Yẹra fún Àjàgà Àwọn Àṣà Tí Kò Bá Ìlànà Kristẹni Mu
1 Àìmọye àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ló máa ń dẹ́rù pa àwọn èèyàn tó sì tún máa ń kó wọn sínú ọ̀pọ̀ ìṣòro. Jésù sọ nípa àwọn akọ̀wé àti Farisí ọjọ́ rẹ̀ pé: “Wọ́n di àwọn ẹrù wíwúwo, wọ́n sì gbé wọn lé èjìká àwọn ènìyàn.” (Mát. 23:4) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àṣà kan wà tí kò tako ìlànà Ìwé Mímọ́ ní ti gidi, àní wọ́n lè jẹ́ ẹrù wíwúwo. Bọ́ràn ṣe rí gan an nìyẹn ní ti àwọn àṣà kan tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó. Ẹrù wíwúwo tí àwọn ìnáwó tí kò pọn dandan máa ń fà àti fífi àkókò ṣòfò láìnídìí lè máà jẹ́ kí ayẹyẹ ìgbéyàwó kan jẹ́ àkókò ayọ̀ mọ́.
2 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́ tónítóní, èyí ló sì mú ká máa yẹra fún àwọn àṣà àti ìṣe tó tako àwọn ìlànà Bíbélì. Síbẹ̀, Sátánì máa ń lo àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ táa mọ̀ dáadáa pé ó jẹ́ ti àwọn abọ̀rìṣà, láì tíì sọ ti àwọn ọ̀nà mìíràn tó fara sin tó máa ń lò láti tàn wá jẹ. A ní láti wà lójúfò sí gbogbo ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tó lòdì sí ìlànà Kristẹni nígbà ayẹyẹ ìgbéyàwó. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó ń lò? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa ayẹyẹ ìgbéyàwó lọ́nà àṣà ìbílẹ̀.—2 Kọ́r. 2:11.
3 Àwọn Ìgbéyàwó Lọ́nà Àṣà Ìbílẹ̀: Ìwọ̀nyí lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ó bófin mu, ó sì tún lọ́lá pẹ̀lú. Nítorí náà, kò sóhun tó burú nínú rẹ̀ fún ìjọ Kristẹni bí a bá ṣe é lọ́nà tó tọ́. Báwo la ṣe ń ṣe ìgbéyàwó tó bófin mu lọ́nà àṣà ìbílẹ̀? Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ilé ẹjọ́ gíga kan ní Nàìjíríà sọ pé: “Kí ayẹyẹ ìgbéyàwó lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ tó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀, àwọn ohun pàtàkì tí a béèrè fún wà. Kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tí a béèrè náà yàtọ̀ láti àgbègbè kan sí òmíràn, àmọ́ àwọn ìlànà gbígbòòrò kan wà tí wọ́n máa ń bára dọ́gba nígbà mìíràn.” Àwọn ìlànà gbígbòòrò yìí ni pé (a) àwọn méjèèjì ti gbọ́dọ̀ tóótun gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí láti ṣègbéyàwó, àti pé (b) a gbọ́dọ̀ san owó orí ìyàwó fún àwọn òbí tàbí alágbàtọ́ ẹni tó ń relé ọkọ náà.
4 Ilé ẹjọ́ náà ṣàlàyé pé ó dìgbà táa bá mú ọmọbìnrin náà lọ sílé ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tí ayẹyẹ náà bá ti wá sí ìparí ká tó lè sọ pé a f ìdí ìgbéyàwó kan tí a ṣe lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ múlẹ̀. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìgbéyàwó ò tíì ṣe o. Nípa bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ báa ṣe ṣàlàyé tẹ́lẹ̀, ìgbéyàwó lọ́nà àṣà ìbílẹ̀ ní nínú sísan owó orí ìyàwó àti fífa ìyàwó léni lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, fífa ìyàwó léni lọ́wọ́ ni a máa ń ṣe ní ọjọ́ kan náà tí a tẹ́wọ́ gba owó orí ìyàwó. Láti àkókò náà lọ ni a sì ti ń ka àwọn méjèèjì sí tọkọtaya. Àmọ́ ṣáá o, kí ẹnì kan tó lè gbádùn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i nínú ìjọ, yàtọ̀ sí ti jíjẹ́ akéde, ìgbéyàwó tó ṣe lọ́nà àṣà ìbílẹ̀ ni ó gbọ́dọ̀ lọ forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní ìjọba ìbílẹ̀ tó wà, ìyẹn láwọn ìpínlẹ̀ tí èyí bá ti ṣeé ṣe.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1991, ojú ìwé 1 àti 2.
