ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 11/15 ojú ìwé 28
  • Ṣọ́ra Fún Ríra Ipò!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣọ́ra Fún Ríra Ipò!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 11/15 ojú ìwé 28

Ṣọ́ra Fún Ríra Ipò!

ÀWỌN ará àdúgbò Símónì ará Samáríà bọ̀wọ̀ fún un gan-an. Ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa ni ó gbé ayé, àwọn ènìyàn sì gba ti iṣẹ́ idán pípa rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi máa ń sọ nípa rẹ̀ pé: “Ọkùnrin yìí jẹ́ Agbára Ọlọ́run, tí a lè pè ní Títóbi.”—Ìṣe 8:9-11.

Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí Símónì di Kristẹni tí a batisí, ó rí agbára kan tí ó ju èyí tí òun ń lò tẹ́lẹ̀ lọ. Ìyẹn ni agbára tí a fi fún àwọn àpọ́sítélì Jésù, tí ó fi ṣeé ṣe fún wọn láti fún àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ẹ̀bùn àgbàyanu ti ẹ̀mí mímọ́. Ó wu Símónì gan-an tí ó fi fi owó lọ̀ wọ́n, ó sí wí pé: “Ẹ fún èmi náà ní ọlá àṣẹ yìí, kí ẹnikẹ́ni tí mo bá gbé ọwọ́ mi lé lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.”—Ìṣe 8:13-19.

Àpọ́sítélì Pétérù bá Símónì wí pé: “Kí fàdákà rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí ìwọ rò pé o lè tipasẹ̀ owó rí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run gbà. Ìwọ kò ní ipa tàbí ìpín kankan nínú ọ̀ràn yìí, nítorí pé ọkàn-àyà rẹ kò tọ́ lójú Ọlọ́run.”—Ìṣe 8:20, 21.

Láti inú àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí ní ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì náà “simony” [ríra ipò], ti wá, a sì ti túmọ̀ rẹ̀ sí “ẹ̀ṣẹ̀ rírà ipò tàbí títà á, tàbí ríra ìgbéga nínú ìjọ.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia sọ pé, ní pàtàkì láti ọ̀rúndún kẹsàn-án sí ìkọkànlá “àṣà ríra ipò gbalẹ̀ kan ní àwọn ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, ní àárín àwùjọ àwọn àlùfáà kéékèèké, ní àárín àwọn alákòóso gíga ṣọ́ọ̀ṣì, àti nínú ìgbìmọ̀ tí póòpù ti ń ṣolórí pàápàá.” Ìtẹ̀jáde kẹsàn-án ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica (1878) sọ pé: “Ẹ̀kọ́ nípa ìtàn ìpàdé ìkọ̀kọ̀ tí àwọn lóókọlóókọ tí ń yan Póòpù sípò máa ń ṣe mú kí ó dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lójú pé kò sí ìyànsípò kan tí wọ́n ṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì náà, tí kì í ṣe pé wọ́n fi owó rà á ni, tí ó sì jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, àṣà fífi owó ra ipò tí wọ́n ń dá ní ìpàdé ìkọ̀kọ̀ náà ló jẹ́ ìwà aburú tó hàn gbangba, ló jẹ́ ìwà àìlójútì rárá, ni wọn kò sì fi bò páàpáà.”

Àwọn Kristẹni tòótọ́ tòde òní gbọ́dọ̀ yàgò fún rírà ipò. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan lè yin àwọn tí ó lè fún wọn ní àǹfààní ẹrù iṣẹ́ láyìnjù tàbí kí wọ́n fún wọn lẹ́bùn tàbùàtabua. Ní ọ̀nà kejì, àwọn tí ó lè fún wọn ní irú àǹfààní ẹrù iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè ṣe ojúsàájú sí àwọn tí ó lágbára àtifún wọn lẹ́bùn tàbùàtabua, tí wọ́n sábà máa ń hára gàgà láti fúnni lẹ́bùn. Ọ̀ràn méjèèjì jẹ́ ti ríra ipò, ó sì ṣe kedere pé Ìwé Mímọ́ dẹ́bi fún irú ìwà bẹ́ẹ̀. Pétérù rọ Símónì pé: “Nítorí náà, ronú pìwà dà ìwà búburú rẹ yìí, kí o sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé, bí ó bá ṣeé ṣe, kí a lè dárí ète búburú ọkàn-àyà rẹ [“ètekéte rẹ yìí,” New Jerusalem Bible] jì ọ́; nítorí mo rí i pé òróòró onímájèlé àti ìdè àìṣòdodo ni ọ́.”—Ìṣe 8:22, 23.

Ó dùn mọ́ni pé, Símónì rí i pé ìfẹ́-ọkàn òun kò dára. Ó bẹ àwọn àpọ́sítélì pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bá mi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà kí ìkankan nínú ohun tí ẹ sọ má bàa dé bá mi.” (Ìṣe 8:24) Ní kíkọbira sí ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú àkọsílẹ̀ yìí, àwọn ojúlówó Kristẹni ń tiraka láti yẹra fún àbàwọ́n èyíkéyìí tí ríra ipò lè kó bá wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́