ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 5/1 ojú ìwé 5-7
  • Ta Ni Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Jèhófà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjẹ́pàtàkì Orúkọ Rẹ̀
  • Àwọn Ànímọ́ Jèhófà Títayọ Jù Lọ
  • Ọlọ́run Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
  • Àǹfààní Mímọ Jèhófà
  • Ta Ni Ọlọrun Tòótọ́ Náà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ẹ Gbé Jèhófà Ga Nítorí Òun Nìkan Ni Ọlọ́run Tòótọ́
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 5/1 ojú ìwé 5-7

Ta Ni Jèhófà?

JÈHÓFÀ sọ fún ọ̀kan lára àwọn olùjọsìn rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Kò sí ènìyàn tí ó lè rí mi kí ó sì wà láàyè síbẹ̀.” (Ẹ́kísódù 33:20) “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,” àwọn ènìyàn kò sì lè fi ojúyòójú wọn rí i. (Jòhánù 4:24) Gan-an gẹ́gẹ́ bí wíwo oòrùn ní ọ̀sán gangan ti lè bà wá lójú jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwo Orísun agbára bíbùáyà tí kì í ṣe pé òun ni ó dá oòrùn wa lílágbára nìkan ni, ṣùgbọ́n tí ó tún dá ẹgbàágbèje oòrùn mìíràn nínú àgbáálá ayé ṣe lè bà wá lójú jẹ́.

Ó dùn mọ́ni pé, kò di ìgbà tí a bá rí Ọlọ́run kí a tó lè mọ̀ nípa rẹ̀. Bíbélì jẹ́ kí a mọ Ẹni tí ó ṣètò ẹ̀bùn àgbàyanu náà, ilẹ̀ ayé, fún wa, ó sì ṣí àkópọ̀ ìwà rẹ̀ payá. Nítorí náà, ó yẹ kí a yẹ Bíbélì wò láti mọ̀ nípa Bàbá tí ó fún wa ní ìyè, tí ó sì pèsè ilé mèremère tí a ti lè gbádùn ìgbésí ayé wa fún wa.

Ìjẹ́pàtàkì Orúkọ Rẹ̀

Gbogbo orúkọ ni ó ní ìtumọ̀, àní bí ọ̀pọ̀ kò tilẹ̀ mọ ohun tí ó túmọ̀ sí lónìí. Fún àpẹẹrẹ, orúkọ èdè Gẹ̀ẹ́sì náà, Dáfídì, wá láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí ó túmọ̀ sí “Olùfẹ́.” Orúkọ Ẹlẹ́dàá náà, Jèhófà, pẹ̀lú ní ìtumọ̀. Kí ni ó túmọ̀ sí? Nínú èdè Bíbélì ti ìpilẹ̀ṣẹ̀, Hébérù, orúkọ lẹ́tà mẹ́rin, YHWH, ni a fi kọ orúkọ àtọ̀runwá náà, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà 7,000 tí ó fara hàn nínú apá tí a fi èdè Hébérù kọ nínú Bíbélì. A lóye pé orúkọ àtọ̀runwá náà túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Ó túmọ̀ sí pé Jèhófà ń lo ọgbọ́n láti mú kí òun di ohunkóhun tí ó bá fẹ́ láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Òun ni Ẹlẹ́dàá, Onídàájọ́, Olùgbàlà, Ẹni tí ń gbé ìwàláàyè ró, nítorí náà, ó lè mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Ní àfikún sí i, nínú èdè Hébérù, orúkọ náà, Jèhófà, ṣiṣẹ́ bí oríṣi ọ̀rọ̀ ìṣe kan tí ó fi ìgbésẹ̀ kan tí ó wà lẹ́nu àtiparí hàn. Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ṣì ń mú kí òun di olùmú àwọn ète òun ṣẹ. Ó jẹ́ Ọlọ́run alààyè!

Àwọn Ànímọ́ Jèhófà Títayọ Jù Lọ

Bíbélì ṣàpèjúwe Ẹlẹ́dàá náà gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Gbólóhùn náà, “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” tú ọ̀rọ̀ Hébérù kan tí ó nítumọ̀ gidigidi. Ó túmọ̀ sí inú rere tí ń fi ìfẹ́ so ara rẹ̀ mọ́ ohun kan títí tí ó fi máa mú ète rẹ̀ fún ohun náà ṣẹ. A tún lè túmọ̀ rẹ̀ sí “ìfẹ́ dídúró ṣinṣin.” Inú rere Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ so ara rẹ̀ mọ́ àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀, ó sì ń mú ète àgbàyanu rẹ̀ ṣẹ. O kò ha ní ṣìkẹ́ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹni náà tí ó fún ọ ní ìwàláàyè bí?

