ORÍ KỌKÀNLÁ
Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Agbo Ilé Rẹ
1. Kí ni àwọn nǹkan tí ó lè fa ìpínyà nínú ìdílé?
ALÁYỌ̀ ni àwọn tí ó jẹ́ apá kan àwọn ìdílé tí ìfẹ́, ìfòyebánilò, àti àlàáfíà wà. A retí pé, irú ìyẹn ni ìdílé rẹ jẹ́. Ó bani nínú jẹ́ pé, àìmọye ìdílé kùnà láti bá àpèjúwe yẹn mu, wọ́n sì pínyà fún ìdí kan tàbí òmíràn. Kí ní ń pín agbo ilé níyà? Nínú orí yìí, a óò jíròrò ohun mẹ́ta. Nínú àwọn ìdílé kan, àwọn mẹ́ḿbà kì í ṣe onísìn kan náà. Nínú àwọn ìdílé mìíràn, ó lè jẹ́ pé kì í ṣe àwọn òbí kan náà ni ó bí àwọn ọmọ. Nínú àwọn mìíràn ẹ̀wẹ̀, wàhálà àtirí oúnjẹ òòjọ́ tàbí ìfẹ́ ọkàn fún ohun ìní ti ara púpọ̀ sí i, dà bí èyí tí ń pín àwọn mẹ́ḿbà ìdílé níyà. Síbẹ̀, àwọn àyíká ipò tí ń pín agbo ilé kan níyà lè ṣàìnípa lórí òmíràn. Kí ní ń fa ìyàtọ̀ náà?
2. Níbo ni àwọn kan ń yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà nínú ìgbésí ayé ìdílé, ṣùgbọ́n kí ni orísun dídára jù lọ fún irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀?
2 Ojú ìwòye jẹ́ kókó kan. Bí o bá fi tọkàntọkàn gbìyànjú láti lóye ojú ìwòye ẹnì kejì, ó ṣeé ṣe kí o fòye mọ bí o ṣe lè pa agbo ilé tí ó wà níṣọ̀kan mọ́. Orísun ìtọ́sọ́nà rẹ jẹ́ kókó kejì. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, àwọn aládùúgbò wọn, àwọn akọ̀rọ̀ nínú ìwé ìròyìn, tàbí àwọn amọ̀nà míràn tí ẹ̀dá ènìyàn gbé kalẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn kan ti rí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ nípa ipò wọn, wọ́n sì ti lo ohun tí wọ́n kọ́. Báwo ni ṣíṣe èyí ṣe lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú agbo ilé?—2 Timoteu 3:16, 17.
BÍ ỌKỌ RẸ BÁ NÍ ÌGBÀGBỌ́ TÍ Ó YÀTỌ̀
3. (a) Kí ni ìmọ̀ràn Bibeli nípa ṣíṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀? (b) Àwọn ìlànà pàtàkì wo ni ó ṣeé fi sílò tí ẹnì kan nínú ìgbéyàwó bá jẹ́ onígbàgbọ́ tí ẹnì kejì sì jẹ́ aláìgbàgbọ́?
3 Bibeli fún wa nímọ̀ràn gidigidi lòdì sí ṣíṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹnì kan tí ó ní ìgbàgbọ́ ìsìn tí ó yàtọ̀. (Deuteronomi 7:3, 4; 1 Korinti 7:39) Ṣùgbọ́n, ó lè jẹ́ pé, o kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti inú Bibeli lẹ́yìn ìgbéyàwó rẹ, ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni ṣíṣe? Dájúdájú, ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó náà ṣì fìdí múlẹ̀. (1 Korinti 7:10) Bibeli tẹnu mọ́ ìwàpẹ́títí ìdè ìgbéyàwó, ó sì fún àwọn tí ó ti ṣègbéyàwó níṣìírí láti wá ọ̀nà láti yanjú aáwọ̀ wọn dípò yíyẹ̀ wọ́n sílẹ̀. (Efesu 5:28-31; Titu 2:4, 5) Ṣùgbọ́n, bí ọkọ rẹ bá fi àtakò gidigidi hàn sí ṣíṣe tí o ń ṣe ìsìn tí ó bá Bibeli mu ńkọ́? Ó lè gbìyànjú láti dí ọ lọ́wọ́ lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, tàbí ó lè sọ pé òun kò fẹ́ kí aya òun máa ya ojúlé kiri, láti máa sọ̀rọ̀ nípa ìsìn. Kí ni ìwọ yóò ṣe?
4. Ní ọ̀nà wo ni aya kan fi lè fi ẹ̀mí ìfọ̀ràn-rora-ẹni-wò hàn bí ọkọ rẹ̀ kò bá ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ̀?
