-
Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Lo Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tí A Dámọ̀rànIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | January
-
-
Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Lo Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tí A Dámọ̀ràn
1. Ojú wo ló yẹ ká fi wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a dámọ̀ràn?
1 Ìgbà gbogbo la máa ń dámọ̀ràn àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé wa mìíràn lọni sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Kì í ṣe pé ká wá sọ ọ́ di àkọ́sórí tí a ó máa kà lóde ẹ̀rí o. Ìdí tá a fi ń dámọ̀ràn wọn síbẹ̀ ni pé ká lè mọ ohun tá a lè sọ. Tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ ara wa ṣàlàyé rẹ̀, yóò túbọ̀ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Tó bá jẹ́ pé ọ̀nà tí a gbà ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ la fi ń wàásù fáwọn èèyàn, àwọn onílé á lè fara balẹ̀ gbọ́ wa, wọ́n á rí i pé òótọ́ inú la fi ń sọ̀rọ̀, wọ́n á sì rí i pé ohun tí à ń sọ dá wa lójú.—2 Kọ́r. 2:17; 1 Tẹs. 1:5.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú nípa àṣà àdúgbò tá a ti ń wàásù nígbà tá a bá ń múra ọ̀nà tá a máa gbà gbọ́rọ̀ wa kalẹ̀ sílẹ̀?
2 Gbọ́rọ̀ Kalẹ̀ Lọ́nà Tí Yóò Bá Ipò Àwọn Èèyàn Mu: Àṣà àdúgbò tá a ti ń wàásù ló máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe máa gbé ìhìn rere kalẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà àwọn èèyàn. Ní ìpínlẹ̀ yín, ṣé ń ṣe lẹ máa ń kọ́kọ́ kí onílé kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ ìwàásù, àbí ẹ kàn lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ láìwulẹ̀ kíni? Àdúgbò kọ̀ọ̀kan ló ní àṣà tiẹ̀, kódà ohun tó wu ẹnì kan lè má wu ẹlòmíràn. Bákan náà, ó yẹ ká máa fi òye béèrè ìbéèrè. Ìbéèrè tó bá àwọn èèyàn lára mu ládùúgbò kan lè bí àwọn ará ibòmíràn nínú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká jẹ́ olóye ká sì mọ ohun táwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa fẹ́.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ipò àwọn tí à ń wàásù fún àti nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́?
3 Síwájú sí i, nígbà tí a bá ń múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ó yẹ ká tún máa ronú nípa ipò àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa àti nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kí ọ̀nà tó o máa gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Mátíù 6:9, 10 fún ẹni tó jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì paraku yàtọ̀ sí bó o ṣe máa ṣàlàyé fún ẹni tí kò mọ “Àdúrà Olúwa.” Tí a bá lè jókòó ká ronú díẹ̀ ká tó jáde lọ sóde ẹ̀rí, a ó lè máa gbọ́rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn.—1 Kọ́r. 9:20-23.
4. Kí nìdí tí ìmúrasílẹ̀ fi ṣe pàtàkì?
4 Kódà bá a bá fẹ́ lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tá a dámọ̀ràn bó ṣe wà nínú ìwé tàbí a fẹ́ lò lára rẹ̀, kò sí ohun tó dà bíi pé ká múra sílẹ̀ dáadáa. Ẹ jẹ́ ká máa fara balẹ̀ ka àpilẹ̀kọ tàbí àkòrí tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí nínú ìwé tá a fẹ́ fi lọni ká sì wá àwọn kókó tó lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Lẹ́yìn èyí, ká wá mú un wọ inú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fẹ́ lò. Ohun tó máa jẹ́ ká lè fi ìtara fi ìwé wa lọ àwọn èèyàn ni pé ká mọ ohun tó wà nínú ìwé náà.
5. Kí lohun tó lè mú ká múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn, báwo la sì ṣe lè ṣe é?
5 Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Mìíràn: Ṣé àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dámọ̀ràn nìkan la gbọ́dọ̀ lò ni? Rárá o. Tó o bá ti ń lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan táwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbọ́, máa lò ó lọ. Tó bá wá jẹ́ pé ìwé ìròyìn lo fẹ́ fi lọni, ohun tó wà níwájú ìwé ìròyìn nìkan kọ́ ló yẹ kó o máa lò, tún máa wọ́nà láti fi àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé náà han àwọn tó lè nífẹ̀ẹ́ sí i ní ìpínlẹ̀ yín. Tí ẹ bá fẹ́ ṣe àṣefihàn bẹ́ ẹ ṣe máa lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, ẹ lè lo èyí táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ yín fẹ́ràn. Nípa báyìí gbogbo wa á lè mọ bá a ṣe lè wàásù ìhìn rere lọ́nà tó múná dóko.
-
-
Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé ÌròyìnIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | January
-
-
Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Jan. 15
“Gbogbo wa là ń fẹ́ kí ayé wa àti tàwọn ọmọ wa dùn bí oyin ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé èyí kọjá agbára àwọn láti ṣe. Ǹjẹ́ o gbà pé a lè pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa yóò ṣe rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí fi hàn wá látinú Bíbélì pé ọwọ́ wa ló wà, nítorí ohun tá a bá fòní ṣe ló máa pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa á ṣe rí.” Ka Diutarónómì 30:19.
Ile Iṣọ Feb. 1
“Ǹjẹ́ kì í bani lọ́kàn jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n ń rẹ́ jẹ tí wọ́n sì ń fojú wọn gbolẹ̀? [Mẹ́nu kan ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lágbègbè yín láìpẹ́ yìí, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀mí èèyàn. Ó tún ṣàlàyé bó ṣe máa gbà wá lọ́wọ́ ìyà tó ń jẹ aráyé lónìí.” Ka Sáàmù 72:12-14.
Jí Feb. 8
“Gbogbo wa la máa ń mọyì dókítà tó bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lé tọ́jú wa nígbà tá a bá ń ṣàìsàn. Ṣùgbọ́n ńjẹ́ o ró pé ọ̀pọ̀ aláìsàn ń ro ti àwọn dókítà mọ́ tiwọn? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro àwọn dókítà àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí iṣẹ́ ìṣègùn lọ́jọ́ iwájú.” Ka Aísáyà 33:24.
“Lóde òní, ọ̀kan lára ohun tó jẹ́ ìṣòro ńlá fáwọn èèyàn ni bí wọ́n ṣe máa dín pákáǹleke kù. Àbí o ò gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ti sọ pé bó ṣe máa rí nìyẹn. [Ka 2 Tímótì 3:1.] Ìwé ìròyìn yìí dá àwọn àbá kan tó lè ran ìwọ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti dín pákáǹleke kù.”
-