ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ̀kọ́ Látọ̀dọ̀ Arìnrìn-Àjò Ojú Òkun
    Ilé Ìṣọ́—2000 | August 15
    • Ẹ̀kọ́ Látọ̀dọ̀ Arìnrìn-Àjò Ojú Òkun

      DÍDÁ nìkan rin ìrìn àjò lójú agbami òkun lè tánni lókun. Àárẹ̀ tó ń mú kára ẹni kú tipiri lè kó arìnrìn-àjò ojú òkun náà sínú ewu, kó wá di pé ó ṣe àṣìṣe, kó sì ṣe àwọn ìpinnu tí kò dára. Nítorí ìdí èyí, ó mọyì iṣẹ́ tí ìdákọ̀ró ń ṣe gan-an ni. Ó ń fún atukọ̀ ojú omi tí àárẹ̀ ti mú láyè láti sinmi dáadáa, kí agbára rẹ̀ sì dọ̀tun láìsí pé ìjì gbé e lọ síbi tó léwu. Nígbà kan náà, ìdákọ̀ró òkun náà yóò jẹ́ kí iwájú ọkọ̀ òkun náà dorí kọ ibi tí ẹ̀fúùfù àti ìjì wà, yóò sì mú kí ọkọ̀ náà dúró gbagidi sí ibi tí mìmì kan ò ti lè mì ín.

      Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn atukọ̀ ṣe ń dojú kọ onírúurú ewu lójú òkun, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn Kristẹni ń fìgbà gbogbo kojú pákáǹleke inú ayé yìí, tí ara wọ́n sì máa ń fẹ́ sinmi. Àní, ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jésù dá a lábàá fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.” (Máàkù 6:31) Lóde òní, àwọn kan máa ń rin ìrìn àjò fún àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tàbí kí àwọn àti ìdílé wọn lọ gbádùn ara wọn lópin ọ̀sẹ̀. Irú àkókò yìí lè mára tuni, kó sì tún sọ okun ẹni dọ̀tun. Àmọ́, báwo la ṣe lè rí i dájú pé a ò kóra wa sínú ewu nípa tẹ̀mí nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀? Kí ló lè jẹ́ ìdákọ̀ró tẹ̀mí wa, tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dènà sísú lọ kí á sì mú ìdúró wa?

      Jèhófà ti fi ìwà ọ̀làwọ́ pèsè ohun kan tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa. Kì í ṣe nǹkan mìíràn bí kò ṣe Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Mímọ́ rẹ̀. Bí a bá ń kà á lójoojúmọ́, a óò sún mọ́ Jèhófà, a ò sì ní sú lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ lè mẹ́sẹ̀ wa dúró, kí ó sì jẹ́ kí a borí àwọn ìdẹwò Sátánì àti ayé rẹ̀. Títẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà déédéé, kódà ní àkókò tí a bá yí ọwọ́ padà díẹ̀, lè jẹ́ ìdákọ̀ró fún wa nípa tẹ̀mí.—Jóṣúà 1:7, 8; Kólósè 2:7.

      Onísáàmù náà rán wa létí pé “aláyọ̀ ni ènìyàn” tí “inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.” (Sáàmù 1:1, 2) Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ yóò fún wa ní àbájáde “aláyọ̀” ti jíjẹ́ ẹni tí a tù lára ní tòótọ́, tí a sì sọ okun rẹ̀ dọ̀tun, tí ó sì múra tán láti máa bá ipa ọ̀nà Kristẹni rẹ̀ nìṣó.

  • Ṣé Wàá Fẹ́ Ká Bẹ̀ Ọ́ Wò?
    Ilé Ìṣọ́—2000 | August 15
    • Ṣé Wàá Fẹ́ Ká Bẹ̀ Ọ́ Wò?

      Àní nínú ayé onídààmú yìí, ìmọ̀ pípéye láti inú Bíbélì nípa Ọlọ́run, Ìjọba rẹ̀, àti ète àgbàyanu rẹ̀ fún aráyé, lè fún ọ láyọ̀. Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i tàbí kí ẹnì kan kàn sí ọ nílé láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó bá yẹ lára èyí tí a tò sí ojú ìwé 2.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́