5 Àwọn ìpínlẹ̀ kan wà tó jẹ́ pé kò sí ìpèsè fún fífi orúkọ ìgbéyàwó tí a ṣe lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Bí àwọn méjì tí wọ́n fẹ́ ṣègbéyàwó bá rí i pé bọ́ràn ṣe rí nìyẹn níbi tí wọ́n ń gbé, yóò dára bí wọ́n bá kúkú ṣe ìgbéyàwó alárédè. Eléyìí yàtọ̀ sí fífi orúkọ ìgbéyàwó tí a ṣe lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Òun tún yàtọ̀ pátápátá sí ìgbéyàwó lọ́nà àṣà ìbílẹ̀. Èèyàn tiẹ̀ lè ṣe eléyìí lẹ́yìn tó bá ti kọ́kọ́ ṣe ìgbéyàwó lọ́nà àṣà ìbílẹ̀. Ní irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, a dá a lábàá pé kí á ti san owó orí ìyàwó kí á sì ti fà á lé ọkọ lọ́wọ́ bó bá ṣe lè yá tó ṣáájú ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìgbéyàwó alárédè. Kò pọn dandan láti ṣe oríṣi ìgbéyàwó méjèèjì pa pọ̀. Bó ti wù kó rí, àwọn tọkọtaya lọ́la náà ní láti gbé e yẹ̀ wò bóyá kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbéyàwó lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ lè mú kí àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ kọsẹ̀.—Róòmù 14:13, 21.
6 Ọ̀kan lára àwọn àṣà táwọn kan ti mú wọnú àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó Kristẹni láwọn apá ibì kan lórílẹ̀ èdè yìí ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ni àṣà lílo “alága ìjókòó” tó jẹ́ obìnrin nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìgbéyàwó lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀. Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó mọṣẹ́ dunjú kan ni ẹni yìí tí wọn yóò háyà láti gbẹnu sọ fún ìyàwó àti ìdílé rẹ̀, ẹni yìí máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ tó dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in gba owó àtàwọn ohun ṣíṣeyebíye mìíràn lọ́wọ́ ọkọ àtàwọn ẹbí rẹ̀. Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni láti “wà láìsí ìfẹ́ owó.” Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kínní kejì ká sì tún fẹ́ ire fún àwọn arákùnrin wa. (Héb. 13:5; Fílí. 2:4) Ó dájú pé Kristẹni kan tó bá ń lo ẹ̀bùn ìjáfáfá tó ní láti mú káwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ fi tipátipá tàbí ìtìjú fi ohun ìní ti ará sílẹ̀, kò hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àmọ̀ràn tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí.
7 Owó Orí Ìyàwó: Àṣà sísan owó orí ìyàwó kò burú. (Jẹ́n. 24:53, 54) Ta ló yẹ kó gba owó orí ìyàwó? Bàbá ìyàwó tàbí alágbàtọ́ ló máa ń gbà á. Iye tí owó orí ìyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́ yàtọ̀ síra ní àgbègbè kan sí òmíràn. Nígbà mìíràn, ìjọba máa ń fi òté lé iye tí ẹnì kan gbọ́dọ̀ san. Níbi tọ́ràn bá ti rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí òfin.—Róòmù 13:1-7.
8 Àwọn ẹ̀bùn lè wà lára owó orí ìyàwó, ó sì lè máà sí lára rẹ̀. Bí ọkọ ìyàwó bá fẹ́ láti fi ẹ̀bùn mìíràn kún owó orí ìyàwó tí a fòté lé, kò sóhun tó kan ìjọ nípa ìyẹn. Ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò fi ìwà àìnífẹ̀ẹ́ hàn bí bàbá ìyàwó bá tún ń béèrè àwọn ẹ̀bùn lóríṣiríṣi, yàtọ̀ sí ohun tí òfin béèrè tàbí kó yarí pé kí ọkọ ìyàwó san owó orí ìyàwó tó pọ̀ ju ohun tí òfin fòté lé lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní bójú mú pé kó fàyè gba àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tí kò sóhun tó kàn wọ́n pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì láti wá bá a béèrè fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Àwọn òbí ìyàwó ló bí i; kì í ṣe àwọn ará àdúgbò. Àwọn bàbá tí wọ́n jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ dúró gbọn-in fún ohun tó tọ́, láìka ohun táwọn mọ̀lẹ́bí tí wọn kì í ṣe ará lè sọ sí. Ó ṣe pàtàkì láti rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà ju láti rí ìtẹ́wọ́gbà èèyàn lọ.
