Irú Ọjọ́ Ọ̀la Wo Lo Fẹ́ fún Àwọn Ọmọ Rẹ?
O HA ka àwọn ọmọ rẹ sí ogún ṣíṣeyebíye bí? (Sáàmù 127:3) Tàbí kẹ̀, o ha ka títọ́ wọn sí ẹrù ìnáwó, èyí tí kò sí ìdánilójú pé yóò yọrí sí rere? Kàkà kí ọmọ títọ́ mú owó wọlé, ṣe ni ó ń náni lówó títí wọn yóò fi tójúúbọ́. Gan-an gẹ́gẹ́ bí bíbójútó ogún ti béèrè fún ìwéwèé tó yanjú, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn ọmọ títọ́ ní àtọ́yanjú.
Àwọn òbí tó bìkítà fẹ́ láti tọ́ ọmọ wọn sọ́nà rere ní àárọ̀ ọjọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan búburú tí ń bani nínú jẹ́ gan-an ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé yìí, àwọn òbí lè ṣe ohun púpọ̀ láti dáàbò bo ọmọ wọn. Gbé ọ̀ràn Werner àti Eva, tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú, yẹ̀ wò.a
Nígbà Tí Àwọn Òbí Bìkítà Ní Tòótọ́
Werner ròyìn pé dípò kí àwọn òbí òun fọwọ́ lẹ́rán máa wòye, ó ní wọ́n fi ojúlówó ìfẹ́ hàn nínú ohun tí ń lọ ní ilé ìwé. “Mo mọrírì àwọn àbá tó wúlò tí wọ́n fún mi gan-an ni, mo sì nímọ̀lára pé wọ́n bìkítà fún mi, wọ́n sì ń tì mí lẹ́yìn. Gẹ́gẹ́ bí òbí, wọn ò gbàgbàkugbà, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé ọ̀rẹ́ mi gidi ni wọ́n.” Nígbà tí ìdààmú bá Eva nítorí iṣẹ́ tí wọ́n fún un ní ilé ìwé, tí ó fi sorí kọ́, tí kò sì lè sùn, Francisco àti Inez, tí í ṣe àwọn òbí rẹ̀, lo àkókò tó jọjú láti bá a sọ̀rọ̀, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ní ti èrò orí àti tẹ̀mí.
Báwo ni Francisco àti Inez ṣe wá ọ̀nà láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n sì múra wọn sílẹ̀ fún ìgbé ayé àgbàlagbà? Tóò, láti ìgbà tí àwọn ọmọ náà ti wà ní kékeré jòjòló, ni àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ yìí ti ń mú wọn wọnú ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ tí wọ́n ń ṣe. Kàkà tí Inez àti Francisco ì bá fi máa re òde ìgbafẹ́ pẹ̀lú kìkì àwọn ọ̀rẹ́ wọn àgbàlagbà nìkan, ibikíbi tí wọ́n bá ń lọ ni wọ́n ń mú àwọn ọmọ wọn lọ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí onífẹ̀ẹ́, wọ́n tún fún àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn ní ìtọ́sọ́nà yíyẹ. Inez sọ pé: “A kọ́ wọn láti máa bójú tó ilé, láti máa ṣún nǹkan lò, àti láti máa tọ́jú aṣọ ara wọn. A sì ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́ láti yan iṣẹ́ tí wọn yóò ṣe, kí ẹrù iṣẹ́ wọ́n má sì ṣe ìpalára fún àwọn nǹkan tẹ̀mí.”
Àbí ẹ ò rí bó ti ṣe kókó tó láti mọ àwọn ọmọ yín, kí ẹ sì tọ́ wọn sọ́nà gẹ́gẹ́ bí òbí! Ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò àgbègbè mẹ́ta tí ẹ ti lè ṣe èyí: (1) Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti yan iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó dáa; (2) múra wọn sílẹ̀ láti lè kojú másùnmáwo nílé ìwé àti níbi iṣẹ́; (3) fi bí wọ́n ṣe lè tẹ́ àwọn àìní wọn tẹ̀mí lọ́rùn hàn wọ́n.
Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Yan Iṣẹ́ Tó Bójú Mu
Níwọ̀n bí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí ẹnì kan ń ṣe ti máa ń nípa lórí bó ṣe lówó lọ́wọ́ sí, tó sì tún máa ń gba púpọ̀ lára àkókò rẹ̀, jíjẹ́ òbí rere wé mọ́ ríronú nípa ibi tí ìfẹ́-ọkàn ọmọ kọ̀ọ̀kan wà àti ohun tó mọ̀ ọ́n ṣe. Níwọ̀n bí kò ti sí ọmọlúwàbí kankan tí ó fẹ́ di bùkátà rẹ̀ ru àwọn ẹlòmíràn, àwọn òbí ní láti ronú dáadáa nípa bí wọ́n ṣe lè múra ọmọ wọn sílẹ̀ láti bọ́ ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Yóò ha pọndandan fún ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ láti lọ kọ́ṣẹ́ kí ó bàa lè gbé ìgbé ayé tó yanjú bí? Gẹ́gẹ́ bí òbí tó bìkítà ní tòótọ́, sapá gidigidi láti ran ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ láti ṣiṣẹ́ kárakára, ìfẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, àti mímọ bí a ti ń bá àwọn èèyàn gbé láìjà láìta.
Gbé ọ̀ràn Nicole yẹ̀ wò. Ó wí pé: “Àwọn òbí mi mú kí n máa bá wọn ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ àgbàfọ̀ wọn. Wọ́n dá a lábàá pé kí n máa mú lára owó tí wọ́n ń san fún mi sílẹ̀ fún níná nínú ilé, kí n sì máa ná ìyókù tàbí kí n tọ́jú rẹ̀ pa mọ́. Èyí jẹ́ kí n nímọ̀lára pé mo ti tó fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, ó sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an lẹ́yìn ìgbà náà.”
Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kò sọ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ pàtó tí ẹnì kan gbọ́dọ̀ yàn. Ṣùgbọ́n ó pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà yíyèkooro. Fún àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.” Nígbà tó ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà, ó sọ pẹ̀lú pé: “A gbọ́ pé àwọn kan ń rìn ségesège láàárín yín, láìṣiṣẹ́ rárá ṣùgbọ́n tí wọ́n ń tojú bọ ohun tí kò kàn wọ́n. Irúfẹ́ àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni a pa àṣẹ ìtọ́ni fún, tí a sì fún ní ọ̀rọ̀ ìyànjú nínú Jésù Kristi Olúwa pé nípa ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún.”—2 Tẹsalóníkà 3:10-12.
Síbẹ̀, ríríṣẹ́ àti rírí towó ṣe kọ́ ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ayé kì í pẹ́ sú àwọn tí ń kánjú àtilà, wọ́n sì lè wá rí i pé ‘ẹ̀fúùfù ni àwọn ń lépa.’ (Oníwàásù 1:14) Dípò kí àwọn òbí máa rọ àwọn ọmọ wọn láti lépa dídi olókìkí àti ọlọ́lá, ì bá dára bí wọ́n bá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ọgbọ́n tó wà nínú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù tí Ọlọ́run mí sí, pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé. Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:15-17.
Báwo Lo Ṣe Lè Tẹ́ Àìní Wọn Nípa Èrò Ìmọ̀lára Lọ́rùn?
Gẹ́gẹ́ bí òbí, èé ṣe tí o kò fi ṣe bí ẹni tí ń kọ́ àwọn eléré ìdárayá? Kì í ṣe kí àwọn eléré ìdárayá tó ń bójú tó máa sá eré tete tàbí kí wọ́n lè fò kan ọ̀run nìkan ló máa ń gbájú mọ́. Ṣùgbọ́n, ó tún ń sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìṣarasíhùwà òdì, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ fi kún okun inú wọn. Nínú ọ̀ràn tìrẹ, báwo lo ṣe lè fún àwọn ọmọ rẹ ní ìṣírí, kí o gbé wọn ró, kí o sì sún wọn ṣiṣẹ́?
