyí wé ohun tí Jèhófà Ọlọ́run pàṣẹ fún Ísírẹ́lì láti máa ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìkórè. Nígbà Àjọ Ìkórè Oko, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe àpéjọ ìsìn nígbà tí tọmọdé tàgbà, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, máa ń gbé nínú àwọn ilé onígbà díẹ̀, tí a fi ewé igi rírẹwà tí ó tutù yọ̀yọ̀ ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Àkókò ayọ̀ ńláǹlà ni èyí jẹ́ fún wọn, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ àkókò láti ronú jinlẹ̀ lórí ìdáǹdè tí Ọlọ́run fún àwọn baba ńlá wọn nígbà Ìjádelọ kúrò ní Íjíbítì.—Léfítíkù 23:40-43.
Nígbà àjọ̀dún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, ni wọ́n ń mú ọrẹ ẹbọ wá fún. (Diutarónómì 8:10-20) Ní ti ìgbàgbọ́ àwọn onímọlẹ̀ tí a mẹ́nu kàn ṣáájú, kò sí ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa irè oko, irú bíi ṣírí àlìkámà, bí èyí tí ó ní ọkàn.b Ìwé Mímọ́ sì fi hàn kedere pé àwọn òrìṣà kò lẹ́mìí, wọn kò lè sọ̀rọ̀, wọn kò lè ríran, wọn kò lè gbọ́ràn, wọn kò lè gbóòórùn, wọn kò lè nímọ̀lára, tàbí kí wọ́n ṣèrànlọ́wọ́ èyíkéyìí fún àwọn olùjọsìn wọn.—Orin Dáfídì 115:5-8; Róòmù 1:23-25.
Àwọn Kristẹni lónìí kò sí lábẹ́ májẹ̀mú Òfin tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ní tòótọ́, Ọlọ́run ‘mú un kúrò lójú ọ̀nà nípa kíkàn án níṣòó mọ́ òpó igi oró Jésù.’ (Kólósè 2:13, 14) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú “òfin Kristi,” wọ́n sì ń fi ìmọrírì dáhùn pa dà sí gbogbo ohun tí Ọlọ́run pèsè.—Gálátíà 6:2.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní kedere pé àjọ̀dún àwọn Júù jẹ́ “òjìji àwọn nǹkan tí ń bọ̀,” ó fi kún un pé, “ṣùgbọ́n ohun gidi náà jẹ́ ti Kristi.” (Kólósè 2:16, 17) Lójú ìwòye èyí, àwọn Kristẹni tòótọ́ tẹ́wọ́ gba èrò Ìwé Mímọ́ náà pé: “Àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ wọ́n fi ń rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù, kì í sì í ṣe sí Ọlọ́run . . . Ẹ̀yin kò lè máa mu ife Jèhófà àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Kọ́ríńtì Kíní 10:20, 21) Ní àfikún sí i, àwọn Kristẹni ń kọbi ara sí àṣẹ náà láti “jáwọ́ nínú fífọwọ́ kan ohun àìmọ́.” Àwọn àjọ̀dún ìkórè tí a ń ṣe ní àdúgbò rẹ ha ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà tàbí ìsìn èké bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ojúlówó Kristẹni lè yẹra fún mímú inú bí Jèhófà nípa kíkọ níní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ tí a ti sọ dẹ̀gbin.—Kọ́ríńtì Kejì 6:17.
Nígbà tí ọmọ kan tí ó nímọrírì bá rí ẹ̀bùn kan gbà láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀, ta ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀? Àlejò pátápátá kan tàbí òbí rẹ̀? Nípa àdúrà àtọkànwá, àwọn olùjọsìn Ọlọ́run ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, Bàbá wọn ọ̀run, lójoojúmọ́, fún ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀ ní yanturu.—Kọ́ríńtì Kejì 6:18; Tẹsalóníkà Kíní 5:17, 18.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Inú ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì Àtijọ́ kan tí ó túmọ̀ sí “ègé búrẹ́dì” ni a ti mú ọ̀rọ̀ náà “Lammas” jáde.
b Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures sọ pé: “A kò lo neʹphesh (ọkàn) láti tọ́ka sí dídá irúgbìn ní ‘ọjọ́’ kẹta ọjọ́ ìṣẹ̀dá (Jẹ́ 1:11-13) tàbí lẹ́yìn náà, níwọ̀n bí irúgbìn kò ti ní ẹ̀jẹ̀.”—Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.