9 Àwọn bàbá kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tiẹ̀ ti yàn láti má ṣe gba owó orí ìyàwó rárá. Bí tọkọtaya kan bá sì wá sọ pé ìgbéyàwó lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ làwọ́n fẹ́ ṣe dípò ìgbéyàwó alárédè, ó lè di dandan pé kí bàbá ìyàwó (tàbí alágbàtọ́, ìyẹn bí bàbá bá ti kú) gba iye owó díẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bí owó orí ìyàwó, dípò kó ní òun kò ní gba ohunkóhun. Ìdí abájọ ni pé ṣíṣàì san owó orí ìyàwó lè mú kí ìgbéyàwó tí a ṣe lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ máà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Bó bá jẹ́ ìgbéyàwó alárédè ni wọ́n fẹ́ ṣe, tí bàbá ìyàwó sì wá sọ pé òun ò ní gba owó orí ìyàwó, kò sẹ́ni tó máa bi í pé kí ló dé tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé owó orí ìyàwó kì í ṣe dandan béèyàn bá fẹ́ ṣe ìgbéyàwó alárédè.
10 Ṣíṣe Oríṣi Ìgbéyàwó Méjì Pa Pọ̀: Oríṣi ìgbéyàwó méjì lòfin Nàìjíríà fọwọ́ sí, ìyẹn ni ìgbéyàwó lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀, àti ìgbéyàwó alárédè. Èyíkéyìí téèyàn bá ṣe nínú méjèèjì ló dára. Àmọ́ àwọn arákùnrin kan máa ń fẹ́ láti ṣe ìgbéyàwó lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ (èyí tó ní gbígbé oúnjẹ àti ọtí fún àwọn àna nínú), tí àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu yóò sì tẹ̀ lé e, lẹ́yìn náà kí wọ́n tún wá ṣe ti alárédè, èyí tó ní àsọyé ìgbéyàwó tí wọn yóò sọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba nínú, lẹ́yìn náà, àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu mìíràn yóò tún ṣẹlẹ̀. Ṣíṣe àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí lè mú kéèyàn ṣe àwọn ìnáwó tí kò pọn dandan. Béèyàn bá ti ṣayẹyẹ ìgbéyàwó lọ́nà tí àṣà ìbílẹ̀ tán, ìgbéyàwó ti ṣe nìyẹn. Bó ti wù kó rí, bí tọkọtaya bá ṣe ìgbéyàwó wọn lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ níbi tí kò ti sí ìpèsè fún fífi orúkọ ìgbéyàwó táa ṣe lọ́nà àṣà ìbílẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin, yóò dára kí wọ́n tún ṣe ìgbéyàwó alárédè. Kì í ṣe àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ló máa mú kí ìgbéyàwó náà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Béèyàn bá ṣe àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ńṣe lèèyàn kàn ń fowó ṣòfò láìnídìí. Àwọn tọkọtaya míì ti tọrùn bọ gbèsè tó wúwo, èyí tó ti mú kí àìfararọ bá ìgbéyàwó wọn, nítorí pé wọ́n kó àwọn èèyàn lẹ́nu jọ lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí tiẹ̀ ló dá ìṣòro tó ń peléke sí i yìí sílẹ̀ pàápàá?
11 Ìwé 1 Jòhánù 2:16 mẹ́nu kan kókó pàtàkì kan tó fà á, ó sọ pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.” Ọ̀pọ̀ àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu tí a ṣe lẹ́yìn ayẹyẹ ìgbéyàwó ni a ti lò láti fi ṣàṣefihàn ọrọ̀ lọ́nà ṣekárími. Èyí sì ti mú kí àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu táa ṣe táyé gbọ́ tọ́run mọ̀ di èyí táwọn èèyàn ń gbà bí ẹni gba igbá ọtí. Àwọn èèyàn kan ti juwọ́ sílẹ̀ láti ṣe bí àwọn mìíràn ti ṣe nítorí pé wọn ò fẹ́ jẹ́ aláìbẹ́gbẹ́mu. Wọ́n tìtorí èyí ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣàfarawé àwọn ẹlòmíràn. Àwọn kan ṣètò àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu níbi tí wọ́n ti filé pọntí, tí wọ́n ti fọ̀nà rokà pẹ̀lú èrò pé báwọn èèyàn bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ṣe máa rí ẹ̀bùn gbà tó.
