Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Jésù rọni pé: ‘Ẹ tiraka tokuntokun láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé, nítorí, mo sọ fún yín, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò wá ọ̀nà láti wọlé ṣùgbọ́n wọn kì yóò lè ṣe bẹ́ẹ̀.” (Lúùkù 13:24) Kí ni ó ní lọ́kàn, báwo sì ni ó ṣe kàn wá lónìí?
A lè lóye àyọkà gbígbádùnmọ́ni yìí dáadáa bí a bá ronú lórí àyíká ipò rẹ̀. Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà àjọ̀dún títún tẹ́ńpìlì yà sí mímọ́. Ó sọ nípa bí òun ṣe jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn fún àwọn àgùntàn Ọlọ́run, ó sì tọ́ka sí i pé àwọn Júù ní gbogbogbòò kò sí lára irú àwọn àgùntàn bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọn kọ̀ láti fetí sílẹ̀. Nígbà tí ó wí pé “ọ̀kan” ni òun àti Baba òun, àwọn Júù gbé òkúta sókè láti sọ ọ́ lù ú. Ó sá lọ sí Péríà, ní òdì kejì Odò Jọ́dánì.—Jòhánù 10:1-40.
Níbẹ̀, ọkùnrin kan béèrè pé: “Olúwa, díẹ̀ ha ni àwọn tí a ó gbà là bí?” (Lúùkù 13:23) Ìyẹn jẹ́ ìbéèrè tí ó yẹ kí ó béèrè, níwọ̀n bí àwọn Júù ìgbà náà ti ronú pé kìkì iye kéréje ni yóò yẹ fún ìgbàlà. Ní gbígbé ìwà wọn yẹ̀wò, kò ṣòro láti mọ àwọn tí wọ́n rò pé yóò para pọ̀ jẹ́ àwọn kéréje náà. Ṣùgbọ́n, ẹ wo bí èrò wọn ti lòdì tó, bí àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà ti fi hàn!
Fún nǹkan bí ọdún méjì, Jésù ti wà láàárín wọn, ó ń kọ́ni, ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó sì ń nawọ́ ṣíṣeé ṣe náà láti di ajogún Ìjọba ọ̀run síni. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àwọn, àti àwọn aṣáájú wọn ní pàtàkì, gbéra ga nítorí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, tí a sì fi Òfin Ọlọ́run lé wọn lọ́wọ́. (Mátíù 23:2; Jòhánù 8:31-44) Ṣùgbọ́n wọ́n kọ etí dídi sí ohùn Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà. Ṣe ni ó dà bí pé ilẹ̀kùn tí ó ṣí sílẹ̀ wà níwájú wọn, tí ipò jíjẹ́ mẹ́ńbà nínú Ìjọba náà sì jẹ́ olórí èrè tí wọn yóò gbà, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti wọlé. Kìkì ìwọ̀nba díẹ̀, tí púpọ̀ lára wọn jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀, ni wọ́n gbọ́ ìhìn iṣẹ́ òtítọ́ Jésù, tí wọ́n dáhùn padà, tí wọ́n sì dìrọ̀ mọ́ ọn.—Lúùkù 22:28-30; Jòhánù 7:47-49.
Ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àwọn wọ̀nyí ní wọ́n wá di ẹni tí a fẹ̀mí yàn. (Ìṣe 2:1-38) Wọn kò sí lára àwọn oníṣẹ́ àìṣòdodo tí Jésù mẹ́nu kàn, tí wọn yóò sunkún, tí wọn yóò sì payín keke nítorí pípàdánù àǹfààní tí a ṣí sílẹ̀ fún wọn.—Lúùkù 13:27, 28.
Nítorí náà, ní ọ̀rúndún kìíní “ọ̀pọ̀” náà tọ́ka sí àwọn Júù ní gbogbogbòò, àti ní pàtàkì àwọn aṣáájú ìsìn. Àwọn wọ̀nyí sọ pé àwọn fẹ́ ojú rere Ọlọ́run—ṣùgbọ́n kìkì ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti ọ̀nà wọn, kì í ṣe ti Ọlọ́run. Ní ìyàtọ̀ pátápátá, àwọn “díẹ̀” tí wọ́n dáhùn padà tọkàntọkàn ní dídi apá kan Ìjọba náà wá di àwọn mẹ́ńbà ẹni àmì òróró ti ìjọ Kristẹni.
Nísinsìnyí, ṣàyẹ̀wò ìfisílò tí ó gbòòrò sí i tí ó wáyé ní ọjọ́ wa. Àìníye ènìyàn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ni a ti kọ́ pé ọ̀run ni wọ́n ń lọ. Ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn yìí ni a kò gbé ka ìmọ̀ pípéye láti inú Ìwé Mímọ́. Gẹ́gẹ́ bí ti àwọn Júù ìṣáájú, àwọn wọ̀nyí ń fẹ́ ojú rere Ọlọ́run kìkì lórí ìlànà tiwọn fúnra wọn.
