ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rq ẹ̀kọ́ 4 ojú ìwé 8-9
  • Ta Ni Eṣu?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Eṣu?
  • Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣọ́ra! Sátánì Fẹ́ Pa Ọ́ Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Sátánì
    Jí!—2013
  • Mọ Ọ̀tá Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ta Ni Sátánì? Ṣó Wà Lóòótọ́?
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
rq ẹ̀kọ́ 4 ojú ìwé 8-9

Ẹ̀kọ́ 4

Ta Ni Eṣu?

Satani Eṣu​—⁠níbo ni ó ti wá? (1, 2)

Báwo ni Satani ṣe ń ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà? (3-7)

Èé ṣe tí ó fi yẹ kí o kọjú ìjà sí Eṣu? (7)

1. Ọ̀rọ̀ náà “eṣu” túmọ̀ sí ẹnì kan tí ń sọ̀rọ̀ ẹlòmíràn ní búburú. “Satani” túmọ̀ sí ọ̀tá tàbí alátakò. Àwọn orúkọ wọ̀nyí ni a fi ń pe olórí ọ̀tá Ọlọrun. Ní ìbẹ̀rẹ̀, òún jẹ́ áńgẹ́lì pípé kan ní ọ̀run pẹ̀lú Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, òun ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó sì fẹ́ ìjọsìn tí ó tọ́ sí Ọlọrun.​—⁠Matteu 4:​8-⁠10.

2. Áńgẹ́lì yìí, Satani, lo ejò kan láti bá Efa sọ̀rọ̀. Nípa píparọ́ fún un, ó mú kí ó ṣàìgbọràn sí Ọlọrun. Satani tipa báyìí ta ko ohun tí a ń pè ní “ipò ọba aláṣẹ” Ọlọrun, tàbí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹni Gíga Jù Lọ. Satani gbé ìbéèrè dìde nípa bóyá Ọlọrun ń ṣàkóso ní ọ̀nà yíyẹ, àti fún ire àwọn ọmọ abẹ́ Rẹ̀. Satani tún gbé ìbéèrè dìde nípa bóyá ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí yóò jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọrun. Nípa ṣíṣe èyi, Satani sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọrun. Ìdi tí ó fi di ẹni tí a ń pè ní Satani Eṣu nìyẹn.​—⁠Genesisi 3:​1-⁠5; Jobu 1:​8-⁠11; Ìṣípayá 12:⁠9.

3. Satani ń gbìyànjú láti tan àwọn ènìyàn sínú jíjọ́sìn rẹ̀. (2 Korinti 11:​3, 14) Ọ̀nà kan tí òun ń gbà ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà jẹ́ nípasẹ̀ ìsìn èké. Bí ìsìn kan bá ń fi irọ́ kọ́ni nípa Ọlọrun, ó ń mú ète Satani ṣẹ ní ti gidi. (Johannu 8:44) Àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà ìsìn èké lè fi tọkàntọkàn gbà gbọ́ pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọrun tòótọ́ náà. Ṣùgbọ́n, Satani ni wọ́n ń jọ́sìn ní ti gidi. Òun ni ‘ọlọrun ayé yìí.’​—⁠2 Korinti 4:⁠4.

4. Ìbẹ́mìílò tún jẹ́ ọ̀nà míràn tí Satani ń gbà mú àwọn ènìyàn wá sí abẹ́ agbára rẹ̀. Wọ́n lè pe àwọn ẹ̀mí láti dáàbò bò wọ́n, láti pa àwọn ẹlòmíràn lára, láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la, tàbí láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Satani ni agbára búburú tí ó wà lẹ́yìn gbogbo àṣà wọ̀nyí. Láti mú inú Ọlọrun dùn, a kò gbọdọ̀ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò.​—⁠Deuteronomi 18:​10-⁠12; Ìṣe 19:​18, 19.

5. Satani tún ń ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà nípasẹ̀ ìgbéraga nípa ẹ̀yà ìran tí ó kọjá àlà àti jíjọ́sìn ètò àjọ ìṣèlú. Àwọn kan ń ronú pé, orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà ìran wọn sàn ju àwọn yòókù lọ. Ṣùgbọ́n èyí kì í ṣe òtítọ́. (Ìṣe 10:​34, 35) Àwọn ènìyàn míràn ń gbára lé ètò àjọ ìṣèlú láti yanjú ìṣòro ènìyàn. Nípa ṣíṣe èyí, wọ́n ń kọ Ìjọba Ọlọrun sílẹ̀. Òun ni ojútùú kan ṣoṣo sí àwọn ìṣòro wa.​—⁠Danieli 2:⁠44.

6. Ọ̀nà míràn tí Satani ń gbà ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà jẹ́ nípa fífi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ dẹ wọ́n wò. Jehofa sọ fún wa láti yẹra fún àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀, nítorí ó mọ̀ pé wọn yóò pa wá lára. (Galatia 6:​7, 8) Àwọn ènìyàn kan lè fẹ́ kí o dara pọ̀ mọ́ wọn nínú irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, rántí pé Satani gan-⁠an ni ó fẹ́ kí o ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí.​—⁠1 Korinti 6:​9, 10; 15:⁠33.

7. Satani lè lo inúnibíni tàbí àtakò láti mú kí o fi Jehofa sílẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn olólùfẹ́ rẹ lè bínú gan-⁠an nítorí pé o ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Àwọn mìíràn lè fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà. Ṣùgbọ́n, ta ni o jẹ ní gbèsè ìwàláàyè rẹ? Satani fẹ́ láti dẹ́rù bà ọ́, kí o lè dá kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Jehofa dúró. Má ṣe jẹ́ kí Satani ṣẹ́gun! (Matteu 10:​34-⁠39; 1 Peteru 5:​8, 9) Nípa kíkọjú ìjà sí Eṣu, ìwọ́ lè mú Jehofa láyọ̀, kí o sì fi hàn pé o rọ̀ mọ́ ipò ọba aláṣẹ Rẹ̀.​—⁠Owe 27:⁠11.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ìsìn èké, ìbẹ́mìílò, àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ń ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Kọjú ìjà sí Satani nípa bíbá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jehofa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́