-
Gbèsè Tá A Jẹ Àwọn ÈèyànIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | July
-
-
Gbèsè Tá A Jẹ Àwọn Èèyàn
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí i pé dandan ni kóun wàásù fáwọn èèyàn. Ó mọ̀ dájú pé Jèhófà ti ṣe ohun tó lè mú kí onírúurú èèyàn rí ìgbàlà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ṣíṣeyebíye ti Ọmọkùnrin Rẹ̀ ọ̀wọ́n. (1 Tím. 2:3-6) Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Èmi jẹ́ ajigbèsè sí àwọn Gíríìkì àti àwọn Aláìgbédè, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn òpònú.” Látàrí èyí, Pọ́ọ̀lù fi ìháragàgà àti àìṣàárẹ̀ ṣiṣẹ́ kára kó lè san gbèsè tó jẹ àwọn èèyàn nípa wíwàásù ìhìn rere fún wọn.—Róòmù 1:14, 15.
2 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn Kristẹni òde òní náà ń lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti wàásù ìhìn rere fáwọn aládùúgbò wọn. Bí “ìpọ́njú ńlá” ṣe ń yára sún mọ́lé yìí, ó túbọ̀ jẹ́ kánjúkánjú fún wa láti wá àwọn olóòótọ́ èèyàn rí. Ǹjẹ́ kí ojúlówó ìfẹ́ tá a ní fáwọn èèyàn sún wa láti máa fi taratara ṣiṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí.—Mát. 24:21; Ìsík. 33:8.
3 Bá A Ó Ṣe Máa San Gbèsè Náà: Ọ̀nà pàtàkì tá à ń gbà mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ àwọn èèyàn lọ ni nípasẹ̀ ìwàásù ilé-dé-ilé. Láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn èèyàn kì í bá ti í sí nílé, ohun tá a lè ṣe tí a ó fi lè máa bá àwọn tó pọ̀ nílé ni pé ká kọ àkọsílẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́, ká sì máa padà lọ síbẹ̀ lásìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. (1 Kọ́r. 10:33) A tún lè ráwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tá a bá ń wàásù láwọn ibi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé, láwọn òpópónà, láwọn ibi ìgbafẹ́, níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí, láwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí àti nípa lílo fóònù. A wá lè bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń sa gbogbo ipá mi láti lo gbogbo ọ̀nà tó bá ṣeé ṣe láti wá àwọn èèyàn rí kí n bàa lè máa wàásù ọ̀rọ̀ ìyè fún wọn?’—Mát. 10:11.
4 Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan rí i pé ojúṣe òun ni láti mọ bóun ṣe máa wá gbogbo èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù òun rí. Ilé kan wà tí wíńdò rẹ̀ máa ń wà ní títì pa ní gbogbo ìgbà tí kì í sì í sẹ́nì kankan níbẹ̀. Àmọ́, lọ́jọ́ kan tí aṣáájú ọ̀nà yẹn ò lọ sóde ẹ̀rí, ó gba iwájú ilé tó sábà máa ń wà ní títì pa náà kọjá, ó sì rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan níwájú ilé náà. Torí pé kò fẹ́ kí àǹfààní yẹn kọjá lọ, ó yà síbẹ̀ ó sì tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé náà. Ọkùnrin kan ló dáhùn, ìfèròwérò tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ yẹn sì mú kí aṣáájú ọ̀nà yẹn àtọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọkùnrin náà léraléra. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bá a sì ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ó ti ṣèrìbọmi, ó sì ti di arákùnrin wa. Ó lóun dúpẹ́ pé arábìnrin yẹn ka iṣẹ́ ìwàásù sí gbèsè tó gbọ́dọ̀ san fáwọn èèyàn.
5 Níwọ̀n bí àkókò ò ti dúró de ẹnì kan, àsìkò tá a wà yìí gan-an la gbọ́dọ̀ san gbèsè tá a jẹ àwọn èèyàn nípa fífi gbogbo ara ṣiṣẹ́ ìwàásù náà.—2 Kọ́r. 6:1, 2.
