ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ̀kọ́ Wo Làpẹẹrẹ Yín ń Kọ́ni?
    Ilé Ìṣọ́—1999 | July 1
    • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ̀kọ́ Wo Làpẹẹrẹ Yín ń Kọ́ni?

      “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.”—ÉFÉSÙ 5:1, 2.

      1. Irú ìtọ́sọ́nà wo ni Jèhófà pèsè fún àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́?

      JÈHÓFÀ ni Olùdásílẹ̀ ètò ìdílé. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ni ìdílé kọ̀ọ̀kan ti wá, nítorí pé òun ló dá ìdílé àkọ́kọ́ sílẹ̀, tó sì fún tọkọtaya àkọ́kọ́ ní agbára ìbímọ. (Éfésù 3:14, 15) Ó fún Ádámù àti Éfà nítọ̀ọ́ni pàtó nípa iṣẹ́ wọn, ó sì tún fún wọn láǹfààní jaburata láti lo àtinúdá wọn bí wọ́n ti ń bójú tó àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28-30; 2:6, 15-22) Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣẹ̀, ipò tí ìdílé ní láti dojú kọ wá lọ́jú pọ̀ pátápátá. Síbẹ̀, Jèhófà fi ìfẹ́ pèsè ìtọ́sọ́nà tí yóò ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti lè kojú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀.

      2. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi ìtọ́ni tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán kún ìmọ̀ràn táa kọ sílẹ̀? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ káwọn òbí bi ara wọn?

      2 Gẹ́gẹ́ bí Atóbilọ́lá Olùfúnni Nítọ̀ọ́ni wa, Jèhófà ti ṣe ohun tó ju ká kàn pèsè ìtọ́sọ́nà táa ti kọ sílẹ̀, nípa ohun tó yẹ ká ṣe àti èyí tó yẹ ká yẹra fún. Láyé àtijọ́, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì, àtàwọn olórí ìdílé ló lò láti fúnni nítọ̀ọ́ni táa ti kọ sílẹ̀ àti èyí táa fẹnu sọ. Lọ́jọ́ tiwa lónìí, àwọn wo ló ń lò láti fúnni ní irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tí a ń fẹnu sọ? Àwọn Kristẹni alàgbà àti àwọn òbí ló ń lò. Bóo bá jẹ́ òbí, ǹjẹ́ ò ń ṣe ipa tìrẹ láti fún ìdílé rẹ̀ nítọ̀ọ́ni lọ́nà tí Jèhófà là sílẹ̀?—Òwe 6:20-23.

      3. Kí làwọn olórí ìdílé lè rí kọ́ lára Jèhófà ní ti kíkọ́ni lọ́nà tó gbéṣẹ́?

      3 Báwo ló ṣe yẹ ká firú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ni láàárín ìdílé? Jèhófà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Lọ́nà tó ṣe kedere, ó sọ àwọn ohun tó tọ́ táa gbọ́dọ̀ ṣe àti àwọn ohun búburú táa gbọ́dọ̀ sá fún, kò sì tún dẹ́kun sísọ wọ́n ní àsọtúnsọ. (Ẹ́kísódù 20:4, 5; Diutarónómì 4:23, 24; 5:8, 9; 6:14, 15; Jóṣúà 24:19, 20) Ó lo àwọn ìbéèrè tí ń múni ronú jinlẹ̀. (Jóòbù 38:4, 8, 31) Nípasẹ̀ lílo àkàwé àti ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn kan, ó ń ru ìmọ̀lára wa sókè, ó sì ń mọ ọkàn-àyà wa, bí amọ̀kòkò ṣe ń famọ̀ mọ̀kòkò. (Jẹ́nẹ́sísì 15:5; Dáníẹ́lì 3:1-29) Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn nígbà tẹ́ẹ bá ń kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́?

      4. Kí la kọ́ lára Jèhófà ní ti báa ṣe ń báni wí, èé sì ti ṣe tí ìbáwí fi ṣe pàtàkì?

      4 Bó bá dọ̀ràn ohun tó tọ́, Jèhófà kò gba gbẹ̀rẹ́ rárá o, ṣùgbọ́n ó mọ ipa tí àìpé lè ní lórí ẹ̀dá. Nítorí náà, kó tó di pé yóò fìyà jẹ àwọn èèyàn aláìpé, yóò ti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, yóò ti kì wọ́n nílọ̀ léraléra, yóò sì ti tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn létí lọ́pọ̀ ìgbà. (Jẹ́nẹ́sísì 19:15, 16; Jeremáyà 7:23-26) Tó bá sì fẹ́ báni wí, níwọ̀n-níwọ̀n ni yóò ṣe é, kò jẹ́ ṣe é láṣejù. (Sáàmù 103:10, 11; Aísáyà 28:26-29) Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ la ṣe ń báwọn ọmọ wa lò, a jẹ́ pé lóòótọ́ la mọ Jèhófà, á sì wá rọrùn fáwọn náà láti mọ̀ ọ́n.—Jeremáyà 22:16; 1 Jòhánù 4:8.

      5. Kí làwọn òbí lè kọ́ lára Jèhófà nípa fífetísílẹ̀?

      5 Lọ́nà tò yani lẹ́nu, Jèhófà máa ń tẹ́tí sí wa, gẹ́gẹ́ bí Baba onífẹ̀ẹ́ tí ń gbé lókè ọ̀run. Kì í pàṣẹ wàá lásán. Ó máa ń rọ̀ wá pé ká tú ọkàn-àyà wa jáde sóun. (Sáàmù 62:8) Báa bá sì wá fi èrò tí kò tọ́ hàn, kò jẹ́ bú mọ́ wa látòde ọ̀run kí gbogbo ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ló fi ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mà ṣe wẹ́kú o, ó wí pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n”! (Éfésù 4:31–5:1) Ẹ ò rí bí àpẹẹrẹ tí Jèhófà fi lélẹ̀ fáwọn òbí ti dára tó, bí wọ́n ti ń wọ́nà àtifún àwọn ọmọ wọn nítọ̀ọ́ni! Àpẹẹrẹ kan tó wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin ló jẹ́, ọ̀kan tó mú ká fẹ́ rìn ní ọ̀nà ìgbésí ayé tí òun fẹ́.

      Ipa Tí Àpẹẹrẹ Ń Ní Lórí Ẹni

      6. Báwo ni ìwà àti àpẹẹrẹ àwọn òbí ṣe ń nípa lórí àwọn ọmọ wọn?

      6 Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, àpẹẹrẹ tún ń nípa tó jinlẹ̀ lórí àwọn èwe. Báwọn òbí fẹ́, bí wọ́n kọ̀, ó di dandan kí àwọn ọmọ wọn kọ́ àpẹẹrẹ wọn. Èyí lè mú inú òbí dùn—nígbà mí-ìn ó sì lè dà wọ́n lọ́kàn rú—bí wọ́n bá gbọ́ táwọn ọmọ wọn ń sọ ohun táwọn fúnra wọn ti sọ rí. Bí ìwà àti ìṣe àwọn òbí bá fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fáwọn ohun tẹ̀mí, èyí máa ń nípa tó dára lórí àwọn ọmọ.—Òwe 20:7.

      7. Irú àpẹẹrẹ òbí wo ni Jẹ́fútà fi lélẹ̀ fún ọmọbìnrin rẹ̀, kí ló sì yọrí sí?

      7 Bíbélì ṣàkàwé ipa tí àpẹẹrẹ òbí máa ń ní lórí ọmọ. Jẹ́fútà, tí Jèhófà lò láti ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jagun, tó sì ṣẹ́gun fún wọn, jẹ́ olórí ìdílé. Àkọsílẹ̀ táa rí nípa èsì tó fún ọba Ámónì fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jẹ́fútà ti ka ìtàn nípa bí Jèhófà ṣe bá Ísírẹ́lì lò. Ṣe ló ń sọ ìtàn náà bí ẹni pé òun ló kọ ọ́, ó sì fi ìgbàgbọ́ lílágbára tó ní nínú Jèhófà hàn. Kò sí àní-àní pé àpẹẹrẹ tiẹ̀ ló ran ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti nírú ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tó ní, èyí tó mú kó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí àpọ́nbìnrin tó fi gbogbo ayé rẹ̀ fún Jèhófà.—Onídàájọ́ 11:14-27, 34-40; Fi wé Jóṣúà 1:8.

      8. (a) Irú ìṣarasíhùwà rere wo ni àwọn òbí Sámúẹ́lì fi hàn? (b) Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe jàǹfààní?

      8 Táa bá ń sọ̀rọ̀ àwọn ọmọ tó yanjú, àwòfiṣàpẹẹrẹ ni Sámúẹ́lì jẹ́, ó tún jẹ́ wòlíì olóòótọ́ sí Ọlọ́run jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Ṣé ó wù ọ́ kí àwọn ọmọ tìẹ náà yanjú bíi tiẹ̀? Gbé àpẹẹrẹ tí àwọn òbí Sámúẹ́lì, Ẹlikénà àti Hánà, fi lélẹ̀ yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò nǹkan kò gún régé délẹ̀délẹ̀ lágboolé wọn, wọn kì í pa lílọ jọ́sìn ní Ṣílò jẹ, níbi tí àgọ́ ìjọsìn mímọ́ wà. (1 Sámúẹ́lì 1:3-8, 21) Ronú nípa bí ẹ̀mí tí Hánà fi gbàdúrà ti jinlẹ̀ tó. (1 Sámúẹ́lì 1:9-13) Ṣàkíyèsí ojú ìwòye àwọn méjèèjì nípa ìjẹ́pàtàkì mímú ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tí èèyàn bá jẹ́ fún Ọlọ́run ṣẹ. (1 Sámúẹ́lì 1:22-28) Ó dájú pé àpẹẹrẹ rere wọn ran Sámúẹ́lì lọ́wọ́ láti mú àwọn ànímọ́ tó jẹ́ kó lè tọ ọ̀nà tó tọ́ dàgbà—àní nígbà tí àwọn ènìyàn tó yí i ká pàápàá tó yẹ kí wọ́n máa sin Jèhófà kò tiẹ̀ ka ọ̀nà Ọlọ́run sí rárá. Nígbà tó yá, Jèhófà fa ẹrù iṣẹ́ lé Sámúẹ́lì lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 2:11, 12; 3:1-21.

