-
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Moore?Ilé Ìṣọ́—1998 | February 15
-
-
pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò yóò léwu púpọ̀. Àwọn ènìyàn yóò mọ ti ara wọn nìkan pátápátá . . . Wọn yóò jẹ́ aláìmoore gbáà.”—2 Tímótì 3:1, 2, Phillips.
Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, a ti fi ìpọ́nni rọ́pò ìmoore. A máa ń sọ̀rọ̀ ìmoore láti inú ọkàn àyà láìronú nípa àǹfààní ara ẹni. Ṣùgbọ́n, ìpọ́nni, tí kì í sábà dénú, tó sì ń kọjá ààlà, lè wá láti inú ète wíwá ìgbéga tàbí jíjèrè àwọn àǹfààní kan fúnra ẹni. (Júúdà 16) Ní àfikún sí títan ẹni tí a ń pọ́n jẹ, irú ọ̀rọ̀ dídùn bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ èso ìgbéraga àti ìrera. Nígbà náà, ta ni yóò fẹ́ kí a sọ̀rọ̀ ìpọ́nni tí kò dénú sí òun? Ṣùgbọ́n ojúlówó ìmoore ń tuni lára ní tòótọ́.
Ẹni tí ń fi ìmoore hàn ń jàǹfààní nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀yàyà tí ó ń gbádùn, nítorí pé ó moore nínú ọkàn àyà rẹ̀, ń fi kún ayọ̀ àti àlàáfíà tó ní. (Fi wé Òwe 15:13, 15.) Nítorí pé ìmoore sì jẹ́ ànímọ́ rere, ó ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn ìmọ̀lára búburú bí ìbínú, owú, àti ìkórìíra.
‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tí Ó Kún fún Ọpẹ́’
Bíbélì rọ̀ wá láti mú ẹ̀mí ìmoore, tàbí ìṣọpẹ́, dàgbà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́. Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù nípa yín.” (1 Tẹsalóníkà 5:18) Pọ́ọ̀lù sì gba àwọn ará Kólósè nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà yín . . . Ẹ sì fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.” (Kólósè 3:15) Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ sáàmù ló ní àwọn ọ̀rọ̀ ọpẹ́ nínú, tí ń fi hàn pé ìmoore àtọkànwá jẹ́ ànímọ́ ìwà bí Ọlọ́run. (Sáàmù 27:4; 75:1) Ó ṣe kedere pé ó ń dùn mọ́ Jèhófà Ọlọ́run nígbà tí a bá ń fi ọpẹ́ hàn nínú àwọn ọ̀ràn ìgbésí ayé ojoojúmọ́.
Àmọ́ àwọn kókó abájọ wo ni ó lè mú kí ó ṣòro fún wa láti mú ẹ̀mí ìmoore dàgbà nínú ayé aláìlọ́pẹ́ yìí? Báwo ni a ṣe lè máa fi ìwà ìmoore hàn nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́? A óò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
-
-
Mú Ẹ̀mí Ìmoore DàgbàIlé Ìṣọ́—1998 | February 15
-
-
Mú Ẹ̀mí Ìmoore Dàgbà
DÓKÍTÀ kan ní Ìpínlẹ̀ New York gba ẹ̀mí Marie là nínú ipò pàjáwìrì kan. Ṣùgbọ́n Marie ẹni 50 ọdún kò dúpẹ́ lọ́wọ́ dókítà náà, kò sì sanwó ìtọ́jú rẹ̀. Ẹ wo bí èyí tí jẹ́ àpẹẹrẹ àìmoore tó!
Bíbélì sọ pé nígbà kan, bí Jésù ti ń wọnú abúlé kan, ó bá àwọn ọkùnrin mẹ́wàá pàdé tí àrùn ẹ̀tẹ̀ burúkú kọlù. Wọ́n ké jáde sí i ní ohùn rara pé: “Jésù, Olùkọ́ni, ṣàánú fún wa!” Jésù pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ lọ fi ara yín han àwọn àlùfáà.” Àwọn adẹ́tẹ̀ náà tẹ́wọ́ gba ìtọ́ni yìí, bí wọ́n sì ti ń lọ lójú ọ̀nà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára pé a ti mú wọn lára dá.
Mẹ́sàn-án lára àwọn adẹ́tẹ̀ náà ń bá ọ̀nà wọn lọ. Ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó kù, ará Samáríà, pa dà wá láti wá Jésù kàn. Adẹ́tẹ̀ tẹ́lẹ̀rí yìí yin Ọlọ́run lógo, nígbà tí ó sì rí Jésù, ó wólẹ̀ sí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ní ìfèsìpadà, Jésù wí pé: “Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ni a wẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn mẹ́sàn-án yòókù wá dà? Ṣé a kò rí kí ẹnì kankan padà láti fi ògo fún Ọlọ́run bí kò ṣe ọkùnrin yìí tí ó jẹ́ ará orílẹ̀-èdè mìíràn?”—Lúùkù 17:11-19.
Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan ń bẹ nínú ìbéèrè náà pé: “Àwọn mẹ́sàn-án yòókù wá dà?” Gẹ́gẹ́ bí Marie, àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́sàn-án náà ní àlèébù ńlá kan—wọn kò moore. Irú àìmoore bẹ́ẹ̀ gbalégbòde gan-an lónìí. Kí ni ó fa èyí?
Lájorí Okùnfà Àìmoore
Ní pàtàkì, àìmoore ń wá láti inú ìmọtara-ẹni-nìkan. Gbé àpẹẹrẹ àwọn òbí wa ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, yẹ̀ wò. Jèhófà dá àwọn ànímọ́ ti ọ̀run mọ́ wọn ó sì pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò láti láyọ̀ fún wọn, títí kan ọgbà ilé ẹlẹ́wà, àyíká tí kò lálèébù, àti iṣẹ́ tí ó nítumọ̀ tí ó sì ń tẹ́ni lọ́rùn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-29; 2:16, 17) Síbẹ̀, Sátánì lo ire ti ara wọn lòdì sí wọn, gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya, wọ́n ṣàìgbọràn, wọ́n sì tẹ́ńbẹ́lú gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Ìṣípayá 12:9.
Gbé àpẹẹrẹ àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ìgbàanì, tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ àkànṣe ìní rẹ̀, yẹ̀ wò pẹ̀lú. Ẹ wo bí gbogbo òbí tí ó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì yóò ti kún fún ìmoore tó ní òru ọjọ́ Nísàn 14, ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa! Ní alẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé yẹn, áńgẹ́lì Ọlọ́run pa “gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì,” ṣùgbọ́n ó ré ilé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a ti sàmì sí dáradára kọjá. (Ẹ́kísódù 12:12, 21-24, 30) Nígbà tí a sì ti dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò ní Òkun Pupa, pẹ̀lú ọkàn-àyà tí ó kún fún ìmoore, ‘Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin sí Jèhófà.’—Ẹ́kísódù 14:19-28; 15:1-21.
Síbẹ̀síbẹ̀, ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré lẹ́yìn tí wọ́n fi Íjíbítì sílẹ̀, “gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá sì bẹ̀rẹ̀ sí kùn.” Ẹ wo bí wọ́n ṣe yára di aláìmoore tó! Ọkàn wọ́n fà sí ‘jíjókòó ti ìkòkò ẹran, jíjẹ oúnjẹ ní àjẹtẹ́rùn,’ tí wọ́n ti gbádùn ní Íjíbítì, ilẹ̀ ìsìnrú wọn. (Ẹ́kísódù 16:1-3) Ó ṣe kedere pé, ìmọtara-ẹni-nìkan máa ń dènà mímú ẹ̀mí ìmoore dàgbà àti fífi í hàn.
Níwọ̀n bí a ti jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀, gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ni a bí ìwọ̀n ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìtẹ̀sí láti jẹ́ aláìmoore mọ́. (Róòmù 5:12) Jíjẹ́ aláìlọ́pẹ́ tún jẹ́ apá kan ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tí ó jọba lọ́kàn àwọn ènìyàn ayé yìí. Bí atẹ́gùn tí a ń mí sínú, ẹ̀mí yẹn wà níbi gbogbo, ó sì ń nípa lórí wa. (Éfésù 2:1, 2) Nígbà náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a mú ẹ̀mí ìmoore dàgbà. Báwo ni a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Ṣíṣàṣàrò Pọn Dandan
Ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Third New International Dictionary túmọ̀ ìmoore sí “ipò jíjẹ́ ẹni tí ó moore: ìmọ̀lára ìfẹ́ àti ẹ̀mí ọ̀rẹ́ sí ẹni tí ó ṣeni lóore, tí ń súnni láti san oore náà pa dà.” A kò lè gbé ìmọ̀lára wọ̀ tàbí gbé e jù sílẹ̀ bí aṣọ; ó gbọ́dọ̀ wá láti inú ẹni, láìfipá mú un. Ìmoore ju wíwulẹ̀ fi ìwà rere tàbí ìwà ọmọlúwàbí hàn lọ; ó ń wá láti inú ọkàn àyà.
Báwo ni a ṣe lè kọ́ láti jẹ́ ẹni tí ọkàn àyà rẹ̀ kún fún ìmoore? Bíbélì so ọ̀pọ̀ ìmọ̀lára tí a ń ní mọ́ ohun tí a yàn láti ronú lé lórí. (Éfésù 4:22-24) Kíkọ́ láti jẹ́ ẹni tí ó moore ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣàṣàrò lọ́nà tí ó kún fún ìmọrírì lórí inú rere tí a fi hàn sí wa. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Dókítà Wayne W. Dyer, tí ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtọ́jú ọpọlọ, sọ pé: “Ìwọ kò lè ní ìmọ̀lára (èrò ìmọ̀lára) láìjẹ́ pé o ti kọ́kọ́ ronú.”
Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn kíkún fún ọpẹ́ fún àwọn ìṣẹ̀dá tí ó yí wa ká, yẹ̀ wò. Nígbà tí o bá wo òfuurufú tí ó kún fún ìràwọ̀ ní alẹ́ tí ojú ọ̀run mọ́ kedere, báwo ni ìmọ̀lára rẹ ṣe ń rí pẹ̀lú ohun tí o ń wò? Ọba Dáfídì sọ ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tí ó ní jáde pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?” Ní alẹ́ tí gbogbo rẹ̀ pa lọ́lọ́, àwọn ìràwọ̀ bá Dáfídì sọ̀rọ̀, wọ́n sún un láti kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” Èé ṣe tí ọ̀run tí ó kún fún ìràwọ̀ ṣe mú orí Dáfídì wú tó bẹ́ẹ̀? Òun fúnra rẹ̀ fèsì pé: “Mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ; tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.”—Sáàmù 8:3, 4; 19:1; 143:5.
Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì pẹ̀lú mọrírì ìníyelórí ríronú nípa àwọn àgbàyanu ìṣẹ̀dá. Fún àpẹẹrẹ, nípa ipa tí ìkùukùu òjò ń kó nínú bíbomirin ilẹ̀ ayé wa, ó kọ̀wé pé: “Gbogbo ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ń ṣàn lọ sínú òkun, síbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún. Ibi tí àwọn ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ti ń ṣàn jáde lọ, ibẹ̀ ni wọ́n ń padà sí, kí wọ́n bàa lè ṣàn jáde lọ.” (Oníwàásù 1:7) Bí ó ṣe ń rí nìyẹn lẹ́yìn tí òjò àti àwọn odò bá ti bomi rin ilẹ̀ ayé, omi wọn yóò ti inú òkun padà lọ sí inú ìkùukùu. Báwo ni ilẹ̀ ayé yìí ì bá ti rí ká ní kò sí omi tí ń fọ nǹkan mọ́, tí ó ń lọ yípo yípo yìí? Ẹ wo bí Sólómọ́nì yóò ti kún fún ìmoore tó nígbà tí ó ń ronú lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí!
Ẹnì kan tí ó moore tún ń mọyì ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà ìdílé, ọ̀rẹ́, àti ojúlùmọ̀ rẹ̀. Ìwà inú rere wọn máa ń wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Bí ó ti ń fi ìmọrírì ronú lórí ojú rere wọn, ọkàn-àyà rẹ̀ ń kún fún ọpẹ́.
Fífi Ìmoore Hàn
Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ náà, “ẹ ṣeun,” ti rọrùn tó! Ó rọrùn púpọ̀ láti sọ irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ jáde. Àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀ sì pọ̀ rẹpẹtẹ. Ẹ wo bí gbólóhùn náà, Ẹ Ṣeun, tí a fi ọ̀yàyà sọ, tí ó sì tọkàn wa wá, sí ẹnì kan tí ó bá wa ṣí ilẹ̀kùn tàbí tí ó bá wa mú nǹkan tí ó jábọ́ lọ́wọ́ wa, ti ń tuni lára tó! Gbígbọ́ irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ lè mú kí iṣẹ́ akọ̀wé ilé ìtajà kan tàbí agbóúnjẹfúnni ní ilé àrójẹ kan tàbí ti akólẹ́tà kan rọrùn, kí ó sì túbọ̀ mú èrè wá.
Fífi káàdì tí ẹ ṣeun wà lára rẹ̀ ránṣẹ́ jẹ́ ọ̀nà rírọrùn kan láti fi ìmoore hàn fún ìwà inú rere. Ọ̀pọ̀ káàdì tí ó wà nílé ìtajà ń sọ ìmọ̀lára wa jáde lọ́nà tí ó dára púpọ̀. Ṣùgbọ́n kì yóò ha jẹ́ ohun tí ń fi ìfẹ́ ẹni hàn láti fi ọ̀rọ̀ ìmọrírì tí o fọwọ́ ara rẹ kọ kún un bí? Dípò lílo káàdì orí àtẹ, àwọn kan tilẹ̀ yàn láti fi lẹ́tà ṣókí tí wọ́n kọ ní ọ̀rọ̀ ara wọn ránṣẹ́.—Fi wé Òwe 25:11.
Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, àwọn tí wọ́n yẹ fún ìmoore wa jù lọ ni àwọn tí ó sún mọ́ wa jù lọ nínú ilé. Bíbélì sọ nípa aya tí ó dáńgájíá pé: “Olúwa rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.” (Òwe 31:28) Àwọn ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ àtọkànwá tí ọkọ kan sọ sí aya rẹ̀ kì yóò ha ṣèrànwọ́ nínú mímú kí ilé jẹ́ àyíká alálàáfíà àti onítẹ̀ẹ́lọ́rùn bí? Inú ọkọ kì yóò ha sì dùn láti rí aya rẹ̀ tí ń fi ìkíni ọlọ́yàyà àti onímọrírì kí i káàbọ̀ bí ó ti ń wọlé bí? Lóde òní, pákáǹleke tí ó dojú kọ ìgbéyàwó pọ̀, nígbà tí pákáǹleke bá sì pọ̀ jù, inú a máa tètè bíni. Ẹni tí ó bá moore máa ń ṣe tán láti rára gba nǹkan, ó sì tètè ń gbójú fo àṣìṣe, kí ó sì dárí jini.
Àwọn èwe pẹ̀lú ní láti wà lójúfò láti sọ̀rọ̀ ìmọrírì àtọkànwá fún àwọn òbí wọn. Dájúdájú, àwọn òbí kí í ṣe ẹni pípé, ṣùgbọ́n ìyẹn kì í ṣe ìdí fún ṣíṣàì fi ìmọrírì hàn fún ohun tí wọ́n ti ṣe fún ọ. Ìfẹ́ àti ìtọ́jú tí wọ́n ti fún ọ láti ìgbà ìbí kò ṣeé fowó rà. Bí wọ́n bá ti kọ́ ọ ní ìmọ̀ Ọlọ́run, o ní ìdí mìíràn láti fi ìmoore hàn.
Sáàmù 127:3 polongo pé: “Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” Nítorí náà, ó yẹ kí àwọn òbí máa wá ọ̀nà láti gbóríyìn fún àwọn ọmọ wọn dípò rírojọ́ wẹ́wẹ́ nípa àwọn àṣìṣe kéékèèké tí wọ́n bá ṣe. (Éfésù 6:4) Ẹ sì wo irú àǹfààní tí wọ́n ní láti ran àwọn èwe tí ó wà lábẹ́ àbójútó wọn lọ́wọ́ láti mú ẹ̀mí ìmoore dàgbà!—Fi wé Òwe 29:21.
Dídúpẹ́ Lọ́wọ́ Ọlọ́run
Jèhófà Ọlọ́run ni Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Ẹ̀bùn ìwàláàyè ṣe pàtàkì gidigidi, nítorí gbogbo ohun tí a ní tàbí tí a wéwèé yóò di asán bí a bá pàdánù ìwàláàyè. Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá láti rántí pé “ọ̀dọ́ [Jèhófà Ọlọ́run] ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:5, 7, 9; Ìṣe 17:28) Láti mú ọkàn àyà tí ó kún fún ìmoore dàgbà fún Ọlọ́run, a ní láti ṣàṣàrò lórí àwọn ìpèsè ọlọ́làwọ́ rẹ̀ tí ń so ìwàláàyè wa nípa ti ara àti ti ẹ̀mí ró. (Sáàmù 1:1-3; 77:11, 12) Irú ọkàn àyà bẹ́ẹ̀ yóò sún wa láti fi ìmọrírì hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe.
Àdúrà jẹ́ ọ̀nà kan tí ó hàn gbangba tí a lè gbà fi ìmoore wa hàn fún Ọlọ́run. Onísáàmù náà, Dáfídì, polongo pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé. Ká ní mo fẹ́ máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn ni, wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.” (Sáàmù 40:5) Ǹjẹ́ kí a sún àwa náà láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
Dáfídì tún pinnu láti fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ tí ó bá àwọn ẹlòmíràn sọ. Ó wí pé: “Ṣe ni èmi yóò máa fi gbogbo ọkàn àyà mi gbé ọ lárugẹ, Jèhófà; èmi yóò máa polongo gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.” (Sáàmù 9:1) Bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, sísọ èrò wa jáde nípa ṣíṣàjọpín òtítọ́ láti inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú wọn, ni ọ̀nà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dára jù lọ láti fi ìmoore wa hàn fún un. Èyí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ ẹni tí ó moore nínú àwọn apá mìíràn nínú ìgbésí ayé.
Jèhófà sọ pé: “Ẹni tí ń rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ̀ ni ó ń yìn mí lógo; àti ní ti ẹni tí ń pa ọ̀nà tí a là sílẹ̀ mọ́, dájúdájú, èmi yóò jẹ́ kí o rí ìgbàlà.” Ǹjẹ́ kí o ní ayọ̀ tí ń wá láti inú fífi ìmoore àtọkànwá hàn fún un.—Sáàmù 50:23; 100:2.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Rí i dájú pé o kọ ọ̀rọ̀ tìrẹ kún un
-