ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àǹfààní Ṣíṣeyebíye Ni Wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | August
    • Àǹfààní Ṣíṣeyebíye Ni Wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run

      1 Lójúmọ́, ẹgbàágbèje èèyàn ló ń jọlá ìwà ọ̀làwọ́ Jèhófà tó mú kó fi ìwàláàyè jíǹkí wa. (Mát. 5:45) Àmọ́, díẹ̀ ló mọyì àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tó wà nínú kéèyàn fi ìmoore hàn sí Ẹlẹ́dàá nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14) Báwo lo ṣe mọyì àǹfààní ṣíṣeyebíye yìí tó?

      2 Bá a bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ńṣe là ń gbé Ọlọ́run lárugẹ, a sì ń jẹ́ káwọn èèyàn tí ọkàn wọn kò balẹ̀ ní àkókò onírúkèrúdò tá à ń gbé yìí ní ìrètí àti àlàáfíà. (Héb. 13:15) Àwọn tó bá gbọ́ tí wọ́n sì yí ìgbésí ayé wọn padà máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 17:3) Èwo nínú iṣẹ́ téèyàn ń ṣe láyé yìí lèèyàn lè rí àǹfààní tó tóyẹn nínú ẹ̀? Ọ̀nà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fi hàn pé ó mọrírì rẹ̀. Ohun ìṣúra ló kà á sí.—Ìṣe 20:20, 21, 24; 2 Kọ́r. 4:1, 7.

      3 Bá A Ṣe Lè Máa Mọyì Àǹfààní Ṣíṣeyebíye Tá A Ní: Fífi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ àwọn èèyàn wà lára ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti wàásù. Ṣé a máa ń múra láti gbọ́rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà tó fi máa wọ àwọn tó ń gbọ́ wa lọ́kàn? Ǹjẹ́ àwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ jáfáfá lọ́nà tá a gbà ń fèrò wérò pẹ̀lú àwọn èèyàn àti bá a ṣe ń lo Ìwé Mímọ́? Ṣé a máa ń jẹ́rìí kúnnákúnná ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa? Ṣé a mọ bó ṣe yẹ ká bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti bó ṣe yẹ ká máa darí rẹ̀? Bíi tàwọn Kristẹni olùṣòtítọ́, nígbà láéláé àti lóde òní, a mọyì àǹfààní tá a ní yìí gan-an ni, ìyẹn la ṣe máa ń fọwọ́ tó yẹ mú un.—Mát. 25:14-23.

      4 Bá a bá wà lára àwọn òjíṣẹ́ onítara tí ọjọ́ ogbó, àìlera tàbí àwọn ìṣòro líle koko mìíràn ń dà láàmú, á tù wá nínú láti mọ̀ pé Ọlọ́run mọrírì ipá tá à ń sà láti lè máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà gidigidi. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi dá wa lójú pé Jèhófà mọyì irú ìsapá bẹ́ẹ̀ tá à ń ṣe láti sìn ín, kódà bí kò tiẹ̀ jọ àwọn míì lójú.—Lúùkù 21:1-4.

      5 Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà ní ìtẹ́lọ́rùn gan-an. Arábìnrin ẹni ọdún méjìléláàádọ́rùn-ún kan sọ pé: “Àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ fún mi láti sin Ọlọ́run nírú ọ̀nà àkànṣe bẹ́ẹ̀ fún ọgọ́rin ọdún gbáko, tí mi ò sì kábàámọ̀ níṣẹ̀ẹ́jú àáyá kan rí! Ká ní mo lè padà dọmọdé ni, bí mo ṣe gbé ìgbésí ayé mi yìí gẹ́lẹ́ ni ǹ bá gbé e. Ká sòótọ́, ‘inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run sàn ju ìyè.’” (Sm. 63:3) Ǹjẹ́ káwa náà fi hàn pé a mọyì àǹfààní ṣíṣeyebíye tó wà níkàáwọ́ wa, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.

  • Apá Kejìlá: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | August
    • Apá Kejìlá: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú

      Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Láti Bẹ̀rẹ̀ sí Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

      1 Bí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, ẹ̀rù lè máa bà wọ́n tí wọ́n bá rántí pé ó yẹ káwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Báwo la ṣe lè mú kí wọ́n ní ìgboyà tí wọ́n á fi lè máa kópa nínú apá tó ṣe pàtàkì lára iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yìí?—Mát. 24:14; 28:19, 20.

      2 Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá yẹ lẹ́ni tó lè di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, á ti ní láti máa ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ tó ti kọ́ nípa bó ṣe lè máa múra iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ àti bó ṣe lè máa ṣiṣẹ́ nílé ẹ̀kọ́ á ti jẹ́ kó mọ bó ṣe yẹ kó máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, gẹ́gẹ́ bí “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tím. 2:15.

      3 Jẹ́ Kó Rí Ẹ̀kọ Kọ́ Lára Rẹ: Bí Jésù ṣe fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni tó ṣe kedere nígbà tó ń kọ́ wọn ló jẹ́ kí wọ́n lè rí ẹ̀kọ́ tó jíire kọ́ lára rẹ̀. Ó ní: “Gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 6:40) Ó ṣe pàtàkì pé kó o máa fara wé ọ̀nà tí Jésù gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ káwọn èèyàn bàa lè máa rí ẹ̀kọ́ tó dáa kọ́ lára rẹ. Bẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ṣe ń wo bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ ọ̀hún láá máa yé e pé torí àtibẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la ṣe ń ṣe ìpadàbẹ̀wò.

      4 Ṣàlàyé fún akẹ́kọ̀ọ́ náà pé nígbà tá a bá ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnì kan, kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan pé ká ṣàlàyé lẹ́sẹẹsẹ bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó sábà máa ń dáa jù pé ká fi ìpínrọ̀ kan tàbí méjì nínú ìwé tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàpèjúwe fún un. Àwọn àbá tó wúlò nípa bá a ṣe lè ṣe é wà lójú ìwé 4 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí àti lójú ìwé 6 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002.

      5 Nígbà tó bá yẹ, ní kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ tẹ̀ lé ọ lọ síbi ìpadàbẹ̀wò tàbí kó o ní kó tẹ̀ lé akéde kan tó dáńgájíá lọ ṣe àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míì. O lè ní kóun náà sọ òye rẹ̀ lórí ìpínrọ̀ kan tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí ìpínrọ̀ náà dá lé lórí. Bí akẹ́kọ̀ọ́ yìí bá ṣe ń fọkàn sí i, á rọrùn fún un láti mọ bóun náà ṣe lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí yóò máa tẹ̀ síwájú. (Òwe 27:17; 2 Tím. 2:2) Yìn ín, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àwọn ibi tó bá yẹ kó ti ṣàtúnṣe.

      6 Bá a bá ń kọ́ àwọn akéde tuntun láti di olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, á mú kí wọ́n gbára dì pátápátá fún “iṣẹ́ rere,” bíi bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì máa darí rẹ̀ nìṣó. (2 Tím. 3:17) Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó bá a bá ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú wọn láti máa kéde pé: “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́”!—Ìṣí. 22:17.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́