4 Bí ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ní ń mú kí ọkọ mi hùwà bí ó ṣe ń hùwà?’ (Owe 16:20, 23) Bí kò bá lóye ohun tí o ń ṣe ní tòótọ́, ó lè máa dààmú nípa rẹ? Tàbí ó lè wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan, nítorí pé o kò tún bá wọn lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà kan tí wọ́n kà sí pàtàkì. Ọkọ kan wí pé: “Fífi èmi nìkan sílẹ̀ nínú ilé ń mú kí n nímọ̀lára pé a ti pa mí tì.” Ọkùnrin yìí rò pé ìsìn ń gba aya mọ òun lọ́wọ́. Síbẹ̀, ìgbéraga kò mú kí ó gbà pé òún dá nìkan wà. Ọkọ rẹ lè nílò ìdánilójú pé, ìfẹ́ rẹ fún Jehofa kò túmọ̀ sí pé, ó kò nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ nísinsìnyí tó bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Rí i pé o ń lo àkókò pẹ̀lú rẹ̀.
5. Ìwàdéédéé wo ni aya tí ọkọ rẹ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí ó yàtọ̀ ní láti dì mú?
5 Ṣùgbọ́n, o gbọ́dọ̀ gbé ohun kan tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì yẹ̀ wò, bí o bá fẹ́ kojú ipò náà pẹ̀lú ọgbọ́n. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọ àwọn aya pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún awọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ ninu Oluwa.” (Kolosse 3:18) Nípa báyìí, ó kìlọ̀ lòdì sí ẹ̀mí dáńfó gedegbe. Ní àfikún sí i, nípa sísọ pé “gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ ninu Oluwa,” ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí fi hàn pé ìtẹríba fún ọkọ ẹni, ní láti gbé ìtẹríba fún Oluwa yẹ̀ wò pẹ̀lú. Ó gbọ́dọ̀ wà déédéé.
6. Àwọn ìlànà wo ni ó yẹ kí Kristian aya fi sọ́kàn?
6 Lójú Kristian kan, lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ àti jíjẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìgbàgbọ́ ẹni, tí a gbé karí Bibeli, jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́ tí a kò gbọdọ̀ fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. (Romu 10:9, 10, 14; Heberu 10:24, 25) Nígbà náà, kí ni ìwọ yóò ṣe, bí ẹ̀dá ènìyàn kan bá pàṣẹ fún ọ ní tààràtà láti má ṣe tẹ̀ lé ohun kan pàtó tí Ọlọrun béèrè fún? Àwọn aposteli Jesu Kristi polongo pé: “Awa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Àpẹẹrẹ wọ́n pèsè àwòṣe kan tí ó ṣeé mú lò nínú ọ̀pọ̀ ipò nínú ìgbésí ayé. Ìfẹ́ fún Jehofa yóò ha sún ọ láti fún un ní ìfọkànsìn tí ó tọ́ sí i bí? Lọ́wọ́ kan náà, ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí o ní fún ọkọ rẹ yóò ha mú kí o gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọ̀nà kan tí kì yóò bí ọkọ rẹ nínú bí?—Matteu 4:10; 1 Johannu 5:3.
7. Ìpinnu wo ni Kristian aya gbọ́dọ̀ ní?
7 Jesu sọ pé, èyí kò lè fìgbà gbogbo ṣeé ṣe. Ó kìlọ̀ pé, nítorí àtakò sí ìjọsìn tòótọ́, àwọn mẹ́ḿbà tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ nínú àwọn ìdílé kan yóò nímọ̀lára pé a ti pín àwọn níyà, bíi pé idà kan ti pín àwọn àti ìyókù ìdílé wọn níyà. (Matteu 10:34-36) Obìnrin kan ní Japan nírìírí èyí. Ọdún 11 ni ọkọ rẹ̀ fi ta kò ó. Ó hùwà rírorò sí i, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sì tì í mọ́ta. Ṣùgbọ́n ó forí tì í. Àwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ Kristian ràn án lọ́wọ́. Ó gbàdúrà láìdábọ̀, ó sì rí ọ̀pọ̀ ìṣírí láti inú 1 Peteru 2:20. Ó dá obìnrin Kristian yìí lójú pé, bí òún bá dúró ṣinṣin, lọ́jọ́ kan ṣáá, ọkọ òun yóò dara pọ̀ mọ́ òun nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa. Ọkọ rẹ̀ sì ṣe bẹ́ẹ̀.
8, 9. Báwo ni aya kan ṣe lè yẹra fún gbígbé àwọn ohun ìdènà tí kò pọn dandan síwájú ọkọ rẹ̀?
