ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/22 ojú ìwé 12-14
  • Ta Ló Yẹ Kí N Fi Ṣe Àwòkọ́ṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ló Yẹ Kí N Fi Ṣe Àwòkọ́ṣe?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ẹni Àwòkọ́ṣe—Àwọn Tí Ń Ṣàǹfààní àti Àwọn Tí Ń Ṣèpalára
  • Bí Ẹni Tí Ó Jẹ́ Àwòkọ́ṣe Dáradára Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
  • Àwọn Òbí bí Àwòkọ́ṣe
  • Ẹni Àwòkọ́ṣe Tí Ó Dára Jù Lọ
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rẹ́ni Tó Dáa Fi Ṣe Àwòkọ́ṣe?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Wo Ni Mo Fi Ń Ṣe Àwòkọ́ṣe?
    Jí!—2012
  • Ṣé Àwọn Òbí Mi—Ni Yóò Pinnu Ẹ̀sìn Mi Àbí Èmi Fúnra Mi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ẹyin Èwe—Ki Ni Ẹyin Ń Lépa?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 5/22 ojú ìwé 12-14

Ta Ló Yẹ Kí N Fi Ṣe Àwòkọ́ṣe?

“Tálẹ́ńtì tí ó ní bí agbábọ́ọ̀lù-alápẹ̀rẹ̀ kàmàmà. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi fẹ́ràn rẹ̀. Òun ni àwòkọ́ṣe mi nígbà kan, mo sì fẹ́ láti dà bí rẹ̀ àti láti ní ohun tí ó ní.”—Ping, ọ̀dọ́ kan láti Éṣíà.

ÀWỌN ènìyàn tí wọ́n jọ wá lójú tí a sì ń káṣà wọn yìí ni a sábà máa ń pè ní àwòkọ́ṣe. Òǹkọ̀wé Linda Nielsen sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ máa ń káṣà àwọn ènìyàn tí wọ́n bá lóye ìmọ̀lára àti èrò wọn àti àwọn tó bá ń gba àfiyèsí tàbí èrè tí ojú wọn wọ̀.” Nítorí náà, àwọn èwe máa ń ní ìtẹ̀sí láti ka àwọn ojúgbà wọn tí wọ́n gbajúmọ̀ tàbí tí wọ́n jojú ní gbèsè sí. Ṣùgbọ́n ní pàtàkì, ọ̀pọ̀ èwe máa ń fẹ́ láti fi àwọn gbajúgbajà òṣèré inú sinimá, àwọn olórin, àti àwọn eléré ìdárayá ṣe àwòkọ́ṣe.

Dájúdájú, bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn gbajúgbajà ènìyàn ṣe ń fara hàn nínú eré sábà máa ń jẹ́ kìkì ìrísí tí kì í ṣe ojúlówó, ìgbékalẹ̀ tí a fìṣọ́ra ṣe láti fi àwọn àléébù pa mọ́, láti jẹ́ kí a pọ́nni lé àti, ju gbogbo rẹ̀ lọ, láti tajà! Ping, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú, gbà pé: “Mo ra gbogbo fídíò tí agbábọ́ọ̀lù-alápẹ̀rẹ̀ tí mo fẹ́ràn náà wà, mo sì ń wọ irú àwọn aṣọ àti bàtà tí ó máa ń wọ̀.” Àwọn èwe kan máa ń múra bí ti àwọn òṣèré orí tẹlifíṣọ̀n tàbí eléré ìdárayá tí wọ́n fẹ́ràn; wọ́n máa ń ṣe irun wọn bí ti àwọn ẹni náà; wọ́n tilẹ̀ máa ń rìn, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ bí ti àwọn ẹni náà.