Gbé ọ̀ràn Rogério, ọ̀dọ́ ọmọ ọdún 13, yẹ̀ wò. Yàtọ̀ sí pákáǹleke ti inú lọ́hùn-ún tó dé bá a nítorí àwọn ìyípadà nínú ara, ó tún ń fojú winá másùnmáwo nítorí àìsí ìṣọ̀kan láàárín àwọn òbí rẹ̀ àti àìsí ìtọ́jú. Kí ni a lè ṣe fún irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ó lè kó àníyàn bá wọn, tí ó sì lè nípa búburú lórí wọn, má ṣe jọ̀gọ̀nù láé pé o kò lè ṣe ojúṣe òbí. Láìṣe àṣejù nídìí dídáàbòbo ọmọ rẹ, máa fi òye bá a wí, máa rántí nígbà gbogbo pé ọmọ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀. Nípa fífi inú rere àti ìfẹ́ hàn, o lè ṣe ohun púpọ̀ láti mú kí ọ̀dọ́ kan nímọ̀lára pé ẹ̀mí òun dè. Èyí pẹ̀lú kì yóò jẹ́ kí ó dàgbà láìní ìdánilójú àti iyì ara ẹni.
Bó ti wù kí àwọn òbí tìrẹ kógo já tó ní títẹ́ àwọn àìní rẹ lọ́rùn ní ti èrò inú, ohun mẹ́ta lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kógo já gẹ́gẹ́ bí òbí tí ń ṣèrànlọ́wọ́ ní tòótọ́: (1) Yẹra fún jíjẹ́ kí òkè ìṣòro tìrẹ gbà ọ́ lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ìwọ yóò fi dágunlá sí àwọn ìṣòro ọmọ rẹ tó kéré lójú; (2) gbìyànjú láti máa bá wọn sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ lọ́nà tó lárinrin, tó sì gbéṣẹ́; (3) mú ìṣarasíhùwà rere dàgbà nípa bí a ti ń rí ojútùú sí ìṣòro àti bí a ti ń bá àwọn ènìyàn lò.
Nígbà tí Birgit bojú wẹ̀yìn wo àwọn ọdún tó fi ṣe ọ̀dọ́langba, ó wí pé: “Mo ní láti kẹ́kọ̀ọ́ pé o ò lè sọ àwọn èèyàn da ohun tí o fẹ́ kí wọ́n dà. Ìyá mi bá mi sọ̀rọ̀ pé bí mo bá rí ìwà kan tí àwọn kan ń hù tí n kò fẹ́, ohun tí mo lè ṣe ni kí n yẹra fún dídàbí wọn. Ó tún sọ pé ìgbà tó dára jù lọ láti yí ọ̀nà mi padà ni ìgbà tí mo ṣì kéré.”
Síbẹ̀, àwọn ọmọ rẹ nílò ju iṣẹ́ àti ìyèkooro èrò inú. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Mo ha ń wo jíjẹ́ òbí gẹ́gẹ́ bí ẹrù iṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí?’ Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ìwọ yóò fẹ́ láti bójú tó àwọn àìní tẹ̀mí ti àwọn ọmọ rẹ.