8 Ọ̀pọ̀ àwọn ohun gbígbéṣẹ́ ń bẹ tí o lè ṣe tí ó lè nípa lórí ìṣarasíhùwà alábàáṣègbéyàwó rẹ. Fún àpẹẹrẹ, bí ọkọ rẹ bá ta ko ìsìn rẹ, má ṣe fún un ní ìdí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún ṣíṣàwáwí ní àwọn agbègbè míràn. Jẹ́ kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní. Máa tún ìrísí ara rẹ ṣe. Máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àti ìmọrírì lóòrèkóòrè. Dípò ṣíṣe lámèyítọ́, jẹ́ alátìlẹ́yìn. Fi hàn pé, o ń wò ó gẹ́gẹ́ bí olórí. Má ṣe gbẹ̀san bí o bá nímọ̀lára pé ó ti ṣẹ̀ ọ́. (1 Peteru 2:21, 23) Fàyè sílẹ̀ fún àìpé ẹ̀dá ènìyàn, bí aáwọ̀ bá sì ṣẹlẹ̀, jẹ́ ẹni tí yóò kọ́kọ́ tọrọ àforíjì tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀.—Efesu 4:26.
9 Má ṣe jẹ́ kí lílọ sí àwọn ìpàdé jẹ́ ìdí tí oúnjẹ rẹ̀ yóò fi pẹ́ délẹ̀. O tún lè yàn láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian nígbà míràn tí ọkọ rẹ kò bá sí nílé. Ó bọ́gbọ́n mu fún Kristian aya kan láti yàgò fún wíwàásù fún ọkọ rẹ̀, nígbà tí kò bá nífẹ̀ẹ́ sí èyí. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun yóò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn aposteli Peteru pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún awọn ọkọ tiyín, kí ó baà lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ naa, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà awọn aya wọn, nitori jíjẹ́ tí wọ́n ti jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí ìwà mímọ́ yín papọ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Peteru 3:1, 2) Àwọn Kristian aya ń ṣiṣẹ́ lórí bí wọn yóò ṣe túbọ̀ fi àwọn èso tẹ̀mí Ọlọrun hàn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.—Galatia 5:22, 23.
NÍGBÀ TÍ AYA KÌ Í BÁ ṢE KRISTIAN
10. Báwo ni ọkọ kan tí ó jẹ́ onígbàgbọ́ ṣe yẹ kí ó hùwà sí aya rẹ̀ bí aya rẹ̀ bá ní èrò ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀?
10 Bí ọkọ bá jẹ́ Kristian ńkọ́, tí aya kì í sì í ṣe Kristian? Bibeli fúnni ní ìtọ́sọ́nà fún irú ipò bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbàgbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin naa sì faramọ́ bíbá a gbé, kí oun máṣe fi obìnrin naa sílẹ̀.” (1 Korinti 7:12) Ó tún gba àwọn ọkọ níyànjú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ awọn aya yín.”—Kolosse 3:19.
11. Báwo ni ọkọ kan ṣe lè fi ìfòyemọ̀ hàn, kí ó sì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ lo ipò orí lórí aya rẹ̀, bí aya náà kì í bá ṣe Kristian?
11 Bí ìwọ́ bá jẹ́ ọkọ, tí aya rẹ sì ní ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀ sí tìrẹ, rí i dájú pé o bọ̀wọ̀ fún aya rẹ, o sì gba ìmọ̀lára rẹ̀ rò. Gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà, ó yẹ fún òmìnira dé ìwọ̀n àyè kan láti ṣe ìsìn tí ó bá àwọn èrò ìgbàgbọ́ rẹ̀ mu, àní bí o kò tilẹ̀ fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú wọn. Ní ìgbà àkọ́kọ́ tí o bá bá a sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ, má ṣe retí pé kí ó pa gbogbo èrò ìgbàgbọ́ tí ó ti dì mú tipẹ́tipẹ́ tì, fún ohun kan tí ó jẹ́ tuntun. Dípò sísọ pé èké lásán ni ìsìn tí òun àti ìdílé rẹ̀ ti ṣìkẹ́ fún ìgbà pípẹ́, fi sùúrù sakun láti bá a fèrò wérò láti inú Ìwé Mímọ́. Ó lè jẹ́ pé, ó ń rò pé o ti pa òun tì, nítorí tí o ya èyí tí ó pọ̀ jù nínú àkókò rẹ sọ́tọ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Ó lè ta ko àwọn ìsapá rẹ láti ṣiṣẹ́ sin Jehofa, síbẹ̀ ohun tí ó ń dọ́gbọ́n sọ lè wulẹ̀ jẹ́: “Mo nílò díẹ̀ sí i nínú àkókò rẹ!” Ní sùúrù. Pẹ̀lú ìfẹ́ onígbatẹnirò rẹ, bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, o lè ràn án lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́.—Kolosse 3:12-14; 1 Peteru 3:8, 9.
