-
Ìdí Tí Wọn Fi Ń hùwà ipáIlé Ìṣọ́—1998 | November 1
-
-
orí tẹlifíṣọ̀n wa ń fi dá àwọn ọmọ wa lára yá. Kì í ṣe pé a ń fàyè gba ìwà ipá nìkan ni! Ẹ̀yin ènìyàn mi, ó ń dùn mọ́ wa.”
Àwọn ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ tí a ṣe ní ìlànà sáyẹ́ǹsì sọ pé, àgbékalẹ̀ ọpọlọ àti àyíká para pọ̀ ń nípa lórí ìwà ipá tí ènìyàn ń hù. Ọ̀mọ̀wé Markus J. Kruesi, láti Ẹ̀ka Ìwádìí Ọ̀rọ̀ Àwọn Èwe ní Yunifásítì Illinois sọ pé: “Ibi tí gbogbo wa bẹ̀rẹ̀ sí í fẹnu kò sí ni pé, àwọn àyíká eléwu tí àwọn ọmọ tí ń pọ̀ sí i ń bá ara wọn ń mú kí ìwà ipá gbilẹ̀ sí i ní gidi. Àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ láyìíká ń fa àwọn ìyípadà molecule inú ọpọlọ lọ́nà tí ń mú kí àwọn ènìyàn máa hùwà láìro àbájáde rẹ̀ wò.” Ìwé Inside the Brain sọ pé, àwọn kókó bí “ìṣètò ìdílé tí ó forí ṣánpọ́n, ìdílé olóbìí kan tí ń pọ̀ sí i, ipò òṣì tí kò yí padà, àti ìjoògùnyó tó ti di bárakú lè mú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ọpọlọ tẹ̀ sí híhùwà ipá—ohun kan tí a ti rò pé kò lè ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀.”
Wọ́n sọ pé, lára àwọn ìyípadà inú ọpọlọ náà ni ìdínkù nínú ìwọ̀n èròjà serotonin, kẹ́míkà kan tó wà nínú ọpọlọ, tí a rò pé ó máa ń tẹ ìbínú rì. Àwọn ìwádìí fi hàn pé ọtí líle lè dín ìwọ̀n èròjà serotonin inú ọpọlọ kù, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fúnni ní àlàyé tó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu nípa ìbátan tí a ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé ó wà láàárín ìwà ipá àti ọtí àmujù.
Kókó mìíràn tún wà tó kan bí ìwà ipá ṣe ń pọ̀ sí i lónìí. Ìwé alásọtẹ́lẹ̀ kan, tí ó ṣeé fọkàn tán, Bíbélì, sọ pé: “Máa rántí pé, àwọn àkókò tó ṣòro yóò wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, oníwọra, afọ́nnu, àti ajọra-ẹni-lójú; . . . wọn yóò jẹ́ ìkà, aláìláàánú, abanijẹ́, oníwà ipá àti oníkanra; wọn yóò kórìíra ohun rere; wọn yóò jẹ́ aládàkàdekè, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, awúfùkẹ̀ nítorí ìgbéraga . . . Yẹra fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀.” (2 Tímótì 3:1-5, Today’s English Version) Ní tòótọ́, ìwà ipá tí a ń rí lónìí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”
Ohun mìíràn kan tún mú kí àkókò yìí kún fún ìwà ipá púpọ̀. Bíbélì wí pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) A ti lé Èṣù àti ogunlọ́gọ̀ ẹ̀mí èṣù kúrò ní ọ̀run, wọ́n sì ti ń darí gbogbo ìwà ibi wọn sí aráyé. Gẹ́gẹ́ bí “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́,” Èṣù ń lo “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn,” ó sì ń mú kí ìwà ipá gbilẹ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé.—Éfésù 2:2.
Báwo wá ni a ṣe lè kojú “afẹ́fẹ́” oníwà ipá ti ayé òde òní? Báwo ni a sì ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro ní ìtùnbí-ìnùbí?