      9. (a) Kí ló ní ipa rere lórí Tímótì nínú ilé wọn? (b) Irú èèyàn wo ni Tímótì wá dà?

      9 Ṣé kò wù ọ́ kí ọmọ rẹ̀ dà bí Tímótì, ẹni tó jẹ́ pé nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti ń bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ pọ̀? Baba Tímótì sì rèé, kì í ṣe onígbàgbọ́, ṣùgbọ́n ìyá tó bí i lọ́mọ àti ìyá-ìyá rẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa fífi ìmọrírì hàn fún nǹkan tẹ̀mí. Ó dájú pé èyí ṣèrànwọ́ gidigidi láti fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún ìgbésí ayé Tímótì gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. A sọ fún wa pé màmá rẹ̀, Yùníìsì, àti ìyá-ìyá rẹ̀ Lọ́ìsì ní “ìgbàgbọ́ . . . láìsí àgàbàgebè kankan.” Ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni kì í ṣe ìgbésí ayé alágàbàgebè; ohun tí wọ́n ń sọ pé àwọn gbà gbọ́ gan-an ni wọ́n ń tẹ̀ lé, wọ́n sì kọ́ Tímótì ọ̀dọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tímótì fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán àti pé òun bìkítà nípa ire àwọn ẹlòmíràn.—2 Tímótì 1:5; Fílípì 2:20-22.

      10. (a) Àpẹẹrẹ wo láti ìta ló lè nípa lórí àwọn ọmọ wa? (b) Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tí a bá kíyè sí irú ìsọ̀rọ̀ àti ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọmọ wa?

      10 Kì í ṣe àwọn àpẹẹrẹ ti inú ilé nìkan ló ń nípa lórí àwọn ọmọ wa. Wọ́n láwọn ọmọ tí wọ́n jọ ń lọ sílé ìwé, àpẹẹrẹ àwọn olùkọ́ wà níbẹ̀ tó jẹ́ pé iṣẹ́ wọn ni láti darí ìrònú àwọn èwe, àwọn èèyàn kan tún wà láwùjọ wọn tó gbà pé gbogbo ènìyàn ló yẹ kó tẹ̀ lé àwọn àṣà ẹ̀yà tàbí ti ẹgbẹ́ àwùjọ tó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, àpẹẹrẹ àwọn ìlú-mọ̀ọ́ká eléré ìdárayá táwọn èèyàn ń gbóṣùbà fún nítorí àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe tún ń bẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni tàwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba táwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń sọ itú tí wọ́n ń pa. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé lojú wọn ti rí màbo níbi tógun gbígbóná ti jà. Ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu bí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá jẹ yọ nínú ọ̀rọ̀ tàbí ìṣarasíhùwà àwọn ọmọ wa? Kí la máa ń ṣe nígbà tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ jíjágbe mọ́ wọn tàbí nínà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀ yanjú ìṣòro yẹn? Dípò tí a óò fi jẹ́ kí ara wa bù máṣọ nítorí ohun táwọn ọmọ wa sọ tàbí ṣe, ǹjẹ́ kò ní dáa ká bi ara wa pé, ‘Ohunkóhun ha wà nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá wa lò, tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ báa ṣe lè yanjú ìṣòro yìí bí?’—Fi wé Róòmù 2:4.

      11. Nígbà táwọn òbí bá ṣàṣìṣe, báwo lèyí ṣe lè nípa lórí ìṣarasíhùwà àwọn ọmọ wọn?

      11 Àmọ́ ṣá o, kò lè jẹ́ ìgbà gbogbo ni àwọn òbí aláìpé yóò máa lo ọ̀nà tó dára jù lọ láti yanjú ìṣòro. Wọ́n á ṣàṣìṣe. Tí àwọn ọmọ bá wá mọ̀ bẹ́ẹ̀, ṣé yóò dín ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fáwọn òbí wọn kù? Ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀ o, báwọn òbí bá gbìyànjú láti fojú bíńtín wo àṣìṣe wọn nípa lílo ọlá àṣẹ wọn lọ́nà lílekoko. Ṣùgbọ́n ìyọrísí rẹ̀ lè yàtọ̀ gidigidi bí àwọn òbí bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba àṣìṣe wọn láìjanpata. Nípa èyí, wọ́n lè fi àpẹẹrẹ tó ṣeyebíye lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n ní láti kọ́ ohun kan náà.—Jákọ́bù 4:6.

      Ẹ̀kọ́ Tí Àpẹẹrẹ Wa Lè Kọ́ni

      12, 13. (a) Kí ló yẹ káwọn ọmọ kọ́ nípa ìfẹ́, báwo la sì ṣe lè fi èyí kọ́ wọn dáadáa? (b) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́?

      12 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye ló wà táa lè kọ́ àwọn ọmọ lọ́nà tó gbéṣẹ́ nígbà tí a bá fi àpẹẹrẹ rere gbe ọ̀rọ̀ ẹnu wa táa fi ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́sẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò.

      13 Fífi Ìfẹ́ Àìmọtara-Ẹni-Nìkan Hàn: Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a lè lo àpẹẹrẹ láti jẹ́ kó túbọ̀ ta gbòǹgbò nínú àwọn ọmọ wa ni ohun tí ìfẹ́ túmọ̀ sí. “Àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí [Ọlọ́run] ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:19) Òun ni Orísun ìfẹ́, òun ló sì fi àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó ga lọ́lá jù lọ hàn. Nínú Bíbélì, ó lé ní ìgbà ọgọ́rùn-ún tí a mẹ́nu kan ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà yìí, tí a ń pè ní a·gaʹpe. Òun ni ànímọ́ táa fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. (Jòhánù 13:35) Ó yẹ ká fi irú ìfẹ́ yẹn hàn sí Ọlọ́run àti Jésù Kristi, ó sì tún yẹ káwọn èèyàn máa fi irú rẹ̀ hàn sí ara wọn lẹ́nì kìíní kejì—àní ó yẹ ká fi hàn sáwọn èèyàn tó jẹ́ pé ara wa kì í fi bẹ́ẹ̀ yá mọ́ wọn. (Mátíù 5:44, 45; 1 Jòhánù 5:3) Ká tó lè fi ìfẹ́ yìí kọ́ àwọn ọmọ wa lọ́nà tó gbéṣẹ́, ìfẹ́ yìí gbọ́dọ̀ wà ní ọkàn-àyà wa, kó sì hàn nínú ìgbésí ayé wa. Àmọ́ ṣá o, ìwà wa ń sọ irú ẹni táa jẹ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu wa lọ. Nínú ìdílé, ó ṣe pàtàkì káwọn ọmọ rí i pé ìfẹ́ wà láàárín wa, kí wọ́n sì mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn, kí wọ́n tún rí àwọn ànímọ́ mìíràn tó fara pẹ́ ẹ, irú bíi jíjẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹni ọ̀wọ́n ni wọ́n jẹ́ sí wa. Bí àwọn ànímọ́ wọ̀nyí kò bá sí, ọmọ lè rán, ọpọlọ rẹ̀ lè máà jí pépé, ó tiẹ̀ lè sọ ìmọ̀lára ọmọ dìdàkudà. Ó tún ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọ rí báa ṣe ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ìdílé wa àti báa ṣe ń fi hàn pé wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n sí wa.—Róòmù 12:10; 1 Pétérù 3:8.

      14. (a) Báwo la ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ láti ṣe ojúlówó iṣẹ́, tó ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá? (b) Báwo lo ṣe lè ṣe èyí nínú ìdílé rẹ?

      14 Kíkọ́ bí a ṣe ń ṣiṣẹ́: Iṣẹ́ jẹ́ apá pàtàkì ìgbésí ayé. Béèyàn bá fẹ́ níyì lọ́wọ́ ara ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kò kọ́ báa ti í ṣe ojúlówó iṣẹ́. (Oníwàásù 2:24; 2 Tẹsalóníkà 3:10) Báa bá ní kí ọmọ ṣiṣẹ́ kan, tó sì jẹ́ pé a ò kọ́ ọ tẹ́lẹ̀ bí yóò ṣe ṣe é, ṣùgbọ́n tí kò wá ṣe é dáadáa, táa sì wá fara ya, táà ń fìbínú sọ̀rọ̀, kò dájú pé yóò kọ́ báa ti í ṣe ojúlówó iṣẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà táwọn ọmọ bá kọ́ nǹkan nípa ṣíṣe é pẹ̀lú àwọn òbí wọn, táa sì gbóríyìn fún wọn lọ́nà tó yẹ, ó dájú pé wọn á mọ́ báa ti ń ṣiṣẹ́ tí ń tẹ́ni lọ́rùn. Báwọn òbí bá tún fi àlàyé kún àpẹẹrẹ tí wọ́n ń fi lélẹ̀, àwọn ọmọ kò wulẹ̀ ní kọ́ bí wọn yóò ṣe rí i pé iṣẹ́ kan di ṣíṣe, ṣùgbọ́n wọn a kọ́ bí wọ́n ṣe lè borí ìṣòro, bí wọ́n ṣe lè tẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣe iṣẹ́ títí tí wọn yóò fi parí ẹ̀, wọn yóò sì kọ́ báa ṣe ń ronú jinlẹ̀ àti báa ti ń ṣèpinnu. Nínú irú ipò yìí, a lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Jèhófà pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́, pé ó ń ṣiṣẹ́ rere, àti pé Jésù ń fara wé Baba rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31; Òwe 8:27-31; Jòhánù 5:17) Bó bá jẹ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ ní ìdílé kan ń ṣe, bó sì jẹ́ òwò ni wọ́n ń ṣe, díẹ̀ lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé náà lè jọ máa ṣiṣẹ́. Tàbí kí màmá máa kọ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń se oúnjẹ àti bí wọ́n ṣe ń palẹ̀ mọ́ lẹ́yìn oúnjẹ. Baba tó jẹ́ pé ó níṣẹ́ síbi tó jìnnà sílé lè ṣètò pé kóun pẹ̀lú àwọn ọmọ òun ṣe iṣẹ́ tí òun ní sílé. Ẹ wo bó ti ṣàǹfààní tó nígbà tí àwọn òbí bá ní in lọ́kàn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní nǹkan lọ́nà tí wọ́n á fi múra wọn sílẹ̀ de ẹ̀yìn ọ̀la, tí kì í kàn-án ṣe pé kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́ báyìí nìkan!

