“Àwa Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run”
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà . . . Àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:6, 9) Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní mọ̀ dáadáa pé láti ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọ́n ní láti gbára lé Jèhófà Ọlọ́run.
2 Níbi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Inú Ilé: Bí a bá ń fi sọ́kàn pé kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ohun tí Kristi pa láṣẹ wà lára iṣẹ́ tá a gbé lé wa lọ́wọ́, ó bójú mu nígbà náà pé ká máa fi iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe sínú àdúrà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò fi hàn pé a gbára lé Jèhófà, ẹni tó ń mú kí àwọn nǹkan dàgbà.
3 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, ojú ewé 3, ìpínrọ̀ 7, sọ pé: “Bíbẹ̀rẹ̀ àti píparí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pẹ̀lú àdúrà fún ìdarísọ́nà àti ìbùkún Jèhófà ń buyì kún àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó ń fúnni ní ipò ọkàn tí ó jẹ́ ọlọ́wọ̀, ó sì ń pe àfiyèsí sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ tòótọ́ náà.—Jòh. 6:45.”
4 Kí làwọn ohun díẹ̀ tó máa dára pé ká mẹ́nu kàn tá a bá ń gbàdúrà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé? Àpẹẹrẹ àtàtà ni àdúrà àwòkọ́ṣe Jésù àti àdúrà tí Pọ́ọ̀lù gbà nítorí àwọn ará Fílípì jẹ́ fún wa. (Mátíù 6:9-13; Fílí. 1:9-11) Kò pọn dandan kí àdúrà wa gùn jàn-ànràn jan-anran, àmọ́ ó ní láti dá lórí àwọn ohun kan pàtó. Ó ṣe pàtàkì pé ká sọ ọ̀rọ̀ ìyìn yíyẹ sí Jèhófà nítorí àìlóǹkà àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ nínú àdúrà wa. A lè mẹ́nu kan ìtóbilọ́lá rẹ̀, ipò ọlá ńlá rẹ̀ àti àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó jẹ́ pípé. (Sm. 145:3-5) Dídárúkọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nínú àdúrà, bóyá ká tún mẹ́nu kan bí ipò nǹkan ṣe rí fún un, àti gbígbàdúrà pé kó ní ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí tún ṣàǹfààní. Bó ṣe ń tẹ̀ síwájú, a lè tọrọ ìbùkún Jèhófà lórí àwọn ìsapá tó ń ṣe láti wá sí ìpàdé àti láti sọ òtítọ́ tó ń kẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Nínú àdúrà wa, ká tún máa tọrọ ìbùkún Jèhófà lórí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé.
5 Àkókò wo ló máa bójú mu láti gbàdúrà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ó yẹ ká máa fi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tó bá ti fìdí múlẹ̀. Àmọ́ o, ṣe àlàyé kúnnákúnná fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nípa ọ̀nà tó yẹ láti gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí gba àdúrà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa gbára lé Jèhófà fún ìbùkún rẹ̀ lórí àwọn ìsapá wa bá a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.