Àwọn Ẹni Àwòkọ́ṣe—Àwọn Tí Ń Ṣàǹfààní àti Àwọn Tí Ń Ṣèpalára

O béèrè pé: ‘Ìpalára wo ló wà nínú fífẹ́ràn ẹnì kan?’ Ìyẹn sinmi lé ẹni tí o fẹ́ràn náà. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Bíbélì kò fún wa níṣìírí láti máa ṣe ọmọlẹ́yìn àwọn ènìyàn. (Mátíù 23:10) Àmọ́ ó sọ fún wa pé kí a jẹ́ “aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Hébérù 6:12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ó fi lè sọ pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.”—1 Kọ́ríńtì 11:1.

Ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń jẹ́ Tímótì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó bá Pọ́ọ̀lù ṣọ̀rẹ́ ní àwọn ìgbà tí wọ́n jọ rìnrìn àjò bí míṣọ́nnárì. (Ìṣe 16:1-4) Pọ́ọ̀lù wá ka Tímótì sí “ọmọ [rẹ̀] olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 4:17) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù, Tímótì wá di ọkùnrin Kristẹni kan tí ó tayọ.—Fílípì 2:19-23.

Àmọ́, kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí o bá yan ẹni àwòkọ́ṣe tí kò yẹ? Ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń jẹ́ Richard sọ pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 15, ọmọ kan tí a jùmọ̀ ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ kan náà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mario di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi. Kristẹni ni àwọn òbí mi, wọ́n sì gbìyànjú láti ràn mí lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Àmọ́ gbogbo ohun amóríyá—orin dísíkò, àpèjẹ, alùpùpù, àti àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀—ló pé sọ́wọ́ Mario. Ó lè ṣe ohun tí ó bá fẹ́, nígbà tí ó bá fẹ́. Èmi kò sì láǹfààní irú rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí mo di ọmọ ọdún 16, mo sọ fún àwọn òbí mi pé ń kò fẹ́ jẹ́ Kristẹni mọ́, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀.”

Àwọn ewu tí ó jọra ha wà nínú kíka àwọn gbajúgbajà àti àwọn akọni eléré ìdárayá sí ẹni àwòkọ́ṣe bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ewu wà níbẹ̀. Wàyí o, kò sí ohun tí ó burú nínú fífẹ́ràn agbára ìṣeǹkan tí eléré ìdárayá, òṣèré, tàbí olórin kan ní. Àmọ́ bí ara rẹ léèrè pé, ‘Irú àpẹẹrẹ wo ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi lélẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn?’ A kò ha mọ ọ̀pọ̀ àwọn akọni eléré ìdárayá, àwọn olórin, àti àwọn tí ń ṣe irú eré mìíràn sí ẹni tí ìṣekúṣe, oògùn líle, àti ọtí líle ti jàrábà wọn? Kì í ha ṣe òtítọ́ tún ni pé púpọ̀ wọn ń gbé ìgbésí ayé àìláyọ̀, tí kò nítumọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní owó àti òkìkí? Bí o bá rò ó wò lọ́nà yìí, àǹfààní wo ni ó lè ti inú kíkáṣà irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wá?

Òtítọ́ ni pé kíkó àṣà irun, aṣọ, tàbí ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ gbajúgbajà kan lè dà bí nǹkan kékeré. Ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ sí fífàyègba ayé láti “sọ ọ́ dà bí òun ti dà.” (Róòmù 12:2, Phillips) Bí ó ṣe dà tí ó sọ ọ́ dà yẹn lè kọ́kọ́ dà bí èyí tí ó gbádùn mọ́ni. Àmọ́ bí o bá juwọ́ sílẹ̀ pátápátá fún àwọn agbára ìdarí rẹ̀, ó lè sọ ọ́ dà bí ó ti dà lọ́nà kan tí ó dájú pé yóò mú kí o kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Bíbélì sọ nínú Jákọ́bù 4:4 pé: “Ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run.”