-
-
Apá Kọkànlá: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ SíwájúIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | July
-
-
Apá Kọkànlá: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Bá A Ṣe Lè Kọ́ Akéde Tuntun Kó Lè Máa Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
1 Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó máa báwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere pàdé. Báwo la ṣe lè ran akéde tuntun náà lọ́wọ́ kó lè mọ bá a ṣe ń ṣe ìpadàbẹ̀wò lọ́nà tó múná dóko kó sì mú kí ìfẹ́ ẹni tó wàásù fún jinlẹ̀ sí i?
2 Ìgbà àkọ́kọ́ tá a bá wàásù fẹ́ni kan ló yẹ ká ti bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò. Gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó máa fi àwọn tó ń wàásù fún sọ́kàn. (Fílí. 2:4) Máa kọ́ ọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé bó ṣe lè mú kí wọ́n máa sọ èrò inú wọn jáde, bó ṣe lè máa fetí sílẹ̀ bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ àti bó ṣe lè máa fiyè sí ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Bí ẹnì kan bá fìfẹ́ hàn, sọ fún akéde tuntun náà pé kó kọ ohun tó bá ẹni náà jíròrò sílẹ̀. Àkọsílẹ̀ yẹn ni kó o lò láti fi bá a múra ìjíròrò tó máa tẹ̀lé e.
3 Kọ́ Ọ Bó Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ Kó Tó Lọ Ṣe Ìpadàbẹ̀wò: Ẹ jọ jíròrò ohun tó bá ẹni náà sọ nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n pàdé, kó o sì fi hàn án bó ṣe máa múra kókó ọ̀rọ̀ tó máa fa onílé náà mọ́ra sílẹ̀. (1 Kọ́r. 9:19-23) Ẹ jọ múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ṣókí. Kí èyí dá lórí ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú ìpínrọ̀ kan nínú ìwé kan tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Láfikún sí i, ẹ múra ìbéèrè kan tó máa fi kádìí ìjíròrò náà èyí tó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe láti lè ṣe ìpadàbẹ̀wò mìíràn. Jẹ́ kí akéde tuntun náà mọ bó ṣe lè fi kún ìmọ̀ tẹ́ni náà ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà tó bá ń bẹ̀ ẹ́ wò.
4 Ó tún dáa láti bá akẹ́kọ̀ọ́ náà múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó rọrùn, èyí tó lè lò nígbà ìpadàbẹ̀wò. Lẹ́yìn tó bá ti kí onílé, ó lè sọ pé: “Mo gbádùn ìfèròwérò wa ọjọ́sí, ìdí nìyẹn tí mo ṣe ní kí n padà wá ká lè tún sọ̀rọ̀ díẹ̀ lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa [mẹ́nu ba ẹṣin ọ̀rọ̀ kan].” O tún lè kọ́ akéde tuntun náà bó ṣe máa fèsì bó bá jẹ́ ẹlòmíì ló bá nílé dípò ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.
5 Máa Padà Lọ Láìjáfara: Gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa yíyára ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó bá fìfẹ́ hàn. Ká bàa lè máa bá àwọn èèyàn nílé, àfi ká rí i pé à ń padà lọ bẹ̀ wọ́n wò léraléra. Kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà bó ṣe lè máa bá wọn ṣàdéhùn pé òun á padà bẹ̀ wọ́n wò, kó o sì ràn án lọ́wọ́ bó ṣe lè máa mú àdéhùn náà ṣẹ. (Mát. 5:37) Kọ́ akéde tuntun yìí bó ṣe lè jẹ́ onínúure, bó ṣe lè máa gba tàwọn ẹlòmíràn rò àti bó ṣe lè máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ wíwá àwọn ẹni bí àgùntàn kiri àti lásìkò tó bá ń kọ́ wọn kí ìfẹ́ tí wọ́n ní lè máa jinlẹ̀ sí i.—Títù 3:2.
-