TÍTỌ́ ÀWỌN ỌMỌ
12.Àní bí ọkọ kan àti aya rẹ̀ bá ní ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀, báwo ni a ṣe lè lo àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ nínú títọ́ àwọn ọmọ?
12 Nínú agbo ilé kan tí kò wà ní ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn, ìtọ́ni ìsìn tí a óò fún àwọn ọmọ máa ń di ọ̀ràn àríyànjiyàn nígbà míràn. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lo àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́? Bibeli yan olórí ẹrù iṣẹ́ ti fífún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni fún bàbá, ṣùgbọ́n ìyá pẹ̀lú ní ipa pàtàkì láti kó. (Owe 1:8; fi wé Genesisi 18:19; Deuteronomi 11:18, 19.) Àní bí bàbá náà kò bá tilẹ̀ tẹ́wọ́ gba ipò orí Kristi, òun ṣì ni olórí ìdílé náà.
13, 14. Bí ọkọ bá ka mímú àwọn ọmọ lọ sí àwọn ìpàdé Kristian tàbí kíkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn léèwọ̀ fún aya rẹ̀, kí ni aya lè ṣe?
13 Àwọn bàbá kan tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ kì í ṣàtakò bí màmá bá ń fún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni lórí ọ̀ràn ìsìn. Àwọn mìíràn sì máa ń ṣàtakò. Bí ọkọ rẹ bá kọ̀ láti gbà ọ́ láyè láti mú àwọn ọmọ lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ tàbí tí ó tilẹ̀ kà á léèwọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn nínú ilé ńkọ́? Wàyí o, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ojúṣe wà tí o ní láti mú wà déédéé—ojúṣe rẹ sí Jehofa Ọlọrun, sí ọkọ tí ó jẹ́ orí rẹ, àti sí àwọn ọmọ rẹ àyànfẹ́. Báwo ni o ṣe lè mú ìwọ̀nyí wà déédéé?
14 Dájúdájú, ìwọ yóò gbàdúrà lórí ọ̀ràn náà. (Filippi 4:6, 7; 1 Johannu 5:14) Ṣùgbọ́n ní àbárèbábọ̀, ìwọ ni o gbọ́dọ̀ pinnu ipa ọ̀nà tí ìwọ yóò tọ̀. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ní mímú un ṣe kedere sí ọkọ rẹ pé, kì í ṣe pé o ń pe ipò orí rẹ̀ níjà, àtakò rẹ̀ lè rọlẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Kódà, bí ọkọ rẹ bá kà á léèwọ̀ fún ọ láti mú àwọn ọmọ rẹ lọ sí àwọn ìpàdé tàbí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn, ìwọ́ ṣì lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Nípa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ rẹ ojoojúmọ́ àti àpẹẹrẹ rere rẹ, gbìyànjú láti gbin ìwọ̀n ìfẹ́ fún Jehofa, ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀wọ̀ fún àwọn òbí—títí kan bàbá wọn—àníyàn onífẹ̀ẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, àti ìmọrírì fún àṣà ṣíṣiṣẹ́ tọkàntọkàn, sí wọn lọ́kàn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, bàbá náà lè ṣàkíyèsí àwọn ìyọrísí rere náà, ó sì lè mọrírì bí àwọn ìsapá rẹ ṣe níyelórí tó.—Owe 23:24.
15. Kí ni ẹrù iṣẹ́ bàbá tí ó jẹ́ onígbàgbọ́ nínú kíkọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́?
15 Bí o bá jẹ́ ọkọ kan tí ó jẹ́ onígbàgbọ́, tí aya rẹ kì í sì í ṣe onígbàgbọ́, nígbà náà, o gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ rẹ “ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.” (Efesu 6:4) Síbẹ̀, bí o ṣe ń ṣe èyí, o ní láti fi inú rere, ìfẹ́, àti òye bá aya rẹ lò.
BÍ ÌSÌN RẸ BÁ YÀTỌ̀ SÍ TI ÀWỌN ÒBÍ RẸ
16, 17. Àwọn ìlànà Bibeli wo ni àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ rántí bí wọ́n bá tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ tí ó yàtọ̀ sí ti àwọn òbí wọn?
16 Kì í ṣe ohun tuntun mọ́ fún àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá láti tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye ìsìn tí ó yàtọ̀ sí ti àwọn òbí wọn. O ha ti ṣe ìyẹn bí? Bí o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, Bibeli ní ìmọ̀ràn fún ọ.
