ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Ìfilọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2004 | May
    • Àwọn Ìfilọ̀

      ◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní May: Kí a fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Nígbà tá a bá padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn ìpàdé mìíràn tí ìjọ ṣètò àmọ́ tí wọn kò dara pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ètò àjọ Ọlọ́run, kí a fún wọn ní ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run. Kí a sapá láti fi ìwé yìí bá àwọn èèyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, pàápàá àwọn tó ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. June: Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Bí àwọn onílé bá sọ pé àwọn ò lọ́mọ, fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Nígbà tó o bá ń lo ìwé pẹlẹbẹ náà, sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. July àti August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.”

      ◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní June 1 tàbí bó bá ti ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e.

      ◼ Bí ẹnì kan bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣe ọrẹ tó máa fi sínú àpótí ọrẹ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láti fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ yíká ayé àti Owó Àkànlò fún Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí ó kọ “Watch Tower” sí orí ìwé sọ̀wédowó náà.

  • Fífi Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà Lọni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2004 | May
    • Fífi Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà Lọni

      ◼ “Ǹjẹ́ o rò pé ayé á dára ju bó ṣe wà yìí lọ báwọn èèyàn bá ń fi ọ̀rọ̀ yìí ṣèwà hù? [Ka Mátíù 7:12a. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí olùkọ́ tó ga jù lọ tó tíì gbé ayé rí kọ́ni ló wà nínú ìwé yìí.” Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán àti àkọlé tó wà ní orí 17.

      ◼ “Ọ̀pọ̀ òbí lóde òní ń gbìyànjú láti fi àwọn ìlànà àti àṣà tó dára kọ́ àwọn ọmọ wọn. Ǹjẹ́ o rò pé èyí ṣe pàtàkì? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Òwe 22:6.] Kíyè sí i pé a rọ àwọn òbí láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló. A ṣe ìwé yìí láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀.” Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán àti àkọlé tó wà ní orí 15, 18 tàbí 32.

      ◼ “Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ya àwọn òbí lẹ́nu láti gbọ́ ìbéèrè tí àwọn ọmọ wọn ń béèrè. Kì í rọrùn láti dáhùn àwọn kan lára ìbéèrè wọ̀nyí, àbí ó máa ń rọrùn? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 2 Tímótì 3:14, 15.] Ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ láti kékeré. Ìwé yìí lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ṣe ohun kan náà fún àwọn ọmọ wọn lónìí.” Sọ̀rọ̀ lórí díẹ̀ lára àwọn àwòrán àti àkọlé tó wà ní orí 11 àti 12 tàbí orí 34 sí 36.

  • Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn January
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2004 | May
    • Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn January

      Av. Av. Av. Av.

      Iye: Hrs. Mags. R.V. Bi.St.

      Aṣá. Àkàn. 499 132.8 35.4 61.7 13.3

      Aṣá. Déédéé 26,112 54.7 17.2 20.7 5.6

      Aṣá. Olù. 5,234 48.0 13.6 15.1 4.0

      Akéde 224,042 10.7 4.2 3.9 1.2

      ÀRÒPỌ̀ 255,887 Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 629

  • Ohun Tó Lè Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2004 | May
    • Ohun Tó Lè Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́

      Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣiṣẹ́ sin aráàlú nípa títan ìhìn rere kálẹ̀. (Fílí. 2:17) Kí èyí lè ṣeé ṣe, àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí a sábà máa ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwé àṣàrò kúkúrú àtàwọn àpilẹ̀kọ ní ogún èdè la ti fi sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì báyìí. Àdírẹ́sì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni: www.watchtower.org. A ò ṣètò ibùdó ìsọfúnni yìí fún pínpín àwọn ìtẹ̀jáde lọ́ọ́lọ́ọ́ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìdí tí a fi ṣètò rẹ̀ ni láti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún gbogbo àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí láti ní ìsọfúnni pípéye nípa ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni látinú Bíbélì.

      Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a ti fi ohun pàtàkì kan sí ibùdó ìsọfúnni wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láfikún sí i. Èyí ni ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tó wà ní okòó-lé-nígba [220] èdè. Bákan náà, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde January 1 àti January 8, 2004, a ti ń kọ àdírẹ́sì ibùdó ìsọfúnni wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sí ojú ewé tó gbẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní gbogbo èdè.

      Báwo lo ṣe lè lo àdírẹ́sì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì yìí? Ó ṣeé ṣe kó o pàdé ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn, àmọ́ tó jẹ́ pé èdè mìíràn nìkan ló gbọ́. Bó bá jẹ́ ẹni tó máa ń ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè tọ́ka sí àdírẹ́sì ibùdó ìsọfúnni wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, èyí tó wà lójú ewé tó gbẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè ṣeé ṣe fún un láti ṣàyẹ̀wò ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ní èdè ìbílẹ̀ rẹ̀, títí dìgbà tí wàá fi lè padà wá láti fún un ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè rẹ̀. Tàbí kẹ̀, o lè sọ fún ìjọ tàbí àwùjọ tó ń bójú tó èdè ẹni náà pé kí wọ́n lọ bẹ̀ ẹ́ wò.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́