-
Kíkó Àwọn Èèyàn Jọ Látinú Gbogbo ÈdèIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2002 | July
-
-
4 Ǹjẹ́ a lè túbọ̀ sa gbogbo agbára wa láti polongo ìhìn rere náà fún àwọn èèyàn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwa, tí wọ́n wà ní ìpínlẹ̀ wa? (Kól. 1:25) Àwọn ìjọ kan ṣètò láti máa lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù láwọn àdúgbò táwọn èèyàn ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn akéde yóò kọ́kọ́ kọ́ èdè ọ̀hún níwọ̀nba, débi tí yóò fi ṣeé ṣe fún wọn láti gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà rírọrùn, irú bí: “Ẹ ǹ lẹ́ ńbí o. A mú ìhìn rere wá fún un yín ni o. [Lẹ́yìn náà, fi ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé pẹlẹbẹ kan tó wà ní èdè náà lọ̀ ọ́.] Ó dìgbà.” Ní tòótọ́, Jèhófà máa ń bù kún irú àwọn ìsapá tá a bá bẹ̀rẹ̀ lọ́nà wẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀!
-
-
Ipa Tí Àwọn Fídíò Tá A Fi Ń Jẹ́rìí Ń Ní Lórí Àwọn ÈèyànIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2002 | July
-
-
4 Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Arábìnrin kan pàdé obìnrin kan tó lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn ìbéèrè kan tó fẹ́ béèrè nípa wa àti nípa àwọn ohun tá a gbà gbọ́. Arábìnrin náà padà lọ pẹ̀lú fídíò náà, Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ètò Àjọ Tí Ń Jẹ́ Orúkọ Yẹn], ó sì jẹ́ kí obìnrin náà àti ọkọ rẹ̀ wò ó. Fídíò yìí wú wọn lórí gan an, wọ́n sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Látàrí ìjẹ́rìí àtàtà tí wọ́n ti gbà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìgbésí ayé wọn bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.
-