-
-
Bí A Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Ní Ìtùnbí-ìnùbíIlé Ìṣọ́—1998 | November 1
-
-
Bí A Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Ní Ìtùnbí-ìnùbí
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ láti ìgbà tí a ti ṣẹ̀dá ènìyàn ni ènìyàn ti ń hùwà ipá. Bíbélì tọpa ìwà ipá sẹ́yìn dé ọ̀dọ̀ Kéènì, ẹ̀gbọ́n Ébẹ́lì, tó tún jẹ́ àrẹ̀mọ tọkọtaya ènìyàn kìíní. Nígbà tí Ọlọ́run gba ẹbọ tí Ébẹ́lì rú, tí kò gba ti Kéènì, “ìbínú” Kéènì “gbóná gidigidi.” Kí ló ṣe nínú ipò náà? “Kéènì bẹ̀rẹ̀ sí fipá kọlu Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.” Lẹ́yìn náà, ó bá ara rẹ̀ nínú ìjàngbọ̀n lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 4:5, 8-12) Ìwà ipá tí Kéènì hù kò yanjú ìṣòro ipò búburú tí Kéènì wà níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀.
Báwo ni a ṣe lè yẹra fún ọ̀nà ìgbésí ayé Kéènì, ti fífi ìwà ipá yanjú ìṣòro?
Fífi Ìráragbaǹkan Rọ́pò Ìwà Ipá
Ṣàgbéyẹ̀wò ọkùnrin kan tó wòran bí a ṣe pa Sítéfánù, Kristẹni ajẹ́rìíkú kìíní, tó sì fara mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà. (Ìṣe 7:58; 8:1) Ọkùnrin náà, Sọ́ọ̀lù ará Tásù, kò fara mọ́ èrò ìsìn tí Sítéfánù ní, ó sì ṣètìlẹ́yìn fún ṣíṣìkà pa á gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí ó tọ́ láti fòpin sí àwọn ìgbòkègbodò Sítéfánù. A gbà pé, ó ṣeé ṣe kí Sọ́ọ̀lù má ti jẹ́ oníwà ipá ní gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀. Síbẹ̀, ó múra tán láti fara mọ́ ìwà ipá gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti yanjú ìṣòro. Kété lẹ́yìn tí Sítéfánù kú, Sọ́ọ̀lù “bẹ̀rẹ̀ sí hùwà sí ìjọ [Kristẹni] lọ́nà bíburú jáì. Ó ń gbógun ti ilé kan tẹ̀ lé òmíràn àti pé, ní wíwọ́ àti ọkùnrin àti obìnrin jáde, òun a fi wọ́n sẹ́wọ̀n.”—Ìṣe 8:3.
Bí ọ̀mọ̀wé Bíbélì náà, Albert Barnes, ṣe wí, ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí a túmọ̀ sí ‘láti hùwà sí lọ́nà bíburú jáì” ń tọ́ka sí irú ìsọdahoro tí àwọn ẹranko ẹhànnà, bí kìnnìún àti ìkookò, lè fà. Barnes ṣàlàyé pé, “Sọ́ọ̀lù gbógun ti ṣọ́ọ̀ṣì náà bí ẹranko ẹhànnà kan—èdè lílágbára kan, tó fi bí ó ṣe fi ìtara àti ìbínú ṣe inúnibíni náà hàn.” Nígbà tí Sọ́ọ̀lù forí lé Damásíkù láti tún kó ọ̀pọ̀ ọmọ ẹ̀yìn Kristi, ó “ṣì ń mí èémí ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣìkàpànìyàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa [Kristi].” Bí ó ti ń lọ, Jésù tó ti jíǹde náà bá a sọ̀rọ̀, èyí sì yọrí sí yíyí Sọ́ọ̀lù padà sí ìsìn Kristẹni.—Ìṣe 9:1-19.