Bí A Ṣe Lè Bójú Tó Àìní Wọn Nípa Tẹ̀mí
Nígbà tí Jésù Kristi ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, ó wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mátíù 5:3) Kí ni títẹ́ àwọn àìní tẹ̀mí lọ́rùn wé mọ́? Àwọn ọmọ máa ń jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ bí àwọn òbí wọ́n bá fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní fífi ìgbàgbọ́ hàn nínú Jèhófà Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu [Ọlọ́run] dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ṣùgbọ́n, kí ìgbàgbọ́ tó lè ní ìtumọ̀ tí ó ṣe gúnmọ́, a nílò àdúrà. (Róòmù 12:12) Bí o bá mọ àìní rẹ nípa tẹ̀mí, ìwọ yóò máa wá ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá, gẹ́gẹ́ bí bàbá Sámúsìnì ti ṣe, ọmọ tí ó di gbajúgbajà Onídàájọ́ Ísírẹ́lì. (Onídàájọ́ 13:8) O kò ní fi mọ sí àdúrà nìkan, ṣùgbọ́n ìwọ yóò tún lọ sínú Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí, fún ìrànlọ́wọ́.—2 Tímótì 3:16, 17.b
Láìka gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí ó wà nínú pípèsè ìtọ́sọ́nà yíyèkooro, ìtìlẹyìn èrò inú, àti ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí sí, èrè wà nínú ọmọ títọ́. Baba ọmọ méjì ní Brazil sọ pé: “Èmi kò tilẹ̀ mọ bí ì bá ṣe rí ká ní n kò bí àwọn ọmọ mi. Nǹkan rere tí a ń fi fún wọn kò lóǹkà.” Nígbà tí ìyá wọn ń ṣàlàyé ìdí tí àwọn ọmọ náà fi ń ṣe dáadáa, ó fi kún un pé: “A sábà máa ń wà pa pọ̀, a sì máa ń gbìyànjú láti mú kí ilé dùn yùngbà. Àti pé, lékè gbogbo rẹ̀, ìgbà gbogbo ni a máa ń gbàdúrà fún àwọn ọmọ náà.”
Priscilla rántí ìfẹ́ àti sùúrù tí àwọn òbí rẹ̀ fi bá a lò nígbàkigbà tí ìṣòro bá dé. Ó sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi tòótọ́ ni wọ́n jẹ́, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ nínú ohun gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, mo nímọ̀lára ní tòótọ́ pé wọ́n ń ṣe mi bí ‘ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’” (Sáàmù 127:3) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ òbí mìíràn, èé ṣe ti o kò ṣètò àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ kí ẹ bàa lè máa ka Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni pa pọ̀? Gbígbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìlànà Bíbélì yẹ̀ wò lábẹ́ ipò tí ó wọ̀ lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn, kí wọ́n sì ní ìrètí tòótọ́ fún ọjọ́ ọ̀la.
Ìgbà Tí Gbogbo Ọmọ Yóò Wà Lábẹ́ Ààbò
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ọ̀la pòkúdu fún ọ̀pọ̀ ọmọ lónìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé ilẹ̀ ayé yóò jẹ́ ilé aláàbò fún aráyé láìpẹ́. Sáà ronú nípa àkókò náà nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, nígbà tí àwọn òbí kò ní dààmú mọ́ nípa ààbò ọmọ wọn! (2 Pétérù 3:13) Gbìyànjú láti fojú inú wo ìmúṣẹ gíga lọ́lá tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò ní: “Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n.” (Aísáyà 11:6) Lónìí pàápàá, ààbò tẹ̀mí tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣàpèjúwe ti ń ní ìmúṣẹ ìṣàpẹẹrẹ láàárín àwọn tí ń sin Jèhófà. Láàárín wọn, ìwọ yóò gbádùn àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run. Bí o bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, o lè ní ìdánilójú pé òun lóye ìmọ̀lára rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fàyàrán ìdààmú àti àdánwò tó lè dé bá ọ. Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí o sì nírètí nínú Ìjọba rẹ̀.
Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà ìyè ayérayé nípa fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Bí o bá sá di Jèhófà Ọlọ́run, ọjọ́ ọ̀la rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ lè dára ju ohun tí o lè ronú kàn. O lè ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé tí onísáàmù náà ní, ẹni tí ó kọ ọ́ lórin pé: “Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.”—Sáàmù 37:4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A lo àwọn orúkọ àfirọ́pò nínú àpilẹ̀kọ yìí.
b Wo orí 5 sí 7 nínú ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.