Bí Ẹni Tí Ó Jẹ́ Àwòkọ́ṣe Dáradára Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́

Bí ó ti wù kí ó rí, kíkáṣà ẹnì kan tí ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ lè ní ipa rere lórí ìgbésí ayé rẹ! O lè rí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ “àpẹẹrẹ . . . nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́” láàárín àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ. (1 Tímótì 4:12) Òtítọ́ ni pé ó yẹ kí o ṣọ́ra nípa bí o ṣe ń yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́, kódà nínú ìjọ Kristẹni pàápàá. (2 Tímótì 2:20, 21) Ṣùgbọ́n kì í sábà ṣòro láti mọ àwọn tí “ń rìn nínú òtítọ́” nínú ìjọ ní ti gidi. (2 Jòhánù 4) Ìlànà tí ó wà ní Hébérù 13:7 sọ pé: “Bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.” Ní ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ojúgbà rẹ, a kò tíì mọ bí ìwà wọn yóò ṣe rí. Àmọ́ àwọn àgbàlagbà wà nínú ìjọ tí wọ́n ti fi ìdúróṣinṣin wọn hàn, ó sì bọ́gbọ́n mu láti máa mọ̀ wọ́n.

O lè béèrè pé, ‘Láti máa mọ àwọn àgbàlagbà kẹ̀?’ Òtítọ́ ni pé èyí lè má dà bí ohun tí ń wuni lákọ̀ọ́kọ́. Ṣùgbọ́n rántí àjọṣe tí Tímótì ní pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ àgbàlagbà náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù mọ ohun tí Tímótì lè wá dà lọ́jọ́ iwájú, ó sì fún un níṣìírí láti “rú sókè bí iná, ẹ̀bùn Ọlọ́run” tí ń bẹ nínú rẹ̀. (2 Tímótì 1:6) Kì yóò ha ṣàǹfààní láti ní ẹnì kan tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́, tí yóò sì fún ọ níṣìírí, ẹnì kan tí ń rọ̀ ọ́ láti ṣìkẹ́ àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ọ?

Èwe kan tí ń jẹ́ Bryan rí i pé èyí rí bẹ́ẹ̀. Ìgbà tí ó ń ní ìmọ̀lára àìjámọ́ǹkan ni ó di ojúlùmọ̀ àgbàlagbà àpọ́n kan, tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Bryan sọ pé: “Mo fẹ́ràn àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí ó ní nípa àwọn ẹlòmíràn, àti èmi pàápàá; ìtara tí ó ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́; àti àwọn àwíyé gbígbádùnmọ́ni tí ó máa ń sọ.” Bryan ti ń jàǹfààní àfiyèsí tí Kristẹni àgbàlagbà yìí ń fún un. Ó sọ ní ṣàkó pé: “Èyí ti ràn mí lọ́wọ́ láti máà jẹ́ ohun tí mo jẹ́ tẹ́lẹ̀ mọ́—onítìjú àti ẹni tí kò lọ́yàyà.”

Àwọn Òbí bí Àwòkọ́ṣe

Ìwé náà, Adolescence—Generation Under Pressure, sọ pé, àwọn òbí nìkan ni “agbára ìdarí òde pàtàkì jù lọ tí ó lè ṣèrànwọ́ tàbí tí ó lè ṣèdíwọ́ fún aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà kan tí a lè mú bí àpẹẹrẹ láti ní ìwà tí ó tẹ́ni lọ́rùn.” Ìwé náà fi kún un pé, láìsí ọgbọ́n ìtọ́sọ́nà àti ìfinipeni lọ́nà ṣíṣekedere yẹn níbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ “yóò dà bí ọkọ̀ òkun tí kò ní ìtọ́kọ̀, tí ìgbì òkun ń gbá káàkiri.”

Ìmọ̀ràn yìí ṣàgbéyọ ohun tí ọmọlẹ́yìn Jákọ́bù kọ ní ohun tí ó lé ní 1,900 ọdún sẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ ọ́ nínú Jákọ́bù 1:6 pé: “Kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá, nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyè méjì dà bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì, tí a sì ń fẹ́ káàkiri.” Ó ṣeé ṣe kí o mọ àwọn èwe kan tí wọ́n rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí gbígbádùn àwọn ohun amóríyá òde òní, wọn kò sì ronú nípa ọjọ́ iwájú.