Lẹ́yìn ìyípadà yẹn, ọ̀nà tí Sọ́ọ̀lù gbà ń hùwà sí àwọn ẹlòmíràn yí padà. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé ní ọdún 16 lẹ́yìn náà fi ìyípadà yìí hàn. Àwùjọ àwọn ènìyàn kan wá sí ìjọ ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Áńtíókù, wọ́n sì rọ àwọn Kristẹni níbẹ̀ láti mú ara wọn bá Òfin Mósè mu. “Ìyapa . . . tí kì í ṣe kékeré” ló wáyé. Sọ́ọ̀lù tí a ti wá mọ̀ dáradára sí Pọ́ọ̀lù nígbà náà kó ipa kan nínú awuyewuye náà. Ó dájú pé awuyewuye náà le gan-an. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù kò hu ìwà ipá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fara mọ́ ìpinnu ìjọ náà láti mú ọ̀ràn náà tọ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ìjọ Jerúsálẹ́mù lọ.—Ìṣe 15:1, 2.
Ní Jerúsálẹ́mù, “awuyewuye púpọ̀” tún wáyé níbi ìpàdé àwọn alàgbà náà. Pọ́ọ̀lù dúró títí di ìgbà tí “gbogbo ògìdìgbó náà pátá dákẹ́ jẹ́ẹ́,” kí ó tó ṣèròyìn ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àgbàyanu tí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe láàárín àwọn onígbàgbọ́ tí kò dádọ̀dọ́. Lẹ́yìn ìjíròrò kan tí a gbé karí Ìwé Mímọ́, àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù náà dé “orí ìfìmọ̀ṣọ̀kan” láti máà tún fi ẹrù ìnira kankan kún un láìpọndandan fún àwọn onígbàgbọ́ tí kò dádọ̀dọ́ náà, ṣùgbọ́n kí wọ́n ṣí wọn létí “láti máa ta kété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti sí ẹ̀jẹ̀ àti sí ohun tí a fún lọ́rùn pa àti sí àgbèrè.” (Ìṣe 15:3-29) Láìsíyèméjì, Pọ́ọ̀lù ti yí padà. Ó kọ́ láti máa yanjú àwọn ọ̀ràn ní ìtùnbí-ìnùbí.
Kíkojú Àwọn Èrò Oníwà Ipá
Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù ṣíni létí pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni, tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi, kí ó máa fún àwọn tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹ̀lú ìwà tútù.” (2 Tímótì 2:24, 25) Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì, alábòójútó kan tí kò dàgbà tó o, pé kí ó máa bójú tó àwọn ìṣòro ní pẹ̀lẹ́tù. Pọ́ọ̀lù kò yẹra fún ohun tó jẹ́ òtítọ́. Ó mọ̀ pé ìmọ̀lára lè ru láàárín àwọn Kristẹni pàápàá. (Ìṣe 15:37-41) Pẹ̀lú èrò rere, ó gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” (Éfésù 4:26) Ọ̀nà tó yẹ láti gbà kápá irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ ni kí a kápá ìbínú láìsí pé a fìrunú bú jáde. Àmọ́, báwo ni a ṣe lè ṣàṣeyọrí èyí?