      15. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbàgbọ́? Ṣàkàwé.

      15 Dídi ìgbàgbọ́ mú lójú hílàhílo: Ìgbàgbọ́ pẹ̀lú jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa. Nígbà táa bá jíròrò ìgbàgbọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, àwọn ọmọ lè kọ́ láti mọ báwọn ṣe lè ṣàlàyé rẹ̀. Wọ́n tún lè wá mọ àwọn àmì tó ń fi hàn pé ìgbàgbọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà nínú ọkàn-àyà wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá rí àwọn òbí wọn tí ń fi ìgbàgbọ́ tí kò mì hàn lójú àwọn àdánwò lílekoko, ẹ̀kọ́ yìí lè wà lọ́kàn wọn jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Obìnrin kan wà ní Panama tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí pá a láyà pé òun máa lé e jáde nílé bí kò bá dẹ́kun sísin Jèhófà. Síbẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọmọ kéékèèké mẹ́rin tó ní, ó máa ń fẹsẹ̀ rìn kìlómítà mẹ́rìndínlógún, lẹ́yìn náà ni yóò wá wọ bọ́ọ̀sì fún ọgbọ̀n kìlómítà mìíràn kó tó lè dé Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nítòsí. Nítorí àpẹẹrẹ tó wúni lórí yìí, ogún èèyàn látinú ìdílé rẹ̀ ló ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́.

      Fífi Àpẹẹrẹ Lélẹ̀ Nínú Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́

      16. Èé ṣe táa fi dámọ̀ràn kíka Bíbélì lójoojúmọ́?

      16 Ọ̀kan lára àwọn àṣà tó ṣeyebíye jù lọ tí ìdílé lè dá sílẹ̀—àṣà tí yóò ṣàǹfààní fún àwọn òbí, tí yóò sì jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn ọmọ láti tẹ̀ lé ni—kíka Bíbélì déédéé. Bó ṣe wù kó rí, ka Bíbélì díẹ̀ lójúmọ́. Kì í ṣe bí ibi táa kà ti pọ̀ tó ló ṣe pàtàkì. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni ṣíṣe é déédéé àti ọ̀nà táa gbà ṣe é. Ní ti àwọn ọmọ, ohun tí o lè fi kún Bíbélì kíkà náà ni títẹ́tí sí kásẹ́ẹ̀tì Iwe Itan Bibeli Mi, bó bá wà lédè rẹ. Kíka apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ ká fi èrò Ọlọ́run sọ́kàn. Bó bá sì jẹ́ pé ìdílé lápapọ̀ ló ń ka Bíbélì yìí, tí kì í ṣe pé olúkúlùkù ń dá tiẹ̀ kà, èyí lè ran gbogbo ìdílé náà lọ́wọ́ láti rìn ní ọ̀nà Jèhófà. Ohun tí a rọ̀ wá láti máa ṣe nìyẹn nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ táa wò ní àwọn Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́,” èyí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Ẹ̀yin Ìdílé—Ẹ Jẹ́ Kí Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́ Jẹ́ Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Yín!—Sáàmù 1:1-3.

      17. Báwo ni kíka Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìdílé àti mímọ àwọn ẹsẹ pàtàkì-pàtàkì sórí ṣe ń ṣèrànwọ́ láti fi ìmọ̀ràn  Éfésù 6:4 sọ́kàn?

      17 Kíka Bíbélì papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ nínú lẹ́tà rẹ̀, tí a mí sí, èyí tó kọ sí àwọn Kristẹni ní Éfésù, pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ní ṣáńgílítí, “ìlànà èrò orí” túmọ̀ sí “fífi nǹkan síni lọ́kàn”; nítorí náà a rọ àwọn Kristẹni baba láti fi Jèhófà Ọlọ́run sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn—kí wọ́n ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ èrò Ọlọ́run. Fífún àwọn ọmọ níṣìírí láti mọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì-pàtàkì sórí lè ṣèrànwọ́ láti lè ṣe èyí. Ìdí táa fi ń ṣe èyí ni pé kí èrò Jèhófà lè máa darí èrò àwọn ọmọ, kí ìfẹ́-ọkàn àti ìwà wọn bàa lè máa fi ìlànà Ọlọ́run hàn bí wọ́n ti ń dàgbà yálà àwọn òbí wà pẹ̀lú wọn tàbí wọn kò sí. Bíbélì ló jẹ́ ìpìlẹ̀ fún irú èrò bẹ́ẹ̀.—Diutarónómì 6:6, 7.

      18. Nígbà táa bá ń ka Bíbélì, kí la nílò láti lè (a) lóye rẹ̀ kedere? (b) jàǹfààní láti inú ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀? (d) ṣe àwọn ohun tó fi hàn nípa ète Jèhófà? (e) jàǹfààní láti inú ohun tó sọ nípa ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn?

      18 Àmọ́ ṣá o, bí Bíbélì yóò bá nípa lórí ìgbésí ayé wa, ó pọndandan pé ká mọ ohun tó sọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lo jẹ́ pé kí wọ́n tó lè lóye àwọn ẹsẹ kan wọn gbọ́dọ̀ kà á lọ́pọ̀ ìgbà. Láti lè lóye àwọn gbólóhùn kan dáadáa, ó lè béèrè pé ká yẹ àwọn ọ̀rọ̀ wò nínú ìwé atúmọ̀ èdè tàbí ká lo ìwé náà, Insight on the Scriptures. Bó bá jẹ́ pé ìmọ̀ràn tàbí àṣẹ ló wà nínú ẹsẹ náà, ẹ gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipò òde òní tó mú kó yẹ ní títẹ̀lé. Lẹ́yìn náà, ẹ wá lè béèrè pé, ‘Báwo ni fífi ìmọ̀ràn yìí sílò ṣe lè ṣàǹfààní fún wa?’ (Aísáyà 48:17, 18) Bí ẹsẹ náà bá ń sọ nípa àwọn apá kan nínú ète Jèhófà, ẹ lè béèrè pé, ‘Báwo lèyí ṣe nípa lórí ìgbésí ayé wa?’ Ó sì lè jẹ́ pé àkọsílẹ̀ kan tó sọ nípa ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn ni ẹ̀ ń kà. Wàhálà wo ni wọ́n dojú kọ nínú ìgbésí ayé wọn? Báwo ni wọ́n ṣe kojú rẹ̀? Báwo la ṣe lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ wọn? Gbogbo ìgbà ni kí ẹ máa fàyè sílẹ̀ láti jíròrò ohun tí àkọsílẹ̀ náà túmọ̀ sí nínú ìgbésí ayé wa lóde ìwòyí.—Róòmù 15:4; 1 Kọ́ríńtì 10:11.

      19. Nípa jíjẹ́ aláfarawé Ọlọ́run, kí la óò máa pèsè fún àwọn ọmọ wa?

      19 Ọ̀nà rere lèyí mà jẹ́ láti tẹ èrò Ọlọ́run mọ́ wa lọ́kàn o! Nípa báyìí, a óò lè ràn wá lọ́wọ́ ní ti gidi láti di “aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) A óò sì pèsè àpẹẹrẹ tó yẹ kí àwọn ọmọ wa tẹ̀ lé.

      Ǹjẹ́ O Rántí?

      ◻ Báwo làwọn òbí ṣe lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ Jèhófà?

      ◻ Èé ṣe tó fi yẹ káwọn òbí fi àpẹẹrẹ rere gbe ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà lẹ́sẹ̀?

      ◻ Kí làwọn ẹ̀kọ́ díẹ̀ tó jẹ́ pé nípa àpẹẹrẹ ló dára jù kí àwọn òbí fi wọ́n kọni?

      ◻ Báwo la ṣe lè jàǹfààní ní kíkún láti inú kíka Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìdílé?

  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́—1999 | July 1
    • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé

      “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.”—MÁTÍÙ 4:4.