17 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí awọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Oluwa, nitori èyí jẹ́ òdodo: ‘Bọlá fún baba rẹ ati ìyá rẹ.’” (Efesu 6:1, 2) Ìyẹ́n ní ọ̀wọ̀ tí ó gbámúṣé fún àwọn òbí nínú. Ṣùgbọ́n, bí ìgbọràn sí àwọn òbí tilẹ̀ ṣe pàtàkì, a kò gbọdọ̀ ṣe é láìka Ọlọrun tòótọ́ sí. Nígbà tí ọmọ kan bá dàgbà tó láti bẹ̀rẹ̀ sí í dápinnu ṣe, ó ń tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ sí i fún àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀. Kì í ṣe nínú ọ̀ràn òfin ayé nìkan ni èyí ti jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n, ní pàtàkì, nínú òfin àtọ̀runwá pẹ̀lú. Bibeli sọ pé: “Olúkúlùkù wa ni yoo ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọrun.”—Romu 14:12.
18, 19. Bí àwọn ọmọ bá ní ìsìn tí ó yàtọ̀ sí ti àwọn òbí wọn, báwo ni wọ́n ṣe lè ran àwọn òbí wọn lọ́wọ́ láti lóye ìgbàgbọ́ wọn dáradára sí i?
18 Bí èrò ìgbàgbọ́ rẹ bá mú kí o ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ, gbìyànjú láti lóye ojú ìwòye àwọn òbí rẹ. Ó ṣeé ṣe kí inú wọ́n dùn, bí kíkọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli àti fífi wọ́n sílò, bá ti yọrí sí sísọ ọ́ di ẹni tí ó túbọ̀ ń bọ̀wọ̀ fúnni, tí ó túbọ̀ jẹ́ onígbọràn, tí ó túbọ̀ jẹ́ aláápọn sí i nínú ohun tí wọ́n bá ní kí o ṣe. Ṣùgbọ́n, bí ìgbàgbọ́ rẹ tuntun bá tún mú kí o kọ àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti àṣà tí àwọn fúnra wọn ṣìkẹ́ sílẹ̀, wọ́n lè rò pé o ń ta ogún tí wọ́n fẹ́ láti fi lé ọ lọ́wọ́ nù. Wọ́n tún lè máa bẹ̀rù nípa ire rẹ, bí ohun tí o ń ṣe kò bá wọ́pọ̀ ní àwùjọ náà tàbí bí ó bá yí àfiyèsí rẹ kúrò nínú àwọn ìlépa tí àwọ́n rò pé ó lè mú ọ láásìkí nípa ti ara. Ìgbéraga pẹ̀lú lè jẹ́ ìdènà kan. Wọ́n lè rò pé, ohun tí o ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, ìwọ ni o tọ̀nà, àwọn ni àwọ́n kùnà.
19 Nítorí náà, bí ó ba ti lè tètè yá tó, gbìyànjú láti mú àwọn òbí rẹ mọ díẹ̀ lára àwọn alàgbà tàbí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú, láti inú ìjọ àdúgbò. Fún àwọn òbí rẹ níṣìírí láti bẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba wò, kí wọ́n sì fetí ara wọn gbọ́ ohun tí a ń jíròrò, kí wọ́n sì fúnra wọn rí irú ènìyàn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ìṣarasíhùwà àwọn òbí rẹ lè tutù pẹ̀sẹ̀. Àní nígbà tí àwọn òbí bá ranrí pátápátá, tí wọ́n run àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí wọ́n sì ka lílọ sí àwọn ìpàdé Kristian léèwọ̀ fún àwọn ọmọ wọn, àǹfààní máa ń wà láti kàwé níbòmíràn, láti bá àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni sọ̀rọ̀, àti láti jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà. O sì tún lè gbàdúrà sí Jehofa. Àwọn ọ̀dọ́ kan ní láti dúró títí di ìgbà tí wọ́n bá dàgbà tó láti gbé lẹ́yìn òde ilé ìdílé, kí wọ́n tó lè ṣe púpọ̀ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun yòówù tí ipò inú ilé lè jẹ́, má ṣe gbàgbé láti “bọlá fún baba rẹ ati ìyá rẹ.” Ṣe ipa tìrẹ láti mú kí àlàáfíà wà nínú ilé. (Romu 12:17, 18) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun.
ÌPÈNIJÀ JÍJẸ́ ÒBÍ NÍNÚ ÌGBÉYÀWÓ ÀTÚNṢE
20. Àwọn ìmọ̀lára wo ni àwọn ọmọ́ lè ní, bí bàbá wọn tàbí ìyá wọn bá jẹ́ òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe?