12 Ó máa ń ṣòro láti darí irú àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu bẹ́ẹ̀ níbi táwọn èèyàn ti pọ̀ bí eṣú. Ọtí máa ń pọ̀ yamùrá lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn kan sì ti hùwà tí kò bójú mu nítorí pé wọ́n mu ọtí líle ní àmujù. Kò sáyè fún irú ìwà báyìí láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.—1 Pét. 4:3; Éfé. 5:18.
13 Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa náà máa ṣe ohun tí ayé ń ṣe, kódà bí kò bá tiẹ̀ sí àwọn òfin kan ní pàtó tó ka àwọn ohun kan léèwọ̀? Ká má rí i! Ìwé Róòmù 12:2 gbà wá níyànjú pé ká “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” Kò tán síbẹ̀ o, a kà á nínú 1 Kọ́ríńtì 10:23 pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ṣàǹfààní. Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ní ń gbéni ró.” Àwọn Kristẹni ìjímìjí kò jẹ́ kí irú ìgbésí ayé ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà táwọn èèyàn tó yí wọn ká ń gbé nípa lórí wọn. Wọ́n yàtọ̀ pátápátá. Báwa náà bá fẹ́ máa gbádùn ojú rere Jèhófà, a gbọ́dọ̀ yẹra fún ẹ̀mí ayé.
14 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí òfin kankan tó kà á léèwọ̀ láti ṣe àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, ǹjẹ́ kò ní dára jù bí a bá jẹ́ kí ẹyọ kan ṣoṣo tẹ́ wa lọ́rùn ká bàa lè yẹra fún àwọn ìnira ti kò pọn dandan? Ó dájú pé eléyìí yóò mú kí ẹrù wa fúyẹ́ ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” táa wà yìí. (2 Tím. 3:1) Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. . . . Ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi . . . Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:28-30) Ìmúdánilójú yìí mà ń tuni lára gan an ni o! A tipa báyìí dá a lábàá pé kí àwọn tọkọtaya ronú lórí ṣíṣe àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu kan ṣoṣo péré níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn.
15 Yẹra fún Àwọn Àṣà Ayé: Àṣà kan táwọn aráyé ń dá tó ti wá bẹ̀rẹ̀ sí fìdí múlẹ̀ láwọn ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó Kristẹni lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ní “fífọ́n” owó níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu tàbí níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó táa ṣe lọ́nà ti ìbílẹ̀. Òye tí àwa Kristẹni ní yóò mú ká kọ àṣà yìí tó jẹ́ ti ayé sílẹ̀ pátápátá. Bíbélì dẹ́bi fún irú fífi ọrọ̀ ẹni hàn lọ́nà ṣekárími bẹ́ẹ̀. (1 Jòh. 2:15-17) Kò tiẹ̀ tún sí ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tó wà nínú ìwé Mátíù 6:1-4.
16 A ti kíyè sí i pé níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó kan, tàbí níbi àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó táa ṣe lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀, àwọn arákùnrin kan máa ń lo àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run wa láti kọrin ìyìn fún àwọn èèyàn. Ṣé torí nǹkan táa ṣe pèsè àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run wa rèé? Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀! Ńṣe lèyí túmọ̀ sí pé a ń gbé ìjọsìn ẹ̀dá lárugẹ, ó sì ṣe kedere pé Ìwé Mímọ́ dẹ́bi fún èyí. (Róòmù 1:25) Dájúdájú, bí ẹnì kan bá ń fi irú ògo bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn, a jẹ́ pé ẹni yẹn kì í ṣe “ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run,” nìyẹn.—1 Kọ́r.10:31.
17 A máa ń rí àwọn tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ nígbà mìíràn tí wọ́n máa ń dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin fàlàlà ní àwọn ibi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ìgbéyàwó àti àwọn àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà mìíràn. Bíbélì dẹ́bi fún “dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀” pẹ̀lú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ táa ti yọ lẹ́gbẹ́. (1 Kọ́r. 5:9-13) Ojúṣe ẹni tó ń ṣètò àpèjẹ kan ni láti rí i dájú pé àpèjẹ náà ni a bójú tó dáadáa. Bí àwọn táa ti yọ lẹ́gbẹ́ bá máa wá síbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu náà, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni lè parí èrò sí pé kò yẹ kí àwọn lọ síbẹ̀, nítorí ìdarísọ́nà Pọ́ọ̀lù tó wà nínú ìwé 1 Kọ́ríńtì 5:11.