      1. Kí ni Bíbélì sọ nípa ojúṣe àwọn olórí ìdílé láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀nà Jèhófà?

      LEMỌ́LEMỌ́ ni Jèhófà Ọlọ́run ń rán àwọn olórí ìdílé létí pé, kí wọ́n má ṣe gbàgbé ojúṣe wọn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ yóò mú àwọn ọmọ wọn gbára dì fún ìgbésí ayé ti ìsinsìnyí, ó sì tún lè múra wọn sílẹ̀ fún ìgbésí ayé tí ń bọ̀. Áńgẹ́lì kan tó ń ṣojú fún Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé ojúṣe rẹ̀ ni láti kọ́ agboolé rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọn bàa lè “pa ọ̀nà Jèhófà mọ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:19) A sọ fún àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣàlàyé fáwọn ọmọ wọn, bí Ọlọ́run ṣe dá Ísírẹ́lì nídè kúrò lọ́wọ́ Íjíbítì àti bó ṣe fún wọn ní Òfin ní Òkè Sínáì, ní Hórébù. (Ẹ́kísódù 13:8, 9; Diutarónómì 4:9, 10; 11:18-21) A wá gba àwọn olórí ìdílé Kristẹni níyànjú láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Kódà bó bá jẹ́ pé òbí kan ṣoṣo ló ń sin Jèhófà, ẹnì kan ṣoṣo yẹn gbọ́dọ̀ sapá láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ní ọ̀nà Jèhófà.—2 Tímótì 1:5; 3:14, 15.

      2. Ǹjẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wúlò rárá nínú ìdílé tí kò sọ́mọ? Ṣàlàyé.

      2 Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn ìdílé tí wọ́n ní ọmọ nìkan ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìdílé wà fún. Bí tọkọtaya bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé bí kò tiẹ̀ tíì sí ọmọ láàárín wọn, èyí ń fi hàn pé wọ́n mọrírì àwọn ohun tẹ̀mí gan-an.—Éfésù 5:25, 26.

      3. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé jẹ́ èyí táa ń ṣe déédéé?

      3 Kí nǹkan lè rí bó ti yẹ kó rí, ìkẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ohun táa gbọ́dọ̀ máa ṣe déédéé, èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí Jèhófà kọ́ Ísírẹ́lì nínú aginjù pé: “Ènìyàn kì í tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni ènìyàn fi ń wà láàyè.” (Diutarónómì 8:3) Bí ipò ìdílé bá ṣe rí ni yóò pinnu bí ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn yóò ṣe rí, àwọn ìdílé kan lè ṣètò pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ tàwọn; àwọn mìíràn sì lè gé àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn kúrú ṣùgbọ́n kó jẹ́ lójoojúmọ́. Ètò èyíkéyìí tẹ́ẹ bá ṣe, ẹ má ṣe ní in lọ́kàn pé, ìgbà tí àyè bá wà la lè ṣèkẹ́kọ̀ọ́. ‘Ẹ ra àkókò padà’ nítorí ẹ̀. Bẹ́ẹ bá sa gbogbo ipá yín láti wá àkókò fún un, èrè rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ. Ìwàláàyè àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ wà nínú ewu.—Éfésù 5:15-17; Fílípì 3:16.

      Ète Tó Yẹ Ká Ní Lọ́kàn

      4, 5. (a) Nípasẹ̀ Mósè, kí ni Jèhófà fi síwájú àwọn òbí pé ó jẹ́ ète pàtàkì tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ wọn? (b) Kí ni ìyẹn ń béèrè lónìí?

      4 Nígbákigbà tẹ́ẹ bá fẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín, yóò dáa púpọ̀ bẹ́ẹ bá láwọn ète pàtó lọ́kàn. Gbé díẹ̀ nínú àwọn ohun táa lè ṣe yẹ̀ wò.

      5 Nígbàkigbà tẹ́ẹ bá fẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, wá ọ̀nà láti gbé ìfẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run ró. Nígbà táa pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, kí wọ́n tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè darí àfiyèsí wọn sí ohun tí Jésù Kristi wá pè ní “àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin.” Èwo ni? “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:36, 37; Diutarónómì 6:5) Mósè rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin, kí wọ́n sì fi kọ́ àwọn ọmọ wọn. Ìyẹn á béèrè pé kí wọ́n máa sọ ọ́ lásọtúnsọ, kí wọ́n pe àfiyèsí àwọn ọmọ wọn sí ìdí tí wọ́n fi ní láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìwà àti ìṣe tó lè ṣèdíwọ́ fún fífi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn, bákan náà wọn yóò jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè fi ìfẹ́ hàn fún Jèhófà nínú ìgbésí ayé wọn. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ tiwá nílò irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀? Wọ́n nílò rẹ̀ mọ̀nà! Àwọn náà nílò ìrànlọ́wọ́ láti lè ‘dá adọ̀dọ́ ọkàn-àyà wọn,’ ìyẹn ni pé, kí wọ́n yọ ohunkóhun tó bá máa ṣèdíwọ́ fún ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run kúrò lọ́kàn wọn. (Diutarónómì 10:12, 16; Jeremáyà 4:4) Lára irú àwọn ohun tó lè ṣèdíwọ́ bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ fún àwọn nǹkan ayé àti wíwá àǹfààní láti ri ara wa bọ inú àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀. (1 Jòhánù 2:15, 16) Ìfẹ́ fún Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó múná, ìfẹ́ táa fi hàn, èyí tí ń sún wa láti ṣe ohun tó wu Baba wa ọ̀run. (1 Jòhánù 5:3) Kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ lè ní àǹfààní tí yóò wà fún ìgbà pípẹ́, gbogbo ìgbà tí ẹ bá ń ṣe é lẹ gbọ́dọ̀ ṣe é lọ́nà tí yóò gbà fún ìfẹ́ yìí lókun.

      6. (a) Kí là ń béèrè láti lè gbin ìmọ̀ pípéye sínú àwọn ọmọ? (b) Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìmọ̀ pípéye?

      6 Gbin Ìmọ̀ Pípéye tí Ọlọ́run Ń Béèrè Sí Wọn Lọ́kàn. Kí lèyí ń béèrè? Ohun tó ń béèrè ju pé ká kàn lè ka ìdáhùn jáde nínú ìwé ìròyìn tàbí ìwé kan. Ká tó lè lóye àwọn lájorí ọ̀rọ̀ àti àwọn èrò pàtàkì-pàtàkì lọ́nà tó ṣe kedere, ó sábà máa ń béèrè ìjíròrò tó kúnná. Ìmọ̀ pípéye ṣe pàtàkì gidigidi táa bá fẹ́ gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, ó tún ṣe pàtàkì fún pípọkànpọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù gan-an nígbà táa bá ń yanjú ìṣòro ìgbésí ayé, nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì táa bá fẹ́ ṣe ohun tó wu Ọlọ́run.—Fílípì 1:9-11; Kólósè 1:9, 10; 3:10.

      7. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti mọ bí wọn yóò ṣe fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò? (b) Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe tẹnu mọ́ ìníyelórí irú ète bẹ́ẹ̀?

      7 Kọ́ wọn báa ṣe lè lo ohun táa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Pẹ̀lú ète yìí lọ́kàn, nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, béèrè pé: ‘Báwo lohun táa ń kọ́ yìí ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé wa? Ǹjẹ́ ó ń béèrè pé ká ṣàtúnṣe àwọn ọ̀nà táa gbà ń ṣe nǹkan ní lọ́ọ́lọ́ọ́? Èé ṣe tó fi yẹ ká ṣàtúnṣe?’ (Òwe 2:10-15; 9:10; Aísáyà 48:17, 18) Báa bá ń fún àwọn ohun tí a ń kọ́ ní àfiyèsí tí ó tó, yóò jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú ìdàgbàsókè tẹ̀mí àwọn mẹ́ńbà ìdílé.

      Fi Ọgbọ́n Lo Àwọn Irinṣẹ́ Ẹ̀kọ́

      8. Àwọn irinṣẹ́ wo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà ti pèsè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

      8 “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè irinṣẹ́ rẹpẹtẹ táa lè fi kẹ́kọ̀ọ́. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, táa lè lo pẹ̀lú Bíbélì, wà lédè mọ́kànléláàádóje [131]. Àwọn ìwé táa lè lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lédè mẹ́tàléláàádọ́jọ [153], a ní ìwé pẹlẹbẹ lédè igba ó lé ọgọ́rin àti mẹ́rin [284], kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tísí ń bẹ lédè mọ́kànlélọ́gọ́ta [61], fídíò wà lédè mọ́kànlélógójì [41], èyí tó tún pabanbarì ni ti ètò ìsọfúnni orí kọ̀ǹpútà tó wà fún ṣíṣèwádìí lórí Bíbélì lédè mẹ́sàn-án!—Mátíù 24:45-47.

      9. Báwo la ṣe lè lo ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a yàn sínú ìpínrọ̀ yìí nígbà táa bá ń fi Ilé Ìṣọ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé?

      9 Ọ̀pọ̀ ìdílé ló ń fi àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn múra sílẹ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ti ìjọ. Ìyẹn á mà ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an o! Torí pé inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ni lájorí oúnjẹ tẹ̀mí tí a ń pèsè láti gbé àwọn ènìyàn Jèhófà ró kárí ayé wà. Nígbà tẹ́ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ẹ má fi mọ́ sórí kíka àwọn ìpínrọ̀ àti dídáhùn àwọn ìbéèrè táa tẹ̀ jáde lásán. Ẹ fi tọkàntọkàn wá bí ẹ ó ṣe lóye rẹ̀. Ẹ wáyè láti wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a yàn ṣùgbọ́n tí a kò fà yọ. Ké sí àwọn mẹ́ńbà ìdílé láti sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ṣe kan kókó tó wà nínú ìpínrọ̀ tí à ń gbé yẹ̀ wò. Jẹ́ kí ó wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin.—Òwe 4:7, 23; Ìṣe 17:11.

      10. Kí la lè ṣe láti jẹ́ kí àwọn ọmọ wa kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ àti láti jẹ́ kó jẹ́ àkókò tí yóò tù wọ́n lára?