20 Nínú ọ̀pọ̀ ilé, ipò tí ń mú ìpènijà títóbi jù lọ wá kì í ṣe ọ̀ràn ìsìn bí kò ṣe ti ìṣòro ìdílé ìgbéyàwó àtúnṣe. Ọ̀pọ̀ agbo ilé lónìí ní àwọn ọmọ tí wọ́n wá láti inú ìgbéyàwó ìṣáájú ti ọ̀kan lára àwọn òbí tàbí ti àwọn òbí méjèèjì. Nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ lè máa jowú, wọ́n lè má di kùnrùngbùn tàbí kí wọ́n tilẹ̀ má mọ ibi àátẹ̀sí. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, wọ́n lè fojú tín-ín-rín ìsapá àtọkànwá tí òbí inú ìgbéyàwó àtúnṣe náà ń ṣe, láti jẹ́ bàbá rere tàbí ìyá rere. Kí ni ó lè ṣèrànwọ́ láti mú kí ìdílé onígbèéyàwó àtúnṣe yọrí sí rere?
21. Láìka àyíká ipò àrà ọ̀tọ̀ wọn sí, èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe yíjú sí àwọn ìlànà tí a rí nínú Bibeli fún ìrànlọ́wọ́?
21 Mọ̀ pé, láìka wí pé àwọn àyíká ipò wọ̀nyí jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí, àwọn ìlànà Bibeli tí ń mú àṣeyọrí wá nínú agbo ilé mìíràn ṣeé mú lò níhìn-ín pẹ̀lú. Fún ìgbà díẹ̀, ṣíṣàìka àwọn ìlànà wọ̀nyẹn sí lè dà bíi pé ó dín ìṣòro kù, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí ó yọrí sí ìrora ọkàn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (Orin Dafidi 127:1; Owe 29:15) Mú ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ dàgbà—ọgbọ́n láti fi àwọn ìlànà Ọlọrun sílò pẹ̀lú àǹfààní pípẹ́ títí lọ́kàn, àti òye láti mọ ìdí tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé fi ń sọ ohun kan, tí wọ́n sì ń ṣe ohun kan. Ó tún yẹ kí o ní ẹ̀mí ìfọ̀rànrora-ẹni-wò.—Owe 16:21; 24:3; 1 Peteru 3:8.
22. Èé ṣe tí ó fi lè ṣòro fún àwọn ọmọ láti tẹ́wọ́ gba òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe?
22 Bí o bá jẹ́ òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe, o lè rántí pé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ ìdílé náà, àwọn ọmọ náà tẹ́wọ́ gbà ọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí o di òbí wọn nínú ìgbéyàwó àtúnṣe, ìṣarasíhùwà wọ́n lè ti yí padà. Ní rírántí òbí tí ó bí wọn gan-an tí kò gbé pẹ̀lú wọn mọ́, àwọn ọmọ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìṣòro àìmọ ibi àátẹ̀sí, bóyá kí wọ́n máa nímọ̀lára pé o fẹ́ já ìfẹ́ni tí wọ́n ní fún òbí tí kò sí lọ́dọ̀ wọn mọ́ gbà mọ́ àwọn lọ́wọ́. Nígbà míràn, wọ́n lè rán ọ létí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé, ìwọ kì í ṣe bàbá àwọn tàbí ìyá àwọn. Irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ máa ń dunni gan-an. Síbẹ̀, “má ṣe yára ní ọkàn rẹ láti bínú.” (Oniwasu 7:9) O ní láti lo ìfòyemọ̀ àti ìfọ̀rànrora-ẹni-wò láti lè kojú èrò ìmọ̀lára àwọn ọmọ wọ̀nyẹn.
23. Báwo ni a ṣe lè lo ìbáwí nínú ìdílé tí ó ní àwọn ọmọ láti inú ìgbéyàwó ìṣáájú?
23 Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ṣe pàtàkì nígbà tí a bá ń báni wí. Ìbáwí tí ó ṣe déédéé, ṣe pàtàkì. (Owe 6:20; 13:1) Níwọ̀n bí àwọn ọmọ kò sì ti rí bákan náà, ìbáwí lè yàtọ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan sí òmíràn. Àwọn òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe kan rí i pé, ó kéré tán, ní ìbẹ̀rẹ̀, ó lè sàn jù fún òbí tí ó bí wọn gan-an láti bójú tó apá yìí. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé, kí àwọn òbí méjèèjì fohùn ṣọ̀kan lórí ìbáwí náà, kí wọ́n sì fara mọ́ ọn, kì í ṣe kí wọ́n máa fojú rere hàn sí ọmọ tiwọn ju ọmọ inú ìgbéyàwó ìṣáájú lọ. (Owe 24:23) Ìgbọràn ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n a ní láti máa fàyè sílẹ̀ fún àìpé. Má ṣe hùwà padà lọ́nà tí ó ré kọjá ààlà. Fi ìfẹ́ báni wí.—Kolosse 3:21.
24. Kí ni ó lè ṣèrànwọ́ láti yẹra fún àwọn ìṣòro ìwà híhù láàárín àwọn mẹ́ḿbà ẹ̀yà òdì kejì nínú ìdílé onígbèéyàwó àtúnṣe?
