ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 10/15 ojú ìwé 5-7
  • Ayọ̀ Tòótọ́—Kí Ni Àṣírí Rẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayọ̀ Tòótọ́—Kí Ni Àṣírí Rẹ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jíjẹ́ Ẹni Tẹ̀mí Ń Mú Ayọ̀ Wá
  • Agbára Wa Láti Ṣe Yíyàn
  • Ọgbọ́n Ọlọ́run àti Ìgbọràn—Àṣírí Náà
  • Bí A Ṣe Lè Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ayọ Tootọ Ninu Ṣiṣiṣẹsin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Aláyọ̀ Ni Àwọn Tó Ń Sin “Ọlọ́run Aláyọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ibo Ni A Ti Lè Rí Ayọ̀ Tòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 10/15 ojú ìwé 5-7

Ayọ̀ Tòótọ́—Kí Ni Àṣírí Rẹ̀?

A DÁ ẹ̀dá ènìyàn láti jẹ́ aláyọ̀. Èé ṣe tí ìyẹn lè dá wa lójú? Toò, gbé ìbẹ̀rẹ̀ ènìyàn yẹ̀ wò.

Jèhófà Ọlọ́run dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ pẹ̀lú agbára láti ní ayọ̀. A fi Ádámù àti Éfà sínú párádísè kan, ọgbà ìtura tí a ń pè ní Édẹ́nì. Ẹlẹ́dàá pèsè gbogbo ohun kò-ṣeé-máà-ní nípa ti ara ti ìgbésí ayé fún wọn. Ọgbà náà ní “onírúurú igi . . . tí ó dára ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9) Ìlera Ádámù àti Éfà jí pépé, ara wọ́n le, wọ́n sì rẹwà—wọ́n jẹ́ ẹni pípé, wọ́n sì láyọ̀ ní tòótọ́.

Ṣùgbọ́n, kí ni àṣírí ayọ̀ wọn? Ṣé ilé párádísè wọn ni tàbí ìjẹ́pípé wọn nípa ti ara? Àwọn ẹ̀bùn tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ̀nyí fi kún adùn ìgbésí ayé wọn. Ṣùgbọ́n ayọ̀ wọn kò sinmi lórí irú àwọn ohun tí a lè fojú rí bẹ́ẹ̀. Ọgbà Édẹ́nì kì í ṣe ọgbà ìtura ẹlẹ́wà kan lásán. Ó jẹ́ ibi mímọ́ kan, ibi ìjọsìn Ọlọ́run. Agbára láti ní ipò ìbátan onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn àti láti dì í mú ni àṣírí ayọ̀ wọn ayérayé. Láti jẹ́ aláyọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ ẹni tẹ̀mí.—Fi wé Mátíù 5:3.

Jíjẹ́ Ẹni Tẹ̀mí Ń Mú Ayọ̀ Wá

Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ádámù ní ipò ìbátan tẹ̀mí pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó jẹ́ ipò ìbátan onífẹ̀ẹ́, oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ bíi ti ọmọkùnrin kan pẹ̀lú bàbá rẹ̀. (Lúùkù 3:38) Nínú ọgbà Édẹ́nì, Ádámù àti Éfà ní ipò pípé tí ó yọ̀ǹda fún wọn láti tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn láti jọ́sìn lọ́rùn. Nípa ìgbọràn onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n bá fi tinútinú ṣe sí Jèhófà, wọn yóò mú ọlá àti ògo wá fún Ọlọ́run ju bí àwọn ẹranko ti lè ṣe lọ. Wọ́n lè fi òye yin Ọlọ́run fún àwọn àgbàyanu ànímọ́ rẹ̀, wọ́n sì lè gbárùkù ti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ lẹ́yìn. Wọ́n tún lè máa bá a nìṣó láti rí ìfẹ́ Jèhófà àti àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ gbà.

Ipò ìbátan tímọ́tímọ́ tí wọ́n ní pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá yìí àti ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn òfin rẹ̀ mú ojúlówó ayọ̀ wá fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́. (Lúùkù 11:28) A kò retí pé kí Ádámù àti Éfà gbé ìgbésí ayé dányìíwò kí wọ́n tó ṣàwárí àṣírí ayọ̀. Wọ́n jẹ́ aláyọ̀ gbàrà láti ìgbà tí a ti dá wọn. Wíwà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run àti títẹríba fún ọlá àṣẹ rẹ̀ mú kí wọn jẹ́ aláyọ̀.

Ṣùgbọ́n, ayọ̀ yẹn wọmi gbàrà tí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Nípa ṣíṣọ̀tẹ̀, Ádámù àti Éfà ba ipò ìbátan wọn tẹ̀mí pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Wọn kì í ṣe ọ̀rẹ́ Ọlọ́run mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Ó dà bíi pé láti ọjọ́ tí a ti lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà náà ni Jèhófà kò ti bá wọn sọ̀rọ̀ mọ́ rárá. Wọ́n pàdánù ìjẹ́pípé wọn, ìfojúsọ́nà fun wíwà láàyè títí láé, àti ọgbà tí ó jẹ́ ilé wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:23) Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, níwọ̀n bí wọ́n ti pàdánù ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n pàdánù àṣírí ayọ̀.