      10 Bí àwọn ọmọ bá wà nínú ìdílé rẹ, kí lẹ lè ṣe láti mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ yín má wulẹ̀ jẹ́ àṣà ìdílé lásán, ṣùgbọ́n kó jẹ́ àkókò tí ń gbéni ró, tó ń gbádùn mọ́ni, àti àkókò ayọ̀? Gbìyànjú láti jẹ́ kí olúkúlùkù kópa nínú ẹ̀, kí wọ́n bàa lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ẹ̀ ń kọ́. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ṣètò pé kí ọmọ kọ̀ọ̀kan ní Bíbélì àti ìwé ìròyìn tirẹ̀ tí ẹ óò fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Ní ṣíṣàfarawé ìfẹ́ tí Jésù fi hàn, òbí kan lè jẹ́ kí ọmọ kékeré kan jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ òun, ó tilẹ̀ lè rọra fi ọwọ́ gbá ọmọ náà mọ́ra. (Fi wé Máàkù 10:13-16.) Olórí ìdílé lè sọ pé kí ọ̀dọ́mọdé kan ṣàlàyé àwòrán tó wà lójú ìwé tí à ń kẹ́kọ̀ọ́. Kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tó bẹ̀rẹ̀, a lè sọ fún ọmọ tó kéré pé òun ni yóò ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. A lè sọ fún èyí tó dàgbà díẹ̀ láti mẹ́nu kan àwọn àǹfààní tó wà nínú fífi àwọn ohun táa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílò.

      11. Àwọn irinṣẹ́ mìíràn tó wà fún kíkẹ́kọ̀ọ́ la ti pèsè, níbi tí wọ́n bá sì ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó, báwo la ṣe lè lò wọ́n lọ́nà tí yóò ṣàǹfààní fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé?

      11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè lo Ilé Ìṣọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ìjíròrò rẹ, má ṣe gbàgbé àwọn irinṣẹ́ yòókù tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, táa ní ní ọ̀pọ̀ èdè. Bó bá jẹ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni tàbí àlàyé lórí gbólóhùn kan nínú Bíbélì lo fẹ́ mọ̀, ìwé Insight on the Scriptures lè pèsè rẹ̀. A lè dáhùn àwọn ìbéèrè mìíràn nípa yíyẹ ìwé Watch Tower Publications Index wò tàbí nípa lílo ètò ìsọfúnni orí kọ̀ǹpútà tí Society ṣe. Kíkọ́ báa ṣe lè lo àwọn irinṣẹ́ wọ̀nyí, bí wọ́n bá wà lédè rẹ, lè jẹ́ apá ṣíṣeyebíye nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ. Pẹ̀lú èrò àtiru ìfẹ́ àwọn èwe sókè, o tún lè ya àkókò pàtó sọ́tọ̀ láti wo díẹ̀ lára àwọn fídíò Society tó kún fún ẹ̀kọ́, tàbí láti tẹ́tí sílẹ̀ sí apá kan nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó wà nínú kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tísí, lẹ́yìn náà kẹ́ẹ wá jíròrò rẹ̀. Lílo àwọn irinṣẹ́ wọ̀nyí dáadáa fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ gbádùn mọ́ni, kó sì ṣe gbogbo ìdílé láǹfààní.

      Mú Un Bá Ìṣòro Ìdílé Rẹ Mu

      12. Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ṣe ń kó ipa pàtàkì nínú kíkojú àwọn ìṣòro tó ń fẹ́ àmójútó kánjúkánjú nínú ìdílé?

      12 O lè jẹ́ pé àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ tó jẹ́ ti ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ni ìdílé rẹ fi ń kẹ́kọ̀ọ́. Bó ti wù kó rí, rí i pé o mọ ìṣòro tó wà nínú ìdílé rẹ. Tó bá jẹ́ pé màmá wọn kì í lọ síbi iṣẹ́, ó lè ṣeé ṣe fún un láti lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ lójoojúmọ́ nígbà tí wọ́n bá ti ilé ìwé dé. Nípa bẹ́ẹ̀ ó lè yanjú àwọn ìṣòro kan; àwọn mìíràn sì lè túbọ̀ gba àfiyèsí. Nígbà tí àwọn ìṣòro tí ń fẹ́ àmójútó kánjúkánjú bá jẹ yọ nínú ìdílé, má ṣe pa wọ́n tì. (Òwe 27:12) Yàtọ̀ sí àwọn ìṣòro ilé ìwé, àwọn ìṣòro mìíràn tún lè wà lára ìwọ̀nyí. Wá àwọn ọ̀rọ̀ tó bá a mu táa ti tẹ̀ jáde, kí o sì fi ohun tí ẹ óò kẹ́kọ̀ọ́ tó ìdílé rẹ létí.

      13. Èé ṣe tí ìjíròrò ìdílé nípa báa ṣe lè kojú ipò òṣì ṣe lè ṣàǹfààní?

      13 Fún àpẹẹrẹ, apá tó pọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé wà nínú ipò òṣì paraku; nítorí náà ní ọ̀pọ̀ ibi, ó lè pọndandan láti jíròrò báa ṣe lè kojú rẹ̀. Ǹjẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí a gbé ka àwọn ipò nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an àti àwọn ìlànà Bíbélì lè ṣàǹfààní fun agboolé rẹ?—Òwe 21:5; Oníwàásù 9:11; Hébérù 13:5, 6, 18.

      14. Àwọn ipò wo ló lè mú kí ìjíròrò ìdílé nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwà ipá, ogun, àti àìdásí-tọ̀túntòsì àwọn Kristẹni bọ́ sákòókò?

      14 Kókó mìíràn tó yẹ kẹ́ jíròrò ni ìwà ipá. Gbogbo wa ló yẹ ká tẹ ojú ìwòye Jèhófà mọ́ lọ́kàn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13; Sáàmù 11:5) Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lórí kókó yìí lè fún wa láǹfààní láti jíròrò báa ṣe lè kojú àwọn abúmọ́ni nílé ẹ̀kọ́, bóyá ó yẹ ká kọ́ eré ìgbèjà ara-ẹni, àti báa ṣe lè yan eré ìnàjú tó dára. Yánpọnyánrin ti di ohun tó wà káàkiri; ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀-èdè ni ogun abẹ́lé, ìjà òṣèlú tàbí ti ẹ̀yà, tàbí ogun àwọn àjọ ìpàǹpá ti ń jà. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ìdílé rẹ lè nílò ìjíròrò nípa pípa ìwà rere Kristẹni mọ́ nígbà tí ẹ bá bára yín láàárín àwọn ẹgbẹ́ tí ń bára wọn jà.—Aísáyà 2:2-4; Jòhánù 17:16.

      15. Báwo ló ṣe yẹ ká gbé ìtọ́ni nípa ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó kalẹ̀ fáwọn ọmọ?

      15 Báwọn ọmọ ti ń dàgbà, wọ́n nílò ẹ̀kọ́ nípa ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó, èyí tó bá ọjọ́ orí wọn mu. Láwọn àwùjọ kan, èèwọ̀ ni, àwọn òbí kò jẹ́ jíròrò ọ̀ràn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Àwọn ọmọ tí wọn kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀ sì lè gbọ́ ojú ìwòye òdì lọ́dọ̀ àwọn èwe mìíràn, àbájáde rẹ̀ sì lè burú jáì. Ǹjẹ́ kò ní dáa ká kúkú fara wé Jèhófà, ẹni tí kò pẹ́ ọ̀rọ̀ yìí sọ, ṣùgbọ́n tó fúnni nímọ̀ràn tó mọ́yán lórí nípa rẹ̀ nínú Bíbélì? Ìmọ̀ràn Ọlọ́run yóò ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti ní ọ̀wọ̀ ara ẹni, kí wọ́n sì máa buyì fún àwọn ẹ̀yà òdìkejì. (Òwe 5:18-20; Kólósè 3:5; 1 Tẹsalóníkà 4:3-8) Kódà bó bá jẹ́ pé ẹ ti jíròrò àwọn ọ̀ràn yìí rí, má ṣe lọ́tìkọ̀ láti jíròrò ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Bí ipò tuntun bá ti ń dìde, àsọtúnsọ ṣe pàtàkì.

      16. (a) Nínú agboolé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, nígbà wo ni wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé? (b) Ọ̀nà wo lo gbà yanjú àwọn ìṣòro kan kí o bàa lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé?

      16 Ìgbà wo lo dáa ká máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé? Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì yíká ayé, ọ̀pọ̀ ìdílé ṣètò ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Monday fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn. Àwọn mìíràn yan ọjọ́ tó yàtọ̀. Ní Ajẹntínà, ìdílé ẹlẹ́ni mọ́kànlá, tí wọ́n ní ọmọ mẹ́sàn-án, máa ń jí ní aago márùn-ún ìdájí láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn. Nítorí àkókò iṣẹ́ wọn tó yàtọ̀ síra, kò sí àkókò mìíràn tí wọ́n lè fi sí. Lóòótọ́ kò rọrùn, ṣùgbọ́n ètò yìí jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ̀ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ṣe pàtàkì, ó ṣe kókó. Ní orílẹ̀-èdè Philippines, alàgbà kan darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé pẹ̀lú aya rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bí wọ́n ti ń dàgbà. Láàárín ọ̀sẹ̀, àwọn òbí tún máa ń bá ọmọ kọ̀ọ̀kan ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tirẹ̀, káwọn ọmọ náà bàa lè sọ òtítọ́ di tiwọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, arábìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí máa ń mú àwọn ọmọ rẹ̀ lọ wọkọ̀ ilé ẹ̀kọ́ lárààárọ̀. Nígbà tí wọ́n bá ń dúró de ọkọ̀, wọ́n máa ń lo nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá pa pọ̀ láti ka àwọn ẹ̀kọ́ táa gbé ka Ìwé Mímọ́, tó bá ipò wọn mu, wọn á sì jíròrò rẹ́, lẹ́yìn náà màmá wọn á wá gbàdúrà ṣókí káwọn ọmọ náà tó wọkọ̀. Ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Kóńgò, obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ti pa ìdílé náà tì, ní láti ṣiṣẹ́ àṣekára láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nítorí pé kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé. Ọmọkùnrin rẹ̀ tó ti dàgbà ṣèrànwọ́ nípa bíbẹ ìdílé náà wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí màmá rẹ̀ àti àwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin yóò kópa nínú rẹ̀. Màmá náà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa mímúra sílẹ̀ dáadáa. Ǹjẹ́ àwọn ipò kan wà tó mú kí ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ṣòro nínú agboolé rẹ? Máà jẹ́ kó rẹ̀ ọ́. Máa fi taratara wá ìbùkún Jèhófà lórí ìsapá rẹ láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ẹ̀ ń ṣe déédéé.—Máàkù 11:23, 24.