Ṣùgbọ́n, àwọn díẹ̀ ti wà ní àkókò wa tí wọ́n fi ìrẹ̀lẹ̀ dáhùn padà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n sì wà ní ìlà fún rírí ojú rere rẹ̀. Èyí ti yọrí sí dídi tí wọ́n di “àwọn ọmọ ìjọba náà.” (Mátíù 13:38) A bẹ̀rẹ̀ sí ké sí irú “àwọn ọmọ” ẹni àmì òróró bẹ́ẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ó ti pẹ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gbà pé ẹ̀rí náà pé Ọlọ́run ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò fi hàn pé ní pàtàkì a ti pe àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ ti òkè ọ̀run. Nítorí náà, àwọn tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí ti lóye pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé ni a ń nawọ́ rẹ̀ jáde báyìí. Àwọn wọ̀nyí ti wá pọ̀ ju iye àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí ń dínkù sí i, àwọn tí wọ́n ní ìrètí lílọ sí ọ̀run. Lúùkù 13:24 kò ní ìmúṣẹ ní pàtàkì sí àwọn tí kò lọ sí ọ̀run lára, ṣùgbọ́n ó ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n fún wọn.
Nípa rírọ̀ wá láti tiraka tokuntokun, kì í ṣe pé Jésù ń sọ pé òun tàbí Baba òun gbé ìdènà sí iwájú wa kí ó bàá lè dí wa lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n Lúùkù 13:24 jẹ́ kí a lóye pé ohun tí Ọlọ́run ń béèrè fún jẹ́ ohun tí yóò mú kí a mú àwọn tí kò yẹ kúrò. “Ẹ tiraka tokuntokun” túmọ̀ sí lílàkàkà, lílo ara ẹni. A wá lè bi ara wa pé, ‘Mo ha ń lo ara mi bí?’ A lè tún Lúùkù 13:24 sọ lọ́rọ̀ mìíràn pé, ‘Mo gbọ́dọ̀ tiraka tokuntokun láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé, nítorí ọ̀pọ̀ yóò wá ọ̀nà láti wọlé, ṣùgbọ́n wọn kì yóò lè wọlé. Nítorí náà mo ha ń tiraka tokuntokun bí? Mo ha dà bí eléré ìdárayá kan nínú pápá ìṣeré ìdárayá ìgbàanì tí ó lo gbogbo agbára rẹ̀ láti gba ẹ̀bùn náà? Irú eléré ìdárayá bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ afaraṣemáfọkànṣe tàbí ẹlẹ́mìí jẹ́-n-dẹ̀-ẹ́-jẹ́jẹ́. Mo ha ń dẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ bí?’
Ọ̀rọ̀ Jésù fi hàn pé àwọn kan lè wá ọ̀nà láti ‘gba ẹnu ọ̀nà náà wọlé’ ní kìkì àkókò tí ó rọgbọ fún wọn, ní ọ̀nà kan tí ó wù wọ́n. Irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ lè nípa lórí olúkúlùkù Ẹlẹ́rìí. Àwọn kan lè ronú pé, ‘Mo mọ àwọn Kristẹni olùfọkànsìn tí wọ́n ti tiraka fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ nǹkan rúbọ; síbẹ̀, títí tí wọ́n fi kú, òpin ètò burúkú yìí kò dé. Nítorí náà, bóyá kí n kúkú dẹ̀ ẹ́ díẹ̀, kí n gbé ìgbésí ayé irú èyí tí ó wọ́pọ̀.’
Ó rọrùn láti ronú bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó ha bọ́gbọ́n mu ní tòótọ́ bí? Fún àpẹẹrẹ, àwọn àpọ́sítélì ha ronú lọ́nà yẹn bí? Rárá o. Wọ́n lo gbogbo agbára wọn fún ìjọsìn tòótọ́—títí tí wọ́n fi kú. Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù lè sọ pé: “[Kristi] ni ẹni tí a ń kéde . . . Fún ète yìí ni èmi ń ṣiṣẹ́ kára ní tòótọ́, mo ń tiraka ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ rẹ̀, èyí tí ń fi agbára ṣiṣẹ́ nínú mi.” Lẹ́yìn náà ó kọ̀wé pé: “Fún ète yìí ni àwa ń ṣiṣẹ́ kára, tí a sì ń tiraka, nítorí tí a ti gbé ìrètí wa lé Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo onírúurú ènìyàn, ní pàtàkì ti àwọn olùṣòtítọ́.”—Kólósè 1:28, 29; 1 Tímótì 4:10.
A mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ṣe ohun tí ó yẹ gan-an ní títiraka tokuntokun. Ẹ wo bí ó ṣe yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tó láti lè sọ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.” (2 Tímótì 4:7) Nítorí náà, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tí a kọ sílẹ̀ nínú Lúùkù 13:24, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè béèrè pé, ‘Mo ha jẹ́ aláápọn àti onítara bí? Àní, mo ha fi ẹ̀rí tí ó tó hàn pé mo fi ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù náà, “Ẹ tiraka láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé” sọ́kàn bí?’