Àwọn Ìsọfúnni Tó Dára Gan-an Láti Kà!
Ǹjẹ́ o gbà pé àkòrí àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ tó ti kọjá tó wà nísàlẹ̀ yìí fi hàn pé á dára gan-an láti kà wọ́n?
“Fífi Ẹ̀mí Ọlọ́run Hàn”
“Ṣíṣe Àkóso Ahọ́n”
“Kí Ló Dé Tí Rúkèrúdò Fi Gbayé Kan?”
“Bí A Ṣe Lè Yẹra fún Kíkábàámọ̀”
“Àwọn Onígbèéraga àti Àwọn Onírẹ̀lẹ̀”
Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn jáde nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láti ọdún 1966 sí 1969. Ǹjẹ́ a lè sọ pé ìgbà ti lọ lórí wọn débi pé a ò lè jàǹfààní nínú wọn mọ́? Rárá o! O ṣì lè rí àwọn ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ ti ọdún 1966 sí 1969 gbà lédè Gẹ̀ẹ́sì nìkan. Akéde èyíkéyìí tó bá nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ yìí lè béèrè fún wọn nípa fíforúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ rẹ̀.
Kí alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run wo ibi ìkówèésí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láti mọ àwọn ìdìpọ̀ tí kò sí níbẹ̀ kó sì kọ̀wé béèrè fún wọn.