      Èrè Àìṣàárẹ̀

      17. (a) Kí o bàa lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tó ń lọ déédéé, kí là ń béèrè? (b) Ìrírí wo ló ṣàkàwé ìníyelórí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí à ń ṣe déédéé lọ́nà tí Jèhófà fẹ́?

      17 Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí a ń ṣe déédéé ń béèrè ìwéwèé. Ó béèrè pé ká má ṣàárẹ̀. Ṣùgbọ́n àǹfààní tí ń wá láti inú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, ó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Òwe 22:6; 3 Jòhánù 4) Franz àti Hilda, tí wọ́n wà ní Germany, tọ́ ìdílé ọlọ́mọ mọ́kànlá dàgbà. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ọmọbìnrin wọn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Magdalena wí pé: “Ohun tí mo gbà pé ó ṣe pàtàkì jù lọ lónìí ni pé ilẹ̀ ọjọ́ kan kò ní mọ́ ká má gba ìtọ́ni nípa tẹ̀mí.” Nígbà tí ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni di èyí tó gbóná janjan lábẹ́ ìjọba Adolf Hitler, baba Magdalena lo Bíbélì láti mú kí ìdílé rẹ̀ gbára dì fún ìdánwò tó mọ̀ pé ó ń bọ̀. Kò pẹ́ púpọ̀, àwọn aláṣẹ fipá kó àwọn ọmọ kéékèèké inú ilé náà kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, wọ́n kó wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ atúnniṣe; wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn tó ṣẹ́ kù, wọ́n tì wọ́n mọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n àti àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Wọ́n pa díẹ̀ lára wọn. Gbogbo wọn ló di ìgbàgbọ́ wọn mú—kì í ṣe lákòókò inúnibíni gbígbóná janjan yẹn nìkan ṣoṣo ṣùgbọ́n, láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e pàápàá, àwọn tó là á já lára wọn kò sọ ìgbàgbọ́ nù.

      18. Báwo la ṣe san èrè fún ìsapá àwọn òbí kan tí wọ́n jẹ́ anìkàntọ́mọ?

      18 Ọ̀pọ̀ òbí anìkàntọ́mọ, àti àwọn mìíràn tí ọkọ tàbí aya wọn kò tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn wọn, máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ déédéé láti inú Bíbélì. Obìnrin opó kan ní Íńdíà, tó jẹ́ anìkàntọ́mọ, ṣíṣẹ kára láti gbin ìfẹ́ fún Jèhófà sínú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kọ̀, tí kò dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Jèhófà mọ́, ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́. Ó bẹ Jèhófà pé kó dákun kó dárí ji òun fún àṣìṣe èyíkéyìí tóun ti lè ṣe lọ́nà tí òun gba tọ́ ọmọ náà. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé ọmọ náà ti gbà gbé ohun tó ti kọ́ pátápátá. Lẹ́yìn ohun tó lé lọ́dún mẹ́wàá, ọmọkùnrin táà ń wí yìí padà wá, ó tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí, ó sì di alàgbà nínú ìjọ. Ní báyìí, aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún ni òun àtìyàwó ẹ̀. Ayọ̀ ńláǹlà ló máa ń jẹ́ fún irú àwọn òbí yìí, àwọn tí wọ́n fi ìmọ̀ràn Jèhófà àti ti ètò àjọ rẹ̀ sọ́kàn láti máa pèsè ìtọ́ni Bíbélì fún agbo ìdílé wọn déédéé! Ǹjẹ́ ò ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò nínú ìdílé rẹ?

      Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

      ◻ Èé ṣe tí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé fi ṣe pàtàkì?

      ◻ Kí ló yẹ kó jẹ́ ète wa nígbàkigbà táa bá fẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé?

      ◻ Àwọn irinṣẹ́ wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún wa, táa lè fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́?

      ◻ Báwo la ṣe lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ìṣòro ìdílé mu?

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

      Níní ète pàtó lọ́kàn yóò mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ̀ sunwọ̀n sí i

  • Ẹ̀yin Ìdílé, Ẹ Máa Yin Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Apá kan Ìjọ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—1999 | July 1
    • Ẹ̀yin Ìdílé, Ẹ Máa Yin Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Apá kan Ìjọ Rẹ̀

      “Inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni èmi yóò ti máa fi ìbùkún fún Jèhófà.”—SÁÀMÙ 26:12.

      1. Yàtọ̀ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ àti gbígbàdúrà nínú ilé, apá wo ló tún ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́?

      ÌJỌSÌN Jèhófà kò mọ sórí gbígbàdúrà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé nìkan, ìgbòkègbodò gẹ́gẹ́ bí apá kan ìjọ Ọlọ́run tún wà níbẹ̀. A pàṣẹ fún Ísírẹ́lì ìgbàanì láti “pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké,” láti wá kọ́ òfin Ọlọ́run, kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀. (Diutarónómì 31:12; Jóṣúà 8:35) Àtarúgbó àti ‘ọ̀dọ́kùnrin àti wúńdíá’ la rọ̀ láti nípìn-ín nínú yíyin orúkọ Jèhófà. (Sáàmù 148:12, 13) Irú ètò kan náà ló wà nínú ìjọ Kristẹni. Nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba jákèjádò ayé, àwọn ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọmọdé máa ń kópa fàlàlà nínú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí àwùjọ lè lóhùn sí, tayọ̀tayọ̀ lọ̀pọ̀lọpọ̀ sì fi ń ṣe é.—Hébérù 10:23-25.

      2. (a) Èé ṣe tí ìmúrasílẹ̀ fi jẹ́ kókó pàtàkì nínú ríran àwọn èwe lọ́wọ́ láti gbádùn àwọn ìpàdé? (b) Àpẹẹrẹ ta ló ṣe pàtàkì jù?

      2 Àmọ́ ṣá o, ríran àwọn èwe lọ́wọ́ láti kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ tó gbámúṣe lè jẹ́ ìpèníjà. Táwọn ọmọ kan tó ń bá àwọn òbí wọn wá sípàdé kì í bá gbádùn ìpàdé náà ńkọ́, kí lò lè jẹ́ ìṣòro wọn? Ká sòótọ́, àwọn ọmọdé tó pọ̀ jù lọ ló jẹ́ pé wọn kò lè pọkàn pọ̀ lọ títí, nǹkan kì í sì í pẹ́ sú wọn. Ṣùgbọ́n, ìmúrasílẹ̀ lè mú kí ìṣòro yìí ṣeé yanjú. Bí a kò bá múra ìpàdé sílẹ̀, àwọn ọmọ kò ní lè kópa nínú ẹ̀ lọ́nà tó nítumọ̀. (Òwe 15:23) Bí kò bá sì sí ìmúrasílẹ̀, yóò ṣòro fún wọn láti ní ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí lọ́nà tí yóò fi tẹ́ wa lọ́rùn. (1 Tímótì 4:12, 15) Kí la wá lè ṣe? Èkíní, káwọn òbí bi ara wọn léèrè bóyá àwọn pàápàá ń múra ìpàdé sílẹ̀. Àpẹẹrẹ wọn lè nípa tó lágbára gan-an lórí àwọn ọmọ. (Lúùkù 6:40) Ṣíṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé dáadáa tún jẹ́ kókó pàtàkì tó lè ṣèrànwọ́.

      Sísọ Ọkàn-Àyà Ẹni Di Alágbára

      3. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, èé ṣe tó fi yẹ ká sapá gidigidi láti sọ ọkàn-àyà di alágbára, kí sì ni èyí ń béèrè?

      3 Kò yẹ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé jẹ́ àkókò tí a óò wulẹ̀ máa rọ́ ìmọ̀ síni lórí ṣùgbọ́n ó yẹ kó jẹ́ àkókò tí a óò fi sọ ọkàn-àyà ẹni di alágbára. Èyí ń béèrè pé ká mọ ìṣòro táwọn mẹ́ńbà ìdílé dojú kọ, ká sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ olúkúlùkù wọn. Jèhófà ni “olùṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà.”—1 Kíróníkà 29:17.

      4. (a) Kí ló túmọ̀ sí táa bá sọ pé ‘ọkàn-àyà kù fún ẹnì kan’? (b) Kí ló wé mọ́ ‘jíjèrè ọkàn-àyà’?