18 Nítorí àwọn ọ̀f ìn wọ̀nyí, a ní láti ‘máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí a ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n.’ A ní láti ‘ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú, ṣùgbọ́n kí á máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ,’ nínú ọ̀ràn bí èyí àti àwọn mìíràn. (Éfé. 5:15-17) Èyí ń béèrè pé ká ní ìṣarasíhùwà tó bójú mu nípa àwọn àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà táa ṣètò dáadáa táa sì bójú tó lọ́nà tó wuyì lè mú ìtura wá. Àmọ́ ṣá, ìwọ̀nyí kì í ṣe nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. Ọ̀pọ̀ ni kì í nípìn-ín ní kíkún nínú iṣẹ́ ìsìn pápá àti àwọn ìpàdé nítorí pé wọ́n lọ sí àwọn àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ayẹyẹ ìgbéyàwó. A kìlọ̀ fún wa pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn èèyàn yóò di “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tím. 3:1, 4) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò iye àkókò táa ń lò láti fi ṣètò àwọn ayẹyẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti èyí táa fi ń lọ síbẹ̀. Àbí ó lè jẹ́ pé ẹ̀mí yìí, tó ti gbòde kan nínú ayé lónìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí wa, bóyá ní àwọn ọ̀nà tá ò tiẹ̀ ronú nípa ẹ̀ pàápàá?
19 Àwọn ìgbésẹ̀ tó gbéṣẹ́ wo la lè gbé láti rí i dájú pé a bọlá fún Jèhófà láwọn ibi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ìgbéyàwó wa? Ìwé Òwe 15:22 jẹ́ ká mọ ìjẹ́pàtàkì “ọ̀rọ̀ ìfinúkonú” ká bàa lè dènà ‘àwọn ìwéwèé tó máa ń já sí pàbó.’ Bóo bá ń múra láti ṣègbéyàwó, kí ló dé tóò fi jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn òbí ìyàwó rẹ, kóo jẹ́ kí wọ́n ti mọ̀ ṣáájú, àwọn ohun tí o lè ṣe àtàwọn èyí tí o kò lè ṣe? Bákan náà ni yóò tún dára kí o jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí agbára rẹ ká láti ṣe. Gẹ́gẹ́ bí 1 Kọ́ríńtì 7:29-31 ti rán wa létí, “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.” Nítorí náà, àkókò kọ́ nìyí fún wa láti máa ‘lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, nítorí ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.’
20 Ìwé Òwe 21:5, sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” Bí a bá fara balẹ̀ wéwèé ṣáájú àkókò, táa sì pinnu báa ṣe fẹ́ kí èrò pọ̀ tó níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu àti iye èèyàn tí a lè bójú tó, èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti dènà àwọn ìṣòro tó máa ń jẹ yọ láwọn ibi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu ayẹyẹ ìgbéyàwó àtàwọn àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà mìíràn. Ìwéwèé ṣáájú àkókò máa ń ṣàǹfààní kódà tó fi dórí irú ìgbéyàwó táa bá fẹ́ ṣe, bóyá ti àṣà ìbílẹ̀ ni o àbí ti alárédè.
21 Lákòótán, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, a fẹ́ láti wà ní mímọ́ tónítóní ká sì yẹra fún àwọn ọ̀nà ayé ní àwọn ibi àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wa. Níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù,” ńṣe ló yẹ ká kọjú mọ́ àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí dáadáa, kì í ṣe pé ká máa ṣe ọmọ jayéjayé kiri. Ǹjẹ́ ká máa “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” nínú àwọn ọ̀ràn bí èyí tàbí àwọn mìíràn. Kódà nínú àwọn ọ̀ràn ti ara ẹni bí àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó àti àwọn àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà mìíràn, a óò ṣe dáadáa báa bá fi àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ sílò, ká bàa lè máa mú inú Jèhófà dùn nínú ohun gbogbo. Ǹjẹ́ ká pinnu láti má ṣe “máa mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀,” nípa àwọn ohun táa bá ṣe ní àwọn àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wa. (Fílí. 1:10, 11) Báa ti ń kọbi ara sí àwọn ìṣílétí wọ̀nyí tó wà nínú Ìwé Mímọ́, táa sì ń fi wọ́n sílò, táa tún wá ń ṣègbọràn sí ìkésíni onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Jésù tó wà nínú ìwé Mátíù 11:28-30, ó dájú pé a óò rí ‘ìtura fún ọkàn wa.’