Gbára Lé Okun Tí Jèhófà Ń Fúnni
1 Ìdí pọ̀ tá a fi ní láti gbára lé Jèhófà. Wíwàásù ìhìn rere náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” jẹ́ iṣẹ́ tí ń kani láyà. (Mát. 24:14) Gbogbo ìgbà la ń bá ara àìpé wa wọ̀yá ìjà. (Róòmù 7:21-23) Kò tán síbẹ̀ o, a “ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí [tí agbára wọn kọjá ti ẹ̀dá].” (Éfé. 6:11, 12) Ó ṣe kedere pé a nílò ìrànwọ́. Báwo la ṣe lè rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà?
2 Nípasẹ̀ Àdúrà: Ọ̀fẹ́ ni Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó bá béèrè fún un. (Lúùkù 11:13) Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ọ́ bíi pé o kò ní ìdánilójú tó tó láti jẹ́rìí láti ilé dé ilé, ní òpópónà, tàbí lórí tẹlifóònù? Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ọ́ láti jẹ́rìí lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà? Ǹjẹ́ báwọn èèyàn ṣe ń dágunlá ní ìpínlẹ̀ yín ti dín ìtara rẹ kù? Ká ní wọ́n fagbára mú ọ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ tàbí láti ba ìwà títọ́ rẹ jẹ́ ńkọ́? Gbára lé Jèhófà. Gbàdúrà fún okun.—Fílí. 4:13.
3 Nípasẹ̀ Ìdákẹ́kọ̀ọ́: Bí a ṣe máa ń rí okun gbà nígbà tí a bá jẹ oúnjẹ ti ara, bẹ́ẹ̀ náà ni fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tó jẹ́ ti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” bọ́ ara wa déédéé ṣe máa ń fún wa lágbára nípa tẹ̀mí. (Mát. 4:4; 24:45) Nígbà tí wọ́n bi Stanley Jones léèrè ohun tó fún un lókun láti fara da dídáwà ní àhámọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún ní China láìsí Bíbélì, ó sọ pé: “A lè dúró gbọin-in bí a bá ní ìgbàgbọ́. Àmọ́ ṣá o, a ní láti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́. Bí a kò bá kẹ́kọ̀ọ́, a kò ní ní okun inú.”
4 Nípa Lílọ sí Ìpàdé: Níbi ìpàdé Kristẹni kan tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kìíní, Júdásì àti Sílà “fi ọ̀pọ̀ àwíyé fún àwọn ará ní ìṣírí wọ́n sì fún wọn lókun.” (Ìṣe 15:32) Bákan náà lónìí, ohun tí a bá gbọ́ ní àwọn ìpàdé máa ń mú kí ìmọrírì tá a ní nítorí ohun tí Jèhófà ṣe fún wa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, ó máa ń gbé ìgbàgbọ́ wa ró, ó sì máa ń ta wá jí láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìpàdé máa ń mú ká pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ [wa] fún ìjọba Ọlọ́run,” tí wọ́n jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún wa.—Kól. 4:11.
5 A ń fẹ́ ìrànwọ́ ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí. (2 Tím. 3:1) A mú un dá àwọn tí ó bá ń gba okun látọ̀dọ̀ Jèhófà lójú pé: “Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì. Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.”—Aísá. 40:31.