      4 Kí ni Jèhófà lè rí bó bá yẹ ọkàn-àyà àwọn ọmọ wa wò? Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni yóò wí pé, àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ohun tó dára nìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀, ìwọ̀nba ni ìrírí tí ọ̀dọ́mọdé tàbí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ní nípa ọ̀nà Jèhófà. Nítorí pé kò nírìírí, ‘ọkàn-àyà lè kù fún un,’ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ ọ́. Lóòótọ́, gbogbo èrò-ọkàn rẹ̀ lè máà burú, ṣùgbọ́n kí ẹnì kan tó lè mú ọkàn-àyà rẹ̀ wá sí ipò tí yóò wu Ọlọ́run, yóò ná onítọ̀hún lákòókò. Èyí ń béèrè pé kí onítọ̀hún mú ìrònú rẹ̀, ohun tó wù ú, ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, ìmọ̀lára rẹ̀, àti àwọn góńgó rẹ̀ bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu, dé àyè tó ṣeé ṣe fún èèyàn aláìpé. Nígbà tẹ́nìkan bá ṣe ẹni ti inú rẹ̀ bẹ́ẹ̀, lọ́nà tí ó wu Ọlọ́run, ó “ń jèrè ọkàn-àyà” nìyẹn.—Òwe 9:4; 19:8.

      5, 6. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti “jèrè ọkàn-àyà”?

      5 Ǹjẹ́ àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti “jèrè ọkàn-àyà”? Lóòótọ́, kò séèyàn tó lè fi ipò ọkàn-àyà tó dáa sínú ẹlòmíràn. Olúkúlùkù wa la fi òmìnira ìfẹ́-inú jíǹkí, ọ̀pọ̀ nǹkan tí à ń ṣe ló sì sinmi lé ohun tí a bá fàyè gba ara wa láti ronú lé lórí. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn òbí lè lo ìfòyemọ̀ láti mú kí ọmọ kan sọ̀rọ̀ jáde, kí wọ́n fi lè mọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀ àti ibi tó ti nílò ìrànlọ́wọ́. Lo àwọn ìbéèrè bí ‘Kí lèrò rẹ nípa èyí?’ àti ‘Kí ló tiẹ̀ wù ẹ́ láti ṣe?’ Lẹ́yìn náà, fara balẹ̀, jẹ́ kó sọ̀rọ̀. Máà jẹ́ kí ara rẹ gbóná jù. (Òwe 20:5) Ipò tí ó fi inú rere, òye, àti ìfẹ́ hàn ṣe pàtàkì bóo bá fẹ́ dé inú ọkàn-àyà ènìyàn.

      6 Kóo lè sọ èrò-ọkàn wọn di èyí tó gbámúṣé, máa jíròrò àwọn èso tẹ̀mí déédéé pẹ̀lú wọn—mú un lọ́kọ̀ọ̀kan—kí ẹ sì máa ṣiṣẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé láti lè mú un dàgbà. (Gálátíà 5:22, 23) Gbé ìfẹ́ fún Jèhófà àti Jésù Kristi ró nínú wọn, kì í ṣe nípa wíwulẹ̀ sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ wọn ṣùgbọ́n nípa jíjíròrò àwọn ìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ wọn àti ọ̀nà táa lè gbà fi ìfẹ́ yẹn hàn. (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Mú kí ìfẹ́ wọn láti ṣe ohun tó tọ́ lágbára sí i nípa ríronú lórí àǹfààní tí yóò tibẹ̀ jáde. Mú kí ìfẹ́ láti kórìíra èrò búburú, ọ̀rọ̀ burúkú, àti ìwà abèṣe dàgbà nínú wọn nípa jíjíròrò àwọn jàǹbá tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè fà. (Ámósì 5:15; 3 Jòhánù 11) Fi hàn bí ìrònú, ọ̀rọ̀ ẹnu, àti ìwà—ì báà jẹ́ rere tàbí búburú—ṣe lè nípa lórí ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà.

      7. Kí la lè ṣe láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro àti láti ṣe ìpinnu lọ́nà tí wọn kò fi ní jìnnà sí Jèhófà?

      7 Nígbà tí ọmọ kan bá níṣòro tàbí bá ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì kan, a lè béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Ojú wo lo rò pé Jèhófà yóò fi wò ó? Kí lo mọ̀ nípa Jèhófà tóo fi sọ bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ o ti gbàdúrà sí i nípa rẹ̀?’ Tí o kò bá jẹ́ kó dìgbà táwọn ọmọ ti di géńdé kóo tó ràn wọ́n lọ́wọ́, yóò jẹ́ kí wọ́n lè gbé ìgbésí ayé kan tí wọn yóò fi tètè sapá láti mọ ìfẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n a sì ṣe é. Bí wọ́n ti ń di ẹni tó ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, inú wọn yóò máa dùn láti máa rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀. (Sáàmù 119:34, 35) Èyí yóò mú kí wọ́n mú ìmọrírì dàgbà fún àǹfààní tí wọ́n ní láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ Ọlọ́run tòótọ́.

      Mímúra Àwọn Ìpàdé Ìjọ Sílẹ̀

      8. (a) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi gbogbo ohun tó ń fẹ́ àfiyèsí kún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa? (b) Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe pàtàkì tó?

      8 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ ká fún láfiyèsí nígbà táa bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Báwo lo ṣe lè mọ gbogbo wọn? Kò ṣeé ṣe láti ṣe ohun gbogbo lọ́wọ́ kan náà. Ṣùgbọ́n ó lè rọrùn díẹ̀ tóo bá lè ní àkọọ́lẹ̀ kékeré kan. (Òwe 21:5) Máa yẹ̀ ẹ́ wò lóòrèkóòrè, kóo sì ronú lórí ohun tó yẹ ká pàfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí. Nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ nínú ìtẹ̀síwájú mẹ́ńbà ìdílé kọ̀ọ̀kan. Ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí a ń jíròrò yìí jẹ́ apá pàtàkì nínú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó wà fáwọn Kristẹni, èyí tó ń mú wa gbára dì fún ìgbésí ayé ìsinsìnyí, tó tún ń múra wa sílẹ̀ fún ìyè ayérayé tí ń bọ̀.—1 Tímótì 4:8.

      9. Àwọn góńgó wo tó ní í ṣe pẹ̀lú mímúra ìpàdé sílẹ̀ ni a lè ṣiṣẹ́ lé lórí nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa?

      9 Ǹjẹ́ o fi mímúra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀ kún ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ? Bí ẹ ti ń kẹ́kọ̀ọ́ pọ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ lè ṣiṣẹ́ lé lórí ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Àwọn kan lára wọn lè gba ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, oṣù, kódà ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá kẹ́ẹ tó parí ẹ̀. Gbé àwọn góńgó wọ̀nyí yẹ̀ wò: (1) kí olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé múra láti dáhùn nínú ìpàdé ìjọ; (2) kí olúkúlùkù rí i pé òun dáhùn ní ọ̀rọ̀ ara òun; (3) kí olúkúlùkù lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú ìdáhùn rẹ̀; àti (4) kí olúkúlùkù lè fọ́ ọ̀rọ̀ sí wẹ́wẹ́ láti jẹ́ ká mọ bí a óò ṣe fi sílò. Gbogbo èyí ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ó sọ òtítọ́ di tara rẹ̀.—Sáàmù 25:4, 5.

      10. (a) Báwo la ṣe lè fún gbogbo ìpàdé ìjọ wa ní àfiyèsí? (b) Èé ṣe tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ fi tọ́?

      10 Kódà bó bá jẹ́ pé orí ẹ̀kọ́ tí a óò kọ́ láàárín ọ̀sẹ̀, èyí tí ń bẹ nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ni ẹ ń gbé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín kà, ẹ má ṣe fojú kéré mímúra sílẹ̀ fún Ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, yálà lẹ́nìkọ̀ọ̀kan tàbí gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú jẹ́ apá pàtàkì nínú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ táa ṣe fún wa, ká lè máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà. O lè ṣeé ṣe fún yín láti máa múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbo ìdílé lóòrèkóòrè. Èé ṣe? Bẹ́ẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, ẹ óò túbọ̀ jáfáfá sí i lọ́nà tí ẹ gbà ń kẹ́kọ̀ọ́. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ẹ óò jèrè ọ̀pọ̀ àǹfààní láti inú àwọn ìpàdé náà. Ìyẹn nìkan kọ́, ẹ jíròrò àwọn àǹfààní tó wà nínú mímúra ìpàdé sílẹ̀ déédéé àti ìjẹ́pàtàkì níní àkókò pàtó tí a yà sọ́tọ̀ fún un.—Éfésù 5:15-17.

      11, 12. Báwo ni mímúra sílẹ̀ fún orin tí a óò kọ nínú ìjọ ṣe lè ṣe wá láǹfààní, báwo la sì ṣe lè ṣe èyí?

      11 Nínú àwọn Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́,” a rọ̀ wá láti máa múra apá mìíràn nínú àwọn ìpàdé wa sílẹ̀—ìyẹn ni orin kíkọ. Ǹjẹ́ o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ òtítọ́ Bíbélì mọ́ wa lọ́kàn, kí a sì túbọ̀ gbádùn àwọn ìpàdé ìjọ.

      12 Ìmúrasílẹ̀ tó wé mọ́ kíka ọ̀rọ̀ orin táa fẹ́ kọ nípàdé jáde àti jíjíròrò ìtumọ̀ wọn lè ràn wá lọ́wọ́ láti kọrin jáde láti inú ọkàn-àyà wa. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, wọ́n ń lo àwọn ohun èlò orin dáadáa nínú ìjọsìn. (1 Kíróníkà 25:1; Sáàmù 28:7) Ǹjẹ́ ẹ lẹ́nìkan nínú ìdílé yín tó mọ ohun èlò orin kan lò? Kí ló de ti ẹ̀ ò lo ohun èlò orin yẹn láti fi àwọn orin Ìjọba tí ẹ óò kọ lọ́sẹ̀ náà dánra wò, kí ẹ sì wá jùmọ̀ kọrin náà gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ohun mìíràn tẹ́ẹ tún lè ṣe ni pé kí ẹ lo ohùn orin táa ti gbà sílẹ̀. Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn ara wa ń kọ orin lọ́nà tó dùn jọjọ tí wọn ò sì ní lo ohun èlò ìkọrin èyíkéyìí. Bí wọ́n bá ń rìn lójú ọ̀nà tàbí tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ nínú oko, wọ́n sábà máa ń gbádùn kíkọ àwọn orin tí a óò kọ nípàdé ìjọ lọ́sẹ̀ yẹn.—Éfésù 5:19.