Ìwọ ha ní ìbùkún níní àwọn òbí tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ìjọ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o ha ń tẹ̀ lé ìdarí wọn bí? Àbí gbogbo ìgbà ni o máa ń bá wọn jà? Òtítọ́ ni pé àwọn òbí rẹ kì í ṣe ẹni pípé. Àmọ́ má sọ pé o kò rí àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní—àwọn ànímọ́ tí yóò dára kí o fara wé. Kristẹni ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Jarrod kọ̀wé pé: “Àwọn òbí mi jọ mí lójú gan-an. Ìtara onífaradà wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ọ̀nà tí wọ́n gbà kojú ìṣòro ìṣúnná owó, àti ìṣírí tí wọ́n fún mi láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, gbogbo rẹ̀ ní ipa dídára lórí mi. Àwọn òbí mi ti sábà ń jẹ́ àwòkọ́ṣe mi.”

Ẹni Àwòkọ́ṣe Tí Ó Dára Jù Lọ

Nígbà tí àjọ aṣèwádìí náà, Gallup, béèrè lọ́wọ́ àwọn èwe kan ní United States nípa ẹni tí wọ́n rò pé ó tóbi jù lọ nínú ìtàn, púpọ̀ jù lọ lára wọn tọ́ka sí àwọn òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ìpín 6 nínú ọgọ́rùn-ún péré lára wọn ló tọ́ka sí Jésù Kristi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ fún wa pé Jésù Kristi fi “àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún [wa] kí [a] lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21; Hébérù 12:3) Ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun. (Mátíù 11:28, 29) Ṣùgbọ́n báwo ni o ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù?

Mọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù dáradára. Gbìyànjú láti ka àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere látòkèdélẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìwé náà, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí.a Ṣàkíyèsí ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni, ọ̀nà ìyọ́nú tí ó gbà bá àwọn ènìyàn lò, àti ìgboyà tí ó fi hàn nígbà tí ó wà nínú pákáǹleke. Ìwọ yóò rí i pé Jésù ni àwòkọ́ṣe dídárajùlọ tí o lè fara wé.

Bí o bá ṣe mọ ẹni àwòkọ́ṣe pípé náà tó, ni ọkàn rẹ kò ní fà mọ́ àwọn ojúgbà tàbí àwọn gbajúgbajà tí ó léwu láti bá rìn tó. Ṣé o rántí Ping àti ìfẹ́ tí ó ní fún akọni eléré ìdárayá kan? Ping ṣì máa ń gbádùn gbígbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ó ti wá rí i pé kò bọ́gbọ́n mu láti máa fi àwọn gbajúgbajà ṣe àwòkọ́ṣe.

Richard náà ńkọ́? Ẹni tí ó yàn bí àwòkọ́ṣe sún un sí fífi ìsìn Kristẹni sílẹ̀. Àmọ́, Richard wá mọ ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó ti lé ní ẹni 20 ọdún, tí ń jẹ́ Simon, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Richard sọ pé: “Simon mú mi lọ́rẹ̀ẹ́, ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé a lè gbádùn ìgbésí ayé láìsí pé a fọwọ́ rọ́ àwọn ìlànà Bíbélì sẹ́yìn. Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀wọ̀ fún Simon, àpẹẹrẹ rẹ̀ sì kó ipa pàtàkì nínú pípadà mi sínú ìjọ àti yíya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Ayọ̀ mi kún sí i nísinsìnyí, ìgbésí ayé mi sì ní ìtumọ̀ gidi.”

Òtítọ́ ni, ẹni tí o yàn bí àwòkọ́ṣe ṣe pàtàkì ní ti gidi!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ní ìfùsì rere lè ràn ọ́ lọ́wọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́