Jèhófà ń lọ́ra láti bínú, ó sì ń yára láti dárí àwọn ìṣìnà wa jì wá. Ó ń múni lọ́kàn yọ̀ láti sún mọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ó ń gbójú fo ìwà àìtọ́. Ó polongo pé: “Èmi, Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, mo kórìíra ìjanilólè pa pọ̀ pẹ̀lú àìṣòdodo.” (Aísáyà 61:8) Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo, òun kò ní fàyè gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ń mójú kuku láti máa bá ìwà burúkú wọn lọ títí láé. Nípa báyìí, a lè ní ìdánilójú pé láìpẹ́, Jèhófà yóò ṣàtúnṣe àìsídàájọ́ òdodo nínú ayé. Òun kò ní dágunlá sí àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.

Kò rọrùn láti wà déédéé nínú fífi ìfẹ́ hàn àti ṣíṣe ìdájọ́ òdodo. Bí o bá jẹ́ òbí, ó ha ṣòro fún ọ láti pinnu ìgbà tí ó yẹ kí o bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí nígbà tí wọ́n bà hùwà tí kò tọ́, bí ó ṣe yẹ kí o bá wọn wí àti bí ó ṣe yẹ ki ìbáwí náà tó? Ó ń béèrè ọgbọ́n ńlá láti lè mú kí a wà déédéé nínú ṣíṣe ìdájọ́ òdodo àti fífi ìyọ́nú onífẹ̀ẹ́ hàn. Ànímọ́ yẹn ni Jèhófà ń fi hàn ní yanturu nígbà tí ó bá ń bá àwọn ẹ̀dá ènìyàn lò. (Róòmù 11:33-36) Ní tòótọ́, a lè rí ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá náà níbi gbogbo, fún àpẹẹrẹ nínú àwọn ohun àgbàyanu tí ń bẹ nínú ìṣẹ̀dá tí ó yí wa ká.—Sáàmù 104:24; Òwe 3:19.

Àmọ́ ṣáá o, níní ọgbọ́n nìkan kò tó. Láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, Ẹlẹ́dàá náà gbọ́dọ̀ ní agbára, Bíbélì sì ṣí i payá pé ó lágbára gan-an: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.” (Aísáyà 40:26) Pẹ̀lú “ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga,” Jèhófà ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan. Irú ànímọ́ báyìí kò ha ní fà ọ́ mọ́ ọn bí?

Ọlọ́run Gbogbo Orílẹ̀-Èdè

O lè ṣe kàyéfì pé, ‘Kì í ha ṣe Jèhófà ni Ọlọ́run “Májẹ̀mú Láéláé,” Ọlọ́run Ísírẹ́lì ìgbàanì bí?’ Òtítọ́ ni pé Jèhófà ṣí ara rẹ̀ payá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ pé òun ni ó dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, Jèhófà ni Ọlọ́run “láti ọ̀dọ̀ ẹni tí olúkúlùkù ìdílé . . . lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀.” (Éfésù 3:15) Bí o bá gbà gbọ́ pé ó tọ́ láti bọ̀wọ̀ fún àwọn baba ńlá rẹ, kì yóò ha jẹ́ ohun yíyẹ láti wárí fún Ẹni náà tí ó fún ọkùnrin àkọ́kọ́, baba ńlá gbogbo wa, tí gbogbo ìran tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ìwàláàyè bí?