Lónìí, kò rọrùn láti kápá ìbínú. Dókítà Deborah Prothrow-Stith, igbákejì ọ̀gá àgbà Ilé Ẹ̀kọ́ Ìlera Aráàlú ti Havard, sọ pé: “Dídi kùnrùngbùn ló wọ́ pọ̀. Ní gidi, agbára láti máa wà nírẹ̀ẹ́pọ̀—jíjọ ṣàdéhùn, gbígbà fúnra ẹni, fífọ̀rọ̀ rora ẹni wò, dídárí jini—ni a sábà máa ń kà sí ti àwọn ọ̀lẹ.” Síbẹ̀, ìwọ̀nyẹn jẹ́ àwọn ànímọ́ alágbára, wọ́n sì ṣe pàtàkì fún kíkápá èrò oníwà ipá tí ó lè dìde lọ́kàn wa.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni, ó kọ́ nípa ọ̀nà tó sàn jù láti bójú tó ìyàtọ̀ tí ń wà nínú èrò àwọn ènìyàn. A gbé e karí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Gẹ́gẹ́ bí àgbà onímọ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù, Pọ́ọ̀lù mọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dunjú. Lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó gbọ́dọ̀ ti mọ̀ dáradára ni: “Má ṣe ìlara ọkùnrin oníwà ipá, bẹ́ẹ̀ ni kí o má yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀.” “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá, ẹni tí ó sì ń ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀ sàn ju ẹni tí ó kó ìlú ńlá.” “Bí ìlú ńlá tí a ya wọ̀, láìní ògiri, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí kò kó ẹ̀mí rẹ̀ níjàánu.” (Òwe 3:31; 16:32; 25:28) Síbẹ̀, ìmọ̀ yẹn kò dí Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ híhùwà ipá sí àwọn Kristẹni, kí òun náà tó yí padà. (Gálátíà 1:13, 14) Ṣùgbọ́n kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ nígbà tó di Kristẹni, tí ó fi ń yanjú àwọn ọ̀ràn àríyànjiyàn tó kan ìmọ̀lára nípa ríronújinlẹ̀ àti rírọni dípò kí ó lo ìwà ipá?
Pọ́ọ̀lù fún wa ní ìdí kan nígbà tí ó wí pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 11:1) Ó mọrírì ohun tí Jésù Kristi ti ṣe fún un gidigidi. (1 Tímótì 1:13, 14) Kristi di àpẹẹrẹ fún un láti tẹ̀ lé. Ó mọ bí Kristi ṣe jìyà nítorí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀. (Hébérù 2:18; 5:8-10) Ó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti wádìí, kí ó sì mọ̀ dájú pé, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa Mèsáyà náà ṣẹ sára Jésù pé: “A ni ín lára dé góńgó, ó sì jẹ́ kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́; síbẹ̀síbẹ̀, kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀. A ń mú un bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa; àti bí abo àgùntàn tí ó yadi níwájú àwọn olùrẹ́run rẹ̀, òun kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀ pẹ̀lú.” (Aísáyà 53:7) Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.”—1 Pétérù 2:23, 24.
Ìmọrírì tí Pọ́ọ̀lù ní fún ọ̀nà tí Jésù Kristi gbà kojú àwọn ipò nínira mú kí ó yí padà. Ó lè fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ìṣítí pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kólósè 3:13) Mímọ̀ pé kò yẹ kí a máa hùwà ipá kò tó. Mímọrírì ohun tí Jèhófà àti Jésù Kristi ti ṣe fún wa ń ṣèrànwọ́ láti fúnni ní ìsúnniṣe tí a nílò, kí a lè borí àwọn èrò oníwà ipá.
Ṣé Ó Ṣeé Ṣe?
Ọkùnrin kan ní Japan nílò irú ìsúnniṣe tó lágbára bẹ́ẹ̀. Baba rẹ̀, tó jẹ́ sójà tí ń yára bínú, fi ìwà ipá jẹ gàba lórí ìdílé rẹ̀. Nítorí pé ọkùnrin yìí fojú winá ìwà ipá, ó sì ń rí i tí ìyá rẹ̀ ń fojú winá rẹ̀ bákan náà, ó ní èrò híhùwà ipá. Ó ń di idà samurai méjì tó tóbi ju ara wọn lọ mọ́ra kiri, ó máa ń yọ idà náà láti fi yanjú àwọn ìṣòro àti láti fi dẹ́rù ba àwọn ènìyàn.
