Èèpo ẹ̀yìn ìwé
Ìwé Mìíràn Wo
• ni ó ti nípa lórí púpọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú èyí tí ó ga lọ́lá jù lọ lára iṣẹ́ ọnà, ìwé kíkọ, àti orin ayé, tí ó sì tún nípa gíga gidigidi lórí òfin lẹ́sẹ̀ kan náà?
• ni ó ti la ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣíṣe àdàkọ láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn já síbẹ̀ tí ó ṣì tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní bí a ti ṣe kọ ọ́ tẹ́lẹ̀ ní ti gidi?
• ni ó ti súnni láti ní irú àìnímọtara ẹni nìkan bẹ́ẹ̀ tí àwọn kan fi ṣe tán láti fara gba ìnira àní àti láti fẹ̀mí wewu láti lè ṣètumọ̀ rẹ̀?
• ni a ti túmọ̀ sí ohun tí ó ju 2,100 èdè lọ, ní mímú kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára ìdílé ẹ̀dá ènìyàn?
• ni ó mẹ́nu kan àwọn òtítọ́ tí ó bá àwọn ìlànà sáyẹ́ǹsì tí a kò ṣàwárí títí di ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà mu?
• ni ó ní àwọn ìlànà tí kò mọ sí sáà kan tí ó lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti inú onírúurú ipò àtilẹ̀wá ní ti ẹ̀yà, ìran, àti orílẹ̀-èdè láti lè mú ipò ìgbé ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i?
• ni ó ní àwọn àwítẹ́lẹ̀ tí a kò fi ọ̀rọ̀ onítumọ̀ púpọ̀ sọ tí ó ṣẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn òkodoro òtítọ́ ìtàn ṣe fi hàn?
Kò ha ní yẹ kí a ṣàyẹ̀wò irú ìwé bẹ́ẹ̀ bí?