ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/99 ojú ìwé 7
  • Ṣé Ò Ń Kó Lọ Síbòmíràn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ò Ń Kó Lọ Síbòmíràn?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ara Ẹ Ṣe Lè Mọlé Nínú Ìjọ Tuntun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Kí a Gbé Ìjọ Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Ìjọ Máa Yin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Bí Ara Ẹ Ṣe Lè Mọlé Nínú Ìjọ Tó O Wà Báyìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 10/99 ojú ìwé 7

Ṣé Ò Ń Kó Lọ Síbòmíràn?

Bó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni ni ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ àti àwọn ẹlòmíràn gbọ́dọ̀ lo ìdánúṣe láti ṣe. Nípa gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì tí a ṣàlàyé nísàlẹ̀ yìí, kò ní pẹ́ tí gbogbo èèyàn yóò fi mọ̀ pé ìjọ tóo ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ nìyẹn.

(1) Gbàrà tóo bá ti mọ ibi tí o ń ṣí lọ, akọ̀wé ìjọ rẹ lè gba àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba ìjọ rẹ tuntun. Bóo bá ti dé ibẹ̀, wá gbọ̀ngàn náà rí lọ́gán kí o sì mọ àwọn àkókò ìpàdé. Bó bá jẹ́ pé ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ju ẹyọ kan lọ, béèrè orúkọ ìjọ tí o ń gbé ìpínlẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn alàgbà. Má ṣe jáfara láti lọ sí àwọn ìpàdé àti láti di ojúlùmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ.

(2) Akọ̀wé ìjọ tí o wà àti ti ìjọ rẹ tuntun yóò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti rí i pé wọ́n fi káàdì ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn, Congregation’s Publisher Record, tìẹ àti ti ìdílé ẹ ránṣẹ́. Wọ́n á tún kọ lẹ́tà àlàyé nípa rẹ sí àwọn alàgbà ìjọ rẹ tuntun. (Wo Àpótí Ìbéèrè inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1991.) Kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ rẹ tuntun sọ fún Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tó bá yẹ nípa dídé rẹ kí ó lè wá bá ọ kí ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ àwùjọ tuntun tí wàá máa bá ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.—Róòmù 15:7.

(3) Gbogbo akéde tó wà ní ìjọ rẹ tuntun ló ní ojúṣe tó ń máyọ̀ wá—láti di ojúlùmọ̀ rẹ kí wọ́n sì mú kí ara tù ẹ́. (Fi wé 3 Jòhánù 8.) Àmọ́ ṣá o, èyí túmọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ máa lọ sí àwọn ìpàdé kí o lè máa gbádùn pàṣípààrọ̀ ìṣírí tí ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin.

(4) Kò yẹ kí o dúró di ìgbà tí gbogbo iṣẹ́ tó yẹ ní ṣíṣe nípa ṣíṣílọ rẹ bá parí kí o tó bẹ̀rẹ̀ síí kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá pẹ̀lú ìjọ rẹ tuntun. Bí o ṣe ń fi àwọn ire Ìjọba náà sí ipò kìíní, àwọn ọ̀ràn yòókù yóò rí àbójútó, ara á sì tù ẹ́ dáadáa ní àgbègbè rẹ tuntun. (Mát. 6:33) Bóo bá ti fìdí múlẹ̀ ní ibùgbé rẹ tuntun, o lè ké sí àwọn kan nínú ìjọ rẹ láti wá bẹ̀ ẹ́ wò kí o sì túbọ̀ dojúlùmọ̀ wọn.—Róòmù 12:13b.

Iṣẹ́ ńlá ni kíkó lọ síbòmíràn jẹ́. Ṣùgbọ́n, tí gbogbo àwọn tọ́ràn kàn bá ṣe ohun tí a dábàá, kò ní sí ìfàsẹ́yìn kankan nípa tẹ̀mí. Gbogbo àwọn tọ́ràn kàn ni ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa yóò wú lórí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́