      Bí Ìdílé Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Sílẹ̀

      13, 14. Èé ṣe tí ìjíròrò ìdílé tó múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá fi ṣe pàtàkì?

      13 Jíjẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jèhófà àti ète rẹ̀ jẹ́ apá pàtàkì mìíràn nínú ìgbésí ayé wa. (Aísáyà 43:10-12; Mátíù 24:14) Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, báa bá múra ìgbòkègbodò yìí sílẹ̀, a óò gbádùn rẹ̀ dáadáa, a óò sì lè kẹ́sẹ járí. Báwo la ṣe lè ṣe èyí nínú ìdílé?

      14 Gẹ́gẹ́ bó ti máa ń rí nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa, ó ṣe pàtàkì láti múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀. Kì í ṣe ohun táa fẹ́ ṣe nìkan ló yẹ ká jíròrò ṣùgbọ́n ó tún yẹ ká jíròrò ìdí táa fi fẹ́ ṣe é. Lọ́jọ́ Jèhóṣáfátì Ọba, a fún àwọn ènìyàn ní ìtọ́ni láti inú òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Bíbélì sọ fún wa pé wọn “kò . . . tíì múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀.” Èyí mú kí àwọn ohun tó lè fà wọ́n kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ tètè fà wọ́n lọ. (2 Kíróníkà 20:33; 21:11) Góńgó wa kì í ṣe ká kàn ròyìn wákàtí táa lò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, tàbí ká kàn fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbọ́dọ̀ jẹ́ fífi ìfẹ́ hàn sí Jèhófà àti sí àwọn èèyàn tí wọ́n láǹfààní láti yan ìyè. (Hébérù 13:15) Ó jẹ́ ìgbòkègbodò kan táa ti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 3:9) Àǹfààní ńláǹlà mà lèyí jẹ́ o! Báa ti ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, a ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́. (Ìṣípayá 14:6, 7) Àkókò wo ni a tún lè ní láti gbé ìmọrírì wa ró fún èyí bí kò ṣe ìgbà tí a bá ń jíròrò nínú ìdílé, yálà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí nígbà táa bá ń jíròrò ẹsẹ tó jẹ mọ́ ọn láti inú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́!

      15. Nígbà wo la lè múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá gẹ́gẹ́ bí ìdílé?

      15 Nígbà mìíràn, ǹjẹ́ ẹ máa ń lo àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín láti ran àwọn mẹ́ńbà ìdílé yín lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá tọ̀sẹ̀ náà? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣàǹfààní púpọ̀. (2 Tímótì 2:15) Ó lè ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìsìn wọn nítumọ̀, kó sì méso jáde. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè ya odidi àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ kan sọ́tọ̀ fún irú ìmúrasílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé o lè sọ̀rọ̀ ṣókí lórí apá tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá tàbí kóo sọ ọ́ ní àwọn àkókò mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀.

      16. Jíròrò ìjẹ́pàtàkì ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí.

      16 Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lè dá lórí onírúurú ìgbésẹ̀, irú bí àwọn tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí: (1) Múra ọ̀rọ̀ kan táa gbé kalẹ̀ dáadáa sílẹ̀, kí o sì fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nínú Bíbélì tí a óò kà kún un bí àyè bá yọ̀ǹda. (2) Rí i dájú pé tó bá ṣeé ṣe, olúkúlùkù ní àpò òde ẹ̀rí, Bíbélì, ìwé ìkọ-nǹkan-sí, kálàmù tàbí pẹ́ńsù, ìwé àṣàrò kúkúrú, àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó bójú mu. Kò pọndandan kí àpò òde ẹ̀rí jẹ́ olówó ńlá, àmọ́ o yẹ kó ṣeé rí mọ́ni. (3) Jíròrò ibi tẹ́ẹ ti lè jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà àti bí ẹ óò ṣe ṣe é. Tẹ̀ lé ìpele kọ̀ọ̀kan nínú ìtọ́ni yìí fún àkókò tí ẹ óò fi ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Fún wọn ní ìmọ̀ràn tó lè ṣèrànwọ́, ṣùgbọ́n máà jẹ́ kí ìmọ̀ràn rẹ pọ̀ jù.

      17, 18. (a) Irú ìmúrasílẹ̀ wo ló lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá wa túbọ̀ méso jáde? (b) Apá wo nínú ìmúrasílẹ̀ yìí la lè máa ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?

      17 Apá pàtàkì nínú iṣẹ́ tí Jésù Kristi yàn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20) Ohun tó wé mọ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ju wíwàásù lọ. Ó ń béèrè kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbéṣẹ́ nínú ṣíṣe èyí?

      18 Gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ẹ jíròrò ẹni tí ó dáa kí ẹ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. Àwọn kan lára wọn ti lè gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́; ó sì lè jẹ́ pé àwọn kan kàn tẹ́tí sílẹ̀ ni. Ó lè jẹ́ pé ẹnu iṣẹ́ ilé dé ilé lẹ ti bá wọn pàdé tàbí kó jẹ́ lẹ́nu ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà nínú ọjà tàbí nílé ẹ̀kọ́. Ẹ jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ṣamọ̀nà yín. (Sáàmù 25:9; Ìsíkíẹ́lì 9:4) Ẹ pinnu ẹni tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín fẹ́ lọ bẹ̀ wò lọ́sẹ̀ yẹn. Kí lẹ óò jọ sọ? Ìjíròrò ìdílé lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan yín lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀. Ẹ kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ẹ fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn sílẹ̀ àti àwọn kókó yíyẹ láti inú ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Má gbìyànjú àtisọ̀rọ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan. Béèrè ìbéèrè tí onílé yóò máa ronú lé lórí di ìgbà mí-ìn lọ́wọ́ rẹ̀. Èé ṣe tí ẹ kò fi ìpadàbẹ̀wò tí olúkúlùkù yóò ṣe kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdílé yín lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ìgbà tí ẹ óò lọ síbẹ̀, àti ohun tí ẹ retí láti ṣe níbẹ̀. Ṣíṣe èyí lè jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ti ìdílé lápapọ̀ túbọ̀ méso jáde.

      Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Fífi Ọ̀nà Jèhófà Kọ́ni

      19. Bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá fẹ́ máa bá a nìṣó ní rírìn ní ọ̀nà Jèhófà, kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ nírìírí rẹ̀, kí ló sì ń pa kún èyí?

      19 Ìpèníjà ńlá ló jẹ́ láti jẹ́ olórí ìdílé nínú ayé búburú yìí. Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò sinmi láti rí i pé àwọn ba ipò tẹ̀mí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ́. (1 Pétérù 5:8) Ìyẹn nìkan kọ́, àní lónìí, wàhálà pọ̀ lọ́rùn ẹ̀yin òbí, pàápàá ẹ̀yin òbí anìkàntọ́mọ. Ó ṣòro fún yín láti ráyè ṣe gbogbo ohun tẹ́ẹ fẹ́ ṣe. Àmọ́ gbogbo akitiyan wọ̀nyẹn yẹ ní ṣíṣe, kódà bó bá jẹ́ pé ìmọ̀ràn kan péré lẹ lè lò lẹ́ẹ̀kan, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yóò mú kí ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín sunwọ̀n sí i. Rírí i pé àwọn tó sún mọ́ ọ ń fi tòótọ́tòótọ́ rìn ní ọ̀nà Jèhófà jẹ́ èrè tí ń mọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Láti lè kẹ́sẹ járí ní ọ̀nà Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé rí ayọ̀ nínú wíwà nínú àwọn ìpàdé ìjọ àti nínú kíkópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Bí ìyẹn yóò bá ṣẹlẹ̀, ìmúrasílẹ̀ ṣe pàtàkì—ìmúrasílẹ̀ tí ń sọ ọkàn-àyà wa di alágbára, tó sì ń mú wa gbára dì láti kópa tó nítumọ̀.

      20. Kí ló lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ní irú ayọ̀ tí a sọ nínú 3 Jòhánù 4?

      20 Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ti ràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, ó kọ̀wé pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 4) Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé táa ṣe pẹ̀lú àwọn ète tó ṣe kedere lọ́kàn àti àwọn olórí ìdílé tí wọ́n jẹ́ onínúure, tí wọ́n sì ṣe tán láti ṣèrànwọ́ láti yanjú ìṣòro olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé lè ṣe bẹbẹ láti ran ìdílé lọ́wọ́ láti nípìn-ín nínú irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀. Nípa mímú ìmọrírì dàgbà fún ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́, àwọn òbí lè ran ìdílé wọn lọ́wọ́ láti gbádùn ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ.—Sáàmù 19:7-11.

      Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

      ◻ Èé ṣe tí ìmúrasílẹ̀ fún ìpàdé fi ṣe pàtàkì fáwọn ọmọ wa?

      ◻ Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti “jèrè ọkàn-àyà”?

      ◻ Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún gbogbo ìpàdé?

      ◻ Báwo ni mímúra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá gẹ́gẹ́ bí ìdílé ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jáfáfá?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́