-
Fí Ọwọ́ Tó Tọ́ Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́runIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2001 | December
-
-
3 Ka Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Jáde Tààràtà: Bí àwọn èèyàn tó ń gbé lágbègbè rẹ bá máa ń ṣiyè méjì nípa ohun tó jẹ́ ìgbàgbọ́ àwọn tí ń gbé àpò kiri láti wàásù, o lè gbìyànjú láti wàásù láìgbé àpò òde ẹ̀rí dání. O lè kó ìwé tó o fẹ́ fi lọni sínú àpò pẹlẹbẹ kan, kí o sì mú Bíbélì rẹ dání tàbí kí o fi sínú àpò aṣọ rẹ. Nígbà náà, bó o ti ń bá ẹni kan fọ̀rọ̀ wérọ̀, rọra fa Bíbélì yọ láìjẹ́ kí ẹni náà máa ronú pé ìwàásù tó ń gba àkókò lo fẹ́ gbẹ́nu lé. Yálà o wà lórí ìjókòó tàbí o wà lórí ìdúró, rọra yí ara lọ́nà tí ẹni tó o ń bá sọ̀rọ̀ á fi lè máa fojú bá Bíbélì tó o ń kà náà lọ. O tiẹ̀ lè ní kó ka ẹsẹ Bíbélì kan sókè ketekete. Bó bá fojú ara rẹ̀ rí ohun tí Bíbélì sọ, èyí á tẹ ọ̀rọ̀ náà mọ́ ọn lọ́kàn ju pé kó kàn fetí gbọ́ ọ lásán. Àmọ́ ṣá o, láti mú kí ibi tí o kà yé e, tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó gbé kókó ibẹ̀ yọ.
-
-
Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2002Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2001 | December
-
-
3 Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́: Bá a bá ń jẹ́ kí Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa nígbà gbogbo, a ó lè lo àyè èyíkéyìí tó bá yọ láti kà á. Ọ̀pọ̀ nínú wa máa ń ní ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ lóòjọ́ tá a lè lò fún un. Ó mà ń ṣeni láǹfààní o láti ka ojú ewé kan, ó kéré tán lójoojúmọ́! Ìyẹn ti tó fún wa láti lè máa bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tí a ṣètò fún ilé ẹ̀kọ́ náà lọ.—Sm. 1:1-3.
-