Ẹlẹ́dàá aráyé kì í ṣe aláìgbatẹnirò. Lóòótọ́, nígbà kan ó ní ipò ìbátan àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n, nígbà náà pàápàá, ó fi tayọ̀tayọ̀ gba gbogbo ẹni tí ó bá ké pe orúkọ rẹ̀. Ọlọ́gbọ́n ọba kan ní Ísírẹ́lì sọ nínú àdúrà rẹ̀ sí Jèhófà pé: “Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, tí kì í ṣe ara àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí ó sì ti ilẹ̀ jíjìnnà wá ní tòótọ́ nítorí orúkọ rẹ . . . , kí ìwọ alára fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, . . . kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè náà ké pè ọ́ sí; kí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé lè wá mọ orúkọ rẹ.” (1 Àwọn Ọba 8:41-43) Títí di òní olónìí, àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè lè wá mọ Jèhófà, kí wọ́n sì ní ipò ìbátan tí ó nítumọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ṣùgbọ́n báwo ni ìyẹn ṣe kàn ọ́?

Àǹfààní Mímọ Jèhófà

Láti padà sí àkàwé inú àpilẹ̀kọ ìṣáájú, bí o bá rí ẹ̀bùn tí a pọ́n dáradára gbà, ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé ìwọ yóò fẹ́ mọ ohun tí ẹ̀bùn náà wà fún. Báwo ni kí o ṣe lò ó àti bí ó ṣe yẹ kí o tọ́jú rẹ̀? Bákan náà, a fẹ́ mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tí ó pèsè ilẹ̀ ayé fún wa. Bíbélì sọ pé “kò wulẹ̀ dá a lásán,” ṣùgbọ́n ó “ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀,” ìyẹn ni, àwa ẹ̀dá ènìyàn.—Aísáyà 45:18.

Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀dá ènìyàn kò bìkítà fún ẹ̀bùn tí Ẹlẹ́dàá náà pèsè. Wọ́n wà lẹ́nu rírun ilẹ̀ ayé, èyí tí kò mú inú Jèhófà dùn. Síbẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí orúkọ rẹ̀ dúró fún, Jèhófà ṣì pinnu láti mú ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ fún ènìyàn àti ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 115:16; Ìṣípayá 11:18) Òun yóò tún ilẹ̀ ayé ṣe, yóò sì fi fún àwọn tí ó bá ṣe tán láti gbé ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ onígbọràn, kí wọ́n lè jogún rẹ̀.—Mátíù 5:5.

Ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bíbélì ṣàpèjúwe bí àwọn nǹkan yóò ṣe rí nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Kò sí ẹni tí yóò sunkún ìbànújẹ́ tàbí ṣọ̀fọ̀ nígbà náà nítorí pípàdánù olólùfẹ́ kan. Kò sí ẹni tí yóò kígbe fún ìrànwọ́ nítorí àìnírètí tàbí tí àrùn aṣekúpani yóò kọ lù. Àní “ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:26; Aísáyà 25:8; 33:24) Èyí ń ṣàpèjúwe irú ìgbésí ayé tí Jèhófà fẹ́ kí a gbádùn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó dá àwọn baba ńlá wa àkọ́kọ́.

Ní tòótọ́, nísinsìnyí, o lè rí irú ipò párádísè bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn olùjọsìn Jèhófà. Ó sọ fún wọn pé: “Èmi Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Jèhófà jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́ tí ń kọ́ wa, àwa ọmọ rẹ̀, ní ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti gbé ìgbésí ayé. Amọ̀nà rẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn ń pèsè ààbò onífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ìkálọ́wọ́kò. Títẹ̀lé wọn yóò yọrí sí òmìnira àti ayọ̀ tòótọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Wàyí o, Jèhófà ni Ẹ̀mí náà; níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” (2 Kọ́ríńtì 3:17) Nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà tí a là sílẹ̀ nínú Bíbélì, àwọn tí ó tẹ́wọ́ gba ìṣàkóso rẹ̀ ń nírìírí àlàáfíà ọkàn tí yóò gbilẹ̀ láàárín gbogbo aráyé ní ọjọ́ kan.—Fílípì 4:7.

Ẹ wo irú Bàbá onínúure tí Jèhófà jẹ́! Ìwọ ha fẹ́ láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ẹni náà tí ń bẹ lẹ́yìn gbogbo àgbàyanu ìṣẹ̀dá? Fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn àǹfààní rẹ̀ kò ṣeé díye lé nísinsìnyí pàápàá. Ní ọjọ́ ọ̀la àwọn ìbùkún rẹ̀ yóò jẹ́ títí ayérayé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

A lè rí orúkọ àtọ̀runwá náà tí a kọ ní lẹ́tà mẹ́rin ti èdè Hébérù ní ara ògiri ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì àtijọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́