24 Àwọn ìjíròrò ìdílé lè ṣe púpọ̀ láti dènà wàhálà. Ìwọ̀nyí lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. (Fi wé Filippi 1:9-11.) Wọ́n tún lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti rí ipa tí òun lè sà nínú lílé àwọn góńgó ìdílé bá. Ní àfikún sí i, àwọn ìjíròrò ìdílé láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ lè yẹ àwọn ìṣòro ọ̀nà ìwà híhù sílẹ̀. Ó yẹ kí àwọn ọmọbìnrin mọ bí a ṣe ń múra, àti bí a ṣe ń hùwà bí ọmọlúwàbí sí ọkọ ìyá wọn àti sí àwọn ọmọkùnrin tí ọkọ ìyá wọn ti bí tẹ́lẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì nílò ìmọ̀ràn lórí ìwà tí ó tọ́ sí aya bàbá wọn àti sí àwọn ọmọbìnrin tí aya bàbá wọn ti bí tẹ́lẹ̀.—1 Tessalonika 4:3-8.
25. Àwọn ànímọ́ wo ni ó lè ṣèrànwọ́ láti mú kí àlàáfíà wà nínú ìdílé onígbèéyàwó àtúnṣe?
25 Ní kíkojú ìpènijà àrà ọ̀tọ̀ ti jíjẹ́ òbí nínú ìgbéyàwó àtúnṣe, jẹ́ onísùúrù. Ó ń gba àkókò láti mú ipò ìbátan tuntun dàgbà. Jíjèrè ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ àwọn ọmọ tí kì í ṣe ìwọ ni o bí wọn lè jẹ́ òpò tí ń kani láyà. Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe. Ọkàn-àyà ọlọgbọ́n àti onífòyemọ̀, pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn lílágbára láti ṣe ohun tí ó dùn mọ́ Jehofa nínú, ni kọ́kọ́rọ́ sí àlàáfíà nínú ìdílé ìgbéyàwó àtúnṣe. (Owe 16:20) Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ipò míràn.
ÌLÉPA ỌRỌ̀ ÀLÙMỌ́NÌ HA Ń PÍN ÌDÍLÉ RẸ NÍYÀ BÍ?
26. Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ìṣòro àti ìṣarasíhùwà ní ti ọrọ̀ àlùmọ́nì ṣe lè pín ìdílé kan níyà?
26 Àwọn ìṣòro àti ìṣarasíhùwà ní ti ọrọ̀ àlùmọ́nì lè pín ìdílé níyà ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Ó bani nínú jẹ́ pé, ìjiyàn lórí owó àti ìfẹ́ ọkàn fún ọrọ̀—tàbí ó kéré tán láti lè ní ọrọ̀ díẹ̀ sí i—ti dá wàhálà sílẹ̀ nínú àwọn ìdílé kan. Ìpínyà lè jẹ yọ nígbà tí àwọn alábàáṣègbéyàwó méjèèjì bá ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tí wọ́n sì mú ìṣarasíhùwà “owó tèmi nìyí, owó tìrẹ nìyẹn” dàgbà. Àní bí wọ́n bá tilẹ̀ yẹra fún ìjiyàn pàápàá, bí àwọn alábàáṣègbéyàwó méjèèjì bá ń ṣiṣẹ́, wọ́n lè rí i pé àyè díẹ̀ ní àwọn ní fún èkíní kejì. Ìtẹ̀sí tí ń wọ́pọ̀ sí i nínú ayé ni kí àwọn bàbá máa gbé ibi tí ó jìnnà sí àwọn ìdílé wọn fún sáà gígùn—ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún pàápàá—láti baà lè rí owó púpọ̀ sí i ju èyí tí wọ́n lè rí ní ilé lọ. Èyí lè yọrí sí ìṣòro ńláǹlà.
27. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìlànà tí ó lè ṣèrànwọ́ fún ìdílé kan tí ó ní ìṣòro ìṣúnná owó?