Agbára Wa Láti Ṣe Yíyàn

Kí wọ́n tó kú, Ádámù àti Éfà tàtaré àwọn ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ní, ẹ̀rí ọkàn tí a dá mọ́ wọn, àti agbára láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí, sí irú ọmọ wọn. A kò rẹ ìdílé ẹ̀dá ènìyàn nípò wálẹ̀ sí ipò ẹranko. A lè pa dà mú wa bá Ẹlẹ́dàá wa rẹ́. (Kọ́ríńtì Kejì 5:18) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá olóye, àwọn ẹ̀dá ènìyàn ṣì ní agbára láti ṣe yíyàn yálà láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run tàbí láti má ṣe bẹ́ẹ̀. A ṣàkàwé èyí ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, nígbà tí Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní àǹfààní láti yan ìyè tàbí ikú. Nípasẹ̀ agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀, Mósè, Ọlọ́run wí pé: “Mo fi ìyè àti ire, àti ikú àti ibi, síwájú rẹ ní òní.”—Diutarónómì 30:15-18.

Nísinsìnyí pàápàá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn tí a ti pàdánù Párádísè ìpilẹ̀ṣẹ̀, àwa ènìyàn ṣì ní agbára láti ṣe yíyàn tí ó tọ́. A ní ẹ̀rí ọkàn tí ń ṣiṣẹ́ àti agbára tí ó ṣe kókó fún ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ẹni tí àwa jẹ́ ní inú.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:16; Róòmù 7:22) Gbólóhùn yí ní í ṣe pẹ̀lú ànímọ́ tí a bí mọ́ wa, tí gbogbo wa ní, láti lè fi àkópọ̀ ìwà Ọlọ́run hàn, láti ronú bíi tirẹ̀, láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí.

Nípa ti ìwà rere tí a dá mọ́ wa àti ẹ̀rí ọkàn wa, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, à ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí à ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.”—Róòmù 2:14, 15.

Ọgbọ́n Ọlọ́run àti Ìgbọràn—Àṣírí Náà

Ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Bí gbogbo wa bá ní ìtẹ̀sí tí a dá mọ́ wa láti jọ́sìn Ọlọ́run, tí yóò sì yọrí sí gbígbádùn ojúlówó ayọ̀, èé ṣe tí ìbànújẹ́ fi tàn kálẹ̀ tó bẹ́ẹ̀?’ Ìdí rẹ̀ ni pé, láti lè jẹ́ aláyọ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ mú ànímọ́ jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí dàgbà. Bí a tilẹ̀ dá wa ní àwòrán Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, a ti sọ ènìyàn di àjèjì sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀. (Éfésù 4:17, 18) Nítorí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ pàtó láti ní ipò ìbátan tẹ̀mí pẹ̀lú Ọlọ́run, kí a sì dì í mú. Irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ kò lè ṣàdédé bẹ̀rẹ̀.

Jésù mẹ́nu kan ìlànà pàtàkì méjì nínú mímú ànímọ́ jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí dàgbà. Ọ̀kan ni láti jèrè ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, èkejì sì ni láti fi ìgbọràn tẹrí ba fún ìfẹ́ inú rẹ̀. (Jòhánù 17:3) Ní ṣíṣàyọlò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Jésù wí pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn gbọ́dọ̀ wà láàyè, kì í ṣe nípasẹ̀ búrẹ́dì nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’” (Mátíù 4:4) Ní àkókò míràn, Jésù sọ pé: “Oúnjẹ mi ni fún mi láti ṣe ìfẹ́ inú ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:34) A kò ní láti lo ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ní ṣíṣe ìwádìí dányìíwò kí a tó lè ní ayọ̀. Kì í ṣe ìrírí ni àṣírí ayọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, kìkì ọgbọ́n ọlọ́run àti ṣíṣe ìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá wa ni ó lè yọrí sí ayọ̀ tòótọ́ nínú ìgbésí ayé.—Orin Dáfídì 19:7, 8; Oníwàásù 12:13.

Ó ṣe kedere pé, ayọ̀ tí ń wá nípa lílo ọgbọ́n Ọlọ́run àti nípa níní ìdúró rere níwájú rẹ̀ kì í ṣe ohun tí ọwọ́ wa kò lè tẹ̀. (Ìṣe 17:26, 27) Ìmọ̀ Jèhófà àti ète rẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ẹ̀dà tí ó wà ní ọ̀pọ̀ èdè, Bíbélì ń bá a nìṣó láti jẹ́ ìwé tí a ń pín kiri lọ́nà gbígbòòrò jù lọ. Bíbélì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kí o sì gbádùn ojúlówó ayọ̀, nítorí Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé “aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—Orin Dáfídì 144:15, NW.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ìgbésẹ̀ Sí Jíjẹ́ Aláyọ̀

1. Mọrírì ànímọ́ jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí, kí o sì mú un dàgbà. Jésù wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—Lúùkù 11:28.

2. Mọ̀ pé rírí ojú rere Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ọrọ̀ tàbí afẹ́ lọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, ìfọkànsìn Ọlọ́run yìí pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi. . . . Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti ìbora, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn ọkàn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—Tímótì Kíní 6:6-8.

3. Tiraka láti mú ẹ̀rí ọkàn tí a fi Bíbélì kọ́ dàgbà, kí o sì jẹ́ kí ó darí rẹ.—Róòmù 2:14, 15.

4. Pinnu láti ṣègbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ tóótun láti di ọ̀kan lára àwọn ènìyàn rẹ̀. Dáfídì ìgbàanì kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—Orin Dáfídì 144:15, NW.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́