Ibo Ni A Ti Lè Rí Ayọ̀ Tòótọ́?
Ọ̀PỌ̀ ènìyàn rò pé a lè rí ayọ̀ nípa kíkó àwọn ohun ìní ti ara jọ. Ìwọ ńkọ́? Bí àwọn nǹkan ti ara tilẹ̀ lè fi kún ayọ̀ wa ní ti gidi, wọ́n kì í mú un dá wa lójú; bẹ́ẹ̀ sì ni ìtẹ́lọ́rùn ti ara kò gbé ìgbàgbọ́ ró tàbí kájú àwọn àìní tẹ̀mí.
Nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jésù Kristi sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba àwọn ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mátíù 5:3) Jésù tún sọ pé: ‘Ẹ máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.’—Lúùkù 12:15.
Ọ̀pọ̀ ń wá ayọ̀ nípa lílọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ tí ó lòdì sófin àti “àwọn iṣẹ́ ti ẹran ara” mìíràn. (Gálátíà 5:19-21) Ṣùgbọ́n, jíjọ̀wọ́ ara ẹni fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara kì í mú ayọ̀ tòótọ́, tí ó wà pẹ́ títí wá. Ní tòótọ́, àwọn tí ń fi irú àwọn nǹkan báwọ̀nyí ṣèwàhù kì yóò jogún Ìjọba Ọlọ́run.—Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 10.
Nínú wíwá tí wọ́n ń wá ayọ̀ kiri, àwọn mìíràn ń yíjú sí ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, nípa gbígbìyànjú láti mú ọ̀wọ̀ ara ẹni wọn pọ̀ sí i. Àwọn ìwé tí ń pèsè ìmọ̀ràn bí-a-tií-ṣe-é kún inú àwọn ilé ìkówèésí àti ilé ìtàwé, ṣùgbọ́n irú àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ kò tí ì mú ayọ̀ pípẹ́ títí wá fún àwọn ènìyàn. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, níbo ni a ti lè rí ojúlówó ayọ̀?
Láti lè láyọ̀ ní tòótọ́, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí tí a ti dá mọ́ wa. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí jẹ lọ́kàn.” Dájúdájú, kì yóò ṣe wá ní àǹfààní kankan bí a bá mọ àìní yìí, tí a sì kùnà láti ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀. Láti ṣàkàwé: Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí eléré ẹlẹ́mìí ẹṣin kan, tí kò mu omi tí ara rẹ̀ ń fẹ́, lẹ́yìn eré ìje náà? Òun kò ha ní pàdánù omi ara, kí ó sì jìyà àwọn àbájáde eléwu mìíràn láìpẹ́ bí? Lọ́nà kan náà, bí a kò bá tẹ́ àìní wa fún oúnjẹ tẹ̀mí lọ́rùn, a óò rọ nípa tẹ̀mí nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Èyí yóò yọrí sí pípàdánù ìdùnnú àti ayọ̀.
Jésù mọ àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí ní kíkún, ní kíkẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣàṣàrò déédéé nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó lè fi ìrọ̀rùn wá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, kí ó sì kà wọ́n, ó sì kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe bákan náà. (Lúùkù 4:16-21; fi wé Éfésù 4:20, 21.) Jésù tún fi ṣíṣe ìfẹ́ inú Bàbá rẹ̀ ọ̀run wé oúnjẹ. Ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run mú ayọ̀ púpọ̀ wá fún un.—Jòhánù 4:34.
Bẹ́ẹ̀ ni, a kò lè ní ayọ̀ tòótọ́ nípa kíkó àwọn ohun ìní ti ara jọ; bẹ́ẹ̀ sì ni ayọ̀ kì í jẹyọ láti inú gbígbọ́ ti ẹran ara aláìpé. Ayọ̀ tòótọ́ jẹ́ ipò ọkàn àyà, tí a gbé karí ojúlówó ìgbàgbọ́ àti ipò ìbátan rere pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, nígbà náà, onísáàmù náà, Dáfídì, kọrin pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn náà tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn.”—Orin Dáfídì 144:15b, NW.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìgbàgbọ́ àti ipò ìbátan rere pẹ̀lú Ọlọ́run yóò mú ayọ̀ tòótọ́ wá fún ọ