27 A kò lè gbé òfin kalẹ̀ fún bíbójú tó àwọn ipò wọ̀nyí, níwọ̀n bí àwọn ìdílé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ní láti kojú àwọn pákáǹleke àti àìní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, ìmọ̀ràn Bibeli lè ṣèrànwọ́. Fún àpẹẹrẹ, Owe 13:10 (NW) fi hàn pé a lè yẹra fún aáwọ̀ nípa “fífikùn lukùn.” Kì í wulẹ̀ ṣe sísọ ojú ìwòye tẹni nìkan ni èyí ní nínú, ṣùgbọ́n wíwá ìmọ̀ràn àti wíwádìí bí ẹnì kejì ṣe rí ọ̀ràn náà sí. Síwájú sí i, gbígbé ìwéwèé ètò ìnáwó tí ó ṣe déédéé kalẹ̀ lè ṣèrànwọ́ láti mú ìsapá ìdílé wà ní ìṣọ̀kan. Nígbà míràn ó pọn dandan—bóyá fún ìgbà díẹ̀—fún àwọn alábàáṣègbéyàwó méjèèjì láti ṣiṣẹ́ lẹ́yìn òde ilé, láti lè bójú tó àwọn àfikún ìnáwó, ní pàtàkì, nígbà tí àwọn ọmọ tàbí àwọn mìíràn tí ó gbójú lé wọn bá wà. Nígbà tí ọ̀ràn bá rí báyìí, ọkọ náà lè fi aya rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé, òún ṣì ní àkókò fún un. Ọkọ náà pẹ̀lú àwọn ọmọ lè fi tìfẹ́tìfẹ́ ran aya lọ́wọ́ láti ṣe nínú iṣẹ́ tí òun nìkan ì bá ti dá ṣe.—Filippi 2:1-4.
28. Àwọn ìránnilétí wo ni ìdílé kan lè máa fi sọ́kàn, tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà ní ìṣọ̀kan?
28 Bí ó ti wù kí ó rí, fi í sọ́kàn pé bí owó tilẹ̀ jẹ́ kò-ṣeé-mánìí nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí, kì í mú ayọ̀ wá. Ó sì dájú pé, kò lè mú ìwàláàyè wá. (Oniwasu 7:12) Ní tòótọ́, dídarí àfiyèsí tí ó pọ̀ jù sórí ọrọ̀ àlùmọ́nì lè fa ìparun nípa tẹ̀mí àti ti ọ̀nà ìwà híhù. (1 Timoteu 6:9-12) Ẹ wo bí ó ti dára jù tó láti kọ́kọ́ wá Ìjọba Ọlọrun àti òdodo rẹ̀, pẹ̀lú ìdánilójú pé òun yóò bù kún ìsapá wa láti ní àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí ìgbésí ayé! (Matteu 6:25-33; Heberu 13:5) Nípa fífi ire tẹ̀mí ṣáájú àti kíkọ́kọ́ lépa àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun, ìwọ́ lè rí i pé agbo ilé rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àyíká ipò kan lè pín in níyà, yóò di ọ̀kan tí ó wà ní ìṣọ̀kan ní tòótọ́ ní àwọn ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÀWỌN MẸ́ḾBÀ ÌDÍLÉ LÁTI MÚ KÍ ÀLÀÁFÍÀ WÀ NÍNÚ ILÉ?
Ó yẹ kí àwọn Kristian mú ìfòyemọ̀ dàgbà.—Owe 16:21; 24:3.
Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí tọkọtaya ń fi hàn nínú ìgbéyàwó kò sinmi lórí pé wọ́n jọ jẹ́ mẹ́ḿbà ìsìn kan náà.—Efesu 5:23, 25.
Kristian kì yóò mọ̀ọ́mọ̀ ru òfin Ọlọrun láé.—Ìṣe 5:29.
Ẹlẹ́mìí àlàáfíà ni àwọn Kristian.—Romu 12:18.
Má ṣe yára bínú.—Oniwasu 7:9.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 139]
ÌGBÉYÀWÓ TÍ Ó TỌ́ Ń MÚ ỌLÁ ÀTI ÀLÀÁFÍÀ WÁ
Ní òde òní, ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin ń gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya láìjẹ́jẹ̀ẹ́ àdéhùn kankan lábẹ́ òfin. Ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ lè dojú kọ irú ipò yìí. Nínú àwọn ipò kan, ẹgbẹ́ àwùjọ tàbí àṣà ìbílẹ̀ lè fọwọ́ sí àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n kò bófin mu. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli béèrè fún ìgbéyàwò tí a fi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí ó tọ́, lábẹ́ òfin. (Titu 3:1; Heberu 13:4) Fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ nínú ìjọ Kristian, Bibeli tún pàṣẹ pé, ọkọ kan àti aya kan péré ni ó gbọ́dọ̀ wà nínú àjọṣepọ̀ ìgbéyàwó kan. (1 Korinti 7:2; 1 Timoteu 3:2, 12) Títẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n yìí ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ sí níní àlàáfíà nínú ilé rẹ. (Orin Dafidi 119:165) Àwọn ohun tí Jehofa ń béèrè fún kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe tàbí ohun tí ń dẹ́rù pani. Ó ṣètò ohun tí ó fi kọ́ wa láti ṣe wá láǹfàání.—Isaiah 48:17, 18.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 130]
Gbìyànjú láti lóye ojú ìwòye ẹnì kejì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 138]
Yálà o jẹ́ òbí ní tààràtà tàbí ti ìgbéyàwó àtúnṣe, gbára lé Bibeli fún ìtọ́sọ́nà