Nígbà ti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ń jókòó níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà láìkà á sí pàtàkì. Àmọ́, nígbà tí ó ka ìwé kékeré tí a ń pè ní Ihinrere Ijọba Yi,a ó yí padà. Kí ló fà á? Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ka ìwé náà lábẹ́ àwọn ìsọ̀rí ‘Jesu Kristi’ àti ‘Irapada,’ ojú tì mí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ń gbé ìgbésí ayé àìtọ́, mo ṣì fẹ́ láti jẹ́ onínúure sí àwọn tí mo ń bá ṣe pọ̀. Ó ń dùn mọ́ mi láti mú àwọn ọ̀rẹ́ mi láyọ̀, kìkì pé n kò lè ṣe é kọjá ibi tí kò bá ti ní pa mí lára. Àmọ́, Ọmọ Ọlọ́run, Jésù, múra tán láti kú nítorí aráyé, títí kan àwọn ènìyàn bí èmi. Ó kà mí láyà, bí ká ní wọ́n fi òlùgbóńgbó olórí ńlá lù mí.”
Kò bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ kẹ́gbẹ́ mọ́, láìpẹ́, ó forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ní ọ̀kan nínú àwọn ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ilé ẹ̀kọ́ yìí ń ran àwọn tó bá forúkọ sílẹ̀ níbẹ̀ lọ́wọ́ láti jèrè ọgbọ́n tí a fi ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀kọ́ náà fún ọkùnrin yìí ní àǹfààní àjẹmọ́nú kan. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń halẹ̀ mọ́ni, mo sì ń hùwà ipá nítorí pé n kò lè sọ ìmọ̀lára mi fún àwọn ẹlòmíràn. Bí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ láti máa sọ èrò mi jáde, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú pẹ̀lú wọn dípò kí n máa hùwà ipá.”
Ǹjẹ́ ó ti sọ ọ̀nà ìgbésí ayé Kristi di tirẹ̀ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe? A dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ kan, tí ó ti bá mulẹ̀ àjọṣe gbìyànjú láti dí i lọ́wọ́, kí ó má di Kristẹni. “Ọ̀rẹ́” rẹ̀ náà lù ú, ó sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run rẹ̀, Jèhófà. Ọkùnrin tí ń hùwà ipá tẹ́lẹ̀ náà kó ara rẹ̀ ní ìjánu, ó sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé òun kò ní lè máa bá ìmùlẹ̀ àjọṣe náà lọ mọ́. Bí ó ti jẹ́ ìjákulẹ̀ fún “ìmùlẹ̀” náà, ó fi í sílẹ̀ jẹ́ẹ́.
Nípa ṣíṣẹ́gun àwọn èrò oníwà ipá rẹ̀, ọkùnrin onínúfùfù tẹ́lẹ̀ yìí ti jèrè ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí, tí ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti aládùúgbò so pọ̀ ṣọ̀kan. (Kólósè 3:14) Ní gidi, ní báyìí tí ó ti lé ní 20 ọdún tí ó ti di Kristẹni olùṣèyàsímímọ́, ó ń ṣiṣẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ohun ayọ̀ fún un tó láti lè tọ́ka sí i nínú Bíbélì pé àwọn ènìyàn tí ń hùwà bí ẹranko lè kọ́ bí a ṣe ń yanjú ìṣòro ní ìtùnbí-ìnùbí bí òun gan-an ṣe kọ́ ọ! Ẹ sì wo irú àǹfààní tí ó ní láti lè tọ́ka sí arabaríbí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí náà pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun”!—Aísáyà 11:9.
Bí ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti ọkùnrin tí ń hùwà ipá tẹ́lẹ̀ yìí, ìwọ náà lè kọ́ láti bójú tó àwọn ọ̀ràn tí ń múni bínú, kí o yanjú ìṣòro ní ìtùnbí-ìnùbí. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Pọ́ọ̀lù kò yẹra fún ohun tó jẹ́ òtítọ́. Ó mọ̀ pé ìmọ̀lára lè ru láàárín àwọn Kristẹni pàápàá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Mímọrírì ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa ń jẹ́ kí a lè bá àwọn mìíràn gbé lálàáfíà
-